Левит 14 – CARS & YCB

Священное Писание

Левит 14:1-56

Очищение от заразных кожных болезней

1Вечный сказал Мусе:

2– Вот правила о больном во время его очищения. Когда его приведут к священнослужителю, 3пусть священнослужитель выйдет за лагерь и осмотрит его. Если больной исцелился от заразной кожной болезни, 4то пусть священнослужитель велит взять для очищаемого двух живых чистых птиц и кедрового дерева, алой пряжи и иссопа14:4 Иссоп – по всей вероятности, это не собственно иссоп, а один из видов майорана, распространённый в Исраиле. Кедровое дерево, алая шерсть и иссоп были символами очищения от греха в иудейской культуре.. 5Пусть священнослужитель велит убить одну из птиц над глиняным горшком со свежей водой. 6Пусть он возьмёт живую птицу и погрузит её вместе с кедровым деревом, алой пряжей и иссопом в кровь птицы, убитой над свежей водой. 7Пусть он семь раз окропит очищаемого от заразной болезни, объявит его чистым и выпустит живую птицу в открытое поле.

8Пусть очищаемый выстирает одежду, сбреет все волосы, вымоется – и будет чист. Теперь он может войти в лагерь, но должен семь дней жить вне шатра. 9На седьмой день пусть он сбреет все волосы: голову, бороду, брови и остальные волосы. Пусть он выстирает одежду и вымоется – и будет чист.

10На восьмой день он должен принести двух ягнят-самцов и одну годовалую самку – всех без изъяна – с двадцатью четырьмя чашками14:10 Букв.: «три десятых ефы». лучшей муки, смешанной с маслом, для хлебного приношения и одну треть литра14:10 Букв.: «один лог». Также в ст. 12, 15, 21, 24. масла. 11Пусть священнослужитель, совершающий очищение, поставит очищаемого с его приношениями перед Вечным у входа в шатёр встречи.

12Пусть священнослужитель возьмёт одного из ягнят и принесёт его в жертву повинности вместе с одной третью литра масла. Он потрясёт их перед Вечным как приношение потрясания. 13Пусть он заколет ягнёнка в святом месте, где закалывают жертву за грех и жертву всесожжения. Подобно жертве за грех, жертва повинности принадлежит священнослужителю – это великая святыня. 14Пусть священнослужитель возьмёт кровь жертвы повинности и помажет ею мочку правого уха очищаемого, большой палец его правой руки и большой палец правой ноги. 15Пусть священнослужитель возьмёт одну треть литра масла, нальёт в ладонь левой руки, 16погрузит правый указательный палец в масло на ладони и с пальца окропит маслом перед Вечным семь раз. 17Маслом, оставшимся в ладони, священнослужитель помажет мочку правого уха очищаемого, большой палец его правой руки и большой палец правой ноги поверх крови жертвы повинности. 18Оставшееся в ладони масло священнослужитель выльет на голову очищаемого и очистит его перед Вечным.

19Пусть священнослужитель принесёт жертву за грех и очистит очищаемого от нечистоты. После этого священнослужитель заколет жертву всесожжения, 20принесёт её на жертвеннике вместе с хлебным приношением, очистит его, и он будет чист.

21Но если он беден, и такое приношение ему не по средствам, то пусть он возьмёт одного ягнёнка в жертву повинности для потрясания, чтобы очистить себя, и полтора килограмма14:21 Букв.: «одну десятую ефы». лучшей муки, смешанной с маслом, для хлебного приношения, одну треть литра масла 22и двух горлиц или двух молодых голубей, какие будут ему по средствам: одного – в жертву за грех, а другого – для всесожжения.

23На восьмой день пусть он принесёт их, чтобы очиститься, к священнослужителю, к входу в шатёр встречи, перед Вечным. 24Пусть священнослужитель возьмёт ягнёнка жертвы повинности вместе с одной третью литра масла и потрясёт их перед Вечным как приношение потрясания. 25Пусть он заколет ягнёнка жертвы повинности, возьмёт его кровь и помажет ею мочку правого уха очищаемого, большой палец его правой руки и большой палец правой ноги. 26Пусть священнослужитель нальёт масло в ладонь левой руки 27и указательным пальцем правой руки окропит маслом из ладони перед Вечным семь раз. 28Пусть он помажет маслом из ладони те же места, которые он помазал кровью жертвы повинности: мочку правого уха очищаемого, большой палец его правой руки и большой палец правой ноги. 29Остальное масло из ладони пусть священнослужитель выльет на голову очищаемого, чтобы очистить его перед Вечным. 30Пусть он принесёт в жертву горлиц или молодых голубей, какие жертвующему по средствам: 31одного – в жертву за грех, а другого – во всесожжение вместе с хлебным приношением. Так священнослужитель очистит очищаемого перед Вечным.

