Dommerbogen 3 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

Dommerbogen 3:1-31

1Herren lod altså nogle folk blive i landet for at sætte den nye generation af israelitter på prøve, dem, der ikke selv havde været med i krigen mod kana’anæerne. 2Det gjorde han, for at de kunne lære at kæmpe og blive erfarne krigere. 3De folk, som var tilbage i landet, var: filistrene i deres fem byer, kana’anæerne, sidonierne og hivvitterne i Libanons bjerge fra Ba’al-Hermon til Lebo-Hamat. 4Dem ville Herren bruge til at sætte den nye generation af israelitter på prøve for at se, om de ville adlyde de befalinger, han havde givet deres forfædre gennem Moses.

5Israelitterne levede altså side om side med kana’anæerne, hittitterne, amoritterne, perizzitterne, hivvitterne og jebusitterne, 6og de blandede sig med dem ved at lade deres sønner og døtre gifte sig ind i deres familier, og de dyrkede deres guder.

Otniel som befrier

7Israelitterne gjorde, hvad der var ondt i Herrens øjne. De vendte sig fra Herren, deres Gud, og dyrkede i stedet afgudsbilleder af Ba’al og Ashera. 8Da blussede Herrens vrede op imod Israel, og han tillod kong Kushan-Rishatajim af Aram-Naharajim3,8 Den nordvestlige del af Mesopotamien. at besejre dem, så de var underkastet hans herredømme i otte år.

9Men da Israels folk råbte til Herren om hjælp, sendte han en befrier, nemlig Otniel, der var søn af Kalebs yngre bror, Kenaz. 10Herrens Ånd kom over ham, og han blev befrier i Israel. Han gik til angreb mod kong Kushan-Rishatajim og besejrede ham ved Herrens hjælp. 11De næste 40 år var der fred i landet, indtil Otniel døde.

Ehud som befrier

12Igen gjorde israelitterne, hvad der var ondt i Herrens øjne. Så lod Herren kong Eglon af Moab erobre landet. 13Sammen med ammonitterne og amalekitterne besejrede han israelitterne og indtog Palmernes By, Jeriko. 14De næste 18 år var israelitterne underkastet kong Eglon.

15Men da Israel råbte til Herren om hjælp, sendte han dem en ny befrier: Ehud, Geras søn af Benjamins stamme. Han var venstrehåndet. Engang skulle Ehud lede en delegation, der skulle overbringe den årlige skatteafgift fra israelitterne til kong Eglon af Moab. 16Inden han tog hjemmefra, lavede han sig et tveægget sværd, der var en halv meter langt, og spændte det fast ved sin højre side, så det var gemt under hans kappe. 17Han afleverede afgiften til kong Eglon, der var en meget tyk mand, 18og begav sig derefter på vej hjem sammen med de mænd, som havde hjulpet ham med at transportere pengene.

19Men da de nåede til billedstøtterne ved Gilgal, vendte han om og gik tilbage. Ved ankomsten gav han melding om, at han havde et hemmeligt budskab til kongen. „Lad ham komme til mig alene!” befalede kongen, og alle de tilstedeværende gik ud af kongens værelse. 20Da Ehud kom ind i det kølige værelse ovenpå, hvor kongen sad alene, sagde han: „Jeg har et budskab til dig fra Gud.” Idet kong Eglon rejste sig fra sin stol, 21trak Ehud med venstre hånd sværdet, som sad ved hans højre side, og stak det dybt ind i maven på kongen, 22så dybt, at skæftet forsvandt sammen med klingen under fedtlaget. Ehud lod sværdet blive siddende. 23Så gik han ud i søjlegangen, lukkede og låste døren til værelset efter sig og gik sin vej.

24Da han var gået, kom kongens tjenere og så, at døren var låst. „Han er nok gået på toilettet,” tænkte de. 25De ventede længe, men da han ikke åbnede døren til værelset, blev de bekymrede og hentede en nøgle. Da de åbnede døren, fandt de deres herre liggende død på gulvet.

