2 Летопись 6 – CARST & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

2 Летопись 6:1-42

1И Сулаймон сказал:

– Вечный сказал, что будет обитать в густом облаке. 2Я построил для Тебя величественный храм – место, чтобы Тебе обитать там вечно.

Обращение Сулаймона к народу

(3 Цар. 8:14-21)

3Когда всё собрание исроильтян стояло там, царь повернулся и благословил их. 4Затем он сказал:

– Хвала Вечному, Богу Исроила, Который Своей рукой исполнил то, что Своими устами обещал моему отцу Довуду! Ведь Он говорил: 5«Со дня, когда Я вывел Мой народ из Египта, Я не избирал города ни в одном из родов Исроила, чтобы там построить храм для поклонения Мне, и не избирал никого в вожди для Своего народа Исроила. 6Но сейчас Я избрал Иерусалим, чтобы пребывать там, и избрал Довуда, чтобы он правил Моим народом Исроилом».

7Мой отец Довуд думал построить храм для поклонения Вечному, Богу Исроила. 8Но Вечный сказал ему: «Ты задумал построить храм для поклонения Мне, и хорошо сделал, что задумал это. 9Но не ты построишь храм, а твой сын, твоя плоть и кровь, построит храм для поклонения Мне».

10Вечный исполнил Своё обещание. Я сейчас сижу на троне Исроила, который унаследовал от своего отца Довуда, как Вечный и обещал, и я построил храм для поклонения Вечному, Богу Исроила. 11Я поместил туда сундук, в котором находится священное соглашение, которое Вечный заключил с Исроилом.

Молитва Сулаймона при освящении храма

(3 Цар. 8:22-53)

12Сулаймон встал перед жертвенником Вечного, перед всем собранием исроильтян и поднял в молитве руки. 13(Он сделал бронзовый помост длиной в два с половиной метра, столько же в ширину и полтора метра6:13 Букв.: «пять… три локтя». в высоту и поставил его посередине внешнего двора.) Сулаймон встал на помосте, преклонил колени перед всем собранием исроильтян, воздел руки к небу 14и сказал:

– Вечный, Бог Исроила! Нет Бога, подобного Тебе, на небесах или на земле. Ты хранишь соглашение любви с Твоими рабами, которые от всего сердца следуют Твоим путям. 15Ты сдержал Своё обещание, данное Твоему рабу Довуду, моему отцу. Ты произнёс его Своими устами и сегодня Своей рукой исполнил его.

16И теперь, Вечный, Бог Исроила, исполни обещание, которое Ты дал Твоему рабу Довуду, моему отцу, сказав: «Не исчезнет у тебя преемник, сидящий предо Мной на троне Исроила, если только твои сыновья будут держаться верного пути и следовать Моему Закону, слушаясь Меня, как слушался ты». 17И теперь, Вечный, Бог Исроила, пусть исполнится слово, которое Ты дал Твоему рабу Довуду!

18Но будет ли Всевышний действительно обитать на земле с людьми? Небеса, даже небеса небес, не могут вместить Тебя. Что же говорить об этом храме, который я построил! 19Но услышь мою смиренную молитву и мольбу о милости, Вечный, мой Бог! Услышь вопль и молитву, которой молится пред Тобой Твой раб. 20Пусть днём и ночью взор Твой будет обращён на этот храм, на это место, о котором Ты сказал, что там Ты будешь пребывать. Услышь молитву, которой Твой раб станет молиться, обращая свой взор к этому месту. 21Услышь мои смиренные мольбы и мольбы Твоего народа Исраила, когда мы станем молиться, обращая свой взор к этому месту. Услышь с небес, места Твоего обитания, и, услышав, прости.

22Если человек причинит своему ближнему зло, и потребуют от него клятвы, и он придёт и даст клятву перед Твоим жертвенником в этом храме, 23то услышь с небес и воздай. Суди между Твоими рабами и воздай виновному, обрушив на его же голову то, что он сделал, и оправдай невиновного, утвердив его правоту.

24Если Твой народ Исроил потерпит поражение от врагов из-за того, что согрешил против Тебя, но обратится и исповедует Твоё имя, молясь и вознося мольбы перед Тобою в этом храме, 25то услышь с небес и прости грех Твоего народа Исроила и верни его обратно в ту землю, которую Ты дал ему и его предкам.

26Если небеса затворятся и не будет дождя из-за того, что Твой народ согрешил против Тебя, и он обратит молитву к этому месту, исповедует Твоё имя и отвернётся от своего греха, потому что Ты наказал его, 27то услышь с небес и прости грех Твоих рабов, Твоего народа Исроила. Научи их доброму пути, чтобы им ходить по нему, и пошли дождь на землю, которую Ты дал в наследие Твоему народу.