32Вот правила для любого, кто болел заразной кожной болезнью и кому не по средствам принести для своего очищения обычные приношения.

О плесени в домах

33Вечный сказал Мусе и Харуну:

34– Когда вы войдёте в землю Ханаана, которую Я отдаю вам во владение, и Я наведу растущую плесень на какой-нибудь дом в той земле, 35то пусть хозяин дома пойдёт и скажет священнослужителю: «В моём доме я видел что-то похожее на плесень». 36Пусть священнослужитель велит вынести всё из дома, прежде чем войдёт осмотреть плесень, иначе всё в доме будет объявлено нечистым. После этого пусть священнослужитель войдёт и осмотрит дом. 37Пусть он осмотрит плесень на стенах: если на них будут зеленоватые или красноватые пятна, на вид углубляющиеся в поверхность стены, 38то пусть священнослужитель выйдет наружу и запрёт его на семь дней. 39На седьмой день священнослужитель вернётся снова обследовать дом. Если плесень распространилась по стенам, 40то пусть он велит выворотить заражённые камни и бросить их на нечистое место за пределами города. 41Изнутри пусть стены дома выскоблят, а отскоблённую обмазку высыпят на нечистое место за пределами города. 42Пусть старые камни заменят новыми и обмажут дом новой обмазкой.

43Если после того, как камни были выворочены, а дом выскоблили и обмазали, плесень появится в доме снова, 44священнослужитель должен пойти и осмотреть его. Если плесень распространилась по дому – это растущая плесень; дом нечист. 45Пусть дом разрушат, а его камни, строительное дерево и всю обмазку вынесут из города на нечистое место.

46Любой, кто войдёт в дом, когда он заперт, будет нечист до вечера. 47Любой, кто будет в этом доме спать или есть, должен выстирать одежду.

48Но если священнослужитель, который придёт осмотреть его, увидит, что плесень не распространилась после того, как дом был обмазан, то он объявит дом чистым, так как плесень сошла. 49Чтобы очистить дом, пусть он возьмёт двух птиц и кедровое дерево, алую пряжу и иссоп. 50Пусть он заколет одну из птиц над свежей водой в глиняном горшке. 51Пусть он возьмёт кедровое дерево, иссоп, алую пряжу и живую птицу, погрузит их в кровь убитой птицы и в свежую воду и окропит дом семь раз. 52Так он очистит дом кровью птицы, свежей водой, живой птицей, кедровым деревом, иссопом и алой пряжей. 53Пусть он выпустит живую птицу в открытое поле за пределами города. Так он очистит дом, и дом станет чист.

54Таковы правила о любой заразной кожной болезни: о лишае, 55о плесени на одежде и на доме, об опухоли, сыпи и воспалении, 56чтобы определить чистоту чего-либо.

Таковы правила о заразных кожных болезнях и плесени.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 14:1-57

Ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ààrùn ẹ̀tẹ̀ tó mú awọ ara

1Olúwa sọ fún Mose pé, 214.2-32: Mt 8.4; Mk 1.44; Lk 5.14; 17.14.“Èyí ni àwọn ìlànà fún ẹni tí ààrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú ní àkókò ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, bí a bá mú un tọ àlùfáà wá. 3Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò ní ẹ̀yìn ibùdó bí ara rẹ̀ bá ti yá kúrò nínú ààrùn ẹ̀tẹ̀ náà. 4Kí àlùfáà pàṣẹ pé kí a mú ààyè ẹyẹ mímọ́ méjì, igi kedari, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù wá fún ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́. 5Kí àlùfáà pàṣẹ pé kí wọn pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sórí omi tí ó mọ́ tó wà nínú ìkòkò amọ̀. 6Lẹ́yìn náà kí ó ri ààyè ẹyẹ pẹ̀lú igi kedari, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí a ti pa sínú omi náà. 7Ìgbà méje ni kí o wọ́n omi yìí sí ara ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́ kúrò nínú ààrùn ara náà kí ó ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ ní ìta gbangba.

