Второзаконие 28 – CARS & YCB

Священное Писание

Второзаконие 28:1-68

Благословения за послушание

(Лев. 26:1-13; Втор. 7:12-16)

1Если ты будешь полностью послушен Вечному, твоему Богу, и будешь прилежно исполнять все Его повеления, которые я даю тебе сегодня, то Вечный, твой Бог, поставит тебя выше всех народов на земле. 2Все эти благословения ты получишь, если будешь слушаться Вечного, твоего Бога.

3Ты будешь благословен в городе и благословен в селении28:3 Или: «на поле», также в ст. 16..

4Благословен будешь ты множеством детей, земля твоя принесёт обильный урожай, а стада твои и отары – большой приплод: телят и ягнят.

5Твоя корзина и твоя квашня никогда не будут пусты.

6Ты будешь благословен, когда будешь входить и когда будешь выходить.

7Вечный сделает так, что враги, которые поднимутся против тебя, будут разбиты перед тобой. Они пойдут на тебя по одной дороге, но побегут от тебя по семи.

8Вечный наполнит твои амбары и благословит всё, что ты будешь делать своими руками. Вечный, твой Бог, благословит тебя на земле, которую Он даёт тебе.

9Вечный поставит тебя Своим святым народом, как Он клялся тебе, если ты будешь исполнять повеления Вечного, твоего Бога, и ходить Его путями. 10Тогда все народы на земле увидят, что над тобой провозглашено имя Вечного, и будут бояться тебя. 11Вечный даст тебе изобилие во всём – в твоих детях, приплоде скота и урожаях земли – на земле, которую Он клялся твоим предкам дать тебе.

12Вечный откроет тебе небеса, свою богатую сокровищницу, чтобы посылать дождь в срок на твою землю и благословлять всякое дело твоих рук. Ты будешь давать взаймы многим народам, а занимать не будешь ни у кого. 13Вечный сделает тебя головой, а не хвостом. Если ты будешь внимателен к повелениям Вечного, твоего Бога, которые я даю тебе сегодня, и будешь прилежно исполнять их, то ты всегда будешь наверху, а не внизу. 14Не уклоняйся ни от одного из повелений, которые я даю тебе сегодня, ни вправо, ни влево, не следуй за другими богами и не служи им.

Проклятия за непослушание

(Лев. 26:14-39)

15Но если ты не будешь послушен Вечному, твоему Богу, и не будешь прилежно исполнять все Его повеления и установления, которые я даю тебе сегодня, все эти проклятия придут на тебя и будут с тобой.

16Ты будешь проклят в городе и проклят в селении.

17Твоя корзина и твоя квашня всегда будут пусты.

18Дети твои будут немногочисленны, твоя земля будет давать скудный урожай, а стада твои и отары принесут мало приплода: телят и ягнят.

19Ты будешь проклят, когда будешь входить и когда будешь выходить.

20Вечный будет посылать на тебя проклятие, смятение и неудачу во всех делах твоих рук, пока ты не будешь истреблён и не придёшь к быстрой погибели из-за того зла, которое ты сделал, оставив Меня. 21Вечный будет насылать на тебя мор за мором, пока не истребит тебя с земли, в которую ты вступаешь, чтобы завладеть ею. 22Вечный нашлёт на тебя чахотку, лихорадку и воспаление, жару и засуху, знойный ветер и плесень, которые будут преследовать тебя, пока ты не погибнешь. 23Небо над твоей головой станет медью, земля под тобой – железом28:23 То есть не будет дождя, небо будет источать жар, и земля не будет способна что-либо произрастить.. 24Вечный даст твоей стране пыль вместо дождя, и только прах будет падать на тебя с небес, пока ты не погибнешь.

25Вечный сделает так, что ты будешь разбит врагами. Ты пойдёшь на них по одной дороге, а побежишь от них по семи и станешь отвратителен всем царствам на земле. 26Твои трупы будут пищей всем небесным птицам и земным зверям, и некому будет отпугнуть их. 27Вечный нашлёт на тебя нарывы и опухоли Египта28:27 См. Исх. 9:8-11., гноящиеся язвы и чесотку, от которых ты не сможешь исцелиться. 28Вечный поразит тебя безумием, слепотой и помрачением ума. 29В полдень ты будешь бродить на ощупь, как слепец во тьме. Ты будешь неудачлив во всём, что будешь делать; изо дня в день тебя будут притеснять и грабить, и не будет у тебя защитника.