26Mens tjenerne stod og ventede, slap Ehud bort forbi stenstøtterne og videre til Seira. 27Da han var nået sikkert til Efraims højland, satte han vædderhornet for munden og blæste signalet til krig. 28„Følg efter mig!” råbte han. „For Herren vil give jer sejr over vores fjender, moabitterne.”

Hæren fulgte ham, og de besatte vadestederne ved Jordanfloden, så moabitterne ikke kunne komme over. 29Derefter gik de til angreb og dræbte 10.000 af moabitternes tapre og stærke krigere, ikke en eneste undslap. 30Den dag led Moab et sviende nederlag til Israel, hvorefter der var fred i landet de næste 80 år.

31Den næste befrier var Shamgar, Anats søn, som engang reddede Israel ved at slå 600 filistre ihjel med en pigstav.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Onidajọ 3:1-31

1Àwọn wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa fi sílẹ̀ láti dán àwọn ìran tuntun ní Israẹli wò, àwọn ìran tí kò ì tí ì ní ìrírí ogun àwọn ará Kenaani. 2(Ó ṣe èyí láti fi kọ́ àwọn ìran Israẹli tí kò rí ogun rí níbí a ti ṣe ń jagun): 3Àwọn ìjòyè ìlú Filistini márààrún, gbogbo àwọn ará Kenaani, àwọn ará Sidoni, àti àwọn ará Hifi tí ń gbé ní àwọn òkè Lebanoni bẹ̀rẹ̀ láti òkè Baali-Hermoni títí dé Lebo-Hamati. 4A fi àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ láti dán àwọn Israẹli wò bóyá wọn yóò gbọ́rọ̀ sí àwọn òfin Olúwa, èyí tí ó ti fi fún àwọn baba wọn láti ipasẹ̀ Mose.

5Àwọn ọmọ Israẹli gbé láàrín àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti àwọn ará Amori, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi. 6Dípò kí wọ́n run àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Israẹli ń fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọbìnrin Israẹli fún àwọn ará ilẹ̀ náà ní aya, wọ́n sì ń sin àwọn òrìṣà wọn.

Otnieli

7Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe èyí tí ó burú níwájú Olúwa, wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń sin Baali àti Aṣerah. 8Ìbínú Olúwa sì ru sí Israẹli tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ kí Kuṣani-Riṣataimu ọba Aramu-Naharaimu (ìlà-oòrùn Siria) bá wọn jà kí ó sì ṣẹ́gun wọn, Israẹli sì ṣe ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ. 9Ṣùgbọ́n nígbà tí Israẹli kígbe sí Olúwa, Òun gbé olùgbàlà kan dìde fún wọn, ẹni náà ni Otnieli ọmọ Kenasi àbúrò Kalebu tí ó jẹ́ ọkùnrin, ẹni tí ó gbà wọ́n sílẹ̀. 10Ẹ̀mí Olúwa bà lé e, òun sì ṣe ìdájọ́ Israẹli, ó sì síwájú wọn lọ sí ogun. Olúwa sì fi Kuṣani-Riṣataimu ọba Aramu lé Otnieli lọ́wọ́, ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ sì borí Kuṣani-Riṣataimu. 11Ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún títí tí Otnieli ọmọ Kenasi sì kú.

Ehudu

12Àwọn ọmọ Israẹli sì tún padà sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n sì ṣe èyí tí ó burú ní iwájú Olúwa, fún ìdí iṣẹ́ búburú yìí, Olúwa fún Egloni, ọba àwọn Moabu ní agbára ní orí Israẹli. 13Pẹ̀lú ìfi ọwọ́ ṣowọ́pọ̀ ogun àwọn Ammoni àti àwọn ọmọ-ogun Amaleki ní Egloni gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì gba ìlú Ọ̀pẹ (Jeriko). 14Àwọn ọmọ Israẹli sì sin Egloni ọba Moabu fún ọdún méjì-dínlógún.

