2 Chroniques 9 – BDS & YCB

La Bible du Semeur

2 Chroniques 9:1-31

La visite de la reine de Saba

(1 R 10.1-13)

1La reine de Saba9.1 Sur la reine de Saba, voir note 1 R 10.1. Cf. Mt 12.42 ; Lc 11.31., ayant entendu parler de la réputation que Salomon avait acquise, vint à Jérusalem pour éprouver sa sagesse en lui posant des questions difficiles. Elle avait une suite importante et des chameaux chargés d’épices, de parfums, d’or en grande quantité et de pierres précieuses. Elle se présenta devant Salomon et parla avec lui de tout ce qu’elle avait sur le cœur. 2Salomon lui expliqua tout ce qu’elle demandait ; rien n’était trop difficile pour Salomon, il n’y avait aucun sujet sur lequel il ne pouvait lui donner de réponse.

3La reine de Saba constata combien Salomon était rempli de sagesse, elle vit le palais qu’il avait construit, 4les mets de sa table, le logement de ses serviteurs, l’organisation de leur service, leur livrée, ceux qui servaient à manger et à boire et leur tenue, et les holocaustes qu’il offrait dans le temple de l’Eternel. Elle en perdit le souffle 5et elle dit au roi : C’est donc bien vrai ce que j’avais entendu dire dans mon pays au sujet de tes propos et de ta sagesse ! 6Je ne croyais pas ce qu’on disait à ton sujet, avant d’être venue ici et de l’avoir vu de mes propres yeux. Et voici qu’on ne m’a pas raconté la moitié de l’ampleur de ta sagesse. Tu surpasses tout ce que j’avais entendu dire. 7Qu’ils en ont de la chance, tous ceux qui t’entourent et qui sont toujours en ta présence, de pouvoir profiter sans cesse de ta sagesse ! 8Béni soit l’Eternel, ton Dieu, qui t’a témoigné sa faveur en te plaçant sur son trône afin que tu sois roi pour lui, l’Eternel, ton Dieu ! C’est à cause de son amour pour Israël, et pour que ce peuple subsiste pour toujours que ton Dieu t’a établi roi sur ce peuple pour que tu le gouvernes avec justice et équité.

9Ensuite, la reine fit cadeau au roi de trois tonnes et demie d’or, d’une très grande quantité de parfums et d’épices, et de pierres précieuses. Il n’y a plus eu de parfums et d’épices comparables à ceux que la reine de Saba offrit au roi Salomon.

10De plus, les équipages de Hiram et ceux de Salomon qui importaient de l’or d’Ophir ramenèrent aussi de là-bas du bois de santal9.10 Bois précieux importé par les Phéniciens., et des pierres précieuses. 11Le roi utilisa le bois de santal pour faire des escaliers pour le temple de l’Eternel et pour le palais royal, ainsi que des lyres et des luths pour les musiciens. Jamais on n’avait rien vu de pareil auparavant dans le pays de Juda. 12Le roi Salomon donna à la reine de Saba tout ce qu’elle désirait et ce qu’elle demandait – incomparablement plus que ce qu’elle avait apporté au roi. Après cela, elle s’en retourna dans son pays, accompagnée de ses serviteurs.

La richesse de Salomon

(1 R 10.14-29 ; 2 Ch 1.14-17)

13Chaque année, Salomon recevait vingt tonnes d’or, 14sans compter le produit des taxes payées par les importateurs et les marchands ainsi que les tributs versés par tous les rois d’Arabie et les impôts perçus par les gouverneurs du pays qui apportaient de l’or et de l’argent à Salomon. 15Le roi Salomon fit fabriquer deux cents grands boucliers d’or battu, pour lesquels on employa six kilogrammes d’or par pièce, 16et trois cents petits boucliers d’or battu pour chacun desquels on employa trois kilogrammes d’or. Le roi les fit placer dans le palais de la Forêt-du-Liban9.16 Voir 1 R 7.2 et note.. 17Il fit aussi fabriquer un grand trône d’ivoire plaqué d’or pur. 18Six marches y conduisaient, un marchepied en or y était fixé, et il y avait des accoudoirs de part et d’autre du siège, avec, à côté d’eux, deux lions sculptés. 19Douze lions se tenaient debout de part et d’autre des six marches. Rien de semblable n’existait dans aucun royaume. 20Tout le service à boisson du roi Salomon était en or, et toute la vaisselle du palais de la Forêt-du-Liban en or fin. Car, du temps du roi Salomon, l’argent était considéré comme un métal sans grande valeur. 21En effet, le roi disposait d’une flotte de navires au long cours qui naviguaient avec les marins de Hiram, et qui, tous les trois ans, revenaient chargés d’or, d’argent, d’ivoire, de singes et de paons.

Conclusion : richesse et sagesse de Salomon

22Le roi Salomon surpassa tous les rois de la terre par sa richesse et sa sagesse. 23Tous les rois de la terre cherchaient à le rencontrer pour se mettre à l’écoute de la sagesse que Dieu lui avait donnée. 24Et chaque année, ces visiteurs lui apportaient leurs présents : des objets d’argent et d’or, des vêtements, des armes, des épices et des parfums, des chevaux et des mulets. 25Salomon avait quatre mille écuries pour les chevaux et les chars et douze mille hommes d’équipage pour ses chars. Il les cantonna dans des villes de garnison, ainsi qu’auprès de lui à Jérusalem9.25 Voir 2 Ch 1.14.. 26Salomon dominait sur tous les rois de la région s’étendant depuis l’Euphrate jusqu’au pays des Philistins et jusqu’à la frontière d’Egypte9.26 Voir Gn 15.18.. 27Le roi rendit l’argent aussi commun à Jérusalem que les pierres, et les cèdres aussi nombreux que les sycomores qui croissent dans la plaine côtière le long de la Méditerranée. 28Des chevaux étaient importés d’Egypte pour Salomon et de tous les autres pays.