30Ты обручишься с женщиной, но другой возьмёт её и будет спать с ней. Ты построишь дом, но не будешь в нём жить. Ты посадишь виноградник, но не успеешь собрать даже первый урожай. 31Твоего вола заколют у тебя на глазах, но ты не будешь есть его мясо. Твоего осла уведут у тебя силой и не вернут. Твои овцы достанутся врагам, и никто не спасёт их для тебя. 32Твоих сыновей и дочерей отдадут другому народу, и ты истомишь свои глаза, разыскивая их изо дня в день, бессильный хоть что-нибудь сделать. 33Народ, которого ты не знал, будет есть то, что ты произвёл своим трудом на своей земле, а тебя будут только жестоко притеснять всю твою жизнь. 34Ты сойдёшь с ума от того, что увидишь. 35Вечный поразит твои колени и голени болезненными неисцелимыми нарывами, которые распространятся от ступней твоих ног до самого темени.

36Вечный уведёт тебя и царя, которого ты поставишь над собой, к народу неизвестному ни тебе, ни твоим предкам. Там ты будешь служить другим богам, богам из дерева и камня. 37Тебя будут презирать и над тобой будут насмехаться, ты будешь отвратителен всем тем народам, к которым уведёт тебя Вечный.

38Ты будешь сеять на поле много семян, но соберёшь бедный урожай, потому что его пожрёт саранча. 39Ты будешь сажать виноградники и ухаживать за ними, но не пить тебе вина, не собирать плода, потому что виноград сожрут черви. 40По всей стране будут расти маслины, но не видать тебе масла, потому что оливки осыплются. 41У тебя будут сыновья и дочери, но ты не сохранишь их, потому что их уведут в плен. 42Рои саранчи захватят твои деревья и урожаи твоей земли.

43Живущий у тебя чужеземец будет подниматься над тобой всё выше и выше, а ты будешь опускаться всё ниже и ниже. 44Он будет давать тебе взаймы, а ты не будешь давать ему взаймы. Он будет головой, а ты будешь хвостом.

45Все эти проклятия падут на тебя. Они будут преследовать и настигать тебя, пока ты не погибнешь, потому что ты не слушался Вечного, твоего Бога, и не соблюдал повелений и установлений, которые Он дал тебе. 46Эти бедствия будут свидетельством и знамением для тебя и твоего потомства вовеки. 47Так как ты не служил Вечному, твоему Богу, с весельем и радостью во время изобилия, 48то в голоде и жажде, в наготе и страшной нищете ты будешь служить врагам, которых Вечный пошлёт на тебя. Он наденет тебе на шею железное ярмо, пока не погубит тебя.

49Вечный нашлёт на тебя народ издалека, с дальних концов земли, подобный налетающему орлу, народ, чьего языка ты не будешь понимать, 50безжалостный народ, не уважающий старика и не щадящий юноши. 51Он будет пожирать приплод твоего скота и урожаи твоей земли, пока не истребит тебя. Он не оставит тебе ни зерна, ни молодого вина, ни масла, ни телят твоего стада, ни ягнят твоей отары, пока не погубит тебя. 52Он будет осаждать все твои города по всей земле, пока высокие, укреплённые стены, на которые ты полагаешься, не падут. Он будет осаждать все города по всей земле, которую Вечный, твой Бог, даёт тебе.

53Из-за страданий, которые враги причинят тебе во время осады, ты будешь есть своих детей, плоть своих сыновей и дочерей, которых дал тебе Вечный, твой Бог. 54Даже самый изнеженный и чувствительный из ваших людей не станет сострадать28:54 Букв.: «У человека изнеженного и чувствительного среди вас будет дурной глаз против…» См. сноску на 15:9. собственному брату, или любимой жене, или своим уцелевшим детям 55и не даст никому из них ничего из плоти своих детей, которых будет есть сам. Это всё, что у него останется. Вот какие страдания враг причинит тебе во время осады всех твоих городов. 56Самая изнеженная и чувствительная из твоих женщин – такая изнеженная и чувствительная, что не привыкла ступать по земле – поскупится дать28:56 Букв.: «У женщины изнеженной и чувствительной среди вас… будет дурной глаз против…» См. сноску на 15:9. любимому мужу и собственному сыну или дочери 57послед из своего чрева и детей, которых родит. Ведь она захочет съесть их тайно во время осады и в бедствии, которое враг причинит тебе во всех твоих городах.

