以赛亚书 8 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

以赛亚书 8:1-22

预言灾难降临

1耶和华对我说:“你去拿块大的写字板,用通用的文字在上面写上‘玛黑珥·沙拉勒·哈施·罢斯8:1 玛黑珥·沙拉勒·哈施·罢斯”意思是“快速掳掠,迅速抢夺”。2我会吩咐忠信的祭司乌利亚耶比利迦的儿子撒迦利亚为这事做见证。” 3以赛亚与妻子同房,她就怀孕生了个儿子。耶和华对我说:“给他取名叫玛黑珥·沙拉勒·哈施·罢斯4因为这孩子会叫父亲母亲之前,亚述王必把大马士革的财富和撒玛利亚的战利品洗劫一空。” 5耶和华又对我说: 6“因为这些人拒绝接受我如西罗亚河缓缓流水般的温柔照顾,反倒因与利迅利玛利的儿子结盟而欢喜, 7我要差来亚述王的军队,使他们像幼发拉底河的洪流一样汹涌而来,淹没一切水道,漫过河岸, 8席卷犹大,使整个犹大几遭灭顶之灾。他必展开双翼横扫你的土地。”愿上帝与我们同在!

9列国啊,你们必被打垮、击溃!

远方的人啊,你们要听!

整装备战吧,但你们必被击垮!

整装备战吧,但你们必被击垮!

10你们设计谋吧,但休想得逞!

你们定策略吧,但休想成功!

因为上帝与我们同在。

当敬畏主

11耶和华大能的手按在我身上,警告我不可效法这些人。祂说: 12“他们认为是阴谋的,你们不要认为是阴谋。他们所怕的,你们不要怕,也不要畏惧。 13你们当尊万军之耶和华为圣,当敬畏祂,畏惧祂。 14祂必作人的圣所,也要作以色列犹大的绊脚石和使人跌倒的磐石,作耶路撒冷居民的陷阱和网罗。 15许多人必被绊倒,摔得粉身碎骨;他们必被网罗缠住、捕获。” 16我的门徒啊,你们要把上帝的训诲卷起来,用印封好。 17虽然耶和华掩面不顾雅各家,但我仍要等候祂,冀望于祂。 18看啊,我和祂所赐给我的儿女在以色列是征兆。这征兆来自住在锡安山的万军之耶和华。 19有人让你们去求问那些念念有词的巫师和术士,你们不要去。你们要去求问你们的上帝,活人的事怎能求问死人呢? 20人应该遵循耶和华的训诲和法度。人若不遵循祂的话,必看不到曙光。 21他们必困苦,饥饿,到处流浪,并在饥饿中怒气冲冲地咒骂他们的君王,亵渎上帝。 22他们抬头望天,低头看地,看到的尽是患难、痛苦和黑暗。他们必被扔进黑暗中。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 8:1-22

Isaiah àti ọmọ rẹ jẹ ààmì

1Olúwa sọ fún mi pé, mú ìwé ńlá kan, kí o sì fi kálàmù ìkọ̀wé lásán kọ Maha-Ṣalali-Haṣi-Basi: 2Èmi yóò sì mú Uriah àlùfáà àti Sekariah ọmọ Jeberekiah gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí òtítọ́ wá sí ọ̀dọ̀ mi.

3Lẹ́yìn náà, mo lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì obìnrin náà, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Olúwa sì wí fún mi pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Maha-Ṣalali-Haṣi-Basi. 4Kí ọmọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń sọ pé ‘Baba mi’ tàbí ‘Ìyá mi’ gbogbo ọrọ̀ Damasku àti ìkógun ti Samaria ni ọba àwọn Asiria yóò ti kó lọ.”