8“Ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, fá gbogbo irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, lẹ́yìn èyí ó ti di mímọ́. Lẹ́yìn náà ó le wá sínú ibùdó ṣùgbọ́n kí ó wà lẹ́yìn àgọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ méje. 9Kí ó fá gbogbo irun rẹ̀ ní ọjọ́ keje: irun orí rẹ̀, irùngbọ̀n rẹ̀, irun ìpéǹpéjú rẹ̀, àti gbogbo irun rẹ̀ tókù. Kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì mọ́.

10“Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àgbò aláìlábùkù méjì àti abo ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan tí wọn kò ní àlébù wá, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun tí à pòpọ̀ mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ àti òṣùwọ̀n lógù òróró kan. 11Àlùfáà tí ó pè é ní mímọ́: yóò mú ẹni náà tí a ó sọ di mímọ́ àti ọrẹ rẹ̀ wá síwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.

12“Kí àlùfáà mú ọ̀kan nínú àwọn àgbò àti lógù òróró kí ó sì fi rú ẹbọ ẹ̀bi. Kí ó sì fì wọ́n níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì. 13Kí ó pa àgbò náà ní ibi mímọ́ níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ sísun. Bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ẹ̀bi náà jẹ́ ti àlùfáà: ó jẹ́ mímọ́ jùlọ. 14Kí àlùfáà mú nínú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi náà kí ó fi sí etí ọ̀tún ẹni náà tí a ó wẹ̀mọ́, kí ó tún fi sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti orí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀. 15Àlùfáà yóò sì mú díẹ̀ nínú lógù òróró, yóò sì dà á sí àtẹ́lẹwọ́ òsì ara rẹ̀. 16Yóò sì ti ìka ìfábẹ̀lá ọ̀tún rẹ̀ bọ inú òróró àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, yóò sì wọ́n díẹ̀ nínú rẹ̀ níwájú Olúwa nígbà méje. 17Àlùfáà yóò mú lára òróró tí ó kù ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ yóò fi sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí à ó wẹ̀mọ́, lórí ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi. 18Àlùfáà yóò fi òróró tí ó kù ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ ra orí ẹni tí a ó wẹ̀mọ́, yóò sì ṣe ètùtù fún un níwájú Olúwa.

19“Àlùfáà yóò sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀: yóò ṣe ètùtù fún ẹni tí a ó wẹ̀ kúrò nínú àìmọ́ rẹ̀, lẹ́yìn náà àlùfáà yóò pa ẹran ọrẹ ẹbọ sísun. 20Kí àlùfáà kí ó sì rú ẹbọ sísun, àti ẹbọ ohun jíjẹ lórí pẹpẹ, kí àlùfáà kí ó sì ṣe ètùtù fún un: Òun yóò sì di mímọ́.

21“Bí ẹni náà bá jẹ́ tálákà tí kò sì le è kó gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, kí ó mú ọ̀dọ́ àgbò kan bí ẹbọ ẹ̀bi, tí yóò fì, láti ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára, a pò mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ òṣùwọ̀n lógù òróró 22àti àdàbà méjì tàbí ẹyẹlé méjì èyí tí agbára rẹ̀ ká, ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun.

23“Kí ó mú wọn wá ní ọjọ́ kẹjọ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ síwájú àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Olúwa. 24Àlùfáà náà yóò sì mú ọ̀dọ́-àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi pẹ̀lú lógù òróró yóò sì fì wọ́n níwájú Olúwa bí ẹbọ fífì. 25Kí ó pa ọ̀dọ́-àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi kí ó sì mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Kí ó fi sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún. 26Àlùfáà yóò sì da díẹ̀ lára òróró náà sí àtẹ́lẹwọ́ òsì ara rẹ̀. 27Yóò sì fi ìka ìfábẹ̀lá ọ̀tún rẹ̀ wọ́n òróró tí ó wà ní àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀ nígbà méje níwájú Olúwa. 28Àlùfáà yóò sì mú lára òróró ọwọ́ rẹ̀ sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ní ibi kan náà tí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi sí. 29Kí àlùfáà fi ìyókù nínú òróró ọwọ́ rẹ̀ sí orí ẹni náà tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún: láti ṣe ètùtù fún un ní iwájú Olúwa. 30Lẹ́yìn náà kí ó fi àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé rú ẹbọ níwọ̀n tí agbára rẹ̀ mọ. 31Ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ: Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù níwájú Olúwa ní ipò ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́.”

32Òfin nìyí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ààrùn ara tí ó le ran tí kò sì lágbára láti rú ẹbọ tí ó yẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ bí a ti fi lélẹ̀.

Ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ ní inú ilé

33Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé. 34“Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí mo fi fún yín ní ìní, tí mo sì fi ààrùn ẹ̀tẹ̀ sínú ilé kan ní ilẹ̀ ìní yín. 35Kí ẹni tí ó ní ilé náà lọ sọ fún àlùfáà pé, ‘Èmi tí rí ohun tí ó jọ ààrùn ẹ̀tẹ̀ ní ilé mi.’ 36Àlùfáà yóò pàṣẹ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun má ṣe wà nínú ilé náà, kí ó tó lọ yẹ ẹ̀tẹ̀ náà wò, kí ohunkóhun nínú ilé náà má bá à di àìmọ́. Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wọlé lọ láti yẹ ilé náà wò. 37Yóò yẹ ààrùn náà wò, bí ààrùn náà bá ti wà lára ògiri ilé náà nípa ààmì àwọ̀ ewé tàbí ààmì pupa tí ó sì jinlẹ̀, ju ara ògiri lọ. 38Àlùfáà yóò jáde kúrò nínú ilé náà, yóò sì ti ìlẹ̀kùn ilé náà pa fún ọjọ́ méje. 39Àlùfáà yóò padà wá yẹ ilé náà wò ní ọjọ́ keje. Bí ààrùn náà bá ti tàn ká ara ògiri. 40Àlùfáà yóò pàṣẹ kí a yọ àwọn òkúta tí ààrùn náà ti bàjẹ́ kúrò kí a sì kó wọn dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú. 41Yóò sì mú kí wọ́n ha ògiri inú ilé náà yíká. Gbogbo ohun tí wọ́n fi rẹ́ ilé náà tí ó ti ha ni kí wọ́n kó dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú náà. 42Òkúta mìíràn ni kí wọ́n fi dípò àwọn tí a ti yọ dànù, kí wọ́n sì rẹ́ ilé náà pẹ̀lú àwọn ohun ìrẹ́lé tuntun.

43“Bí ààrùn yìí bá tún farahàn lẹ́yìn tí a ti yọ àwọn òkúta wọ̀nyí tí a sì ti ha ilé náà ti a sì tún rẹ́ ẹ. 44Àlùfáà yóò tún lọ yẹ̀ ẹ́ wò bí ààrùn náà bá tún gbilẹ̀ sí i nínú ilé náà: ẹ̀tẹ̀ apanirun ni èyí, ilé náà jẹ́ aláìmọ́. 45Wíwó ni kí a wó o, gbogbo òkúta ilé náà, àwọn igi àti gbogbo ohun tí a fi rẹ́ ẹ ni kí a kó jáde nínú ìlú sí ibi tí a kà sí àìmọ́.

46“Ẹni tí ó bá wọ inú ilé náà lẹ́yìn tí a ti tì í, yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. 47Ẹni tí ó bá sùn nínú ilé náà tàbí tí ó bá jẹun nínú rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀.

48“Bí àlùfáà bá wá yẹ̀ ẹ́ wò tí ààrùn náà kò gbilẹ̀ mọ́ lẹ́yìn tí a ti rẹ́ ilé náà: kí àlùfáà pe ilé náà ní mímọ́, torí pé ààrùn náà ti lọ. 49Láti sọ ilé yìí di mímọ́. Àlùfáà yóò mú ẹyẹ méjì àti igi kedari òdòdó àti hísópù. 50Yóò sì pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sórí omi tí ó mọ́ nínú ìkòkò amọ̀. 51Kí ó ri igi kedari, hísópù, òdòdó àti ààyè ẹyẹ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ òkú ẹyẹ àti omi tí ó mọ́ náà kí ó fi wọ́n ilẹ̀ náà lẹ́ẹ̀méje. 52Yóò fi ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ náà, omi tí ó mọ́, ààyè ẹyẹ, igi kedari, hísópù àti òdòdó sọ ilé náà di mímọ́. 53Kí àlùfáà ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ lẹ́yìn ìlú. Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún ilé náà. Ilé náà yóò sì mọ́.”

54Àwọn wọ̀nyí ni ìlànà fún èyíkéyìí ààrùn àwọ̀ ara tí ó le è ràn ká (ẹ̀tẹ̀), fún làpálàpá, 55àti fún ẹ̀tẹ̀ nínú aṣọ, àti ti ilé, 56fún ìwú, fún èélá àti ibi ara dídán. 57Láti mú kí a mọ̀ bóyá nǹkan mọ́ tàbí kò mọ́.

Ìwọ̀nyí ni àwọn òfin fún ààrùn àwọ̀ ara tí ó ń ràn ká àti ẹ̀tẹ̀.