58Если ты не будешь прилежно следовать всем словам Закона, который записан в этом свитке, и не будешь чтить славное и страшное имя Вечного, твоего Бога28:58 Чтить чьё-либо имя, значит чтить самого носителя этого имени, в данном случае чтить Вечного., 59то Вечный наведёт на тебя и на твоих потомков ужасные несчастья, жестокие и продолжительные бедствия и свирепые, затяжные болезни. 60Он наведёт на тебя все недуги Египта, которых ты ужасался, и они пристанут к тебе. 61Ещё Вечный наведёт на тебя такие болезни и беды, о которых не говорится в этом свитке Закона, пока ты не погибнешь. 62Вас было много, как звёзд на небе, но останется мало, потому что вы не были послушны Вечному, вашему Богу. 63Как Вечный радовался, делая вам добро и умножая ваше число, так Он будет радоваться, губя и истребляя вас. Вы будете искоренены из земли, куда вы вступаете, чтобы завладеть ею.

64Тогда Вечный рассеет вас по всем народам, от одного конца земли до другого. Там вы будете служить другим богам – богам из дерева и камня, которых не знали ни вы, ни ваши предки. 65Между теми народами вы не обретёте покоя, и не будет спокойного места, куда могла бы ступить ваша нога. Там Вечный заставит ваше сердце трепетать, истомит тоской ваши глаза и наполнит отчаянием вашу душу. 66Вы будете жить в постоянной тревоге, полные ужаса и днём, и ночью, никогда не уверенные в своей жизни. 67Утром вы скажете: «Ах, скорее бы вечер!» – а вечером: «О, скорее бы утро!» – от ужаса, который наполнит ваши сердца, и из-за того, что увидят ваши глаза. 68Вечный возвратит вас на кораблях в Египет тем путём, о котором я говорил, что вы никогда не проделаете его вновь. Там вы будете предлагать себя на продажу как рабов и рабынь своим врагам, но никто вас не купит.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 28:1-68

Ìbùkún fún ìgbọ́ràn

128.1-14: Le 26.3-45.Bí ìwọ bá gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ ní kíkún kí o sì kíyèsára láti tẹ̀lé gbogbo ohun tí ó pàṣẹ tí mo fi fún ọ lónìí, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé ọ lékè ju gbogbo orílẹ̀-èdè ayé lọ. 2Gbogbo ìbùkún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ bí o bá gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ:

3Ìbùkún ni fún ọ ni ìlú, ìbùkún ni fún ọ ní oko.

4Ìbùkún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, àti irú ohun ọ̀sìn rẹ àti ìbísí i màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.

5Ìbùkún ni fún agbọ̀n rẹ àti fún ọpọ́n ipò ìyẹ̀fun rẹ.

6Ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá wọlé, ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.

7Olúwa yóò gbà fún ọ pé gbogbo ọ̀tá tí ó dìde sí ọ yóò bì ṣubú níwájú rẹ. Wọn yóò tọ̀ ọ́ wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n wọn yóò sá fún ọ ní ọ̀nà méje.

8Olúwa yóò rán ìbùkún sí ọ àti sí ohun gbogbo tí o bá dáwọ́ rẹ lé. Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún un fún ọ nínú ilẹ̀ tí ó ń fi fún ọ.

9Olúwa yóò fi ọ́ múlẹ̀ bí ènìyàn mímọ́, bí ó ti ṣe ìlérí fún ọ lórí ìbúra, bí o bá pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ mọ́ tí o sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀. 10Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé yóò rí i pé a pè ọ́ ní orúkọ Olúwa, wọn yóò sì bẹ̀rù rẹ. 11Olúwa yóò fi àlàáfíà fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, fún ọmọ inú rẹ, irú ohun ọ̀sìn rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá rẹ láti fún ọ.

12Olúwa yóò ṣí ọ̀run sílẹ̀, ìṣúra rere rẹ̀ fún ọ, láti rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ ní àsìkò rẹ àti láti bùkún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ. Ìwọ yóò yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ṣùgbọ́n ìwọ kò ní í yá lọ́wọ́ ẹnìkankan. 13Olúwa yóò fi ọ́ ṣe orí, ìwọ kì yóò sì jẹ́ ìrù. Bí o bá fi etí sílẹ̀ sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ tí mo fi fún ọ kí o sì máa rọra tẹ̀lé wọn, ìwọ yóò máa wà lókè, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò wà ní ìsàlẹ̀ láé. 14Má ṣe yà sọ́tùn tàbí sósì kúrò, nínú èyíkéyìí àwọn àṣẹ tí mo fi fún ọ ní òní yìí, kí o má ṣe tẹ̀lé àwọn ọlọ́run mìíràn láti máa sìn wọ́n.