28Если землю поразят голод или мор, знойный ветер или плесень, саранча или гусеницы или если враги осадят один из городов Исроила – какая бы ни пришла беда или болезнь, – 29то какую бы молитву, какую бы мольбу ни вознёс один человек или весь Твой народ Исроил, когда все они почувствуют свою скорбь и горесть и будут простирать руки к этому храму, 30услышь с небес, места Твоего обитания. Прости и воздай каждому по его делам, потому что Ты знаешь его сердце (ведь Ты один знаешь человеческие сердца), 31чтобы они боялись Тебя и ходили Твоими путями всё время, что они будут жить на земле, которую Ты дал нашим предкам.

32Также и чужеземца, который не из Твоего народа Исроила, но который пришёл из далёкой земли ради Твоего великого имени и Твоей могучей и простёртой руки, когда он придёт и обратит свою молитву к этому храму, 33то услышь с небес, с места Твоего обитания, и сделай всё, о чём Тебя попросит чужеземец, чтобы все народы на земле узнали Твоё имя и боялись Тебя, как Твой народ Исроил, и узнали, что в этом доме, который я построил, Ты пребываешь.

34Когда Твой народ пойдёт воевать с врагами, каким бы путём Ты его ни повёл, и когда он станет молиться Тебе, обратясь к этому городу, который Ты избрал, и к храму, который я построил для поклонения Тебе, 35то услышь с небес его молитвы и мольбы и приди к нему на помощь.

36Если Твой народ согрешит против Тебя – ведь нет никого, кто бы не грешил, – и Ты разгневаешься на него и отдашь его врагам, которые уведут его пленником в свою землю, будь она далеко или близко, 37то если Твой народ переменится сердцем в земле, где будет пленником, если покается, станет молить Тебя в земле своего плена, говоря: «Мы согрешили, мы сотворили зло и поступали неправедно», 38если Твой народ обратится к Тебе от всего сердца и от всей души в земле врагов, которые пленили его, и станет молиться, обращаясь к земле, которую Ты дал его предкам, к городу, который Ты избрал, и к храму, который я построил для поклонения Тебе, – 39то услышь с небес, места Твоего обитания, его молитвы и мольбы и приди к нему на помощь. Прости тогда Твой народ, который согрешил против Тебя!

40И теперь, Бог мой, да будут глаза Твои открыты и слух Твой чуток к молитвам, которые будут возноситься на этом месте.

41И ныне, встань, о Вечный Бог, и приди на место Своего покоя, Ты и сундук могущества Твоего. Пусть Твои священнослужители, о Вечный Бог, облекутся в спасение, пусть верные Тебе возрадуются о Твоей благости. 42Не отвергни, Вечный Бог, Своего помазанника. Помни о великой любви, обещанной Довуду, Твоему рабу!

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 6:1-42

16.1-39: 1Ọb 8.12-50.Nígbà náà ni Solomoni wí pé, “Olúwa ti sọ wí pé òun yóò máa gbé nínú òkùnkùn tí ó ṣú biribiri; 2ṣùgbọ́n èmi ti kọ́ tẹmpili dáradára fún ọ ibi tí ìwọ yóò máa gbé títí láé.”

3Ní ìgbà tí gbogbo ìjọ Israẹli dúró níbẹ̀, ọba yíjú padà ó sì fi ìbùkún fún gbogbo wọn. 4Nígbà náà ni ó sì wí pé:

“Ògo ni fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ mú ohun tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dafidi baba mi ṣẹ. Nítorí tí ó wí pé, 5‘Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, èmi kò yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli, láti kọ́ ilé, kí orúkọ mi kí ó lè wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yan ẹnikẹ́ni láti jẹ́ olórí lórí Israẹli ènìyàn mi. 6Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi ti yan Jerusalẹmu, kí orúkọ mi le è wà níbẹ̀, èmi sì ti yan Dafidi láti jẹ ọba lórí Israẹli ènìyàn mi.’

7“Baba mi Dafidi ti ní-in lọ́kàn láti kọ́ tẹmpili fún orúkọ Olúwa, àní Ọlọ́run Israẹli. 8Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Dafidi baba mi pé, ‘Nítorí tí ó wà ní ọkàn rẹ láti kọ́ tẹmpili yìí fún orúkọ mi, ìwọ ṣe ohun dáradára láti ní èyí ní ọkàn rẹ̀. 9Ṣùgbọ́n síbẹ̀, ìwọ kọ́ ni yóò kọ́ tẹmpili náà, bí kò ṣe ọmọ rẹ, ẹni tí o jẹ́ ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ rẹ: òun ni yóò kọ́ tẹmpili fún orúkọ mi.’

