Исход 15 – CARS & YCB

Священное Писание

Исход 15:1-27

Песнь Мусы и Марьям

1Тогда Муса с исраильтянами воспели Вечному эту песню:

«Вечному буду петь –

Он высоко вознесён.

Коня и всадника

бросил Он в море.

2Вечный – моя сила и песнь;

Он стал мне спасением.

Он – мой Бог, я восславлю Его;

Он – Бог отца моего: я Его превознесу.

3Вечный – это воин;

Вечный – имя Ему.

4Колесницы и войско фараона

бросил Он в море.

Лучшие воины египтян

утоплены в Тростниковом море.

5Пучина сомкнулась над ними,

и они канули в бездну, как камень.

6Правая рука Твоя, Вечный,

мощью прославилась.

Правая рука Твоя, Вечный,

сокрушила врага.

7Величием Своей славы

Ты поверг восставших против Тебя.

Возгорелся Твой гнев –

он их, как солому, пожрал.

8Дохнул Ты на воды –

вздыбились они,

встали как стена;

сгустилась пучина морская.

9Хвастался враг:

„Погонюсь, настигну их.

Разделю добычу,

натешусь ею.

Вытащу меч –

истребит их моя рука“.

10Но дохнул Ты Своим вихрем,

и накрыло их море.

Утонули они, как свинец,

в могучих водах.

11Кто из богов подобен Тебе, о Вечный?

Кто подобен Тебе,

величественному в святости,

достойному славы,

творящему чудеса?

12Простёр Ты правую руку,

и поглотила врагов земля.

13Своей нетленной любовью

поведёшь Ты народ, который спас.

Своей силой Ты его направишь

к Своему святому жилищу.

14Народы услышат и затрепещут;

ужас охватит филистимских жителей.

15Устрашатся вожди Эдома,

правители Моава затрепещут,

скроются жители Ханаана –

16страх и ужас падут на них.

Силой Твоей руки

они станут как камень –

пока не пройдёт Твой народ, о Вечный,

пока не пройдёт народ, который Ты приобрёл15:16 Или: «сотворил»..

17Ты приведёшь и поселишь их

на горе Своего достояния –

на том месте, Вечный, которое Ты сделал Себе жилищем,

в том святилище, Владыка, которое Твои руки основали.

18Вечный будет царствовать вовеки!»

19Когда лошади, колесницы и всадники фараона вошли в море, Вечный обрушил на них морские воды. А исраильтяне прошли через море, как по суше. 20Пророчица Марьям, сестра Харуна, взяла бубен, и женщины с бубнами, танцуя, пошли за ней. 21Марьям им пела:

«Вечному пойте –

Он высоко вознесён.

Коня и наездника

бросил Он в море».

Воды Мары и Елима

22Муса повёл исраильтян от Тростникового моря, и они вошли в пустыню Сур. Три дня они шли по пустыне, не находя воды. 23Придя в Мару, они не могли пить воду: она была горькой. (Вот почему это место называется Мара («горечь»).) 24Народ стал роптать на Мусу, говоря: «Что нам пить?»

25Муса взмолился к Вечному, и Вечный показал ему кусок дерева. Муса бросил его в воду, и вода стала пригодной для питья.

Там Вечный дал им установленный закон, чтобы испытать их. 26Он сказал:

– Если вы будете внимательно слушать Мой голос, голос Вечного, вашего Бога, и делать то, что Я хочу, если будете послушны Моим повелениям и сохраните Мои установления, то Я не нашлю на вас ни одного из тех недугов, которые наслал на египтян. Ведь Я – Вечный, Который исцеляет вас.

27Они пришли в Елим, где было двенадцать источников воды и семьдесят пальм. Там они расположились лагерем у воды.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 15:1-27

Orin Mose àti Miriamu

115.1: If 15.3.Nígbà náà ni Mose àti àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí Olúwa:

Èmi yóò kọrin sí Olúwa,

nítorí òun pọ̀ ní ògo.

Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún

ni ó ti sọ sínú Òkun.

215.2: Sm 118.14; Isa 12.2.Olúwa ni agbára àti orin mi;

òun ti di Olùgbàlà mi,

òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín,

Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga.

3Ológun ni Olúwa,

Olúwa ni orúkọ rẹ,

4Kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti ogun rẹ̀

ni ó mú wọ inú Òkun.

Àwọn ọmọ-ogun Farao tó jáfáfá jùlọ

ni ó rì sínú Òkun pupa.

5Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀;

wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi Òkun bí òkúta.

6“Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa,

pọ̀ ní agbára.

Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa,

fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú.

7“Nínú agbára ńlá rẹ ti ó tóbi

ìwọ bi àwọn ti ó dìde sí ọ ṣubú.

Ìwọ rán ìbínú gbígbóná rẹ;

Tí ó run wọ́n bí àgémọ́lẹ̀ ìdí koríko

8Pẹ̀lú èémí imú rẹ ni

omi fi ń wọ́jọ pọ̀.

