Mikas Bog 3 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

Mikas Bog 3:1-12

Ledernes ondskab

1Hør efter, Israels folks ledere.

Burde I ikke vide, hvad der er ret og rigtigt?

2Men I hader det gode

og elsker det onde.

I flår huden af mit folk

og kødet af deres knogler.

3I hakker dem i småstykker, som var de kød til en suppegryde,

og derefter tager I bare for jer af retterne.

4Når I så råber til Herren om hjælp,

vil han ikke høre på jer.

Han vender ryggen til

på grund af al jeres ondskab.

5Hør efter, I falske profeter,

som fører Herrens folk på afveje.

I profeterer fred og ingen fare

for dem, som betaler jer godt.

Men I lover krig og ulykke til dem,

som ikke har råd til at betale.

6Engang vil jeres syner holde op,

jeres trolddomskunster vil høre fortiden til.

Det er ude med jer,

og natten vil sænke sig over jer.

7Når det viser sig, at jeres ord var løgn,

ord, der ikke kom fra Gud,

vil I holde jer for munden

og skjule jeres ansigt i skam.

8Men jeg er fyldt med Herrens Ånd og kraft

og viger ikke tilbage for at udpege Israels synd.

9Hør efter, Israels folks ledere.

I, som hader retfærdighed og fordrejer sandheden.

10I bygger jeres magt og rigdom,

på mord, ondskab og korruption.

11Dommerne tager imod bestikkelse,

præsterne kræver betaling for at undervise,

og profeterne vil have penge for at spå.

Samtidig hævder I, at Herren er med jer,

og at intet ondt vil ramme jer.

12Derfor bliver Zion lagt øde som en pløjemark,

Jerusalem bliver til en hob af ruiner,

tempelbjerget bliver dækket af tjørnekrat.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Mika 3:1-12

Bíbá àwọn olórí àti àwọn wòlíì wí

1Nígbà náà, ni mo wí pé,

“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí Jakọbu,

ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli.

Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò ha ni í gba òdodo bí.

2Ẹ̀yin tí ó kórìíra ìre, tí ẹ sì fẹ́ràn ibi;

Ẹ̀yin tí ẹ fa awọ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi ya kúrò lára wọn

àti ẹran-ara wọn kúrò ní egungun wọn;

3Àwọn tí ó jẹ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi,

wọn sì bọ́ awọ ara wọn kúrò lára wọn.

Wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí wẹ́wẹ́;

Wọn sì gé e sí wẹ́wẹ́ bí ẹran inú ìkòkò,

bí ẹran inú agbada?”

4Nígbà náà ni wọn yóò kígbe sí Olúwa,

Ṣùgbọ́n òun kì yóò dá wọn lóhùn.

Ní àkókò náà ni òun yóò fi ojú rẹ̀ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn,

nítorí ibi tí wọ́n ti ṣe.

5Báyìí ni Olúwa wí:

“Ní ti àwọn Wòlíì

tí ń ṣi àwọn ènìyàn mi lọ́nà,

tí ẹnìkan bá fún wọn ní oúnjẹ,

wọn yóò kéde àlàáfíà;

Ṣùgbọ́n tí kò bá fi nǹkan sí wọn ní ẹnu,

wọn yóò múra ogun sí i.

6Nítorí náà òru yóò wá sórí yín,

tí ẹ̀yin kì yóò sì rí ìran kankan,

òkùnkùn yóò sì kùn fún yín,

tí ẹ̀yin kì yóò sì lè sọtẹ́lẹ̀

Oòrùn yóò sì wọ lórí àwọn wòlíì

ọjọ́ yóò sì ṣókùnkùn lórí wọn.

7Ojú yóò sì ti àwọn Wòlíì

àwọn alásọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú yóò sì gba ìtìjú.

Gbogbo wọn ni yóò bo ojú wọn,

nítorí kò sí ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”

8Ṣùgbọ́n ní tèmi,

èmi kún fún agbára pẹ̀lú ẹ̀mí Olúwa,

láti sọ ìré-òfin-kọjá Jakọbu fún un,

àti láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli fún un.

9Gbọ́ ẹ̀yin olórí ilé Jakọbu,

àti ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli,

tí ó kórìíra òdodo

tí ó sì yí òtítọ́ padà;

10Tí ó kọ́ Sioni pẹ̀lú ìtàjẹ̀ sílẹ̀,

àti Jerusalẹmu pẹ̀lú ìwà búburú.

11Àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀,

àwọn àlùfáà rẹ̀ sì ń kọ́ni nítorí owó ọ̀yà

àwọn wòlíì rẹ̀ pẹ̀lú sì ń sọtẹ́lẹ̀ nítorí owó.

Síbẹ̀, wọn gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, wọ́n sì wí pé,

“Nítòótọ́, Olúwa wà pẹ̀lú wa!

Ibi kan kì yóò bá wa.”

12Nítorí náà, nítorí tiyín,

ni a ó ṣe ro Sioni bí oko,

Jerusalẹmu yóò sì di ebè

àti òkè tẹmpili bí i ibi gíga igbó.