1. Kongebog 20 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

1. Kongebog 20:1-43

Kong Ahab besejrer den aramæiske hær i to omgange

1På den tid mobiliserede kong Ben-Hadad af Aram sin hær, og sammen med 32 af sine allierede fyrster og deres utallige heste og stridsvogne belejrede han Samaria, Israels hovedstad. 2-3Så sendte han bud ind i byen til kong Ahab af Israel og lod sige: „Jeg vil have dit sølv og guld. Jeg vil også have dine smukkeste koner og dine stærkeste sønner.”

4„Jeg accepterer, min herre konge,” svarede Ahab tilbage. „Du kan tage, hvad du vil, af det, som er mit.”

5Efter det svar sendte Ben-Hadad budbringerne til Ahab med en ny besked: „Godt nok sagde jeg, at jeg ville have dit sølv og guld, dine koner og dine børn. 6Men i morgen ved denne tid vil jeg sende mine folk til dit palads og dine hoffolks huse for at hente alt af værdi!”

7Da tilkaldte Ahab landets ledende mænd. „Den mand er ondskabsfuld!” sagde han. „Jeg gik med til at give ham mine koner og børn og mit sølv og guld—men nu vil han have alle vores ejendele!”

8„Du skal ikke give efter!” svarede både lederne og folket.

9Derfor sendte Ahab følgende besked med tilbage til kong Ben-Hadad: „Jeg accepterer dit første krav, men ikke mere!”

10Ben-Hadad blev vred og sendte nu følgende budskab til Ahab: „Måtte guderne behandle mig på det grusomste, hvis jeg ikke knuser Samaria, så der kun er støv tilbage!”

11Men Ahab gav svar på tiltale. „Sig til ham,” snerrede han, „at rigtige krigere venter med at prale af sejren, til de har vundet slaget!” 12Dette svar nåede kong Ben-Hadad, mens han sad i sit telt og drak sammen med sine allierede. „Gør klar til angreb!” beordrede han sine officerer, og de gjorde sig klar til at storme byen.

13Imidlertid var der kommet en profet til kong Ahab med et budskab fra Herren: „Se godt på disse mægtige fjendehære! I dag skal du få at se, at jeg er Herren, for jeg vil give dig sejr over dem!”

14„Hvordan vil Herren gøre det?” spurgte Ahab.

Profeten svarede: „Herren siger: ‚Ved hjælp af distriktsguvernørernes elitetropper.’ ”

„Jamen, skal vi angribe først?” spurgte Ahab.

„Ja,” svarede profeten.

15Så mønstrede Ahab distriktsguvernørernes elitetropper—232 i alt. Dertil kom resten af Israels hær på 7000 mand.

16-17Ved middagstid, mens kong Ben-Hadad og de 32 allierede fyrster stadig sad og drak i deres telte, marcherede Ahabs elitetropper ud af byen, fulgt af Israels krigere. Ben-Hadad fik meldingen fra sine udkigsposter: „Der er nogle folk på vej herhen fra byen.” 18Han lod sig ikke forstyrre, men svarede: „Fang dem levende, hvad enten de kommer for at overgive sig eller for at slås.”

19-20Så snart elitetropperne og den øvrige hær kom i kamp med Ben-Hadads folk, slog elitetropperne alle deres modstandere ihjel. Da flygtede den aramæiske hær i panik, og israelitterne forfulgte dem. Kong Ben-Hadad undslap til hest sammen med de øvrige ryttere, 21men hovedparten af stridsvognene og hestene blev taget som krigsbytte af Israels hær, så den aramæiske hær led et stort nederlag.

22Profeten vendte snart efter tilbage til Ahab med følgende råd: „Du må hellere ruste dig til en hård kamp, for den aramæiske konge vil komme tilbage næste år med fornyet styrke.”

23Efter nederlaget sagde Ben-Hadads officerer til ham: „Israels gud er en bjerggud. Det er derfor israelitterne vandt slaget på Samarias bjerg, men hvis vi kan lokke dem ned på sletten, kan vi sagtens slå dem. 24Hør her, hvad vi foreslår: Du skal afsætte alle småkongerne og indsætte guvernører i stedet. 25Så skal du samle en ny hær, lige så stor som den, du mistede, og med lige så mange heste og vogne og mænd som før. Når vi så kæmper på sletten, er vi de stærkeste.”