Ìṣàn omi dìde dúró bí odi;

ibú omi sì dìpọ̀ láàrín Òkun.

9Ọ̀tá ń gbéraga, ó ń wí pé:

‘Èmi ó lépa wọn, èmi ó bá wọn.

Èmi ó pín ìkógun;

Èmi ó tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mi lọ́run lára wọn.

Èmi yóò fa idà mi yọ,

ọwọ́ mi yóò pa wọ́n run.’

10Ìwọ fẹ́ èémí rẹ,

òkun ru bò wọ́n mọ́lẹ̀.

Wọ́n rì bí òjé

ni àárín omi ńlá.

11Ta ni nínú àwọn òrìṣà

tó dàbí rẹ, Olúwa?

Ta ló dàbí rẹ:

ní títóbi,

ní mímọ́ Ẹlẹ́rù ni yìn,

tí ń ṣe ohun ìyanu?

12“Ìwọ na apá ọ̀tún rẹ,

Ilẹ̀ si gbé wọn mì.

13Nínú ìfẹ́ rẹ ti kì í sákí Ìwọ ṣe amọ̀nà

àwọn ènìyàn náà tí Ìwọ ti rà padà.

Nínú agbára rẹ Ìwọ yóò tọ́ wọn,

lọ sí ibi ìjókòó rẹ mímọ́.

14Orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ wọn yóò wárìrì

Ìkáàánú yóò mi àwọn ènìyàn Filistia.

15Ìbẹ̀rù yóò mú àwọn ìjòyè Edomu,

Àwọn olórí Moabu yóò wárìrì

Àwọn ènìyàn Kenaani yóò sì yọ́ dànù;

16Ìbẹ̀rù bojo yóò ṣubú lù wọ́n nítorí

nína títóbi apá rẹ̀

wọn yóò dúró jẹ́ẹ́ láì mira bí i òkúta

Títí àwọn ènìyàn rẹ yóò fi rékọjá, Olúwa,

Títí tí àwọn ènìyàn tí o ti rà yóò fi rékọjá.

17Ìwọ yóò mú wọn wá láti gbìn wọ́n

ni orí òkè ti ìwọ jogún;

Ní ibi ti ìwọ ṣe fún ara rẹ, Olúwa.

Láti máa gbé ibi mímọ́ ti ìwọ fi ọwọ́ rẹ gbé kalẹ̀, Olúwa.

18Olúwa yóò jẹ ọba

láé àti láéláé.”

19Nígbà ti ẹṣin Farao, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ wọ inú Òkun, Olúwa mú kí omi Òkun padà bò wọ́n mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli rìn lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ la Òkun kọjá. 20Miriamu wòlíì obìnrin, arábìnrin Aaroni, mú ohun èlò orin ni ọwọ́ rẹ̀, gbogbo àwọn obìnrin sì jáde tẹ̀lé e pẹ̀lú ìlù òun ijó. 21Miriamu kọrin sí wọn báyìí pé:

“Ẹ kọrin sí Olúwa

Nítorí òun ni ológo jùlọ

Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún

Ni òun bi ṣubú sínú Òkun.”

Omi Mara àti Elimu

22Nígbà náà ni Mose ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn Israẹli jáde láti Òkun pupa lọ sínú ijù Ṣuri. Wọ́n lọ ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú ijù náà, wọn kò sì rí omi. 23Nígbà tí wọ́n dé Mara, wọn kò lè mu omi Mara nítorí omi náà korò (Nítorí náà ni a ṣe pe ibẹ̀ ni Mara: ibi ìkorò). 24Àwọn ènìyàn ń kùn sí Mose wí pé, “Kí ni àwa yóò mu?”

25Mose sì ké pe Olúwa, Olúwa sì fi igi kan hàn án, ó sì sọ igi náà sínú omi, omi náà sì dùn.

Níbẹ̀ ni Olúwa ti gbé ìlànà àti òfin kalẹ̀ fún wọn, níbẹ̀ ni ó sì ti dán wọn wò. 26Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí òfin Olúwa Ọlọ́run, ti ìwọ sì ṣe ohun tí ó tọ́ ni ojú rẹ̀, ti ìwọ sì tẹ̀lé ohun tí ó pàṣẹ, ti ìwọ si pa ìlànà rẹ̀ mọ́. Èmi kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí nínú àwọn ààrùn wọ̀n-ọn-nì ti mo mú wá sórí àwọn ará Ejibiti wá sí ara rẹ, nítorí èmi ni Olúwa ti ó mú ọ láradá.”

27Nígbà ti wọ́n dé Elimu, níbi ti kànga omi méjìlá (12) àti àádọ́rin (70) ọ̀pẹ gbé wà, wọ́n pàgọ́ síbẹ̀ ni etí omi.