Romains 9 – BDS & YCB

La Bible du Semeur

Romains 9:1-33

Israël dans l’histoire du salut

Les sentiments de Paul à l’égard des Israélites

1Je dis la vérité, en tant qu’homme uni à Christ, je ne mens pas ; ma conscience, en accord avec l’Esprit Saint, me rend ce témoignage : 2j’éprouve une profonde tristesse et un chagrin continuel dans mon cœur. 3Oui, je demanderais à Dieu d’être maudit9.3 Autre traduction : Je souhaiterais être maudit. et séparé de Christ pour mes frères, nés du même peuple que moi. 4Ce sont les Israélites. C’est à eux qu’appartiennent la condition de fils adoptifs de Dieu, la manifestation glorieuse de la présence divine, les alliances9.4 Certains manuscrits ont : l’alliance., le don de la Loi, le culte et les promesses ; 5à eux les patriarches ! Et c’est d’eux qu’est issu Christ dans son humanité ; il est aussi au-dessus de tout, Dieu béni pour toujours. Amen !

Le véritable Israël selon l’élection de Dieu

6Ce n’est pas que la Parole de Dieu soit restée sans effet ! Car ce ne sont pas tous ceux qui descendent du patriarche Israël9.6 Autre traduction : tous ceux qui font partie d’Israël. qui constituent Israël ; 7et ceux qui descendent d’Abraham ne sont pas tous ses enfants. Car Dieu dit à Abraham : C’est par Isaac que te sera suscitée une descendance9.7 Gn 21.12.. 8Cela veut dire que tous les enfants de la descendance naturelle d’Abraham ne sont pas enfants de Dieu. Seuls les enfants nés selon la promesse sont considérés comme sa descendance. 9Car telle est la promesse de Dieu : Vers cette époque, je viendrai, et Sara aura un fils9.9 Gn 18.10, 14..

10Et ce n’est pas tout : Rébecca eut des jumeaux nés d’un seul et même père, de notre ancêtre Isaac. 11-12Or, Dieu a un plan qui s’accomplit selon son libre choix et qui dépend, non des actions des hommes, mais uniquement de la volonté de celui qui appelle. Et pour que ce plan demeure, c’est avant même la naissance de ces enfants, et par conséquent avant qu’ils n’aient fait ni bien ni mal, que Dieu dit à Rébecca : L’aîné sera assujetti au cadet9.11-12 Gn 25.23.. 13Ceci s’accorde avec cet autre texte de l’Ecriture : J’ai aimé Jacob, et j’ai écarté Esaü9.13 Ml 1.2-3..

Le Dieu souverain est juste

14Mais alors, que dire ? Dieu serait-il injuste ? Loin de là ! 15Car il a dit à Moïse :

Je ferai grâce à qui je veux faire grâce,

j’aurai compassion de qui je veux avoir compassion9.15 Ex 33.19..

16Cela ne dépend donc ni de la volonté de l’homme, ni de ses efforts, mais de Dieu qui fait grâce. 17Dans l’Ecriture, Dieu dit au pharaon :

Voici pourquoi je t’ai fait parvenir où tu es : pour montrer en toi ma puissance et pour que ma renommée se répande par toute la terre9.17 Ex 9.16 cité selon l’ancienne version grecque..

18Ainsi donc, Dieu fait grâce à qui il veut et il endurcit qui il veut.

19Tu vas me dire : pourquoi alors fait-il encore des reproches ? Car qui a jamais pu résister à sa volonté ? 20Mais, qui es-tu donc toi, un homme, pour critiquer Dieu ? L’ouvrage demandera-t-il à l’ouvrier : « Pourquoi m’as-tu fait ainsi9.20 Voir Es 45.9.? » 21Le potier n’a-t-il pas le droit, à partir du même bloc d’argile, de fabriquer un pot d’usage noble et un autre pour l’usage courant ?

22Et qu’as-tu à redire si Dieu, parce qu’il voulait montrer sa colère et faire connaître sa puissance, a supporté avec une immense patience ceux qui étaient les objets de sa colère, tout prêts9.22 Autre traduction : préparés pour. pour la destruction ? 23Oui, qu’as-tu à redire si Dieu a agi ainsi pour manifester la richesse de sa gloire en faveur de ceux qui sont les objets de sa compassion, ceux qu’il a préparés d’avance pour la gloire ?

Pour les Juifs et pour les non-Juifs

24C’est nous qui sommes les objets de sa compassion, nous qu’il a appelés non seulement d’entre les Juifs, mais aussi d’entre les non-Juifs. 25C’est ce qu’il dit dans le livre du prophète Osée :

Celui qui n’était pas mon peuple,je l’appellerai « mon peuple ».