Kongen fulgte deres råd. 26Næste forår mønstrede han hele den aramæiske hær og marcherede mod Israel, men denne gang planlagde han at møde dem ved byen Afek. 27Også Israel mobiliserede, gjorde forsyningslinierne klar og slog lejr over for dem. Men i sammenligning med den enorme aramæiske hær, der bredte sig ud over hele sletten, lignede israelitternes hær et par små gedeflokke.

28Da kom profeten igen til kong Ahab med et budskab fra Herren: „Siden aramæerne påstår, at jeg er en bjerggud, som ingen magt har på sletterne, vil jeg give dig sejr over deres store hær. I skal erfare, at jeg er den almægtige Gud.”

29I seks dage lå israelitterne og aramæerne over for hinanden i deres lejre og ventede, og på den syvende dag begyndte slaget. Den dag dræbte israelitterne 100.000 aramæiske fodfolk. 30Resten søgte i dækning bag Afeks mure. Men murene styrtede sammen og dræbte endnu 27.000. Ben-Hadad flygtede ind i byen og gemte sig i et baglokale i et af husene. 31Dér opsøgte nogle af hans officerer ham og sagde: „Herre, vi har hørt, at Israels konger har ry for at vise nåde. Giv os tilladelse til at skifte rustningen ud med sækkelærred og at binde et reb om halsen for at vise vores underdanighed. Så vil vi gå til kong Ahab og se, om han vil skåne dit liv.”

32Derpå gik de til Ahab og sagde: „Din tjener Ben-Hadad trygler dig om at skåne hans liv.”

„Lever han endnu?” spurgte Ahab forbavset. „Han er jo min kollega.”

33Det tog mændene som et godt tegn, og de fortsatte i samme skure: „Ja, bestemt, Ben-Hadad og dig har meget tilfælles.”

„Hent ham endelig,” sagde Ahab. Og da Ben-Hadad kom, tog Ahab ham op i sin vogn.

34„Lad os indgå et forlig,” sagde Ben-Hadad. „Jeg lover at levere de byer tilbage, som min far tog fra din far, og jeg giver dig lov til at drive handel i Damaskus, sådan som min far gjorde det i Samaria.” „Det er i orden. Du har din frihed,” svarede Ahab. Ben-Hadad slap altså fri ved at slutte en fredspagt med Ahab.

En profet fordømmer Ahab

35En af profeterne fik da et budskab fra Herren. Han henvendte sig til en af de andre profeter og sagde: „Slå mig med dit sværd!” Men den anden profet nægtede at gøre det. 36Da sagde den første profet: „Fordi du ikke adlød Herrens befaling, bliver du dræbt af en løve, når du går herfra!” Og ganske rigtigt: Da han vendte sig og gik, blev han angrebet af en løve og dræbt.

37Profeten henvendte sig derefter til en anden profet og sagde: „Slå mig med dit sværd!” Og han adlød, så den første profet blev såret.

38Den sårede profet gik nu hen og stillede sig ved vejen for at vente på kong Ahab. Han havde taget bind om hovedet, så det dækkede hans øjne. 39Da kongen kørte forbi, råbte profeten: „Herre, jeg var med i slaget, og en af de andre soldater overlod en krigsfange i min varetægt og sagde: ‚Pas på denne mand! Hvis han slipper væk, må du bøde for det med dit liv eller med en sæk fuld af sølvstykker.’ 40Men i et ubemærket øjeblik, da jeg havde travlt med andre ting, forsvandt fangen.”

„Du har afsagt din egen dom,” svarede kongen. „Du skal dø eller betale løsesummen.”

41I samme øjeblik rev profeten bindet fra øjnene, og kongen genkendte ham som en af profeterne. 42Derpå sagde profeten til kongen: „Hør, hvad Herren siger til dig: Fordi du skånede den mand, som jeg sagde skulle dø, skal du dø i hans sted—og dit folk skal gå til grunde i stedet for hans.”