5Olúwa sì tún sọ fún mi pé:

6Nítorí pé àwọn ènìyàn yìí ti kọ

omi Ṣiloa tí ń sàn jẹ́ẹ́jẹ́ sílẹ̀

tí wọ́n sì ń yọ̀ nínú Resini

àti ọmọ Remaliah,

7Ǹjẹ́ nítorí náà kíyèsi i, Olúwa ń fa omi odò tí ó le,

tí ó sì pọ̀ wá sórí wọn,

àní, ọba Asiria àti gbogbo ògo rẹ̀,

yóò sì wá sórí gbogbo ọ̀nà odò rẹ̀,

yóò sì gun orí gbogbo bèbè rẹ̀,

8yóò sì gbá àárín Juda kọjá,

yóò sì ṣàn bò ó mọ́lẹ̀, yóò sì mú un dọ́rùn.

Nínà ìyẹ́ apá rẹ̀ yóò sì bo gbogbo ìbú ilẹ̀ rẹ̀,

ìwọ Emmanueli.

9Ké ariwo ogun, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí a sì fọ́ ọ yín túútúú,

fetísílẹ̀, ẹ̀yin ilẹ̀ jíjìn réré.

Ẹ palẹ̀mọ́ fún ogun, kí a sì fọ́ ọ túútúú!

10Ẹ gbìmọ̀ pọ̀, yóò sì di asán;

Ẹ gbèrò ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n kì yóò dúró,

nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.

Bẹ̀rù Ọlọ́run

11Olúwa bá mi sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀ o ìkìlọ̀ fún mi pé, èmi kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Ó wí pé:

128.12-13: 1Pt 3.14-15.“Má ṣe pe èyí ní ọ̀tẹ̀

gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn yìí pè ní ọ̀tẹ̀,

má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n bá bẹ̀rù,

má sì ṣe fòyà rẹ̀.

13Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ẹni tí ìwọ yóò kà sí mímọ́,

Òun ni kí o bẹ̀rù

Òun ni kí àyà rẹ̀ fò ọ́,

148.14: Ro 9.32-33; 1Pt 2.8.Òun yóò sì jẹ́ ibi mímọ́

ṣùgbọ́n fún ilé Israẹli méjèèjì ni yóò jẹ́, òkúta tí í mú ni kọsẹ̀

àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú

àti fún àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ni yóò jẹ́ tàkúté àti ìdẹ̀kùn.

15Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni yóò kọsẹ̀,

wọn yóò ṣubú wọn yóò sì fọ́ yángá,

okùn yóò mú wọn, ọwọ́ yóò sì tẹ̀ wọ́n.”

16Di májẹ̀mú náà

kí o sì fi èdìdì di òfin náà láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi.

178.17-18: Hb 2.13.Èmi yóò dúró de Olúwa,

ẹni tí ó ń fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún ilé Jakọbu.

Mo fi ìgbẹ́kẹ̀lé mi sínú rẹ.

18Èmi nìyí, àti àwọn ọmọ tí Olúwa fi fún mi. Àwa jẹ́ ààmì àti àpẹẹrẹ ní Israẹli láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ẹni tí ó ń gbé ní òkè Sioni.

19Nígbà tí àwọn ènìyàn bá sọ fún un yín pé kí ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ àti àwọn oṣó, ti máa ń kún tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ǹjẹ́ kò ha yẹ kí àwọn ènìyàn béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run wọn bí? Èéṣe tí ẹ fi ń bá òkú sọ̀rọ̀ ní orúkọ alààyè? 20Sí òfin àti májẹ̀mú! Bí wọn kò bá sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò rí ìmọ́lẹ̀ ọjọ́. 21Nínú ìnilára àti ebi, ni wọn yóò máa kọjá lọ láàrín ilẹ̀ náà, nígbà tí ebi bá pa wọ́n, nígbà yìí ni wọn yóò máa kanra, wọn yóò wòkè, wọn yóò sì fi ọba àti Ọlọ́run wọn ré. 22Nígbà náà ni wọn yóò sì wolẹ̀, wọn yóò sì rí ìpọ́njú, òkùnkùn àti ìpòrúru tí ó ba ni lẹ́rù, a ó sì sọ wọ́n sínú òkùnkùn biribiri.