10Olúwa sì ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Èmi ti dìde ní ipò Dafidi baba mi, a sì gbé mi ka ìtẹ́ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣe ìlérí, èmi sì ti kọ́ tẹmpili fún orúkọ Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. 11Níbẹ̀ ni èmi sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa sí, nínú èyí ti májẹ̀mú ti Olúwa bá àwọn Israẹli ènìyàn mi dá wà.”

Solomoni gba àdúrà ìyàsímímọ́

12Nígbà naà ni Solomoni dúró níwájú pẹpẹ Olúwa, ní iwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì. 13Solomoni ṣe àga idẹ kan tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gíga, a gbé e sí àárín àgbàlá ti òde. Ó sì dúró ní orí rẹ̀, àti pé ó kúnlẹ̀ lórí eékún rẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí òkè ọ̀run. 14Ó wí pé:

Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, kò sí Ọlọ́run tí ó dàbí rẹ ní ọ̀run àti ní ayé: ìwọ tí o pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi tọkàntọkàn wọn rìn ní ọ̀nà rẹ. 15Ìwọ tí o pa ìlérí tí o ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ Dafidi baba mi mọ́; nítorí ìwọ ti fi ẹnu rẹ ṣe ìlérí àti pé ìwọ ti fi ọwọ́ rẹ mú un ṣẹ; bí ó ti rí lónìí yìí.

16“Nísinsin yìí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, pa ìlérí tí ó ti ṣe mọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ Dafidi baba mi nígbà tí o wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ kù láti ní ọkùnrin láti jókòó níwájú mi lórí ìtẹ́ Israẹli, kìkì bí àwọn ọmọ rẹ tí wọ́n bá kíyèsi ara nínú gbogbo ohun tí wọ́n ṣe láti rìn níwájú mi gẹ́gẹ́ bí òfin mi gẹ́gẹ́ bí o sì ti ṣe.’ 17Nísinsin yìí, Olúwa Ọlọ́run Israẹli, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tí o ti ṣèlérí fún ìránṣẹ́ rẹ Dafidi kí ó wá sí ìmúṣẹ.

18“Ṣùgbọ́n ṣé Ọlọ́run nítòótọ́ yóò máa bá àwọn ènìyàn gbé lórí ilẹ̀ ayé bí? Ọ̀run àti ọ̀run gíga kò le gbà ọ́. Báwo ni ó ṣe kéré tó, ilé Olúwa tí mo ti kọ́! 19Síbẹ̀ ṣe àfiyèsí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún àánú, Olúwa Ọlọ́run mi, gbọ́ ẹkún àti àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ń gbà níwájú rẹ. 20Kí ojú rẹ kí ó lè ṣí sí ilé Olúwa ní ọ̀sán àti lóru, ní ibí yìí tí ìwọ ti wí pé ìwọ yóò fi orúkọ rẹ síbẹ̀. Kí ìwọ kí ó gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà lórí ibí yìí. 21Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ àti ti àwọn ènìyàn Israẹli nígbà tí wọ́n bá ń gbàdúrà lórí ibí yìí. Gbọ́ láti ọ̀run, ibùgbé rẹ, nígbà tí ìwọ bá sì gbọ́, dáríjì.

22“Nígbà tí ọkùnrin kan bá dẹ́ṣẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀, tí a sì mú búra, tí ó sì búra níwájú pẹpẹ rẹ nínú ilé yìí, 23Nígbà naà, gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dáhùn. Ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn ìránṣẹ́ rẹ, san padà fún ẹni tí ó jẹ̀bi nípa mímú padà wá sí orí òun tìkára rẹ̀ ohun tí ó ti ṣe. Ṣe ìdáláre fún olódodo, bẹ́ẹ̀ sì ni, fi fún un gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ̀.

24“Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ Israẹli bá ní ìjákulẹ̀ níwájú àwọn ọ̀tá nítorí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ àti nígbà tí wọ́n bá sì yípadà, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ nínú ilé Olúwa yìí, 25Nígbà náà, gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn Israẹli jì wọ́n kí o sì mú wọn padà wá sílé tí o ti fi fún wọn àti àwọn baba wọn.

26“Nígbà tí a bá ti ọ̀run tí kò sì sí òjò nítorí àwọn ènìyàn rẹ ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ, Nígbà tí wọ́n bá sì gbàdúrà sí ibí yìí tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí ìwọ ti pọ́n wọn lójú, 27nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Israẹli kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ nínú èyí tí wọn ó máa rìn, kí o sì rọ òjò sórí ilẹ̀ tí o ti fi fún àwọn ènìyàn rẹ fún ìní.