Ègún fún àìgbọ́ràn

15Ṣùgbọ́n bí o kò bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì rọra máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí, gbogbo ègún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ:

16Ègún ni fún ọ ní ìlú, ègún ni fún ọ ní oko.

17Ègún ni fún Agbọ̀n rẹ àti ọpọ́n ìpo-fúláwà rẹ.

18Ègún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, ìbísí màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.

19Ègún ni fún ọ nígbà tí o bá wọlé ègún sì ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.

20Olúwa yóò rán ègún sórí rẹ, rúdurùdu àti ìfibú nínú gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ rẹ lé, títí ìwọ yóò fi parun àti wá sí ìparun lójijì nítorí búburú tí o ti ṣe ní kíkọ̀ mi sílẹ̀. 21Olúwa yóò fi àjàkálẹ̀-ààrùn bá ọ jà títí tí yóò fi pa ọ́ run kúrò ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní. 22Olúwa yóò kọlù ọ́ pẹ̀lú ààrùn ìgbẹ́, pẹ̀lú ibà àti àìsàn wíwú, pẹ̀lú ìjóni ńlá àti idà, pẹ̀lú ìrẹ̀dànù àti ìmúwòdù tí yóò yọ ọ́ lẹ́nu títí ìwọ yóò fi parun. 23Ojú ọ̀run tí ó wà lórí rẹ yóò jẹ́ idẹ, ilẹ̀ tí ń bẹ níṣàlẹ̀ rẹ yóò sì jẹ́ irin. 24Olúwa yóò yí òjò ilẹ̀ rẹ sí eruku àti ẹ̀tù; láti ọ̀run ni yóò ti máa sọ̀kalẹ̀ sí ọ, títí tí ìwọ yóò fi run.

25Olúwa yóò fi ọ́ gégùn ún láti ṣubú níwájú àwọn ọ̀tá rẹ. Ìwọ yóò tọ̀ wọ́n wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n ìwọ yóò sá fún wọn ní ọ̀nà méje, ìwọ yóò sì padà di ohun ìbẹ̀rù fún gbogbo ìjọba lórí ayé. 26Òkú rẹ yóò jẹ́ oúnjẹ fún gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko ayé, àti pé kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóò lé wọn kúrò. 27Olúwa yóò bá ọ jà pẹ̀lú oówo, Ejibiti àti pẹ̀lú kókó, ojú egbò kíkẹ̀ àti ìhúnra. 28Olúwa yóò bá ọ jà pẹ̀lú ìsínwín, ojú fífọ́ àti rúdurùdu àyà. 29Ní ọ̀sán gangan ìwọ yóò fi ọwọ́ tálẹ̀ kiri bí ọkùnrin afọ́jú nínú òkùnkùn ìwọ kì yóò ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí o bá ń ṣe, ojoojúmọ́ ni wọn yóò máa ni ọ́ lára àti jà ọ́ ní olè, tí kò sì ní í sí ẹnìkan láti gbà ọ́.

30Ìwọ yóò gba ògo láti fẹ́ obìnrin kan ṣùgbọ́n ẹlòmíràn yóò gbà á yóò sì tẹ́ ẹ́ ní ògo. Ìwọ yóò kọ́ ilé, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò gbé ibẹ̀. Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kò tilẹ̀ ní gbádùn èso rẹ. 31Màlúù rẹ yóò di pípa níwájú rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò jẹ nǹkan kan nínú rẹ̀. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ yóò sì di mímú pẹ̀lú agbára kúrò lọ́dọ̀ rẹ, a kì yóò sì da padà. Àgùntàn rẹ yóò di mímú fún àwọn ọ̀tá rẹ, ẹnìkankan kò sì ní gbà á. 32Àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ yóò di mímú fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ìwọ yóò sì fi ojú rẹ ṣọ́nà dúró dè wọ́n láti ọjọ́ dé ọjọ́, ìwọ yóò sì jẹ́ aláìlágbára láti gbé ọwọ́. 33Èso ilẹ̀ rẹ àti gbogbo iṣẹ́ làálàá rẹ ni orílẹ̀-èdè mìíràn tí ìwọ kò mọ̀ yóò sì jẹ, ìwọ yóò jẹ́ kìkì ẹni ìnilára àti ẹni ìtẹ̀mọ́lẹ̀ 34Ìran tí ojú rẹ yóò rí, yóò sọ ọ́ di òmùgọ̀. 35Olúwa yóò lu eékún àti ẹsẹ̀ rẹ pẹ̀lú oówo dídùn tí kò le san tán láti àtẹ̀lé méjèèjì rẹ lọ sí òkè orí rẹ.

