5. Mosebog 21 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

5. Mosebog 21:1-23

Forskellige sociale og religiøse regler

1Når I har bosat jer i landet, og I finder en mand, der ligger myrdet på marken, uden at I er klar over, hvem gerningsmanden er, 2skal lederne og dommerne måle afstanden mellem gerningsstedet og de omliggende byer. 3Derefter skal lederne i den nærmeste by tage en kvie, der endnu ikke har båret åg, 4og føre den til en uopdyrket dal med en lille flod, hvor de skal brække dens hals. 5Præsterne skal være til stede, for det er deres opgave at fælde dom i retssager, hvor der er tale om vold. Herren har udvalgt dem til at stå for tjenesten ved helligdommen og til at velsigne på hans vegne. 6Derefter skal lederne fra byen nærmest gerningsstedet vaske deres hænder over kvien 7og sige: ‚Vi har hverken været medvirkende eller tilskuere til dette mord. 8Herre, se i nåde til dit folk Israel, som du befriede, så du ikke tilregner dem skyld for et mord, de ikke har ansvar for.’ På den måde bliver folket forsonet med Gud, 9og de undgår straffen for mord. Det er at handle ret i Herrens øjne.

10-11Når Herren, jeres Gud, giver jer sejr i en krig mod et fremmed land, og en af jer får øje på en smuk ung pige blandt krigsfangerne, som han kunne tænke sig at have til kone, 12må han tage hende med hjem. Der skal hun rage håret af, klippe sine negle 13og tage nyt tøj på. Efter at hun har været i huset en måned og sørget over tabet af sine forældre, kan han tage hende til kone og gå i seng med hende. 14Hvis han bagefter ikke længere bryder sig om hende, skal han sætte hende i frihed. Han må ikke sælge hende eller på anden måde behandle hende som en slave, for han har taget hendes ære.

15Hvis en mand har to koner og får børn med dem begge, men elsker den ene og ikke bryder sig om den anden, selv om det er hende, der er mor til hans førstefødte søn, 16må han ikke overdrage førstefødselsretten til nogen af de sønner, han har med den kone, han elsker. 17Han skal anerkende sin førstefødte søn, uanset hvem moderen er, ved at give ham dobbelt så meget i arv som de øvrige sønner.

18En trodsig og oprørsk søn, der ikke vil adlyde sine forældre, selv om de afstraffer ham, 19skal af forældrene føres for byrådet. 20‚Denne søn er trodsig og oprørsk!’ skal forældrene sige til dommerne. ‚Han vil ikke adlyde os, men drikker og fører et udsvævende liv.’ 21Da skal byrådet henrette ham ved stening, for at det onde kan udryddes fra jeres midte. Det skal være et afskrækkende eksempel for resten af de unge i Israel.

22Hvis en mand idømmes dødsstraf og efter henrettelsen hænges op på en træpæl, 23må liget ikke hænge der natten over. Det skal begraves samme dag. For den, der hænges op på et stykke træ, er under Guds dom. I må ikke gøre det land urent, som Herren vil give jer.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 21:1-23

Ìdáríjì ìpànìyàn láìnítumọ̀

1Tí a bá rí ọkùnrin tí a pa, ní ìdùbúlẹ̀ ní pápá nínú ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ láti jogún, tí a kò sì mọ ẹni tí ó pa á, 2àwọn àgbàgbà yín yóò jáde lọ láti wọn jíjìnnà ibi òkú sí ìlú tí ó wà nítòsí. 3Nígbà náà ni àwọn àgbàgbà ìlú tí ó wà nítòsí òkú yóò mú ẹgbọrọ abo màlúù tí kò ì ṣiṣẹ́ rí àti tí kò sì fà nínú àjàgà rí, 4Kí àwọn àgbàgbà ìlú náà kí wọn mú ẹgbọrọ abo màlúù náà sọ̀kalẹ̀ wá sí àfonífojì tí ó ní omi ṣíṣàn kan, tí a kò ro, tí a kò sì gbìn, kí wọn kí ó sì ṣẹ́ ọrùn ẹgbọrọ màlúù náà níbẹ̀ ní àfonífojì náà. 5Àwọn àlùfáà, ọmọ Lefi yóò wá síwájú, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún un àti láti bùkún ní orúkọ Olúwa àti láti parí gbogbo ẹjọ́ àríyànjiyàn àti ọ̀rọ̀ ìlú. 6Nígbà náà ni gbogbo àwọn àgbàgbà ìlú tí ó wà nítòsí yóò wẹ ọwọ́ wọn lórí ẹgbọrọ abo màlúù tí a ti kan ọrùn rẹ̀ ní àfonífojì, 7wọn yóò sì sọ pé, “ọwọ́ wa kò ta ẹ̀jẹ̀ yìí sílẹ̀, tàbí kí ojú wa rí i ní títa sílẹ̀.” 8Dáríjì, Olúwa, àwọn ènìyàn rẹ ni Israẹli, tí ìwọ ti dá sílẹ̀, àti kí ìwọ má ṣe gba ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ ní àárín àwọn ènìyàn rẹ ní Israẹli. Ṣùgbọ́n kí a dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ yìí jì. 9Nígbà náà ni ìwọ wẹ̀ kúrò láàrín rẹ ẹ̀bi títa ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí o ti ṣe èyí tí ó tọ́ níwájú Olúwa.

