Левит 19 – CARST & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

Левит 19:1-37

Различные законы

1Вечный сказал Мусо:

2– Говори с обществом Исроила и скажи им: «Будьте святы, потому что Я, Вечный, ваш Бог, свят.

3Почитайте мать и отца и храните Мои субботы. Я – Вечный, ваш Бог.

4Не обращайтесь к идолам и не отливайте себе богов из металла. Я – Вечный, ваш Бог.

5Приносите Вечному жертву примирения так, чтобы она была принята от вас. 6Её нужно съесть в тот же день, когда вы её приносите, или на следующий день. Всё, что останется до третьего дня, нужно сжечь. 7Если её будут есть на третий день – она нечиста и не будет принята. 8Тот, кто ел её, подлежит наказанию, потому что осквернил святыню Вечного. Он должен быть исторгнут из своего народа.

9Когда ты будешь жать урожай своей земли, не дожинай до края поля и не добирай остатков. 10Не обирай виноградник дочиста и не подбирай упавшие ягоды. Оставляй их бедным и чужеземцам. Я – Вечный, ваш Бог.

11Не кради.

Не обманывай.

Не лгите друг другу.

12Не клянись ложно Моим именем, не бесчести этим имени своего Бога. Я – Вечный.

13Не вымогай у ближнего и не грабь его.

Не удерживай плату наёмнику до утра.

14Не проклинай глухого и не ставь преграду перед слепым. Бойся своего Бога. Я – Вечный.

15Не извращай правосудие; не угождай бедным и не оказывай предпочтения богатым: суди честно.

16Не распространяй слухи в народе.

Не подвергай опасности жизнь своих близких. Я – Вечный.

17Не таи ненависти на брата. Упрекай своего ближнего открыто, чтобы не стать причастным к его вине.

18Не мсти и не таи злобы на соплеменника, но люби ближнего твоего, как самого себя. Я – Вечный.

19Исполняй Мои установления.

Не случай животных разных видов.

Не засаживай поля двумя видами семян.

Не носи одежды, сделанной из разнородных материй.

20Если мужчина переспит с рабыней, обещанной другому, но не выкупленной и не получившей свободу, его нужно наказать, но смерти их предавать нельзя, потому что она не была освобождена. 21Пусть виновный приведёт барана к входу в шатёр встречи для жертвы повинности Вечному. 22Принеся барана в жертву повинности, священнослужитель очистит его перед Вечным от греха, который он совершил, и он будет прощён.

23Когда вы придёте в обещанную вам страну и посадите фруктовые деревья, считайте их плоды недозволенными19:23 Букв.: «необрезанными».. В течение трёх лет считайте их недозволенными и не ешьте. 24На четвёртый год все плоды будут посвящены в жертву хвалы Вечному. 25На пятый год вы можете есть плоды. Так ваш урожай будет увеличен. Я – Вечный, ваш Бог.

26Не ешьте мясо, в котором осталась кровь. Не занимайтесь гаданием и колдовством.

27Не срезайте волос на висках и не стригите края бороды.

28Не делайте порезов на теле, когда оплакиваете умерших, и не делайте татуировок19:27-28 Эти стихи описывают языческие ритуалы скорби, которым исроильтяне не должны были следовать.. Я – Вечный.

29Не оскверняйте своих дочерей, делая из них храмовых блудниц19:29 Храмовые блудницы – имеются в виду «жрицы любви», которые были неотъемлемой частью весьма распространённых в те дни языческих культов плодородия., иначе земля наполнится развратом и растлением.

30Храните Мои субботы и чтите Моё святилище. Я – Вечный.

31Не обращайтесь к вызывателям умерших и не спрашивайте чародеев, потому что вы осквернитесь от них. Я – Вечный, ваш Бог.

32Вставайте перед старцем, выказывайте уважение к престарелым и чтите вашего Бога. Я – Вечный.

33Когда поселенец будет жить с вами на вашей земле, не притесняйте его. 34К чужеземцу, живущему с вами, следует относиться как к уроженцу страны. Любите его, как самого себя, ведь и вы были чужеземцами в Египте. Я – Вечный, ваш Бог.

35Не пользуйтесь неточными мерами, определяя длину, вес или количество. 36Пользуйтесь точными весами и верными гирями, верно взвешивайте сыпучие и жидкие продукты. Я – Вечный, ваш Бог, который вывел вас из Египта.

