4 Царств 9 – CARSA & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

4 Царств 9:1-37

Помазание Иеву на царство в Исраиле

1Пророк Елисей призвал одного из учеников пророческих и сказал ему:

– Поторопись, возьми этот сосуд с маслом и ступай в Рамот Галаадский. 2Когда придёшь туда, разыщи там Иеву, сына Иосафата, внука Нимши. Пойди к нему и уведи его от его друзей во внутреннюю комнату. 3Возьми этот сосуд, полей масло ему на голову и произнеси: «Так говорит Вечный: „Я помазываю9:3 Посредством обряда помазания человек посвящался на определённое служение. Такого помазания удостаивались пророки, цари и священнослужители. тебя в цари Исраила“». Потом открой дверь и беги, не задерживайся!

4И молодой ученик пошёл в Рамот Галаадский. 5Когда он пришёл туда, он увидел военачальников, сидящих вместе.

– У меня есть весть для тебя, военачальник, – сказал он.

– Для кого из нас? – спросил Иеву.

– Для тебя, военачальник, – ответил он.

6Иеву встал и прошёл в дом. И пророк возлил масло на голову Иеву и произнёс:

– Так говорит Вечный, Бог Исраила: «Я помазываю тебя в цари Исраила, народа Вечного. 7Истреби дом Ахава, твоего господина, чтобы Мне отомстить за кровь Моих рабов пророков и за кровь всех рабов Вечного, пролитую Иезевелью. 8Погибнет весь дом Ахава. Я истреблю у Ахава всякого человека мужского пола – и раба, и свободного. 9Я уподоблю дом Ахава дому Иеровоама, сына Невата, и дому Бааши, сына Ахии9:9 См. 3 Цар. 14:10-11; 16:3-4.. 10А Иезевель сожрут псы на участке земли в Изрееле, и никто её не похоронит».

После этого он открыл дверь и убежал. 11Когда Иеву вышел к друзьям, один из них спросил его:

– Всё ли благополучно? Зачем к тебе приходил этот сумасшедший?

– Вы сами знаете, что это за человек и что он может сказать, – ответил Иеву.

12– Неправда! – сказали они. – Расскажи нам.

Иеву сказал:

– Он сказал мне: «Так говорит Вечный: „Я помазываю тебя в цари Исраила“».

13Они заторопились, взяли плащи и постелили их ему прямо на ступеньках. Потом они затрубили в рог и закричали:

– Воцарился Иеву!

Гибель царей Иорама и Охозии

(2 Лет. 22:7-9)

14Иеву, сын Иосафата, внук Нимши, составил заговор против Иорама. (Иорам и весь Исраил защищали Рамот Галаадский от Хазаила, царя Сирии, 15но царь Иорам вернулся в Изреель, чтобы оправиться от ран, которые сирийцы нанесли ему в битве с царём Сирии Хазаилом.) Иеву сказал:

– Если вы согласны, то не давайте никому выйти из города и рассказать новости в Изрееле.

16Он взошёл на колесницу и поехал в Изреель, потому что там отдыхал Иорам, а Охозия, царь Иудеи, пришёл его навестить. 17Когда часовой, стоявший на башне в Изрееле, увидел, как приближаются воины Иеву, он закричал:

– Я вижу воинов!

– Отправь им навстречу всадника, – приказал Иорам. – Пусть спросит: «С миром ли вы?»

18Всадник выехал навстречу Иеву и сказал:

– Царь спрашивает, с миром ли вы?

– Что тебе до мира? – ответил Иеву. – Поезжай за мной.

И часовой доложил:

– Посланец доехал до них, но назад не возвращается.

19Тогда царь послал второго всадника. Подъехав к ним, он сказал:

– Царь спрашивает, с миром ли вы?

Иеву ответил:

– Что тебе до мира? Поезжай за мной.

20И часовой доложил:

– Посланец доехал до них, но и он не возвращается назад. А человек, скачущий впереди, похож на Иеву, сына Нимши, – он скачет, как безумец.

21– Запрягай мою колесницу, – приказал Иорам.

И когда её запрягли, Иорам, царь Исраила, и Охозия, царь Иудеи, выехали в своих колесницах навстречу Иеву. Они встретили его у участка земли, который принадлежал Навоту из Изрееля.

22Увидев Иеву, Иорам спросил:

– Ты с миром, Иеву?

– Какой мир, – ответил Иеву, – пока множатся идолопоклонство и чародейство твоей матери Иезевели?

