以赛亚书 28 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

以赛亚书 28:1-29

北国必遭审判

1以法莲酒徒引以为荣的华冠有祸了!

它坐落在醉酒者肥美的山谷顶上,

它的荣美如将残之花。

2看啊,主已经派来一位强壮有力的人,

他像冰雹和毁灭的暴风,

又像汹涌泛滥的洪水,

他必把那华冠猛力摔在地上。

3以法莲酒徒引以为荣的华冠必被践踏。

4那肥美山谷上将残的荣美之花,

必像夏季到来之前早熟的无花果,

人一看见它就把它摘去吞掉。

5到那日,万军之耶和华必做祂余民的荣冠和华冕。

6祂必使审判官公正断案,

赐力量给守城退敌之人。

7但祭司和先知也因喝酒而摇摇晃晃,

因烈酒而东倒西歪。

他们因烈酒而摇摇晃晃、

酩酊大醉、东倒西歪,

他们错解异象,糊涂判案。

8桌子上到处都是呕吐之物,

一片狼藉。

9他们抱怨我说:

“他想教导谁知识呢?

他想把信息解释给谁呢?

是刚刚断奶、离开母怀的婴孩吗?

10因为他的教导只是命命令令、命命令令、律律例例、律律例例、这里一点、那里一点。”

11因此,耶和华必用外族人的口和语言来教训他们。

12耶和华曾对他们说:

“这是安歇之地,

让疲乏的人安歇吧。

这是安歇之地。”

他们却不肯听。

13所以,对他们来说,

耶和华的话成了命命令令、命命令令、律律例例、律律例例、这里一点、那里一点,

以致他们走路时仰面跌倒,摔伤,落网,被捉。

14你们这些好讥讽、在耶路撒冷统管百姓的人啊,

要听耶和华的话。

15你们说:

“我们已经和死亡立约,

与阴间结盟。

灾难席卷而来的时候,

我们会安然无恙,

因为我们以谎言为庇护所,

以诡诈为藏身处。”

16所以主耶和华说:

“看啊,我要在锡安放一块基石,

一块经过考验的石头,

一块根基稳固的宝贵房角石,

信靠的人必不致蒙羞。

17我必以公平为准绳,

以公义作线锤。

冰雹必砸碎你们虚谎的庇护所,

洪水必淹没你们的藏身处。

18你们和死亡所立的约必被废弃,

与阴间的结盟必不能长久。

灾难席卷而来的时候,

你们必遭毁灭。

19灾难必不分昼夜、日复一日地扫过,

每次扫过都必将你们掳去。”

明白这信息的人都必惊恐万分。

20你们的床太小,不能舒身;

你们的被子太窄,不足裹身。28:20 此处的床和被子象征他们虚假的安全感。

21耶和华必像在毗拉心山一样挺身而出,

像在基遍谷一样发怒,

要完成祂奇异的作为,

成就祂不寻常的工作。

22现在你们不要再讥讽了,

以免捆绑你们的绳索勒得更紧,

因为我已从主——万军之耶和华那里听到毁灭全国的谕旨。

23你们要侧耳听我的声音,

留心听我的话语。

24难道农夫会一直耕地而不撒种吗?

难道他会一直犁地、耙地吗?

25他耙平土地之后,

难道不种小茴香、大茴香吗?

不按行种小麦,

在合适的地方种大麦,

在田边种粗麦吗?

26因为上帝指点他,教导他耕种之道。

27打小茴香不用大槌,用棍子;

打大茴香不用石磙,用棒子。

28做饼的粮食要磨碎,

没有人会不停地在场上碾压粮食。

马拉着石磙在场上轧过,

也不会把麦子磨碎。

29这些知识都是万军之耶和华所赐的,

祂有奇妙的谋略和伟大的智慧。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 28:1-29

Ègbé ni fún Efraimu

1Ègbé ni fún adé ìgbéraga,

fún àwọn ọ̀mùtí Efraimu,

àti fún ìtànná rírọ, ẹwà ògo rẹ̀,

tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú

àti sí ìlú náà

ìgbéraga àwọn tí ọtí wáìnì ń pa tí a rẹ̀ sílẹ̀

2Kíyèsi i, Olúwa ní ẹnìkan tí ó le, tí ó sì lágbára,

gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ yìnyín àti bí ìjì apanirun,

gẹ́gẹ́ bí àrọ̀dá òjò àti òjò tí ó mú ìkún omi wá,

òun yóò fi tipátipá sọ ọ́ sílẹ̀.

3Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efraimu,

ni a ó fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

4Òdòdó tí ó ń rọ náà tí í ṣe ẹwà ògo rẹ̀,

tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú,

yóò dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó pọ́n ṣáájú ìkórè

bí ẹnikẹ́ni bá ti rí i tí ó sì mú un ní ọwọ́ rẹ̀,

òun a sì mì ín.

5Ní ọjọ́ náà Olúwa àwọn ọmọ-ogun

yóò jẹ́ adé tí ó lógo,

àti adé tí ó lẹ́wà

fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù.

6Òun yóò sì jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo

fún ẹni tí ó jókòó ní ìtẹ́ ìdájọ́

àti orísun agbára

fún àwọn ẹni tí ó ń dá ogun padà ní ẹnu ibodè.

7Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí wáìnì

wọ́n pòòrì fún ọtí líle,

Àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí líle

wọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnì

wọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí líle,

wọ́n ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran,

wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá.