37Исполняйте все Мои установления и законы и соблюдайте их. Я – Вечный».

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 19:1-37

Àwọn onírúurú òfin

1Olúwa sọ fún Mose pé, 219.2: Le 11.44,45; 20.7,26; 1Pt 1.16.“Bá gbogbo àpéjọpọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ jẹ́ mímọ́ nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́.

319.3,30: Ek 20.12; De 5.16; Ek 20.8; 23.12; 34.21; 35.23; De 5.12-15.“ ‘Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìyá àti baba rẹ̀, kí ẹ sì ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

419.4: Ek 20.4; Le 26.1; De 4.15-19; 27.15.“ ‘Ẹ má ṣe yípadà tọ ère òrìṣà lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ rọ ère òrìṣà idẹ fún ara yín. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

5“ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa, kí ẹ̀yin kí ó ṣe é ní ọ̀nà tí yóò fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò yín. 6Ní ọjọ́ tí ẹ bá rú u náà ni ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ tàbí ní ọjọ́ kejì; èyí tí ó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta ni kí ẹ fi iná sun. 7Bí ẹ bá jẹ nínú èyí tí ó ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta, àìmọ́ ni èyí jẹ́, kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. 8Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù, nítorí pé ó ti ba ohun mímọ́ Olúwa jẹ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

919.9,10: Le 23.22; De 24.20,21.“ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá kórè nǹkan oko yín, kí ẹ̀yin kí ó fi díẹ̀ sílẹ̀ láìkórè ní àwọn igun oko yín, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ ṣa ẹ̀ṣẹ́ (nǹkan oko tí ẹ ti gbàgbé tàbí tí ó bọ́ sílẹ̀). 10Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kórè oko yín tan pátápátá, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣa èso tí ó rẹ̀ bọ́ sílẹ̀ nínú ọgbà àjàrà yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn aláìní àti fún àwọn àlejò. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

1119.11: Ek 20.15,16; De 5.19.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ parọ́.

“ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ tan ara yín jẹ.

1219.12: Ek 20.7; De 5.11; Mt 5.33.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi orúkọ mi búra èké: kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọ́run rẹ jẹ́. Èmi ni Olúwa.

1319.13: De 24.15; Jk 5.4.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ rẹ́ aládùúgbò rẹ jẹ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ jà á lólè.

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dá owó iṣẹ́ alágbàṣe dúró di ọjọ́ kejì.

1419.14: De 27.18.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣépè lé adití: bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ fi ohun ìdìgbòlù sí iwájú afọ́jú, ṣùgbọ́n bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ: Èmi ni Olúwa.

1519.15: Ek 23.6; De 1.17.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, má ṣe ojúsàájú sí ẹjọ́ tálákà: bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ gbé ti ọlọ́lá lẹ́yìn: ṣùgbọ́n fi òdodo ṣe ìdájọ́, àwọn aládùúgbò rẹ.

16“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ máa ṣèyíṣọ̀hún bí olóòfófó láàrín àwọn ènìyàn rẹ.

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun tí yóò fi ẹ̀mí aládùúgbò rẹ wéwu: Èmi ni Olúwa.

17“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládùúgbò rẹ wí, kí o má ba à jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀.

1819.18: Mt 5.43; 19.19; 22.39; Mk 12.31; Lk 10.27; Ro 13.9; Ga 5.14; Jk 2.8.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san: má sì ṣe bínú sí èyíkéyìí nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ṣùgbọ́n, kí ìwọ kí ó fẹ́ ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ, Èmi ni Olúwa.

1919.19: De 22.9,11.“ ‘Máa pa àṣẹ mi mọ́.

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ohun ọ̀sìn rẹ máa gùn pẹ̀lú ẹ̀yà mìíràn.

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbin dàrúdàpọ̀ oríṣìí irúgbìn méjì sínú oko kan.

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ wọ aṣọ èyí tí a fi oríṣìí ohun èlò ìhunṣọ méjì ṣe.