36Olúwa yóò lé ọ àti ọba tí ó yàn lórí rẹ lọ sí orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ tàbí ti àwọn baba rẹ kò mọ̀. Ibẹ̀ ni ìwọ̀ yóò sì sin ọlọ́run mìíràn, ọlọ́run igi àti òkúta. 37Ìwọ yóò di ẹni ìyanu, àti ẹni òwe, àti ẹni ìfisọ̀rọ̀ sọ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè tí Olúwa yóò darí rẹ sí.

38Ìwọ yóò gbin irúgbìn púpọ̀ ṣùgbọ́n ìwọ yóò kórè kékeré, nítorí eṣú yóò jẹ ẹ́ run. 39Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà púpọ̀ ìwọ yóò sì ro wọ́n ṣùgbọ́n kò ní mú wáìnì náà tàbí kó àwọn èso jọ, nítorí kòkòrò yóò jẹ wọ́n run. 40Ìwọ yóò ní igi olifi jákèjádò ilẹ̀ rẹ ṣùgbọ́n ìwọ kò ní lo òróró náà, nítorí olifi náà yóò rẹ̀ dànù. 41Ìwọ yóò ní àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ṣùgbọ́n ìwọ kò nípa wọ́n mọ́, nítorí wọn yóò lọ sí ìgbèkùn. 42Ọ̀wọ́ eṣú yóò gba gbogbo àwọn igi rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ.

43Àjèjì tí ń gbé láàrín rẹ yóò gbé sókè gíga jù ọ́ lọ, ṣùgbọ́n ìwọ yóò máa di ìrẹ̀sílẹ̀. 44Yóò yà ọ́, ṣùgbọ́n o kì yóò yà á, òun ni yóò jẹ́ orí, ìwọ yóò jẹ́ ìrù.

45Gbogbo ègún yìí yóò wá sórí rẹ, wọn yóò lé ọ wọn yóò sì bá ọ títí tí ìwọ yóò fi parun, nítorí ìwọ kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ìwọ kò sì kíyèsi àṣẹ àti òfin tí ó fi fún ọ. 46Wọn yóò jẹ́ ààmì àti ìyanu fún ọ àti fún irú-ọmọ rẹ títí láé. 47Nítorí ìwọ kò sin Olúwa Ọlọ́run rẹ ní ayọ̀ àti inú dídùn ní àkókò àlàáfíà. 48Nítorí náà nínú ebi àti òǹgbẹ, nínú ìhòhò àti àìní búburú, ìwọ yóò sin àwọn ọ̀tá à rẹ tí Olúwa rán sí ọ. Yóò sì fi àjàgà irin bọ̀ ọ́ ní ọrùn, títí yóò fi run ọ́.

4928.49: 1Kọ 14.21.Olúwa yóò mú àwọn orílẹ̀-èdè wá sí ọ láti ọ̀nà jíjìn, bí òpin ayé, bí idì ti ń bẹ́ láti orí òkè sílẹ̀, orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò gbọ́ èdè wọn. 50Orílẹ̀-èdè tí ó rorò tí kò ní ojúrere fún àgbà tàbí àánú fún ọmọdé. 51Wọn yóò jẹ ohun ọ̀sìn rẹ run àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ títí tí ìwọ yóò fi parun. Wọn kì yóò fi hóró irúgbìn kan fún ọ, wáìnì tuntun tàbí òróró, tàbí agbo ẹran màlúù rẹ kankan tàbí ọ̀wọ́ ẹran àgùntàn rẹ títí ìwọ yóò fi run. 52Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú rẹ títí tí odi ìdáàbòbò gíga yẹn tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé yóò fi wó lulẹ̀. Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú rẹ jákèjádò ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ.

