Daniel 5 – BDS & YCB

La Bible du Semeur

Daniel 5:1-30

L’inscription sur le mur

Un festin sacrilège

1Un jour, le roi Balthazar5.1 Les événements de ce chapitre ont lieu en 539 av. J.-C., 23 ans après la mort de Nabuchodonosor (en 562 av. J.-C.). Balthazar était le fils du dernier roi de Babylone, Nabonide. Il a exercé le pouvoir à la place de son père pendant les dix dernières années de son règne, alors que Nabonide s’était retiré à Téma, une oasis de la péninsule Arabique. Aux v. 2, 11, 18, Nabuchodonosor est appelé son père, ce qui pouvait désigner en araméen soit la succession au trône soit la descendance physique. Il semble, en fait, que Balthazar ait été le petit-fils de Nabuchodonosor par sa mère ou par sa grand-mère – la femme ou la mère de Nabonide (voir 5.10 et note ; Jr 27.7). organisa un banquet en l’honneur de ses mille dignitaires et se mit à boire du vin en leur présence. 2Excité par le vin, Balthazar ordonna d’apporter les coupes d’or et d’argent que Nabuchodonosor, son père5.2 Voir v. 1 et note, 11, 18 ; Jr 27.7., avait rapportées du temple de Jérusalem5.2 Voir 1.2 ; 2 R 25.14-15.. Il voulait s’en servir pour boire, lui et ses hauts dignitaires, ses femmes et ses concubines5.2 Le sens de ces deux mots est incertain. On a retrouvé le second dans les papyrus d’Eléphantine en Egypte, datant du ve siècle av. J.-C., avec le sens de femmes de service.. 3Aussitôt, on apporta les coupes d’or qui avaient été prises dans le temple de Dieu à Jérusalem, et le roi, ses hauts dignitaires, ses femmes et ses concubines s’en servirent pour boire. 4Ils burent et se mirent à louer les dieux d’or, d’argent, de bronze, de fer, de bois et de pierre.

Une main mystérieuse

5A ce moment-là apparurent soudain, devant le candélabre, les doigts d’une main humaine qui se mirent à écrire sur le plâtre du mur du palais royal. Le roi vit cette main qui écrivait. 6Alors son visage devint blême, des pensées terrifiantes l’assaillirent, il se mit à trembler de tout son être et ses genoux s’entrechoquèrent. 7Il ordonna à grands cris de faire venir les magiciens, les astrologues et les devins, et il dit aux sages : Celui qui déchiffrera cette inscription et m’en donnera l’interprétation sera revêtu de pourpre, on lui mettra une chaîne d’or au cou et il partagera le gouvernement du royaume avec deux autres hauts fonctionnaires5.7 il partagera… fonctionnaires. Certains traduisent : il occupera le troisième rang dans le gouvernement du royaume (après Nabonide et Balthazar), mais l’araméen signifie plutôt : « il gouvernera le royaume au sein d’un triumvirat » (voir 6.3)..

8Tous les sages du roi entrèrent dans la salle, mais aucun d’eux ne put déchiffrer l’inscription, ni en faire connaître l’interprétation au roi. 9Alors le roi Balthazar fut encore plus effrayé, il pâlit davantage et ses hauts dignitaires se trouvèrent dans une grande confusion.

10Quand la reine mère5.10 Selon certains, elle serait fille de Nabuchodonosor, mariée à Nabonide. Les reines mères avaient une grande influence dans les cours du Moyen-Orient. entendit ce que disaient le roi et ses hauts dignitaires, elle pénétra dans la salle du festin. Elle prit la parole et dit : Que le roi vive éternellement ! Ne te laisse pas terrifier par tes pensées et que ton visage ne pâlisse pas ainsi ! 11Il y a, dans ton royaume, un homme en qui réside l’esprit des dieux saints ; du temps de ton père5.11 Voir 5.1 et note., on trouva en lui une clairvoyance, une intelligence et une sagesse pareilles à la sagesse des dieux, aussi le roi Nabuchodonosor, ton père, l’a-t-il établi chef des mages, des magiciens, des astrologues et des devins. 12Car cet homme, Daniel, que le roi a nommé Beltshatsar, possède un esprit extraordinaire, de la connaissance et de l’intelligence pour interpréter les rêves, trouver la solution des énigmes et résoudre les problèmes difficiles. Que l’on appelle donc Daniel et il donnera l’interprétation.