23Иорам повернул назад и обратился в бегство, крича Охозии:

– Измена, Охозия!

24Иеву натянул лук и поразил Иорама между лопатками. Стрела пронзила ему сердце, и он осел в колеснице. 25А Иеву сказал своему сановнику Бидкару:

– Подними его и брось на поле, что принадлежало Навоту из Изрееля. Помнишь, как мы с тобой ехали в колесницах за его отцом Ахавом, когда Вечный изрёк о нём такое пророчество: 26«Вчера Я видел кровь Навота и кровь его сыновей, – возвещает Вечный, – и непременно взыщу с тебя за неё на этом участке земли». Итак, подними его и брось на тот самый участок, по слову Вечного9:25-26 См. 3 Цар. 21:19, 24, 29..

27Увидев, что случилось, Охозия, царь Иудеи, бежал по дороге к Бет-Гану9:27 Или: «по дороге, которая ведёт к садовому дому».. Иеву гнался за ним, крича:

– Убейте и этого!

Люди ранили Охозию в колеснице на дороге, поднимающейся к Гуру, что близ Ивлеама, но он скрылся в городе Мегиддо, где и умер. 28Слуги отвезли его на колеснице в Иерусалим и похоронили с предками в его гробнице в Городе Давуда. 29(Охозия стал царём Иудеи на одиннадцатом году правления Иорама, сына Ахава.)

Гибель Иезевели

30А Иеву пошёл в Изреель. Когда Иезевель услышала об этом, она подвела глаза, уложила волосы и стала смотреть в окно. 31Когда Иеву вошёл в ворота, она спросила:

– Обрёл ли покой Зимри, убийца своего господина?9:31 Иезевель намекает здесь на судьбу военачальника Зимри, который убил своего царя Елу и истребил весь царский род, но сам погиб через семь дней (см. 3 Цар. 16:9-20).

32Он поднял взгляд к окну и позвал:

– Кто за меня? Кто?

Из окна выглянули два или три евнуха.

33– Сбросьте её вниз! – сказал Иеву.

Они сбросили её, и её кровь брызнула на стену и на коней, которые растоптали её.

34Иеву зашёл, поел и попил. Потом он сказал:

– Разыщите эту проклятую и похороните, она всё-таки царская дочь.

35Но когда пошли её хоронить, то не нашли ничего, кроме черепа, ног и кистей рук 36и, вернувшись, доложили Иеву, который сказал:

– Это слово Вечного, которое Он изрёк через Своего раба Ильяса из Тишбы: «На земле Изрееля псы сожрут тело Иезевели. 37Труп Иезевели будет на участке Изрееля как навоз на поле, так что никто не скажет: „Это Иезевель“»9:33-37 См. ст. 10 и 3 Цар. 21:23..

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Ọba 9:1-37

A fi ààmì òróró yàn Jehu ní ọba Israẹli

19.1–10.36: 2Ki 22.7-9.Wòlíì Eliṣa fi àṣẹ pe ọkùnrin kan láti ẹgbẹ́ àwọn wòlíì, ó sì wí fún un pé, “Ki agbádá rẹ sínú ọ̀já àmùrè rẹ, gba ṣágo kékeré òróró yìí pẹ̀lú rẹ, kí o sì lọ sí Ramoti Gileadi. 2Nígbà tí o bá dé bẹ̀, wá Jehu ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi kiri. Lọ sí ọ̀dọ̀ ọ rẹ̀, mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀, kí o sì mú un wọ inú yàrá lọ́hùn ún lọ. 3Nígbà náà, mú ṣágo kékeré yìí, kí o sì da òróró náà lé e lórí, kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi fi ààmì òróró yàn Ọ́ ní ọba lórí Israẹli.’ Nígbà náà, ṣí ìlẹ̀kùn, kí o sì sáré; Má ṣe jáfara!”

4Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wòlíì náà lọ sí Ramoti Gileadi. 5Nígbà tí ó dé, ó rí àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí wọ́n jókòó papọ̀. “Èmi ní iṣẹ́ fún ọ, olórí,” Ó wí.

“Sí ta ni nínú wa?” Jehu béèrè.

Òun sì wí pé, “Sí ọ, balógun,” Ó dáhùn.