8Gbogbo orí tábìlì ni ó kún fún èébì

kò sì ṣí ibìkan tí kò sí ẹ̀gbin.

9“Ta ni ẹni náà tí ó ń gbìyànjú àti kọ́?

Ta ni ó sì ń ṣàlàyé ìròyìn in rẹ̀ fún?

Sí àwọn ọmọdé tí a já lẹ́nu ọmú wọn,

sí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́nu ọmú.

10Nítorí tí í ṣe: báyìí ni orí

Ṣe, kí o si túnṣe, ṣe kí o si túnṣe,

àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ

díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn.”

1128.11-12: 1Kọ 14.21.Ó dára báyìí, pẹ̀lú ètè àjèjì àti ahọ́n àìmọ̀

Ọlọ́run yóò bá àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀

1228.12: Mt 11.29.àwọn tí ó sọ fún wí pé,

“Èyí ni ibi ìsinmi, jẹ́ kí àwọn aláàárẹ̀ sinmi”;

àti pé, “èyí ni ibi ìsinmi”

ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sílẹ̀.

13Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa sí wọn yóò di pé

Ṣe, kí o si túnṣe, ṣe kí o si túnṣe,

àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ

díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn

bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubú sẹ́yìn,

wọn yóò fi ara pa, wọn yóò bọ́ sínú okùn

a ó sì gbá wọn mú.

14Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,

tí ń jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jerusalẹmu.

15Ẹ fọ́n pé, “Àwa ti bá ikú mulẹ̀,

pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn.

Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá,

kò le kàn wá lára,

nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o wa

àti àìṣòótọ́ ibi ìpamọ́ wa.”

1628.16: Ro 9.33; 10.11; 1Pt 2.4-6.Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:

“Kíyèsi i, èmi gbé òkúta kan lélẹ̀ ní Sioni, òkúta tí a dánwò,

òkúta igun ilé iyebíye fún ìpìlẹ̀ tí ó dájú;

ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé

kì yóò ní ìfòyà.

17Èmi yóò fi ìdájọ́ ṣe okùn òṣùwọ̀n

àti òdodo òjé òṣùwọ̀n;

yìnyín yóò gbá ààbò yín dànù àti irọ́,

omi yóò sì kún bo gbogbo ibi tí

ẹ ń fi ara pamọ́ sí mọ́lẹ̀.

18Májẹ̀mú yín tí ẹ bá ikú dá ni a ó fa igi lé;

àdéhùn yín pẹ̀lú ibojì ni kì yóò dúró.

Nígbà tí ìbínú gbígbóná náà bá fẹ́ kọjá,

a ó ti ipa rẹ̀ lù yín bolẹ̀.

19Nígbàkúgbà tí ó bá ti wá ni

yóò máa gbé ọ lọ,

ni àràárọ̀, ní ọ̀sán àti ní òru,

ni yóò máa fẹ́ kọjá lọ.”

Ìmòye ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yìí

yóò máa mú ìpayà ńlá wá.

20Ibùsùn kúrú púpọ̀ fún ìnara lé lórí,

ìbora kò fẹ̀ tó láti yí ara yín ká.

21Olúwa yóò dìde sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe

ní òkè Peraṣimu

yóò ru ara rẹ̀ sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe

ní Àfonífojì Gibeoni—

láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, abàmì iṣẹ́ ẹ rẹ̀,

yóò ṣe iṣẹ́ rẹ̀, àní àjèjì iṣẹ́ rẹ̀.

22Ní ìsinsin yìí ẹ dákẹ́ ẹlẹ́yà ṣíṣe,

bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìdè e yín yóò le sí i;

Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ fún mi

nípa àṣẹ ìparun ti ó ti pa lórí gbogbo ilẹ̀ náà.

23Tẹ́tí kí o sì gbọ́ ohùn mi,

fi ara balẹ̀ kí o sì gbọ́ ohun tí mo sọ.

24Nígbà tí àgbẹ̀ kan bá tu ilẹ̀ láti gbìn

yóò ha máa tulẹ̀ títí bi?

Ǹjẹ́ yóò ha máa tu ilẹ̀ kí

ó sì máa jọ̀ ọ́ títí lọ bí?

25Nígbà tí òun bá ti tẹ́ ojú ilẹ̀ rẹ̀ pẹrẹsẹ

òun kò ha ń fúnrúgbìn dílì

kí ó sì fúnrúgbìn kummini ká?

Kí ó sì gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ,

barle tí a yàn,

àti spelti ní ipò rẹ̀?

26Ọlọ́run rẹ̀ tọ́ ọ ṣọ́nà

ó sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀nà tó tọ́.

27Nítorí a kò fi ohun èlò ìpakà dili,

bẹ́ẹ̀ ni a kì í yí kẹ̀kẹ́ ẹrù kiri lórí kummini;

ṣùgbọ́n ọ̀pá ni a fi ń pa dili jáde,

ọ̀gọ ni a sì lu kummini.

28A gbọdọ̀ lọ ìyẹ̀fun kí a tó ṣe àkàrà;

bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì í máa pa á lọ títí láé.

Bí ó tilẹ̀ yí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ìpakà a rẹ̀ lórí i rẹ̀,

àwọn ẹṣin rẹ̀ kò le lọ̀ ọ́.

29Gbogbo èyí pẹ̀lú ti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wá,

oníyanu ní ìmọ̀ràn àti ológo ní ọgbọ́n.