Исход 23 – CARSA & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

Исход 23:1-33

Законы о справедливости и милосердии

1– Не разносите лживых слухов. Не помогайте виновному лжесвидетельством.

2Не следуйте за большинством, творя зло или извращая на суде правду, 3и не потворствуйте бедному в его тяжбе.

4Если увидите, что вол или осёл вашего врага заблудились, то непременно верните их ему. 5Если увидите, что осёл того, кто ненавидит вас, упал под ношей, не оставляйте его так – непременно помогите ему.

6Не лишайте бедняков правосудия. 7Не обвиняйте ложно; не казните невиновного и честного: Я не прощу такого злодеяния.

8Не берите взяток: они ослепляют зрячих и губят невиновных.

9Не угнетайте поселенцев. Вы знаете, каково им, потому что сами были поселенцами в Египте.

Субботний год и субботний день

10– Шесть лет засевайте поля и собирайте урожай, 11а на седьмой год пусть земля отдыхает под паром. Тогда бедняки из народа смогут кормиться от неё, а звери – доедать после них остатки. Так же поступайте с виноградниками и масличными рощами.

12Шесть дней трудитесь, но в седьмой день не работайте, чтобы ваши вол и осёл отдохнули, а раб, рождённый у вас в доме, и поселенец набрались сил.

13Будьте внимательны ко всему, что Я вам сказал. Не призывайте других богов. Пусть ваши уста даже не произносят их имён.

Три ежегодных праздника

14– Три раза в год устраивайте Мне праздник.

15Справляйте праздник Пресных хлебов. Семь дней ешьте хлеб, приготовленный без закваски, как Я повелел вам. Делайте так в установленное время месяца авива (ранней весной), потому что в это время вы вышли из Египта.

Пусть никто не приходит поклоняться Мне с пустыми руками.

16Справляйте праздник Жатвы, когда собираете первые плоды посеянного вами в поле.

Справляйте и праздник Сбора плодов23:16 Позже этот праздник стали называть праздником Шалашей (см. Лев. 23:39-43). в конце года (осенью), когда убираете с поля весь урожай.

17Три раза в год все мужчины должны приходить поклоняться Владыке Вечному.

18Не приносите Мне жертвенной крови вместе с чем-либо, приготовленным на закваске.

Жир от праздничных приношений нельзя хранить до утра.

19Лучшее из первых плодов земли приносите в дом Вечного, вашего Бога.

Не варите козлёнка в молоке его матери.

Ангел, посланный приготовить путь

20– Я посылаю перед вами Ангела, чтобы защищать вас в пути и привести на место, которое Я для вас приготовил. 21Будьте внимательны к Нему и слушайтесь Его. Не восставайте против Него; Он не простит вам отступничества, потому что в Нём Моё имя. 22Если вы будете слушаться Его, если будете исполнять всё, что Я говорю, Я буду врагом вашим врагам и противником вашим противникам. 23Мой Ангел пойдёт перед вами и приведёт вас в землю аморреев, хеттов, перизеев, хананеев, хивеев и иевусеев, и Я погублю их. 24Не поклоняйтесь их богам, не служите им и не подражайте их обычаям. Сокрушите их и разбейте на куски их священные камни. 25Служите Вечному, вашему Богу, и Его благословение будет на вашей пище и воде. Я избавлю вас от болезней, 26и в вашей земле не будет выкидышей и бесплодия. Я сделаю полным число дней вашей жизни.

27Я повергну в смятение любой народ, против которого вы пойдёте, и наведу на него страх. Я обращу в бегство ваших врагов. 28Я пошлю перед вами шершней23:28 Или: «страх». на хивеев, хананеев и хеттов, чтобы прогнать их с вашей дороги. 29Но Я не прогоню их в один год – ведь тогда земля опустеет, а диких зверей станет слишком много. 30Я буду прогонять их от вас постепенно, пока вас не станет достаточно, чтобы завладеть этой землёй.

