4 Царств 15 – CARS & YCB

Священное Писание

4 Царств 15:1-38

Уззия – царь Иудеи

(2 Лет. 26:3-4, 21-23)

1На двадцать седьмом году правления Иеровоама, царя Исраила, в Иудее начал царствовать Уззия, сын Амасии. 2Ему было шестнадцать лет, когда он стал царём, и правил он в Иерусалиме пятьдесят два года. Его мать звали Иехолия, она была родом из Иерусалима. 3Он делал то, что было правильным в глазах Вечного, как и его отец Амасия. 4Лишь святилища на возвышенностях не были ещё уничтожены. Народ продолжал приносить там жертвы и возжигать благовония.

5Вечный поразил царя проказой15:5 См. сноску на 5:1., которая была у него до самой его смерти, и он жил в отдельном доме. Иотам, сын царя, распоряжался во дворце и управлял народом страны.

6Прочие события царствования Уззии и всё, что он сделал, записано в «Книге летописей царей Иудеи». 7Уззия упокоился со своими предками и был похоронен рядом с ними в Городе Давуда. И царём вместо него стал его сын Иотам.

Закария – царь Исраила

8На тридцать восьмом году правления Уззии, царя Иудеи, царём Исраила стал Закария, сын Иеровоама, и правил в Самарии шесть месяцев. 9Он делал зло в глазах Вечного, подобно своим предкам. Он не отвернулся от грехов Иеровоама, сына Невата, к которым тот склонил Исраил.

10Шаллум, сын Иавеша, составил заговор против Закарии. Он поразил его на виду у всего народа15:10 Или: «в Иблеаме»., убил и стал царём вместо него. 11Прочие события царствования Закарии записаны в «Книге летописей царей Исраила». 12Так исполнилось слово Вечного, которое Он сказал Иеву: «Твои потомки будут сидеть на престоле Исраила до четвёртого поколения»15:12 См. 10:30..

Шаллум – царь Исраила

13Шаллум, сын Иавеша, стал царём на тридцать девятом году правления Уззии, царя Иудеи, и правил в Самарии один месяц. 14Из Тирцы в Самарию пришёл Менахем, сын Гади. Он поразил Шаллума, сына Иавеша, в Самарии, убил его и стал царём вместо него.

15Прочие события царствования Шаллума и заговор, который он составил, записаны в «Книге летописей царей Исраила».

16В то время Менахем, выступив из Тирцы, напал на Тифсах со всеми, кто был в городе и в его окрестностях, потому что они отказались открыть ворота. Он разграбил Тифсах и порубил всех беременных женщин.

Менахем – царь Исраила

17На тридцать девятом году правления Уззии, царя Иудеи, царём Исраила стал Менахем, сын Гади, и правил в Самарии десять лет. 18Он делал зло в глазах Вечного. Во все дни царствования он не отворачивался от грехов Иеровоама, сына Невата, к которым тот склонил Исраил.

19В то время в страну вторгся Тиглатпаласар15:19 Букв.: «Пул» – другое имя Тиглатпаласара III (см. ст. 29). Он правил с 745 по 727 гг. до н. э., царь Ассирии, и Менахем дал ему тридцать шесть тонн15:19 Букв.: «тысячу талантов». серебра, чтобы тот помог ему укрепить власть над царством. 20Менахем взыскал эти деньги с Исраила. Каждый богатый человек был обязан внести шестьсот граммов15:20 Букв.: «пятьдесят шекелей». серебра, чтобы отдать их царю Ассирии. Тогда царь Ассирии вернулся назад и не остался в стране.

21Прочие события царствования Менахема и всё, что он сделал, записано в «Книге летописей царей Исраила». 22Менахем упокоился со своими предками. И царём вместо него стал его сын Пекахия.

Пекахия – царь Исраила

23На пятидесятом году правления Уззии, царя Иудеи, царём Исраила стал Пекахия, сын Менахема, и правил в Самарии два года. 24Пекахия делал зло в глазах Вечного. Он не отвернулся от грехов Иеровоама, сына Невата, к которым тот склонил Исраил.

25Его сановник Пеках, сын Ремалии, составил против него заговор. Взяв с собой пятьдесят галаадитян, он напал на Пекахию в крепости царского дворца в Самарии. Пеках убил Пекахию, вместе с Арговом и Арием, и стал царём вместо него. 26Прочие события царствования Пекахии и всё, что он сделал, записано в «Книге летописей царей Исраила».