Celle qui n’était pas la bien-aimée,je la nommerai « bien-aimée »9.25 Os 2.25..

26Au lieu même où on leur avait dit : « Vous n’êtes pas mon peuple », on leur dira alors : « Vous êtes les enfants du Dieu vivant9.26 Os 2.1 ; 1.9.. »

27Et pour ce qui concerne Israël, Esaïe déclare de son côté :

Même si les descendants d’Israëlétaient aussi nombreux que les grains de sable au bord de la mer,

seul un reste sera sauvé.

28Car pleinement et promptement9.28 Autre traduction : de façon décisive.,le Seigneur accomplira sa parole sur la terre9.28 Es 10.22-23 cité selon l’ancienne version grecque..

29Et comme Esaïe l’avait dit par avance :

Si le Seigneur des armées célestesne nous avait laissé des descendants,

nous ressemblerions à Sodome,

nous serions comme Gomorrhe9.29 Es 1.9 cité selon l’ancienne version grecque. Sodome… Gomorrhe: deux villes qui ont subi un terrible jugement de la part de Dieu (Gn 19.23-28)..

Etre juste : par la foi et non par la Loi

30Que dire maintenant ? Voici ce que nous disons : les païens qui ne cherchaient pas à être déclarés justes par Dieu ont saisi cette justice, mais il s’agit de la justice qui est reçue par la foi. 31Les Israélites, eux, qui cherchaient à être déclarés justes en obéissant à une loi, n’y sont pas parvenus9.31 Autre traduction : n’ont pas trouvé une Loi par laquelle ils auraient pu être déclarés justes.. 32Pour quelle raison ? Parce qu’ils ont cherché à être déclarés justes non pas en comptant sur la foi, mais comme si la justice pouvait provenir de la pratique de la Loi. Ils ont buté contre la pierre qui fait tomber, 33conformément à ce que dit l’Ecriture :

Moi, je place en Sionune pierre qu’on heurte,

un rocher qui fait trébucher.

Celui qui met en lui sa confiancene connaîtra jamais le déshonneur9.33 Es 8.14 ; 28.16 cités selon l’ancienne version grecque..

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Romu 9:1-33

Ọlọ́run yan Israẹli

1Òtítọ́ ni èmi ń sọ nínú Kristi, èmi kò ṣèké, ọkàn mi sì ń jẹ́ mi ní ẹ̀rí nínú Ẹ̀mí Mímọ́. 2Pé mo ní ìbìnújẹ́ púpọ̀, àti ìkáàánú ìgbà gbogbo ni ọkàn mi. 39.3: Ek 32.32.Nítorí mo fẹ́rẹ lè gbàdúrà pé kí èmi tìkára mi kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí àwọn ará mi, àwọn ìbátan mi nípa ti ara. 49.4: Ro 3.2; 8.15.Àwọn ẹni tí i ṣe Israẹli; tí àwọn ẹni tí ìsọdọmọ í ṣe, àti ògo, àti májẹ̀mú, àti ìfúnilófin, àti ìsìn Ọlọ́run, àti àwọn ìlérí. 5Tí ẹni tí àwọn Baba í ṣe, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni tí Kristi ti wá nípa ti ara, ẹni tí ó borí ohun gbogbo, Ọlọ́run olùbùkún láéláé. Àmín.

69.6: Ro 2.28-29.Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán. Kì í sá í ṣe gbogbo àwọn tí ó ti inú Israẹli wá, àwọn ni Israẹli: 79.7: Gẹ 21.12; Hb 11.18.Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn ni ọmọ: Ní ọ̀nà mìíràn, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀.” 89.8: Ga 3.29; 4.28.Èyí nì ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ nípa ti ara, ni ọmọ Ọlọ́run: ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìlérí ni a kà ní irú-ọmọ. 99.9: Gẹ 18.10.Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí: “Ní ìwòyí àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sara yóò sì ní ọmọ ọkùnrin.”

109.10: Gẹ 25.21.Kì í sì í ṣe kìkì èyí; Ṣùgbọ́n nígbà tí Rebeka pẹ̀lú lóyún fún ẹnìkan, fún Isaaki baba wa. 11Nítorí nígbà tí kò tí ì bí àwọn ọmọ náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tí ì ṣe rere tàbí búburú—kí ìpinnu Ọlọ́run nípa ti ìyànfẹ́ kí ó lè dúró, 129.12: Gẹ 25.23.kì í ṣe nípa ti iṣẹ́, bí kò ṣe ti ẹni tí ń peni—a ti sọ fún un pé, “Ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.” 139.13: Ml 1.2-3.Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Jakọbu ni mo fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Esau ni mo kórìíra.”