20“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá obìnrin tí ó jẹ́ ẹrú lòpọ̀, ẹni tí a ti mọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn tí a kò sì tí ì rà á padà tàbí sọ ọ́ di òmìnira. Ẹ gbọdọ̀ ṣe ìwádìí kí ẹ sì jẹ wọ́n ní ìyà tó tọ́ ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ pa wọ́n, torí pé kò ì tí ì di òmìnira. 21Kí ọkùnrin náà mú àgbò kan wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé bí i ẹbọ ẹ̀bi sí Olúwa. 22Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú àgbò ẹbọ ẹ̀bi náà níwájú Olúwa fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀. A ó sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ náà jì í.

23“ ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí ẹ sì gbin igi eléso, kí ẹ ká èso wọn sí ohun èèwọ̀. Fún ọdún mẹ́ta ni kí ẹ kà á sí èèwọ̀, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ 24Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹrin, gbogbo èso wọ̀nyí yóò jẹ́ mímọ́, ọrẹ fún ìyìn Olúwa. 25Ní ọdún karùn-ún ni ẹ̀yin tó lè jẹ nínú èso igi náà, kí èso wọn ba à le máa pọ̀ sí i. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

2619.26: Le 3.17; 7.26,27; 17.10-16; De 12.16,23-25; 18.10.“ ‘Ẹ má ṣe jẹ ẹrankẹ́ran pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

“ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ yẹ̀míwò tàbí oṣó.

2719.27: Le 21.5; De 14.1.“ ‘Ẹ má ṣe dá òṣù sí àárín orí yín (fífá irun ẹ̀gbẹ́ orí, tí a ó sì dá irun àárín orí sí) tàbí kí ẹ ré orí irùngbọ̀n yín bí àwọn aláìkọlà ti ń ṣe.

28“ ‘Ẹ má ṣe tìtorí òkú, gé ibi kankan nínú ẹ̀yà ara yín, Ẹ kò sì gbọdọ̀ sín gbẹ́rẹ́ kankan. Èmi ni Olúwa.

2919.29: De 23.17,18.“ ‘Ẹ má ṣe ba ọmọbìnrin yín jẹ́ láti sọ ọ́ di panṣágà, kí ilẹ̀ yín má ba à di ti àgbèrè, kí ó sì kún fún ìwà búburú.

3019.30: Ek 20.8-11; 23.12; 34.21; 35.2,3; Le 19.3; 26.2; De 5.12-15.“ ‘Ẹ gbọdọ̀ máa pa ìsinmi mi mọ́ kí ẹ sì fi ọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi, Èmi ni Olúwa.

3119.31: Le 20.6,27.“ ‘Ẹ má ṣe tọ abókùúsọ̀rọ̀ tàbí àwọn àjẹ́ lọ, ẹ kò gbọdọ̀ tọ̀ wọ́n lẹ́yìn láti jẹ́ kí wọ́n sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

32“ ‘Fi ọ̀wọ̀ fún ọjọ́ orí arúgbó kí ẹ sì bu ọlá fún àwọn àgbàlagbà. Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run yín: Èmi ni Olúwa.

3319.33: Ek 22.21.“ ‘Nígbà tí àjèjì kan bá ń gbé pẹ̀lú yín ní ilẹ̀ yín, ẹ má ṣe ṣe é ní ibi 34kí àjèjì tí ń gbé pẹ̀lú yín dàbí onílé láàrín yín kí ẹ sì fẹ́ràn rẹ̀ bí i ara yín, torí pé ẹ̀yin ti jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Ejibiti rí. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

3519.35,36: De 25.13-16; Òw 20.10; El 45.10.“ ‘Ẹ má ṣe lo òṣùwọ̀n èké, nígbà tí ẹ bá ń díwọ̀n yálà nípa òṣùwọ̀n ọ̀pá, òṣùwọ̀n ìwúwo tàbí òṣùwọ̀n onínú. 36Ẹ jẹ́ olódodo pẹ̀lú àwọn òṣùwọ̀n yín òṣùwọ̀n ìtẹ̀wọ̀n, òṣùwọ̀n wíwúwo, òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun àti òṣùwọ̀n nǹkan olómi yín ní láti jẹ́ èyí tí kò ní èrú nínú. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti.

37“ ‘Ẹ ó sì máa pa gbogbo àṣẹ àti òfin mi mọ́, ẹ ó sì máa ṣe wọ́n. Èmi ni Olúwa.’ ”