43Ærgerlig og vred kørte kong Ahab hjem til Samaria.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Ọba 20:1-43

Beni-Hadadi kọlu Samaria

1Beni-Hadadi ọba Aramu sì gbá gbogbo ogun rẹ̀ jọ. Ọba méjìlélọ́gbọ̀n sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ àti ẹṣin àti kẹ̀kẹ́, ó sì gòkè lọ, ó sì dó ti Samaria, ó sì kọlù ú. 2Ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí ìlú sí Ahabu ọba Israẹli wí pé, “Báyìí ni Beni-Hadadi wí: 3Fàdákà àti wúrà rẹ tèmi ni, àti àwọn tí ó dára jùlọ nínú àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ tèmi ni wọ́n.”

4Ọba Israẹli sì dá a lóhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ṣe wí olúwa mi ọba, èmi àti ohun gbogbo tí mo ní tìrẹ ni.”

5Àwọn oníṣẹ́ náà sì tún padà wá, wọ́n sì wí pé, “Báyìí ni Beni-Hadadi sọ wí pé: ‘Mo ránṣẹ́ láti béèrè fún fàdákà rẹ àti wúrà rẹ, àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ. 6Ṣùgbọ́n ní ìwòyí ọ̀la Èmi yóò rán àwọn ìránṣẹ́ mi sí ọ láti wá ilé rẹ wò àti ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ. Wọn yóò gba gbogbo ohun tí ó bá dára lójú rẹ, wọn yóò sì kó o lọ.’ ”

7Nígbà náà ni ọba Israẹli pe gbogbo àwọn àgbàgbà ìlú, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wo bí ọkùnrin yìí ti ń fẹ́ ìyọnu! Nígbà tí ó ránṣẹ́ fún àwọn aya mi, àti fún àwọn ọmọ mi, àti fún fàdákà mi, àti fún wúrà mi, èmi kò sì fi dù ú.”

8Àwọn àgbàgbà àti gbogbo ènìyàn dá a lóhùn pé, “Má ṣe fi etí sí tirẹ̀ tàbí kí ó gbà fún un.”

9Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn oníṣẹ́ Beni-Hadadi pé, “Sọ fún olúwa mi ọba pé, ‘ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe ohun gbogbo tí ó ránṣẹ́ fún látètèkọ́ṣe, ṣùgbọ́n nǹkan yìí ni èmi kò le ṣe.’ ” Wọ́n padà lọ, wọ́n sì mú èsì padà wá fún Beni-Hadadi.

10Beni-Hadadi sì tún rán oníṣẹ́ mìíràn sí Ahabu wí pé, “Kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú bí eruku Samaria yóò tó fún ìkúnwọ́ fún gbogbo ènìyàn tí ń tẹ̀lé mi.”

11Ọba Israẹli sì dáhùn wí pé, “Sọ fún un pé: ‘Má jẹ́ kí ẹni tí ń hámọ́ra halẹ̀ bí ẹni tí ń bọ́ ọ sílẹ̀.’ ”

12Beni-Hadadi sì gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí òun àti àwọn ọba ń mu ọtí nínú àgọ́ wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, “Ẹ ṣígun sí ìlú náà.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe tan láti kọlu ìlú náà.

Ahabu ṣẹ́gun Beni-Hadadi

13Sì kíyèsi i, wòlíì kan tọ Ahabu ọba Israẹli wá, ó sì wí pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Ìwọ rí gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun yìí? Èmi yóò fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ lónìí, nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”

14Ahabu sì béèrè pé, “Ṣùgbọ́n ta ni yóò ṣe èyí?”

Wòlíì náà sì dáhùn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Nípa ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ àwọn ìjòyè ìgbèríko.’ ”

Nígbà náà ni ó wí pé. “Ta ni yóò bẹ̀rẹ̀ ogun náà?”

Wòlíì sì dalóhùn pé, “Ìwọ ni yóò ṣe é.”

