Исход 13 – CARS & YCB

Священное Писание

Исход 13:1-22

Посвящение первенцев

1Вечный сказал Мусе:

2– Посвяти Мне каждого первенца мужского пола. Каждый первенец, рождённый исраильтянкой, и весь первородный приплод скота принадлежат Мне.

Праздник Пресных хлебов

3Муса сказал народу:

– Помните день, когда вы вышли из Египта, из земли рабства, потому что Вечный вывел вас оттуда могучей рукой. В этот день не ешьте дрожжевой хлеб. 4Вы уходите сегодня в месяце авиве (ранней весной). 5Вечный клялся вашим предкам, что отдаст вам землю хананеев, хеттов, аморреев, хивеев и иевусеев, землю, где течёт молоко и мёд. Когда Он приведёт вас туда, соблюдайте в этом месяце такой обычай: 6семь дней ешьте хлеб, приготовленный без закваски, а на седьмой день устраивайте праздник Вечному. 7Семь дней ешьте пресный хлеб. У вас не должно быть ничего приготовленного на закваске; в ваших землях не должно быть никакой закваски во время этого праздника. 8В тот день пусть каждый скажет своему сыну: «Я поступаю так в память о том, что Вечный сделал для меня, когда я вышел из Египта». 9Этот обычай будет вам как напоминание, как знак на руке, как памятка на лбу о том, что Закон Вечного должен быть у вас на устах. Ведь Вечный вывел вас из Египта могучей рукой. 10Соблюдайте этот обычай в назначенное время из года в год.

Правила о первенцах

11– После того как Вечный введёт вас в землю хананеев и отдаст её вам, как Он клялся вам и вашим предкам, 12посвящайте Вечному всех первенцев. Все первенцы вашего скота мужского пола принадлежат Вечному. 13За первородного ослика принесите выкуп – ягнёнка, а если не выкупите, то сверните ослику шею. За всех своих первенцев отдавайте выкуп.

14В будущем, когда сын спросит у тебя: «Что это значит?» – скажи ему: «Вечный могучей рукой вывел нас из Египта, из земли рабства. 15Когда сердцем фараона завладело упрямство, и он не хотел отпускать нас, Вечный погубил в Египте всех первенцев мужского пола: и людей, и животных. Вот почему я приношу в жертву Вечному всех первенцев мужского пола у скота, а за своих первенцев отдаю выкуп». 16Этот обычай будет как напоминание, как знак на руке, как свидетельство13:16 Или: «повязка». на лбу, что Вечный могучей рукой вывел нас из Египта.

Всевышний сопровождает Свой народ

17Когда фараон отпустил народ, Всевышний не повёл их через землю филистимлян, хотя так было ближе. Всевышний сказал:

– Столкнувшись с филистимлянами в войне, они могут передумать и вернуться в Египет.

18Всевышний повёл народ в обход, пустынной дорогой к Тростниковому морю. Исраильтяне ушли из Египта вооружённые для битвы. 19Муса взял с собой останки Юсуфа, потому что Юсуф в своё время взял с сыновей Исраила клятву, сказав:

– Всевышний непременно придёт к вам на помощь. Когда это случится, заберите с собой мои останки.

20Оставив Суккот, они расположились лагерем в Етаме, на краю пустыни. 21Днём Вечный шёл впереди них в облачном столбе, указывая им путь, а ночью – в огненном столбе, чтобы давать им свет, поэтому так они могли передвигаться и днём, и ночью. 22Ни облачный столб днём, ни огненный столб ночью ни разу не покидали народ Исраила.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 13:1-22

Ìyàsímímọ́ àwọn àkọ́bí

1Olúwa sọ fún Mose pé, 213.2,12,15: Lk 2.23.“Ẹ ya àwọn àkọ́bí yín ọkùnrin sọ́tọ̀ fún mi. Èyí ti ó bá jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ tèmi, ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko.”

3Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ rántí ọjọ́ òní, ọjọ́ ti ẹ jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, kúrò ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin ti ń ṣe ẹrú, nítorí Olúwa mú un yín jáde kúrò ni inú rẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára. Ẹ má ṣe jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú. 4Òní, ní oṣù Abibu (oṣù kẹta ọdún tiwa) lónìí ẹ̀yin ń jáde kúrò ní Ejibiti. 5Ní ìgbà tí Ọlọ́run mú un yín jáde wá sí ilẹ̀ Kenaani, Hiti, Amori, Hifi àti ilẹ̀ àwọn Jebusi; ilẹ̀ tí ó ti ṣe búra láti fi fún àwọn baba ńlá yín, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ẹ ni láti pa ìsìn yìí mọ́ ní oṣù yìí. 6Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà nínú àti pé ní ọjọ́ keje ni àjọ yóò wà fún Olúwa. 7Kí ẹ̀yin ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje yìí; kó má ṣe sí ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe ní sàkání yín. 8Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin ‘Mo ń ṣe èyí nítorí ohun tí Olúwa ṣe fún mi nígbà tí èmi jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.’ 9Ṣíṣe èyí yóò wà fún ààmì ní ọwọ́ rẹ, àti bí ààmì ìrántí ni iwájú orí rẹ, tí yóò máa rán ọ létí òfin Olúwa ní ẹnu rẹ. Nítorí Olúwa mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá rẹ̀. 10Ìwọ gbọdọ̀ pa òfin náà mọ́ ní àkókò tí a yàn bí ọdún tí ń gorí ọdún.

11“Lẹ́yìn tí Olúwa tí mú ọ wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani tí ó sì fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí pẹ̀lú ìbúra fún ọ àti fún àwọn baba ńlá rẹ̀, 1213.12: Ek 34.19,20; Lk 2.23.Ìwọ yóò fi àkọ́bí inú rẹ fún Olúwa. Gbogbo àkọ́bí ti ó jẹ́ akọ ti ẹran ọ̀sìn rẹ ní ó jẹ́ ti Olúwa. 13Ìwọ yóò fi ọ̀dọ́-àgùntàn ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, ǹjẹ́ kí ìwọ ṣẹ́ ẹ ní ọrùn, gbogbo àkọ́bí ọkùnrin ni kí ìwọ kí ó rà padà.

14“Yóò sí ṣe ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín yóò béèrè lọ́wọ́ yín ‘Kí ni èyí túmọ̀ sí?’ Kí ìwọ kí ó sọ fún wọn pé, ‘Pẹ̀lú ọwọ́ agbára ní Olúwa fi mú wa jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, kúrò ní oko ẹrú. 15Ní ìgbà ti Farao ṣe orí kunkun, ti ó kọ̀ láti jẹ́ kí a lọ, Olúwa pa gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ejibiti, àti ènìyàn àti ẹranko. Ìdí èyí ni àwa fi ń fi gbogbo àkọ́bí tí í ṣe akọ rú ẹbọ sí Olúwa láti fi ṣe ìràpadà fún àwọn àkọ́bí wa ọkùnrin.’ 16Èyí yóò sì jẹ́ ààmì ni ọwọ́ yín àti ààmì ní iwájú orí yín pé Olúwa mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá.”

Kíkọjá ni Òkun pupa

17Ní ìgbà tí Farao jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ, Ọlọ́run kò mú wọn tọ ojú ọ̀nà ti ó la orílẹ̀-èdè àwọn Filistini kọjá, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà náà kúrú. Nítorí Ọlọ́run sọ pé, “Bí wọ́n bá dojúkọ ogun, wọ́n lè yí ọkàn wọn padà kí wọ́n padà sí ilẹ̀ Ejibiti.” 18Nítorí náà Ọlọ́run darí àwọn ènìyàn rọkọ gba ọ̀nà aginjù ní apá Òkun Pupa. Àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ìmúra fún ogun.

1913.19: Gẹ 50.25.Mose kó egungun Josẹfu pẹ̀lú rẹ̀ nítorí Josẹfu tí mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra. Ó ti wí pé, “Dájúdájú Ọlọ́run yóò dìde fún ìrànlọ́wọ́ yín ẹ sì gbọdọ̀ kó egungun mi lọ pẹ̀lú yín kúrò níhìn-ín yìí.”

20Wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n láti Sukkoti lọ, wọ́n sì pàgọ́ sí Etamu ní etí aginjù. 21Olúwa sì ń lọ níwájú wọn, nínú ọ̀wọ̀n ìkùùkuu ní ọ̀sán láti máa ṣe amọ̀nà wọn àti ní òru nínú ọ̀wọ̀n iná láti máa tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn, kí wọn lè máa lọ nínú ìrìnàjò wọn ní tọ̀sán tòru. 22Ìkùùkuu náà kò kúrò ní ààyè rẹ̀ ní ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀wọ̀n iná kò kúrò ní ààyè rẹ̀ ni òru, ní iwájú àwọn ènìyàn náà.