6Jehu dìde sókè, ó sì wọ inú ilé lọ. Nígbà náà, wòlíì náà da òróró náà sórí Jehu; ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Èmi fi ààmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn Olúwa Israẹli. 7Kí ìwọ kí ó pa ilé Ahabu ọ̀gá à rẹ̀ run, Èmi yóò sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Olúwa tí a ta sílẹ̀ látọwọ́ ọ Jesebeli. 8Gbogbo ilé Ahabu yóò ṣègbé. Èmi yóò gé e kúrò láti orí Ahabu gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó gbẹ̀yìn ni Israẹli, ẹrú tàbí òmìnira. 9Èmi yóò ṣe ilé Ahabu gẹ́gẹ́ bí ilé Jeroboamu ọmọ Nebati àti ilé Baaṣa ọmọ Ahijah. 10Fún Jesebeli, ajá ni yóò jẹ ẹ́ ní oko Jesreeli, kò sì sí ẹni tí yóò sin òkú rẹ̀.’ ” Nígbà náà ó ṣí ìlẹ̀kùn, ó sì sálọ.

11Nígbà tí Jehu jáde lọ bá àwọn ọgbà ìjòyè e rẹ̀, ọ̀kan nínú wọn sì bi í pé, “Ṣé gbogbo nǹkan dára?”

Kí ni ó dé tí aṣiwèrè fi tọ̀ ọ́ wá, “Ìwọ mọ ọkùnrin náà àti irú nǹkan tí ó ń sọ,” Jehu fèsì.

12“Ìyẹn kì í ṣe òótọ́!” Wọ́n wí. “Sọ fún wa.”

Jehu wí, “Èyí ni ohun tí ó sọ fún mi: ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi fi ààmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli.’ ”

13Wọ́n ṣe gírí, wọ́n sì mú agbádá a wọn, wọ́n sì tàn wọ́n sí abẹ́ rẹ̀ ní orí àtẹ̀gùn. Nígbà náà, wọ́n fọn ìpè, wọ́n sì kígbe, “Jehu jẹ ọba!”

Jehu pa Joramu àti Ahasiah

14Bẹ́ẹ̀ ni Jehu ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi, dìtẹ̀ sí Joramu. (Nísinsin yìí Joramu àti gbogbo Israẹli ti ń dáàbò bo Ramoti Gileadi nítorí Hasaeli ọba Aramu: 15Ṣùgbọ́n ọba Joramu ti padà sí Jesreeli láti lọ sàn nínú ọgbẹ́ tí àwọn ará Aramu ti dá sí i lára nínú ogun pẹ̀lú ọba Hasaeli ti Aramu). Jehu wí pé, “Tí èyí bá jẹ́ ọ̀nà tí ò ń rò, má ṣe jẹ́ kí ẹnìkankan kí ó yọ jáde nínú ìlú ńlá láti lọ sọ ìròyìn náà ní Jesreeli.” 16Nígbà náà Jehu wọ inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì gùn ún lọ sí Jesreeli, nítorí Joramu ń sinmi níbẹ̀ àti Ahasiah ọba Juda sì sọ̀kalẹ̀ láti wá wò Joramu.

17Nígbà tí olùṣọ́ kan tí ó dúró ní ilé ìṣọ́ ní Jesreeli, rí ọ̀wọ́ ogun Jehu tí wọ́n ń súnmọ́ tòsí, ó pè jáde, “Mo rí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó ń bọ̀.”

“Mú ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kan,” Joramu pa á láṣẹ. “Rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wọn kí o sì béèrè pé, ‘Ṣé ẹ̀yin wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ”

18Ọkùnrin ẹlẹ́ṣin náà, lọ láti lọ bá Jehu ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba wí: ‘Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ”

“Kí ni ìwọ ní ṣe pẹ̀lú àlàáfíà?” Jehu sì dáhùn. “Bọ́ sí ẹ̀yìn mi.”

Olùṣọ́ náà sì wí fún un pé, “ìránṣẹ́ náà ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́.”

19Bẹ́ẹ̀ ni, ọba rán ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kejì, Nígbà náà ó wá sí ọ̀dọ̀ wọn, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba sọ:

“Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?” Jehu dáhùn, “Dúró sí ẹ̀yìn mi.”

20Olùṣọ́ náà sì fi sùn. “Ó ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́ pẹ̀lú. Wíwá rẹ̀ sì dàbí ti Jehu ọmọ Nimṣi, ó ń wa kẹ̀kẹ́ bí ti aṣiwèrè.”