Пеках – царь Исраила

27На пятьдесят втором году правления Уззии, царя Иудеи, царём Исраила стал Пеках, сын Ремалии, и правил в Самарии двадцать лет. 28Он делал зло в глазах Вечного. Он не отвернулся от грехов Иеровоама, сына Невата, к которым тот склонил Исраил.

29В дни Пекаха, царя Исраила, царь Ассирии Тиглатпаласар пришёл и взял города Ион, Авель-Бет-Мааху, Ианох, Кедеш и Хацор, земли Галаада, Галилеи и всю землю Неффалима и увёл народ в плен в Ассирию. 30Осия, сын Элы, составил против Пекаха, сына Ремалии, заговор. Он напал на него, убил и стал царём вместо него на двадцатом году правления Иотама, сына Уззии.

31Прочие события царствования Пекаха и всё, что он сделал, записано в «Книге летописей царей Исраила».

Иотам – царь Иудеи

(2 Лет. 27:1-9)

32На втором году правления исраильского царя Пекаха, сына Ремалии, в Иудее начал царствовать Иотам, сын Уззии. 33Ему было двадцать пять лет, когда он стал царём, и правил он в Иерусалиме шестнадцать лет. Его мать звали Иеруша, она была дочерью Цадока. 34Он делал то, что было правильным в глазах Вечного, как и его отец Уззия. 35Лишь святилища на возвышенностях не были уничтожены, народ продолжал приносить там жертвы и возжигать благовония. Иотам перестроил Верхние ворота храма Вечного.

36Прочие события царствования Иотама и то, что он сделал, записано в «Книге летописей царей Иудеи». 37(В те дни Вечный начал посылать против Иудеи Рецина, царя Сирии, и Пекаха, сына Ремалии.) 38Иотам упокоился со своими предками и был похоронен с ними в Городе Давуда, своего предка. И царём вместо него стал его сын Ахаз.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Ọba 15:1-38

Asariah ọba Juda

1Ní ọdún kẹtà-dínlọ́gbọ̀n tí Jeroboamu ọba Israẹli, Asariah ọmọ Amasiah ọba Juda sì bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba. 215.2,3: 2Ki 26.3,4.Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìn-dínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjìléláàdọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jekoliah; ó wá láti Jerusalẹmu. 3Ó ṣe ohun tí ó dára lójú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Amasiah ti ṣe. 4Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò ṣí wọn kúrò; Àwọn ènìyàn náà tẹ̀síwájú láti máa rú ẹbọ àti sun tùràrí níbẹ̀.

515.5-7: 2Ki 26.20-23.Olúwa sì kọlu ọba náà pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀, títí di ọjọ́ tí ó kú, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀tọ̀. Jotamu, ọmọ ọba sì tọ́jú ààfin, ó sì ń darí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.

6Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Asariah, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda. 7Asariah sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀. A sì sin ín sí ẹ̀bá wọn ní ìlú ńlá ti Dafidi. Jotamu ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Sekariah ọba Israẹli

8Ní ọdún kejì-dínlógójì Asariah ọba Juda. Sekariah ọmọ Jeroboamu di ọba Israẹli ní Samaria, ó sì jẹ ọba fún oṣù mẹ́fà. 9Ó ṣe búburú lójú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba rẹ̀ tí ṣe. Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá.

10Ṣallumu ọmọ Jabesi dìtẹ̀ sí Sekariah. Ó dojúkọ ọ́ níwájú àwọn ènìyàn, ó sì pa á, ó sì jẹ ọba dípò rẹ̀. 11Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Sekariah. Wọ́n kọ ọ́ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli. 12Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ fún Jehu jẹ́ ìmúṣẹ: “Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Israẹli títí dé ìran kẹrin.”

Ṣallumu ọba Israẹli

13Ṣallumu ọmọ Jabesi di ọba ní ọdún kọkàn-dínlógójì Ussiah ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní Samaria fún oṣù kan. 14Nígbà náà Menahemu ọmọ Gadi lọ láti Tirsa sí Samaria. Ó dojúkọ Ṣallumu ọmọ Jabesi ní Samaria, ó pa á ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

15Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Ṣallumu, àti ìdìtẹ̀ tí ó dì, a kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli.