Daniel explique l’énigme

13Aussitôt, Daniel fut introduit en présence du roi. Celui-ci prit la parole et lui dit : Es-tu ce Daniel qui fait partie des exilés de Juda, que le roi, mon père, a amenés de Juda ? 14J’ai entendu dire que l’esprit des dieux réside en toi et que tu possèdes une clairvoyance, une intelligence et une sagesse extraordinaires. 15Or, on vient de m’amener les sages et les magiciens pour lire cette inscription et m’en faire connaître l’interprétation ; mais ils n’en ont pas été capables. 16On m’a dit que toi, tu peux donner des interprétations et résoudre les problèmes difficiles. Si donc tu es capable de lire cette inscription et de m’en faire connaître l’interprétation, tu seras revêtu de pourpre, tu porteras une chaîne d’or au cou et tu partageras le gouvernement du royaume avec deux autres hauts fonctionnaires5.16 Voir note v. 7..

17Alors Daniel prit la parole et dit au roi : Garde tes présents et donne tes cadeaux à un autre ! Je vais cependant te déchiffrer l’inscription et t’en faire connaître l’interprétation. 18O roi, le Dieu très-haut avait donné à Nabuchodonosor, ton père, la royauté et la grandeur, la gloire et la majesté. 19Et à cause de la grandeur qu’il lui avait accordée, les gens de tous peuples, de toutes nations et de toutes langues tremblaient de peur devant lui. La vie et la mort de chacun dépendaient de son bon vouloir ; il élevait et abaissait qui il lui plaisait. 20Mais lorsque son cœur s’enorgueillit et qu’il s’endurcit jusqu’à l’arrogance, on lui fit quitter son trône royal et il fut dépouillé de sa gloire. 21Il fut chassé de la société des humains, sa raison devint semblable à celle des bêtes et il se mit à vivre en compagnie des ânes sauvages, on le nourrissait d’herbe comme les bœufs et son corps était trempé par la rosée du ciel. Cela dura jusqu’au jour où il reconnut que le Dieu très-haut est maître de toute royauté humaine et qu’il élève à la royauté qui il veut.

22Et toi, son fils, Balthazar, tu savais tout cela, et cependant tu n’as pas adopté une attitude humble. 23Tu t’es élevé contre le Seigneur du ciel et tu t’es fait apporter les coupes de son temple, puis toi et tes hauts dignitaires, tes femmes et tes concubines5.23 Voir note v. 2., vous y avez bu du vin et tu as loué les dieux d’argent, d’or, de bronze, de fer, de bois et de pierre, des dieux qui ne voient rien, n’entendent rien et ne savent rien. Mais le Dieu qui tient ton souffle de vie dans sa main et de qui dépend toute ta destinée, tu ne l’as pas honoré. 24C’est pourquoi il a envoyé ce tronçon de main pour tracer cette inscription.

25Voici l’inscription qui a été tracée là : « Il a été compté : une mine, un sicle et deux demi-sicles5.25 Il a été compté: …sicles. En araméen : Mené, mené, téqel, et parsin. Les deux premiers termes sont des homonymes : il vaut mieux considérer le premier mené comme une forme du verbe compter ; les trois autres termes sont des noms de monnaies. A partir de ces trois noms de monnaies, Daniel délivre un triple message, en procédant par jeux de mots avec ces noms (v. 26-28) ; ainsi le nom de la mine est homonyme à la formule verbale : il a été compté. Le nom du sicle fait jeu avec le verbe peser. Le nom du demi-sicle fait jeu à la fois avec le verbe diviser et avec le nom des Perses ; autre traduction pour demi-sicles: demi-mines.. »

26Et voici l’interprétation : « une mine » : Dieu a « compté » les années de ton règne et les a menées à leur terme.

27« Un sicle » : Tu as été « pesé » dans la balance et l’on a trouvé que tu ne fais pas le poids.

28« Deux demi-sicles » : Ton royaume a été « divisé » pour être livré aux Mèdes et aux Perses.

29Alors Balthazar ordonna de revêtir Daniel de pourpre, de lui mettre une chaîne d’or au cou et de faire proclamer qu’il partagerait le gouvernement du royaume avec deux autres hauts fonctionnaires5.29 Voir v. 7 et note..