31Я проведу ваши границы от Тростникового моря до Средиземного и от Сирийской пустыни до Евфрата23:31 Букв.: «от Тростникового моря до Филистимского моря и от пустыни до реки».. Я отдам вам во власть жителей этой земли, и вы прогоните их от себя. 32Не вступайте в союз ни с ними, ни с их богами. 33Не давайте им жить на вашей земле, иначе они введут вас в грех против Меня – служение их богам непременно станет для вас западнёй.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 23:1-33

Òfin òdodo àti àánú

123.1: Ek 20.16; 23.7; De 5.20; 19.15-21.“Ìwọ kò gbọdọ̀ tan ìròyìn èké kalẹ̀: Ìwọ kò gbọdọ̀ ran ènìyàn búburú lọ́wọ́ láti jẹ́rìí èké.

2“Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀pọ̀ ènìyàn láti ṣe aburú. Nígbà tí ìwọ bá jẹ́rìí sí ẹjọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po nípa gbígbé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ènìyàn. 323.3,6: Le 19.15.Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúsàájú sí tálákà nínú ẹjọ́ rẹ̀.

4“Bí ìwọ bá ṣe alábàápàdé akọ màlúù tàbí akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ọ̀tá rẹ tí ó ṣìnà lọ, rí i dájú pé o mú un padà wá fún un. 5Bí ìwọ bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹnìkan tí ó kórìíra rẹ tí ẹrù ṣubú lé lórí, má ṣe fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀; rí i dájú pé o ran án lọ́wọ́ nípa rẹ.

6“Ìwọ kò gbọdọ̀ du aláìní ní ìdájọ́ òdodo. 723.7: Ek 20.16; 23.1.Má ṣe lọ́wọ́ nínú ẹ̀sùn èké, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ pa aláìṣẹ̀ tàbí olódodo ènìyàn, nítorí Èmi kò ní dá ẹlẹ́bi láre.

823.8: De 16.19.“Ìwọ kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń fọ́ ojú ọlọ́gbọ́n, ó sì ń ba ọ̀rọ̀ olódodo jẹ́.

923.9: Ek 22.21; Le 19.33,34; De 27.19.“Ìwọ kò gbọdọ̀ pọ́n àjèjì kan lójú, ẹ̀yin sa ti mọ inú àjèjì, nítorí ẹ̀yin náà ti jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Ejibiti.

Òfin Ọjọ́ Ìsinmi

1023.10,11: Le 25.1-7.“Ní ọdún mẹ́fà ni ìwọ yóò gbin oko rẹ, ìwọ yóò sì kóre èso rẹ̀. 11Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, jẹ́ kí ilẹ̀ náà wà ní àìkọ àti ní àìlò, jẹ́ kí ilẹ̀ náà kí ó sinmi. Nígbà náà ni tálákà láàrín yín yóò rí oúnjẹ láti ibẹ̀. Ẹranko igbó yóò sì jẹ èyí tí wọ́n fi sílẹ̀. Ìwọ ṣe bákan náà pẹ̀lú ọgbà àjàrà rẹ àti ọgbà olifi rẹ.

1223.12: Ek 20.8-11; 31.15-17; 34.21; 35.2; De 5.12-15.“Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣe iṣẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì sinmi ní ọjọ́ keje, kí akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ bá à lè ní ìsinmi, kí a sì tú ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti àlejò ti ń gbé ni ilé rẹ lára.

13“Ẹ máa ṣọ́ra, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo wí fún un yín. Ẹ má ṣe pe orúkọ òrìṣà, kí a má ṣe gbọ́ orúkọ wọn ní ẹnu yín.

Àjọ̀dún Mẹ́ta Nínú Ọdún

1423.14-17: Ek 34.22-24; Le 23.1-44; De 16.1-17.“Ní ìgbà mẹ́ta ni ìwọ yóò ṣe àjọ fún mi nínú ọdún.

15“Ṣe àjọ àkàrà àìwú; jẹ àkàrà ti kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje, bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ. Ṣe èyí ní àkókò tí a ti yàn ní oṣù Abibu, nítorí ni oṣù yìí ni ìwọ jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.

“Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá sí iwájú mi ní ọwọ́ òfo.

16“Ṣe àjọ ìkórè pẹ̀lú èso àkọ́so ọ̀gbìn oko rẹ.

“Ṣe àjọ àkójọ oko rẹ ní òpin ọdún, nígbà tí ìwọ bá kó ìre oko rẹ jọ tan.

17“Ní ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn ọkùnrin yín yóò máa wá fi ara hàn ní iwájú Olúwa Olódùmarè.