28“Nígbà tí ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn bá wá sí ilẹ̀ náà, ìrẹ̀dànù tàbí ìmúwòdù, eṣú tàbí ẹlẹ́ǹgà, tàbí nígbà tí àwọn ọ̀tá wọn bá yọ wọ́n lẹ́nu nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú wọn, ohunkóhun, ìpọ́njú tàbí ààrùn lè wá. 29Nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni àwọn ènìyàn rẹ Israẹli olúkúlùkù mọ̀ nípa ìpọ́njú rẹ̀ àti ìbànújẹ́, tí ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé Olúwa yìí. 30Nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run ibùgbé rẹ dáríjì, kí o sì pín fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí i gbogbo ohun tí ó ṣe, nígbà tí ìwọ ti mọ ọkàn rẹ̀ (nítorí ìwọ nìkan ni ó mọ ọkàn ènìyàn) 31Bẹ́ẹ̀ ni kí wọn kí ó lè bẹ̀rù rẹ kí wọn kí ó sì rìn ní ọ̀nà rẹ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n ń gbé nínú ilé tí o ti fi fún àwọn baba wa.

32“Ní ti àwọn àlejò tí wọn kò sí lára àwọn ènìyàn rẹ Israẹli ṣùgbọ́n tí wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn nítorí orúkọ ńlá rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ àti nínà apá rẹ, nígbà tí ó bá wá tí ó sì gbàdúrà pẹ̀lú kíkojú si ilé Olúwa yìí. 33Nígbà náà, gbọ́ láti ọ̀run àní láti ibi ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe ohun tí àwọn àlejò béèrè lọ́wọ́ rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni kí gbogbo àwọn ènìyàn ayé kí wọn lè mọ orúkọ rẹ kí wọn sì bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Israẹli ènìyàn rẹ ti ṣe, kí wọn kí ó sì lè mọ̀ wí pé ilé yìí tí èmi ti kọ, orúkọ rẹ ni ó ń jẹ́.

34“Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ bá lọ sójú ogun lórí àwọn ọ̀tá wọn, nígbàkígbà tí o bá rán wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ si ìhà ìlú yìí tí ìwọ ti yàn àti ilé Olúwa tí èmi ti kọ́ fún orúkọ rẹ. 35Nígbà náà gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì mú ọ̀rọ̀ wọn dúró.

36“Nígbà tí wọ́n bá sì dẹ́ṣẹ̀ sí ọ—nítorí kò sí ènìyàn kan tí kì í dẹ́ṣẹ̀—bí o bá sì bínú sí wọn tí o bá sì fi wọ́n fún àwọn ọ̀tá, tí wọ́n kó wọn ní ìgbèkùn sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré tàbí nítòsí, 37Ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n bá sì yí ọkàn wọn padà ní ilẹ̀ tí wọ́n ti mú wọn ní ìgbèkùn, tí wọ́n sì ronúpìwàdà tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn, wọn ó sì wí pé, ‘Àwa ti dẹ́ṣẹ̀, àwa sì ti ṣe ohun tí kò dára, a sì ti ṣe búburú’. 38Tí wọn bá sì yípadà sí ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn àti ẹ̀mí ní ilẹ̀ ìgbèkùn wọn níbi tí wọ́n ti mú wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà wọn, kojú si ìlú tí ìwọ ti yàn àti lórí ilé Olúwa tí mo ti kọ́ fún orúkọ rẹ; 39Nígbà náà, láti ọ̀run, ibi ibùgbé rẹ, gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn, kí o sì mú ọ̀ràn wọn dúró, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọn, tí wọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.

40“Nísinsin yìí, Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ojú rẹ kí ó ṣí kí o sì tẹ́ etí rẹ sílẹ̀ fún àdúrà sí ibí yìí.

416.41-42: Sm 132.8-10.“Ǹjẹ́ nísinsin yìí dìde, Olúwa Ọlọ́run mi, sí ibi ìsinmi rẹ,

ìwọ àti àpótí ẹ̀rí agbára rẹ.

Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, Olúwa Ọlọ́run mi, kí o wọ̀ wọ́n láṣọ pẹ̀lú ìgbàlà,

jẹ́ kí àwọn àyànfẹ́ kí inú wọn kí ó dùn nínú ilé rẹ.

42Olúwa Ọlọ́run mi, má ṣe kọ̀ ẹni ààmì òróró rẹ.

Rántí ìfẹ́ ńlá tí ó ṣe ìlérí fún Dafidi ìránṣẹ́ rẹ.”