149.14: 2Ki 19.7.Ǹjẹ́ àwa yóò ha ti wí? Àìṣòdodo ha wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run bí? Kí a má ri! 159.15: Ek 33.19.Nítorí ó wí fún Mose pé,

“Èmi ó ṣàánú fún ẹni tí èmi yóò ṣàánú fún,

èmi yóò sì ṣe ìyọ́nú fún ẹni tí èmi yóò ṣe ìyọ́nú fún.”

16Ǹjẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ti ẹni tí ó fẹ́, kì í sì í ṣe ti ẹni tí ń sáré, bí kò ṣe ti Ọlọ́run tí ń ṣàánú. 179.17: Ek 9.16.Nítorí ìwé mímọ́ wí fún Farao pé, “Nítorí èyí náà ni mo ṣe gbé ọ dìde, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé.” 189.18: Ro 11.7.Nítorí náà ni ó ṣe ń ṣàánú fún ẹni tí ó wù ú, ẹni tí ó wù ú a sì mú ní ọkàn le.

19Ìwọ ó sì wí fún mi pé, “Kín ni ó ha tún bá ni wí sí? Nítorí ta ni ó ń de ìfẹ́ rẹ lọ́nà?” 209.20: Isa 29.16; 45.9.Bẹ́ẹ̀ kọ́, ìwọ ènìyàn, tà ni ìwọ tí ń dá Ọlọ́run lóhùn? “Ohun tí a mọ, a ha máa wí fún ẹni tí ó mọ ọ́n pé, ‘Èéṣe tí ìwọ fi mọ mi báyìí?’ ” 219.21: 2Tm 2.20.Amọ̀kòkò kò ha ni agbára lórí amọ̀, nínú ìṣù kan náà láti ṣe apá kan nínú ohun èlò sí ọlá, àti apá kan nínú ohun èlò sí àìlọ́lá?

229.22: Òw 16.4.Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá fẹ́ fi ìbínú rẹ̀ hàn ńkọ́? Tí ó sì fẹ́ sọ agbára rẹ̀ di mí mọ̀, tí ó sì mú sùúrù púpọ̀ fún àwọn ohun èlò ìbínú tí a ṣe fún ìparun; 239.23: Ro 8.29.Àti kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ di mí mọ̀ lára àwọn ohun èlò àánú tí ó ti pèsè ṣáájú fún ògo, 249.24: Ro 3.29.Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn Kèfèrí pẹ̀lú? 259.25: Ho 2.23; 1Pt 2.10.Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hosea pé,

“Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ènìyàn mi,

àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní àyànfẹ́.”

269.26: Ho 1.10.Yóò sì ṣe,

“Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé,

‘ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’

níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ ”

279.27: Isa 10.22-23; Gẹ 22.17; Ho 1.10; Ro 11.5; 2Ọb 19.4; Isa 11.11.Isaiah sì kígbe nítorí Israẹli pé:

“Bí iye àwọn ọmọ Israẹli bá rí bí iyanrìn Òkun,

apá kan ni ó gbàlà.

28Nítorí Olúwa yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé,

yóò parí rẹ̀, yóò sì ké e kúrò ní òdodo.”

299.29: Isa 1.9.Àti bí Isaiah ti wí tẹ́lẹ̀:

“Bí kò ṣe bí Olúwa àwọn Ọmọ-ogun

ti fi irú-ọmọ sílẹ̀ fún wa,

àwa ìbá ti dàbí Sodomu,

a bá sì ti sọ wá dàbí Gomorra.”

309.30: Ro 3.22; 10.6,20; Ga 2.16; 3.24; Fp 3.9; Hb 11.7.Ǹjẹ́ kí ni àwa ó ha wí? Pé àwọn Kèfèrí, tí kò lépa òdodo, ọwọ́ wọn tẹ òdodo, ṣùgbọ́n òdodo tí ó ti inú ìgbàlà wá ni. 319.31: Isa 51.1; Ro 10.2-3; 11.7.Ṣùgbọ́n Israẹli ti ń lépa òfin òdodo, ọwọ́ wọn kò tẹ òfin òdodo. 329.32: 1Pt 2.8.Nítorí kí ni? Nítorí wọn kò wá a nípa ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni pé nípa iṣẹ́ òfin. Nítorí wọn kọsẹ̀ lára òkúta ìkọ̀sẹ̀ ni; 339.33: Isa 28.16; Ro 10.11.Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Kíyèsi, mo gbé òkúta ìkọ̀sẹ̀ kalẹ̀ ní Sioni

àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú,

ẹnikẹ́ni ti ó bá sì gbà a gbọ́, ojú kì yóò tì í.”