Римлянам 3 – CARSA & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

Римлянам 3:1-31

Верность Аллаха

1В чём же тогда преимущество быть иудеем, и есть ли польза в том, чтобы быть в числе обрезанных? 2Большое преимущество во всех отношениях. Прежде всего в том, что иудеям было доверено слово Аллаха.

3И если некоторые из них оказались неверны Аллаху, то разве их неверность может уничтожить верность Аллаха? 4Конечно же нет! Хотя каждый человек лжив3:4 См. Заб. 115:2., но Аллах верен, как об этом и написано:

«Ты справедлив в Своём приговоре

и победил в суде Своём»3:4 Заб. 50:6..

5Но если наша неправедность яснее показывает праведность Аллаха, то значит ли это, что Аллах несправедлив в Своём гневе на нас? (Я говорю по человеческому рассуждению.) 6Конечно нет. Иначе как бы Аллах мог судить мир? 7Но если моя ложь делает ярче истину Аллаха и, таким образом, умножает Его славу, то почему же я судим как грешник? 8Может, нам нужно начать делать зло, чтобы вышло добро? А некоторые клеветники действительно говорят, что я так учу. Эти люди заслуживают осуждения.

Нет ни одного праведного

9Так что же? В лучшем ли мы, иудеи, положении, чем другие? Нет! Я уже говорил о том, что как иудеи, так и люди из других народов – все оказались под властью греха. 10Написано:

«Нет праведного,

нет ни одного!

11Никто не понимает

и никто не ищет Аллаха.

12Все отвернулись от Аллаха,

все, как один, стали негодны,

нет делающего добро,

нет ни одного»3:10-12 Заб. 13:1-3; 52:2-4..

13«Гортань их – открытая могила,

языком своим они лгут»3:13 Заб. 5:10..

«У них на губах яд гадюки»3:13 Заб. 139:4..

14«Уста их полны проклятий и горечи»3:14 Заб. 9:28..

15«Они скоры на кровопролитие;

16где они прошли – там опустошение и горе,

17им неизвестен путь к миру»3:15-17 Мудр. 1:16; Ис. 59:7-8..

18«Они не боятся Аллаха»3:18 Заб. 35:2..

19Но мы знаем, что сказанное в Законе сказано для тех, кто находится под Законом, а значит, абсолютно никто не имеет извинения, и весь мир становится виновным перед Аллахом. 20Никто не будет оправдан перед Ним соблюдением Закона3:20 См. Заб. 142:2.. Через Закон приходит лишь осознание нашего греха.

Праведность по вере

21Но сейчас, независимо от Закона, праведность, о которой свидетельствуют Таурат и Книга Пророков, открыта Аллахом3:21 См., напр., Нач. 15:6; Ис. 28:16; Авв. 2:4.. 22Праведность от Аллаха даётся через веру всем, кто верит в Ису аль-Масиха, потому что нет различия кто ты. 23Ведь все согрешили, и все лишились славы Аллаха, 24и все получают оправдание даром, по благодати, через искупление, совершённое Исой аль-Масихом. 25Аллах сделал Его жертвой умилостивления в крови Его для всех, кто верит. Аллах пожелал проявить Свою справедливость, простив грехи, совершённые в прежние века. 26Он долго терпел, чтобы сейчас, в наше время, показать Свою праведность. Он Сам праведен и оправдывает того, кто верит в Ису.

27Итак, что же с нашей похвальбой? Её больше нет. Какой закон это сделал? Закон дел? Нет, закон веры. 28Мы утверждаем, что человек получает оправдание верой независимо от соблюдения Закона. 29Разве Всевышний является только Богом иудеев? Разве Он не Бог и других народов? Конечно же и других народов, 30потому что есть только один Бог3:30 См. Втор. 6:4., Который оправдает как обрезанных, так и необрезанных по их вере. 31Но это вовсе не значит, что мы верой устраняем Закон, наоборот, мы утверждаем его.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Romu 3:1-31

Ìṣòtítọ́ Ọlọ́run

1Ǹjẹ́ àǹfààní wo ní Júù ní? Tàbí kín ni èrè ilà kíkọ? 23.2: Sm 147.19; Ro 9.4.Púpọ̀ lọ́nà gbogbo; pàtàkì jùlọ ni pé àwọn ni a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lé lọ́wọ́.

3Ǹjẹ́ kí ha ni bí àwọn kan jẹ́ aláìgbàgbọ́? Àìgbàgbọ́ wọn yóò ha sọ òtítọ́ Ọlọ́run di asán bí? 43.4: Sm 51.4.Kí a má rí! Kí Ọlọ́run jẹ́ olóòtítọ́, àti olúkúlùkù ènìyàn jẹ́ èké; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Kí a lè dá ọ láre nínú ọ̀rọ̀ rẹ,

ṣùgbọ́n kí ìwọ lè borí nígbà tí ìwọ bá wá sí ìdájọ́.”