16Ní ìgbà tí Menahemu ń jáde bọ̀ láti Tirsa, ó dojúkọ Tifisa àti gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ìlú ńlá àti agbègbè rẹ̀, Nítorí wọn kọ̀ láti sí ẹnu ibodè. Ó yọ Tifisa kúrò lẹ́nu iṣẹ́, ó sì la inú gbogbo àwọn obìnrin aboyún.

Menahemu ọba Israẹli

17Ní ọdún kọkàn-dínlógójì ti Asariah ọba Juda, Menahemu ọmọ Gadi di ọba Israẹli, ó sì jẹ ọba ní Samaria fún ọdún mẹ́wàá. 18Ó ṣe búburú lójú Olúwa, ní gbogbo ìjọba rẹ̀. Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá.

19Nígbà náà, Pulu ọba Asiria, gbógun ti ilẹ̀ náà, Menahemu sì fún un ní ẹgbẹ̀rin tálẹ́ǹtì fàdákà láti fi gba àtìlẹ́yìn rẹ̀ àti láti fún ìdúró tirẹ̀ lágbára lórí ìjọba. 20Menahemu fi agbára gba owó náà lọ́wọ́ Israẹli. Gbogbo ọkùnrin ọlọ́lá ní láti dá àádọ́ta ṣékélì fàdákà láti fún ọba Asiria. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Asiria padà sẹ́yìn, kò sì dúró ní ilẹ̀ náà mọ́.

21Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Menahemu, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé ọba Israẹli? 22Menahemu sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Pekahiah ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Pekahiah ọba Israẹli

23Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún Asariah ọba Juda, Pekahiah ọmọ Menahemu di ọba Israẹli ní Samaria, ó sì jẹ ọba fún ọdún méjì. 24Pekahiah ṣe búburú lójú Olúwa. Kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó fa Israẹli láti dá. 25Ọ̀kan lára àwọn olórí ìjòyè rẹ̀ Peka ọmọ Remaliah, dìtẹ̀ sí i. Ó mú àádọ́ta àwọn ọkùnrin ti àwọn ará Gileadi pẹ̀lú u rẹ̀. Ó pa Pekahiah pẹ̀lú Argobu àti Arie ní odi ààfin ọba ní Samaria. Bẹ́ẹ̀ ni Peka pa Pekahiah, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

26Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Pekahiah, gbogbo ohun tí ó ṣe, ni a kọ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli.

Peka ọba Israẹli

27Ní ọdún kejìléláàdọ́ta Asariah ọba Juda, Peka ọmọ Remaliah di ọba Israẹli ní Samaria. Ó sì jẹ ọba fún ogún ọdún. 28Ó sì ṣe búburú lójú Olúwa, kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó fa Israẹli láti dá.

29Ní ìgbà Peka ọba Israẹli, Tiglat-Pileseri ọba Asiria wá, ó sì mú Ijoni, Abeli-Beti-Maaka, Janoa, Kedeṣi àti Hasori. Ó gba Gileadi àti Galili pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Naftali. Ó sì kó àwọn ènìyàn ní ìgbèkùn lọ sí Asiria. 30Nígbà náà, Hosea ọmọ Ela, dìtẹ̀ sí Peka ọmọ Remaliah. Ó dojúkọ ọ́, ó sì pa á, ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba ní ogún ọdún Jotamu ọmọ Ussiah.

31Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Peka, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli?

Jotamu ọba Juda

32Ní ọdún keje Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli, Jotamu ọmọ Ussiah ọba Juda bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba. 3315.33-35: 2Ki 27.1-3.Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìn-dínlógún. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jeruṣa ọmọbìnrin Sadoku. 34Ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ Ussiah ti ṣe. 35Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò ṣí wọn kúrò; Àwọn ènìyàn tẹ̀síwájú láti rú ẹbọ àti láti sun tùràrí níbẹ̀: Jotamu tún ìlẹ̀kùn gíga tó ń kọ́ ní ti ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.

36Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jotamu, àti ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda? 37(Ní ayé ìgbàanì, Olúwa bẹ̀rẹ̀ sí ní rán Resini ọba Siria àti Peka ọmọ Remaliah láti dojúkọ Juda). 3815.38: 2Ki 27.9.Jotamu sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú ńlá Dafidi, ìlú ńlá ti baba rẹ̀. Ahasi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.