30Mais, dans la même nuit, Balthazar, roi des Chaldéens, fut tué.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Daniẹli 5:1-31

Àkọsílẹ̀ ara ògiri

1Belṣassari, ọba ṣe àsè ńlá fún ẹgbẹ̀rún (1,000) kan nínú àwọn ọlọ́lá rẹ̀, ó sì mu wáìnì pẹ̀lú u wọn. 2Bí Belṣassari ṣe ń mu wáìnì, ó pàṣẹ pé kí wọn kó kọ́ọ̀bù wúrà àti ti fàdákà wá, èyí tí Nebukadnessari baba rẹ̀ kó wá láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu, kí ọba àti àwọn ọlọ́lá rẹ̀, àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀ kí ó ba à le fi mu wáìnì. 3Wọ́n sì kó kọ́ọ̀bù wúrà àti fàdákà àti fàdákà èyí tí wọ́n kó jáde láti inú tẹmpili, ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀, sì fi mu wáìnì. 4Bí wọ́n ṣe ń mu wáìnì bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń yin òrìṣà wúrà àti fàdákà, ti idẹ, irin, igi àti òkúta.

5Lójijì, ìka ọwọ́ ènìyàn jáde wá, ó sì ń kọ̀wé sára ẹfun ògiri ní ẹ̀gbẹ́ ibi tí fìtílà ń dúró ní ààfin ọba. Ọba ń wo ọwọ́ náà bí ó ṣe ń kọ ọ́. 6Ojú ọba sì yí padà, ẹ̀rù sì bà á, tó bẹ́ẹ̀ tí orúnkún ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì rẹ̀ fi ń gbá ara wọn.

7Ọba kígbe pé, kí wọn pe àwọn awòràwọ̀, àwọn onídán, àti àwọn aláfọ̀ṣẹ wá, ọba sì sọ fún àwọn amòye Babeli pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lè ka àkọsílẹ̀ yìí kí ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, ẹni náà ni a ó fi aṣọ elése àlùkò wọ̀ àti ẹ̀gbà wúrà ni a ó fi sí ọrùn un rẹ̀, òun ni yóò sì ṣe olórí kẹta ní ìjọba à mi.”

8Nígbà náà ni gbogbo àwọn amòye ọba wọ ilé, ṣùgbọ́n, wọn kò le è ka àkọsílẹ̀ náà tàbí sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba. 9Nígbà náà ni Belṣassari ọba bínú gidigidi, ojú u rẹ̀ sì túbọ̀ dàrú sí i. Ẹ̀rù sì ba àwọn ìjòyè Belṣassari.

10Nígbà tí ayaba gbọ́ ohùn ọba àti àwọn ọlọ́lá rẹ̀, ó wá ilé àsè wá. Ó wí pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! Má ṣe jẹ́ kí inú rẹ bàjẹ́, má sì ṣe jẹ́ kí ojú u rẹ fàro. 11Ọkùnrin kan wà ní ìjọba à rẹ, ẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run, mímọ́ ń gbé inú rẹ̀. Ní ìgbà ayé e baba à rẹ, òun ni ó ní ojú inú, òye àti ìmọ̀ bí i ti Ọlọ́run òun ni ọba Nebukadnessari, baba rẹ̀ fi jẹ olórí àwọn apidán, awòràwọ̀, apògèdè àti aláfọ̀ṣẹ. 12Ọkùnrin náà ni Daniẹli ẹni tí ọba ń pè ní Belṣassari, ó ní ẹ̀mí tí ó tayọ, ìmọ̀ àti òye, àti agbára láti túmọ̀ àlá, ó máa ń ṣe àlàyé àlá àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá da ojú rú, ránṣẹ́ pè é, yóò sì sọ nǹkan tí àkọsílẹ̀ ìwé náà túmọ̀ sí.”