53Ìwọ ó sì jẹ èso ọmọ inú rẹ̀, ẹran-ara àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ti àwọn ọmọ rẹ obìnrin tí Olúwa Ọlọ́run ti fi fún ọ; nínú ìdótì náà àti nínú ìhámọ́ náà tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò há ọ mọ́. 54Ọkùnrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù nínú yín, tí ó sì ṣe ẹlẹgẹ́, ojú rẹ̀ yóò korò sí arákùnrin rẹ̀ àti sí aya oókan àyà rẹ̀, àti sí ìyókù ọmọ rẹ̀ tí òun jẹ kù, 55Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fún ẹnikẹ́ni nínú ẹran-ara àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó ń jẹ, nítorí kò sí ohun kan tí ó kù sílẹ̀ fún un nínú ìdótì náà àti ìhámọ́, tí àwọn ọ̀tá yóò fi há ọ mọ́ ní ibodè rẹ gbogbo. 56Obìnrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù nínú yín, tí ó sì ṣe ẹlẹgẹ́, tí kò jẹ́ dáṣà láti fi àtẹ́lẹsẹ̀ ẹ rẹ̀ kan ilẹ̀ nítorí ìkẹ́ra àti ìwà ẹlẹgẹ́, ojú u rẹ̀ yóò korò sí ọkọ oókan àyà rẹ̀, àti sí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ rẹ̀ obìnrin, 57àti sí ọmọ rẹ̀ tí ó ti agbede-méjì ẹsẹ̀ rẹ̀ jáde, àti sí àwọn ọmọ rẹ̀ tí yóò bí. Nítorí òun ó jẹ wọ́n ní ìkọ̀kọ̀, nítorí àìní ohunkóhun nínú ìdótì àti ìhámọ́ náà, tí àwọn ọ̀tá yóò fi há ọ mọ́ ní ibodè rẹ.

58Bí ìwọ kò bá rọra tẹ̀lé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí, tí a kọ sínú ìwé yìí, tí ìwọ kò sì bu ọlá fún ògo yìí àti orúkọ dáradára: orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ, 59Olúwa yóò sọ ìyọnu rẹ di ìyanu, àti ìyọnu irú-ọmọ ọ̀ rẹ, àní àwọn ìyọnu ńlá èyí tí yóò pẹ́, àti ààrùn búburú èyí tí yóò pẹ́. 60Olúwa yóò mú gbogbo ààrùn Ejibiti tí ó mú ẹ̀rù bà ọ́ wá padà bá ọ, wọn yóò sì lẹ̀ mọ́ ọ. 61Olúwa yóò tún mú onírúurú àìsàn àti ìpọ́njú tí a kò kọ sínú Ìwé Òfin yìí wá sórí rẹ, títí ìwọ yóò fi run. 62Ìwọ tí ó dàbí àìmoye bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò ṣẹ́ku kékeré níye, nítorí tí o kò ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ. 63Gẹ́gẹ́ bí ó ti dùn mọ́ Olúwa nínú láti mú ọ ṣe rere àti láti pọ̀ si ní iye, bẹ́ẹ̀ ni yóò dùn mọ́ ọ nínú láti bì ọ́ ṣubú kí ó sì pa ọ́ run. Ìwọ yóò di fífà tu kúrò lórí ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.

64Nígbà náà ni Olúwa yóò fọ́n ọ ká láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè, láti òpin kan ní ayé sí òmíràn. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò ti sin ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run igi àti ti òkúta. Èyí tí ìwọ àti àwọn baba rẹ kò mọ̀. 65Ìwọ kì yóò sinmi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà, kò sí ibi ìsinmi fún àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ. Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti fún ọ ní ọkàn ìnàngà, àárẹ̀ ojú, àti àìnírètí àyà. 66Ìwọ yóò gbé ní ìdádúró ṣinṣin, kún fún ìbẹ̀rùbojo lọ́sàn án àti lóru, bẹ́ẹ̀ kọ́ láé ni ìwọ yóò rí i ní àrídájú wíwà láyé rẹ. 67Ìwọ yóò wí ní òwúrọ̀ pé, “Bí ó tilẹ̀ lè jẹ́ pé ìrọ̀lẹ́ nìkan ni!” Nítorí ẹ̀rù tí yóò gba ọkàn rẹ àti ìran tí ojú rẹ yóò máa rí. 68Olúwa yóò rán ọ padà nínú ọkọ̀ sí Ejibiti sí ìrìnàjò tí mo ní ìwọ kì yóò lọ mọ́. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò tún fi ara rẹ fún àwọn ọ̀tá à rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò rà ọ́.