1823.18: Ek 12.10; 34.25; Le 2.11; 7.15.“Ìwọ kò gbọdọ̀ rú ẹbọ ẹ̀jẹ̀ sí mi ti òun ti àkàrà tó ní ìwúkàrà.

“Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rá ẹbọ àjọ mi ni kò gbọdọ̀ kù títí di òwúrọ̀.

1923.19: Ek 22.29; 34.26; De 26.2-11; 14.21.“Mú àkọ́ká èso ilẹ̀ rẹ tí ó dára jùlọ wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ.

“Ìwọ kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ewúrẹ́ nínú omi ọmú ìyá rẹ̀.

Angẹli Olúwa ni yóò pèsè ọ̀nà sílẹ̀

20“Kíyèsi èmi rán angẹli kan lọ ní iwájú rẹ, láti ṣọ́ ọ ni ọ̀nà àti láti mú ọ dé ibi ti mo ti pèsè sílẹ̀ fún. 21Fi ara balẹ̀, kí o sì fetísílẹ̀ sí i, kí o sì gba ohùn rẹ̀ gbọ́; má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí i, nítorí kò ní fi àìṣedéédéé yín jì yín, orúkọ mi wà lára rẹ̀. 22Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí ohùn rẹ̀ tí ẹ sì ṣe ohun gbogbo ti mo ní kí ẹ ṣe, èmi yóò jẹ́ ọ̀tá àwọn ọ̀tá yín. Èmi yóò sì fóòro àwọn tí ń fóòro yín. 23Angẹli mi yóò lọ níwájú rẹ, yóò sì mú ọ dé ọ̀dọ̀ àwọn ará: Amori, Hiti, Peresi, Kenaani, Hifi àti Jebusi, èmi a sì gé wọn kúrò. 24Ìwọ kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún òrìṣà wọn, bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n, tàbí kí ẹ tẹ̀lé ìṣe wọn. Kí ìwọ kí ó si wó wọn lulẹ̀, kí ìwọ kí ó sì fọ́ ère òkúta wọ́n túútúú. 25Ẹ̀yin yóò sí máa sin Olúwa Ọlọ́run yin, òun yóò si bùsi oúnjẹ rẹ. Èmi yóò mú àìsàn kúrò láàrín rẹ. 26Oyún kò ní bàjẹ́ lára obìnrin kan, bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan kì yóò yàgàn ni ilẹ̀ rẹ. Èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.

27“Èmi yóò rán ẹ̀rù mi lọ ṣáájú rẹ, ìdàrúdàpọ̀ yóò sì wà láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ bá da ojú kọ. Èmi yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ yí ẹ̀yìn padà sí ọ, kí wọn sì sá ní iwájú rẹ. 28Èmi yóò rán oyin ṣáájú rẹ láti lé àwọn ará: Hifi, Kenaani àti Hiti kúrò ni ọ̀nà rẹ. 29Ṣùgbọ́n, Èmi kò ni lé gbogbo wọn jáde ni ọdún kan ṣoṣo, ki ilẹ̀ náà má ba à di ahoro, àwọn ẹranko búburú yóò sì ti pọ̀jù fún ọ. 30Díẹ̀díẹ̀ ni èmi yóò máa lé wọn jáde kúrò ní iwájú rẹ, títí ìwọ yóò fi pọ̀ tó láti gba gbogbo ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ìní.

31“Èmi yóò fi ìdí òpin ààlà ilẹ̀ rẹ lélẹ̀ láti etí Òkun pupa títí dé Òkun àwọn ara Filistini, láti aṣálẹ̀ títí dé etí odò Eufurate: Èmi yóò fa àwọn ènìyàn ti ń gbé ilẹ̀ náà lé ọ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì lé wọn jáde kúrò ní iwájú rẹ. 32Ìwọ kò gbọdọ̀ dá májẹ̀mú kankan pẹ̀lú wọn tàbí pẹ̀lú àwọn òrìṣà wọn. 33Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí wọn gbé ni ilẹ̀ rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóò mú ọ dẹ́ṣẹ̀ sí mi: nítorí bí ìwọ bá sin òrìṣà wọn, èyí yóò jẹ́ ìdẹ̀kùn fun ọ nítòótọ́.”