21“Fi ìwọ̀ kọ́ kẹ̀kẹ́ ogun mi.” Joramu pa á láṣẹ. Àti nígbà tí a fi kọ́, Joramu ọba Israẹli àti Ahasiah ọba Juda, gun kẹ̀kẹ́ lọ, olúkúlùkù nínú kẹ̀kẹ́ ogun tirẹ̀, láti lọ bá Jehu. Wọ́n bá a pàdé ní ibi oko tí ó ti jẹ́ ti Naboti ará Jesreeli. 22Nígbà tí Joramu rí Jehu, ó béèrè pé, “Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà, Jehu?”

“Báwo ni àlàáfíà yóò ṣe wà,” Jehu dáhùn, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí gbogbo ìbọ̀rìṣà àti iṣẹ́ àjẹ́ ti màmá rẹ Jesebeli di púpọ̀?”

23Joramu yí ọwọ́ rẹ̀ padà, ó sì sálọ, ó sì ń pe Ahasiah, “ọ̀tẹ̀ dé, Ahasiah!”

24Nígbà náà, Jehu fa ọrun rẹ̀, ó sì yin Joramu láàrín èjìká méjèèjì. Ọfà náà sì wọ inú ọkàn rẹ̀, ó sì ṣubú lulẹ̀ láti orí kẹ̀kẹ́ rẹ̀. 259.25: On 21.19.Jehu sọ fún Bidikari, balógun kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ pé, “Gbé e sókè kí ó sì jù ú sí orí oko tí ó jẹ́ ti Naboti ará Jesreeli. Rántí bí èmi àti ìwọ ti ń gun kẹ̀kẹ́ papọ̀ lẹ́yìn Ahabu baba à rẹ nígbà tí Olúwa sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀: 26‘Ní àná, mo rí ẹ̀jẹ̀ Naboti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ni Olúwa wí.’ Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ gbé e sókè, kí o sì jù ú sí orí ilẹ̀ oko náà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa.”

27Nígbà tí Ahasiah ọba, Juda rí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó sálọ sójú ọ̀nà sí Beti-Haggani. Jehu sì lépa rẹ̀, ó ń kígbe, “Pa á pẹ̀lú!” Wọ́n ṣá a ní ọgbẹ́ nínú kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Guri lẹ́bàá a Ibleamu, ṣùgbọ́n ó sálọ sí Megido, ó sì kú síbẹ̀. 28Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbé e pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lọ sí Jerusalẹmu, ó sì sin ín pẹ̀lú, baba a rẹ̀ nínú ibojì rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dafidi. 29(Ní ọdún kọkànlá ti Joramu ọmọ Ahabu, Ahasiah ti di ọba Juda.)

A pa Jesebeli

30Nígbà náà Jehu lọ sí Jesreeli. Nígbà tí Jesebeli gbọ́ nípa rẹ̀, ó kun ojú u rẹ̀, ó to irun rẹ̀, ó sì wò jáde láti ojú fèrèsé. 31Bí Jehu ti wọ ẹnu ìlẹ̀kùn, ó béèrè, “Ṣé ìwọ wá ní àlàáfíà, Simri, ìwọ olùpa ọ̀gá à rẹ?”

32Ó gbójú sókè láti wo fèrèsé, ó sì pè jáde, “Ta ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ mi? Ta ni?” Ìwẹ̀fà méjì tàbí mẹ́ta bojú wò ó nílẹ̀. 33Jehu sọ wí pé, “Gbé e jù sílẹ̀!” Wọ́n sì jù ú sílẹ̀. Díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì fọ́n sí ara ògiri àti àwọn ẹṣin bí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn.

34Jehu wọ inú ilé lọ, ó jẹ, ó sì mu. “Tọ́jú obìnrin yẹn tí a fi bú,” Ó wí, “Kí o sì sin ín, nítorí ọmọbìnrin ọba ni ó jẹ́.” 35Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde lọ láti lọ sin ín, wọn kò rí nǹkan kan àyàfi agbárí i rẹ̀, ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì àti ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì. 369.36: On 21.23.Wọ́n padà lọ sọ fún Jehu, ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Elijah ará Tiṣibi wí pé: Ní orí oko Jesreeli ni àwọn ajá yóò ti jẹ ẹran-ara Jesebeli. 37Òkú Jesebeli yóò dàbí ohun ẹ̀gbin ní orí oko Jesreeli, dé bi pé, ẹnikẹ́ni kì yóò lè sọ pé, ‘Jesebeli ni èyí.’ ”