15Ṣùgbọ́n nígbà tí Israẹli tún ké pe Olúwa, Olúwa rán olùgbàlà kan sí wọn, Ehudu ẹni tí ń lo ọwọ́ òsì, ọmọ Gera ti ẹ̀yà Benjamini. Àwọn ọmọ Israẹli fi ẹ̀bùn rán sí Egloni ọba Moabu. 16Ehudu sì rọ idà kan olójú méjì, ìgbọ̀nwọ́ kan ní gígùn; òun sì sán an ní abẹ́ aṣọ rẹ̀ ní itan rẹ̀ ọ̀tún. 17Ó sì mú ọrẹ náà wá fún Egloni ọba Moabu, Egloni ẹni tí ó sanra púpọ̀. 18Lẹ́yìn tí Ehudu ti fi ẹ̀bùn náà fún ọba tan, ó rán àwọn tí ó kó ẹrú náà wá lọ sí ọ̀nà wọn. 19Ṣùgbọ́n nígbà tí òun fúnrarẹ̀ dé ibi ère fínfín tí ó wà létí Gilgali, ó padà sí Egloni, ó sì wí pé, “Ọba, mo ní ọ̀rọ̀ àṣírí láti bá ọ sọ.”

Ọba sì wí pé “Ẹ dákẹ́!” Gbogbo àwọn tí ń ṣọ sì jáde síta kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀.

20Ehudu lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ níbi tí ó ti jókòó ní iyàrá ìtura rẹ̀, Ehudu sì wí fún un pé: “Mo ní ọ̀rọ̀ kan fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Bí ọba sì ti dìde ní orí ìtẹ́ rẹ̀, 21Ehudu fi ọwọ́ òsì rẹ̀ yọ idà láti ibi itan ọ̀tún rẹ̀ ó sì fi gún ọba nínú ikùn rẹ̀. 22Àti idà àti èèkù rẹ̀ sì wọlé ó sì yọ ní ẹ̀yìn rẹ̀. Ehudu kò yọ idà náà, ọ̀rá sì bo idà náà. 23Ehudu ti àwọn ìlẹ̀kùn ní àtì-sínú òun sì bá yàrá òkè jáde, ó sì sálọ.

24Lẹ́yìn tí ó ti lọ àwọn ìránṣẹ́ ọba dé, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ìlẹ̀kùn yàrá òkè ní títì, wọ́n rò pé, “Bóyá ó wà ní ilé ìyàgbẹ́ ní yàrá nínú ilé.” 25Nígbà tí wọ́n dúró dé ibi pé ó jẹ́ ìyanu fún wọn, wọ́n mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn. Níbẹ̀ ni wọ́n ti rí Olúwa wọn tí ó ti ṣubú, ó sì ti kú.

26Nígbà tí wọ́n dúró tí wọn sì ń retí, Ehudu ti sálọ. Ó ti gba ibi tí wọ́n ti ń gbẹ́ òkúta lére, ó sì sálọ sí Seira. 27Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó fọn ìpè ní orí òkè Efraimu, àwọn ọmọ Israẹli sì ba sọ̀kalẹ̀ lọ láti òkè náà wá, òun sì wà níwájú wọn.

28Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí Olúwa ti fi Moabu ọ̀tá yín lé yín lọ́wọ́.” Wọ́n sì tẹ̀lé e, wọ́n sì gba ìwọdò Jordani tí ó lọ sí ilẹ̀ Moabu, wọn ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá. 29Ní báyìí, wọ́n ti pa tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin ará Moabu tí wọ́n jẹ́ alágbára àti onígboyà ènìyàn, kò sí ènìyàn tí ó sálà. 30Ní ọjọ́ náà ni Israẹli ṣẹ́gun àwọn ará Moabu, ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ọgọ́rin ọdún.

Ṣamgari

31Lẹ́yìn Ehudu, ni Ṣamgari ọmọ Anati ẹni tí ó pa ọgọ́rùn-ún mẹ́fà Filistini pẹ̀lú ọ̀pá tí a fi ń da akọ màlúù, òun pẹ̀lú sì gba Israẹli kúrò nínú ìpọ́njú.