13Nígbà náà ni a mú Daniẹli wá síwájú ọba, ọba sì sọ fún un wí pé, “Ṣé ìwọ ni Daniẹli, ọ̀kan lára àwọn tí baba mi mú ní ìgbèkùn láti Juda! 14Mo ti gbọ́ wí pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú rẹ àti wí pé ìwọ ní ojú inú, òye, àti ọgbọ́n tí ó tayọ. 15A ti mú àwọn amòye àti àwọn awòràwọ̀ wá sí iwájú mí kí wọn ba à le è wá ka àkọsílẹ̀ yìí kí wọn sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n wọn kò le è sọ ìtumọ̀ ohun tí ó jẹ́. 16Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ wí pé, ìwọ lè sọ ìtumọ̀, àti wí pé o lè yanjú àwọn ìṣòro tó lágbára. Tí o bá lè ka àkọsílẹ̀ ìwé yìí kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, a ó fi aṣọ elése àlùkò wọ̀ ọ́ pẹ̀lú ẹ̀gbà wúrà ni a ó fi sí ọ lọ́rùn, a ó sì fi ọ́ ṣe olórí kẹta ní ìjọba mi.”

17Nígbà náà ni Daniẹli dá ọba lóhùn wí pé, “Fi ẹ̀bùn rẹ pamọ́ fún ara rẹ, tàbí kí o fún ẹlòmíràn. Síbẹ̀ èmi yóò ka àkọsílẹ̀ náà fún ọba, èmi yóò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.

18“Ìwọ ọba, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo fún Nebukadnessari baba rẹ ní ìjọba, títóbi ògo àti ọlá. 19Nítorí ipò ńlá tí a fi fún un, gbogbo ènìyàn orílẹ̀-èdè àti èdè gbogbo fi ń páyà tí wọ́n sì ń bẹ̀rù rẹ̀. Ó ń pa àwọn tí ó bá wù ú, ó sì ń dá àwọn tí ó bá wù ú sí, ó ń gbé àwọn tí ó bá wù ú ga, ó sì ń rẹ àwọn tí ó bá wù ú sílẹ̀. 20Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn rẹ̀ ga, tí ó sì le koko. Ó bẹ̀rẹ̀ sí i hùwà ìgbéraga, a mú u kúrò lórí ìtẹ́ ọba rẹ̀, a sì gba ògo rẹ̀ kúrò. 21A lé e kúrò láàrín ènìyàn, a sì fún un ní ọkàn ẹranko; ó sì ń gbé pẹ̀lú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì ń jẹ koríko bí i ti màlúù; ìrì ọ̀run ṣì sẹ̀ sí ara rẹ̀, títí tó fi mọ̀ pé, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ń jẹ ọba lórí ìjọba ọmọ ènìyàn, òun sì ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú.

22“Ṣùgbọ́n ìwọ ọmọ rẹ̀, Belṣassari, ìwọ kò rẹ ara à rẹ sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ mọ nǹkan wọ̀nyí. 23Dípò èyí, ìwọ gbé ara à rẹ ga sí Olúwa ọ̀run, a mú ohun èlò inú tẹmpili rẹ̀ wá sí iwájú rẹ, ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ, àwọn ìyàwó ò rẹ àti àwọn àlè rẹ fi ń mu wáìnì. Ìwọ ń yin àwọn òrìṣà fàdákà àti wúrà, idẹ, irin, igi àti ti òkúta, èyí tí kò lè ríran, tí kò le è gbọ́rọ̀ tàbí ní òye nǹkan kan. Ṣùgbọ́n ìwọ kò bu ọlá fún Ọlọ́run ẹni tó ni ẹ̀mí rẹ lọ́wọ́, tí ó sì mọ gbogbo ọ̀nà rẹ. 24Nítorí náà, ó rán ọwọ́ tí ó kọ àkọlé yìí.

25“Èyí ni àkọlé náà tí a kọ:

mene, mene, tekeli, peresini

26“Èyí ni nǹkan tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí:

Mene: Ọlọ́run ti ṣírò ọjọ́ ìjọba rẹ. Ó sì ti mú u wá sí òpin.

27Tekeli: A ti gbé ọ lórí òṣùwọ̀n, ìwọ kò sì tó ìwọ̀n.

28“Peresini: A ti pín ìjọba rẹ a sì ti fi fún àwọn Media àti àwọn Persia.”

29Nígbà náà ni Belṣassari pàṣẹ pé kí a wọ Daniẹli ní aṣọ elése àlùkò, kí a sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn, a sì kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí kẹta ní ìjọba rẹ̀.

30Ní alẹ́ ọjọ́ náà ni a pa Belṣassari, ọba àwọn ara Kaldea. 31Dariusi ará Media sì gba ìjọba nígbà tí ó di ọmọ ọdún méjìlélọ́gọ́ta.