53.5: Ro 5.9; 6.19; 1Kọ 9.8; Ga 3.15.Ṣùgbọ́n bí àìṣòdodo wa bá fi òdodo Ọlọ́run hàn, kín ni àwa ó wí? Ọlọ́run ha jẹ́ àìṣòdodo bí? Nígbà tí ó bá ń fi ìbínú rẹ̀ hàn (Mo fi ṣe àkàwé bí ènìyàn). 6Kí a má rí i. Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, Ọlọ́run yóò ha ṣe lè dájọ́ aráyé? 7Nítorí bí òtítọ́ Ọlọ́run bá di púpọ̀ sí ìyìn rẹ̀ nítorí èké mi, èéṣe tí a fi ń dá mi lẹ́jọ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀? 83.8: Ro 6.1,15.Èéṣe tí a kò fi ṣe búburú kí rere lè jáde wá? Bí àwọn kan tí ń fi ẹnu àtẹ́ sọ wí pé a ń sọ bẹ́ẹ̀; ti àwọn kan sì ń tẹnumọ́ ọn pé a sọ; àwọn ẹni tí ìdálẹ́bi wọn tọ́.

Kò sí olóòtítọ́ kan

93.9: Ro 1.18-32; 2.1-29; 11.32; 3.23.Ǹjẹ́ kí ha ni? Àwa ha sàn ju wọn lọ bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá: nítorí a fihàn ṣáájú pé àti àwọn Júù àti àwọn Giriki, gbogbo wọn ni ó wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀; 103.10-12: Sm 14.1-3; 53.1-3.Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Kò sí ẹni tí í ṣe olódodo, kò sí ẹnìkan

11Kò sí ẹni tí òye yé,

kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run.

12Gbogbo wọn ni ó ti yapa,

wọ́n jùmọ̀ di aláìlérè;

kò sí ẹni tí ń ṣe rere,

kò tilẹ̀ sí ẹnìkan.”

133.13: Sm 5.9; 140.3.“Ibojì tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀fun wọn:

ahọ́n wọn n sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.”

“Oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ lábẹ́ ètè wọn.”

143.14: Sm 10.7.“Ẹnu ẹni tí ó kún fún èpè àti fún oró kíkorò.”

153.15-17: Isa 59.7-8.“Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀:

16ìparun àti ìpọ́njú wà lọ́nà wọn.

17Ọ̀nà àlàáfíà ni wọn kò sì mọ̀:”

183.18: Sm 36.1.“Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.”

193.19: Ro 2.12.Àwa sì mọ̀ pé ohunkóhun tí òfin bá wí, ó ń wí fún àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin: kí gbogbo ẹnu bá à lè dákẹ́ àti kí a lè mú gbogbo aráyé wá sábẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. 203.20: Sm 143.2; Ap 13.39; Ga 2.16; 3.11; Ro 7.7.Nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin, a kì yóò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú rẹ̀: nítorí nípa òfin ni ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ti wá.

Ìṣòdodo nípa ìgbàgbọ́

213.21: Ro 1.17; Fp 3.9; 2Pt 1.1.Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, a ti fi òdodo Ọlọ́run hàn láìsí òfin, tí a ti ń jẹ́rìí sí nípa òfin àti nípa àwọn wòlíì; 223.22: Ro 4.5; 9.30; 10.12; Ga 2.16.Àní òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, sí gbogbo ènìyàn àti gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́: nítorí tí kò sí ìyàtọ̀ láàrín Júù àti Helleni. 233.23: Ro 3.9.Gbogbo ènìyàn ni ó ṣá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run: 243.24: Ro 4.16; 5.9; Ef 2.8; Tt 3.7; Ef 1.7; Kl 1.14; Hb 9.15.Àwọn ẹni tí a ń dá láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kristi Jesu: 25Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run: 263.26: 1Jh 2.2; Kl 1.20.Láti fi òdodo rẹ̀ hàn ní ìgbà ìsinsin yìí: kí ó lè jẹ́ olódodo àti olùdáláre ẹni tí ó gba Jesu gbọ́.

27Ọ̀nà ìṣògo dà? A ti mú un kúrò. Nípa òfin wo? Nípa iṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ kọ́: Ṣùgbọ́n nípa òfin ìgbàgbọ́. 283.28: Ap 13.39; Ro 5.1; Ef 2.9.Nítorí náà a parí rẹ̀ sí pé nípa ìgbàgbọ́ ni a ń dá ènìyàn láre láìsí iṣẹ́ òfin. 293.29: Ro 9.24; Ap 10.34-35.Ọlọ́run àwọn Júù nìkan ha ni bí? Kì í ha ṣe ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Bẹ́ẹ̀ ni, ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú: 303.30: Ro 4.11-12,16.Bí ó ti jẹ́ pé Ọlọ́run kan ni, yóò dá àwọn akọlà láre nípa Ìgbàgbọ́ àti àwọn aláìkọlà nípa ìgbàgbọ́ wọn. 313.31: Ro 8.4; Mt 5.17.Àwa ha ń sọ òfin dasán nípa ìgbàgbọ́ bí? Kí a má rí i: ṣùgbọ́n a ń fi òfin múlẹ̀.