15Nígbà náà ni Ahabu ka àwọn ìjòyè kéékèèkéé ìgbèríko, wọ́n sì jẹ́ igba ó lé méjìlélọ́gbọ̀n (232). Nígbà náà ni ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tókù jọ, gbogbo wọn sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000). 16Wọ́n sì jáde lọ ní ọ̀sán gangan, nígbà tí Beni-Hadadi àti àwọn ọba méjìlélọ́gbọ̀n tí ń ràn án lọ́wọ́ ń mu àmupara nínú àgọ́. 17Àwọn ìjòyè kéékèèkéé ìgbèríko tètè kọ́ jáde lọ.

Beni-Hadadi sì ránṣẹ́ jáde, wọ́n sì sọ fún un wí pé, “Àwọn ọkùnrin ń ti Samaria jáde wá.”

18Ó sì wí pé, “Bí wọ́n bá bá ti àlàáfíà jáde wá, ẹ mú wọn láààyè; bí ti ogun ni wọ́n bá bá jáde, ẹ mú wọn láààyè.”

19Àwọn ìjòyè kéékèèkéé wọ̀nyí ti àwọn ìjòyè ìgbèríko jáde ti ìlú wá, àti ogun tí ó tẹ̀lé wọn. 20Olúkúlùkù sì pa ọkùnrin kọ̀ọ̀kan. Àwọn ará Aramu sì sá, Israẹli sì lépa wọn. Ṣùgbọ́n Beni-Hadadi ọba Aramu sì sálà lórí ẹṣin pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣin. 21Ọba Israẹli sì jáde lọ, ó sì kọlu àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́, ó pa àwọn ará Aramu ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

22Lẹ́yìn náà, wòlíì náà sì wá sọ́dọ̀ ọba Israẹli, ó sì wí pé, “Lọ, mú ara rẹ gírí, kí o sì mọ̀, kí o sì wo ohun tí ìwọ yóò ṣe, nítorí ní àmọ́dún ọba Aramu yóò tún gòkè tọ̀ ọ́ wá.”

23Àwọn ìránṣẹ́ ọba Aramu sì wí fún un pé, “Ọlọ́run wọn, ọlọ́run òkè ni. Ìdí nìyìí tí wọ́n ṣe ní agbára jù wá lọ. Ṣùgbọ́n bí a bá bá wọn jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ dájúdájú. 24Nǹkan yìí ni kí o sì ṣe: Mú àwọn ọba kúrò, olúkúlùkù kúrò ní ipò rẹ̀, kí o sì fi baálẹ̀ sí ipò wọn. 25Kí o sì tún kó ogun jọ fún ara rẹ bí èyí tí ó ti sọnù; ẹṣin fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ fún kẹ̀kẹ́; kí a bá lè bá Israẹli jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Nítòótọ́ àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ.” Ó sì gba tiwọn, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.

26Ó sì ṣe ní àmọ́dún, Beni-Hadadi ka iye àwọn ará Aramu, ó sì gòkè lọ sí Afeki, láti bá Israẹli jagun. 27Nígbà tí a sì ka àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì pèsè oúnjẹ, wọ́n sì lọ pàdé wọn. Àwọn ọmọ Israẹli sì dó ní òdìkejì wọn gẹ́gẹ́ bí agbo ọmọ ewúrẹ́ kékeré méjì, nígbà tí àwọn ará Aramu kún ilẹ̀ náà.

28Ènìyàn Ọlọ́run kan sì gòkè wá, ó sì sọ fún ọba Israẹli pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Nítorí tí àwọn ará Aramu rò pé Olúwa, Ọlọ́run òkè ni, ṣùgbọ́n òun kì í ṣe Ọlọ́run Àfonífojì, nítorí náà èmi ó fi gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yìí lé ọ lọ́wọ́, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ”

29Wọ́n sì dó sí òdìkejì ara wọn fún ọjọ́ méje, àti ní ọjọ́ keje, wọ́n pàdé ogun. Àwọn ọmọ Israẹli sì pa ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) ẹlẹ́ṣẹ̀ nínú àwọn ará Aramu ní ọjọ́ kan. 30Àwọn tókù sì sá àsálà lọ sí Afeki, sínú ìlú tí odi ti wó lù ẹgbàá-mẹ́tàlá-lé ẹgbẹ̀rún (27,000) nínú wọn. Beni-Hadadi sì sálọ sínú ìlú, ó sì fi ara pamọ́ sínú ìyẹ̀wù.

31Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, a ti gbọ́ pé àwọn ọba ilẹ̀ Israẹli jẹ́ ọba aláàánú, mo bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí àwa kí ó tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú aṣọ ọ̀fọ̀ ní ẹ̀gbẹ́ wa, àti okùn yí orí wa ká. Bóyá òun yóò gba ẹ̀mí rẹ là.”

32Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ wọn, Wọ́n sì fi okùn yí orí wọn ká, wọ́n sì tọ ọba Israẹli wá, wọ́n sì wí pé, “ìránṣẹ́ rẹ Beni-Hadadi wí pé, ‘Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí èmi kí ó yè.’ ”

Ọba sì dáhùn wí pé, “Ó ń bẹ láààyè bí? Arákùnrin mi ni òun.”

33Àwọn ọkùnrin náà sì ṣe àkíyèsí gidigidi, wọ́n sì yára gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, wọ́n sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Beni-Hadadi arákùnrin rẹ.”

Ọba sì wí pé, “Ẹ lọ mú u wá.” Nígbà tí Beni-Hadadi jáde tọ̀ ọ́ wá, Ahabu sì mú u gòkè wá sínú kẹ̀kẹ́.

34Beni-Hadadi sì wí pé, “Èmi yóò dá àwọn ìlú tí baba mi ti gbà lọ́wọ́ baba rẹ padà, ìwọ sì le la ọ̀nà fún ara rẹ ní Damasku, bí baba mi ti ṣe ní Samaria.”

Ahabu sì wí pé, “Èmi yóò rán ọ lọ pẹ̀lú májẹ̀mú yìí.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ba dá májẹ̀mú, ó sì rán an lọ.

35Nípa ọ̀rọ̀ Olúwa, ọkùnrin kan nínú àwọn ọmọ àwọn wòlíì sì wí fún èkejì rẹ̀ pé, “Jọ̀ ọ́, lù mí,” ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti lù ú.

36Nígbà náà ni ó wí pé, “Nítorí tí ìwọ kò gba ohùn Olúwa gbọ́, kíyèsi i, bí ìwọ bá kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, kìnnìún yóò pa ọ́.” Bí ó ti jáde lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kìnnìún kan rí i, ó sì pa á.

37Wòlíì náà sì rí ọkùnrin mìíràn, ó sì wí fún un pé, “Jọ̀ ọ́, lù mí.” Bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin náà sì lù ú, ó sì pa á lára. 38Wòlíì náà sì lọ, ó sì dúró de ọba ní ojú ọ̀nà. Ó pa ara rẹ̀ dà ní fífi eérú bo ojú. 39Bí ọba sì ti ń rékọjá, wòlíì náà ké sí i, ó sì wí pé, “ìránṣẹ́ rẹ jáde wọ àárín ogun lọ, ẹnìkan sì wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ìgbèkùn kan, ó sì wí pé, ‘Pa ọkùnrin yìí mọ́. Bí a bá fẹ́ ẹ kù, ẹ̀mí rẹ yóò lọ dípò ẹ̀mí rẹ̀, tàbí kí ìwọ san tálẹ́ǹtì fàdákà kan.’ 40Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ sì ní ìṣe níhìn-ín àti lọ́hùn ún, a fẹ́ ẹ kù.”

Ọba Israẹli sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ìdájọ́ rẹ yóò rí, ìwọ fúnrarẹ̀ ti dá a.”

41Nígbà náà ni wòlíì náà yára, ó sì mú eérú kúrò ní ojú rẹ̀, ọba Israẹli sì mọ̀ ọ́n pé ọ̀kan nínú àwọn wòlíì ni ó ń ṣe. 42Ó sì wí fún ọba pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Ìwọ ti jọ̀wọ́ ọkùnrin tí èmi ti yàn sí ìparun pátápátá lọ́wọ́ lọ. Nítorí náà, ẹ̀mí rẹ yóò lọ fún ẹ̀mí rẹ, ènìyàn rẹ fún ènìyàn rẹ̀.’ ” 43Ọba Israẹli sì lọ sí ilé rẹ̀ ní wíwú gbọ́, inú rẹ sì bàjẹ́, ó sì wá sí Samaria.