Fífẹ́ obìnrin ìgbèkùn

10Nígbà tí o bá lọ sí ogun sí àwọn ọ̀tá rẹ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ tí o sì mú àwọn ìgbèkùn, 11tí o sì rí obìnrin tí ó dára lára àwọn ìgbèkùn, tí o sì ní ìfẹ́ sí i, o lè mu u gẹ́gẹ́ bí aya à rẹ. 12Mú u wá sí ilé e rẹ kí o sì jẹ́ kí ó fá irun orí rẹ̀, gé èékánná an rẹ̀, 13kí o sì mú aṣọ tí ó wọ̀ nígbà tí ó di ìgbèkùn sí ẹ̀gbẹ́ kan. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ń gbé ilé rẹ tí ó sì ti ṣọ̀fọ̀ baba àti ìyá rẹ̀ fún odidi oṣù kan, nígbà náà ni o lè tọ̀ ọ́ lọ kí o sì ṣe ọkọ rẹ̀ kí ó jẹ́ aya rẹ. 14Bí inú rẹ̀ kò bá sì dùn sí i, jẹ́ kí ó lọ sí ibikíbi tí ó bá fẹ́. O kò gbọdọ̀ tà á tàbí lò ó bí ẹrú, lẹ́yìn ìgbà tí o ti dójútì í.

Ẹ̀tọ́ àkọ́bí

15Bí ọkùnrin kan bá ní ìyàwó méjì, tí ó sì fẹ́ ọ̀kan ṣùgbọ́n tí kò fẹ́ èkejì, tí àwọn méjèèjì sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un ṣùgbọ́n tí àkọ́bí jẹ́ ọmọ ìyàwó rẹ̀ tí kò fẹ́ràn. 16Nígbà tí ó bá ń pín ohun ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kò gbọdọ̀ fi ẹ̀tọ́ àkọ́bí fún ọmọ ìyàwó tí kò fẹ́ràn. 17Ó ní láti fi ipò ọmọ ìyàwó rẹ̀ tí kò fẹ́ràn fun un gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí i rẹ̀ nípa fífún un ní ìlọ́po ìpín gbogbo ohun tí ó ní. Ọmọ yẹn ni ààmì àkọ́kọ́ agbára baba rẹ̀. Ẹ̀tọ́ àkọ́bí jẹ́ tirẹ̀.

Ọlọ̀tẹ̀ ọmọ

1821.18-21: El 20.12; 21.15,17; Le 20.9; De 5.16; 27.16.Bí ọkùnrin kan bá ní aláìgbọ́ràn tàbí ọlọ̀tẹ̀ ọmọ tí kò gbọ́rọ̀ sí baba àti ìyá rẹ̀ tí kò sì ní í gbà tí wọ́n bá ń bá a wí, 19baba àti ìyá rẹ̀ yóò gbá a mú, wọn yóò mu wá fún àwọn àgbàgbà ní ẹnu-bodè ìlú u rẹ̀. 20Wọn yóò sì wí fún àwọn àgbàgbà pé, “Ọmọ wa yìí jẹ́ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀. Kò ní gbọ́rọ̀ sí wa lẹ́nu. Ọ̀jẹun àti ọ̀mùtí para ni.” 21Nígbà náà ni gbogbo ọkùnrin ìlú rẹ̀ yóò sọ ọ́ ní òkúta pa. Ìwọ yóò sì mú ìwà ibi kúrò láàrín yín, gbogbo Israẹli yóò gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n.

Onírúurú òfin

2221.22: Ap 5.30; 10.39.Bí ọkùnrin kan tí ó jẹ̀bi ẹ̀sùn bá ní láti kú tí ó sì kú, tí a sì gbé òkú rẹ̀ kọ́ sára igi, 2321.23: Ga 3.13.o kò gbọdọ̀ fi òkú rẹ̀ sílẹ̀ sára igi ní gbogbo òru. Gbìyànjú láti sin ín ní ọjọ́ náà gan an, nítorí ẹni tí a bá gbé kọ́ sórí igi wà lábẹ́ ègún Ọlọ́run. Ìwọ kò gbọdọ̀ ba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún jẹ́.