La fin du règne de Salomon

(1 R 11.41-43)

29Les autres faits et gestes de Salomon, des premiers aux derniers, sont cités dans les Actes du prophète Nathan, dans la prophétie d’Ahiya de Silo et dans les Révélations du prophète Yéedo au sujet de Jéroboam, fils de Nebath. 30Salomon régna quarante ans à Jérusalem sur tout Israël. 31Puis il rejoignit ses ancêtres décédés et on l’enterra dans la Cité de David, son père. Son fils Roboam lui succéda sur le trône.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 9:1-31

Ọbabìnrin Ṣeba bẹ Solomoni wò

19.1-28: 1Ọb 10.1-29.Nígbà tí ayaba Ṣeba gbọ́ nípa òkìkí Solomoni, ó sì wá sí Jerusalẹmu láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè tí ó le. Ó dé pẹ̀lú ẹgbẹ́ ńlá kan pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye wúrà, àti òkúta iyebíye, ó wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn rẹ̀. 2Solomoni sì dá a lóhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyíkéyìí tí kò lè ṣe àlàyé fún. 3Nígbà tí ayaba Ṣeba rí ọgbọ́n Solomoni àti pẹ̀lú ilé tí ó ti kọ́, 4oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì rẹ̀, àti ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti dídúró àwọn ìránṣẹ́ nínú aṣọ wọn, àti àwọn agbọ́tí nínú aṣọ wọn àti ẹbọ sísun tí ó ṣe ní ilé Olúwa, ó sì dá a lágara fún ìyàlẹ́nu.

5Ó sì wí fún ọba pé, “Ìròyìn tí mo gbọ́ ní ìlú mi nípa iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ, òtítọ́ ni. 6Ṣùgbọ́n èmi kò gba ohun tí wọ́n sọ gbọ́ àyàfi ìgbà tí mó dé ibí tí mo sì ri pẹ̀lú ojú mi. Nítòótọ́, kì í tilẹ̀ ṣe ìdájọ́ ìdajì títóbi ọgbọ́n rẹ ní a sọ fún mi: ìwọ ti tàn kọjá òkìkí tí mo gbọ́. 7Báwo ni inú àwọn ọkùnrin rẹ ìbá ṣe dùn tó! Báwo ní dídùn inú àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn tí n dúró nígbà gbogbo níwájú rẹ láti gbọ́ ọgbọ́n rẹ! 8Ìyìn ló yẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ní inú dídùn nínú rẹ tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ láti jẹ ọba fún Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run rẹ fún Israẹli láti fi ìdí wọn kalẹ̀ láéláé, ó sì ti fi ọ́ ṣe ọba lórí wọn, láti ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́.”

9Nígbà náà ni ó sì fún ọba ní ọgọ́fà tálẹ́ǹtì wúrà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye tùràrí, àti òkúta iyebíye. Kò sì tí ì sí irú tùràrí yí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ayaba Ṣeba fi fún ọba Solomoni.

10Àwọn ènìyàn Hiramu àti àwọn ọkùnrin Solomoni gbé wúrà wá láti Ofiri, wọ́n sì tún gbé igi algumu pẹ̀lú àti òkúta iyebíye wá. 11Ọba sì lo igi algumu náà láti fi ṣe àtẹ̀gùn fún ilé Olúwa àti fún ilé ọba àti láti fi ṣe dùùrù àti ohun èlò orin olókùn fún àwọn akọrin. Kò sì ṣí irú rẹ̀ tí a ti rí rí ní ilẹ̀ Juda.

12Ọba Solomoni fún ayaba Ṣeba ní gbogbo ohun tí ó béèrè fún àti ohun tí ó wù ú; ó sì fi fún un ju èyí tí ó mú wá fún un lọ. Nígbà náà ni ó lọ ó sì padà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìlú rẹ̀.

Dídán Solomoni

13Ìwọ̀n wúrà tí Solomoni gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó-lé-mẹ́fà tálẹ́ǹtì, 14Láì tí ì ka àkójọpọ̀ owó ìlú tí ó wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò àti àwọn ọlọ́jà. Àti pẹ̀lú gbogbo àwọn ọba Arabia àti àwọn baálẹ̀ ilẹ̀ náà mu wúrà àti fàdákà wá fún Solomoni.

15Ọba Solomoni sì ṣe igba àṣà wúrà lílù: ẹgbẹ̀ta (6,000) asà tí a fi òlùlù wúrà sí ọ̀kánkán ṣékélì. 16Ó sì ti ṣe ọ̀ọ́dúnrún (300) kékeré ṣékélì tí a fi òlùlù wúrà, pẹ̀lú ọ̀ọ́dúnrún (3,000) ṣékélì wúrà nínú àpáta kọ̀ọ̀kan. Ọba sì kó wọn sínú ààfin ti ó wà ní igbó Lebanoni.

17Nígbà náà ọba sì ṣe ìtẹ́ pẹ̀lú eyín erin ńlá kan ó sì fi wúrà tó mọ́ bò ó. 18Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, àti pẹ̀lú àpótí ìtìsẹ̀ wúrà kan ni a dè mọ́ ọn. Ní ìhà méjèèjì ibi ìjókòó ní ó ní ìgbọ́wọ́lé, pẹ̀lú kìnnìún tí ó dúró lẹ́bàá olúkúlùkù wọn. 19Kìnnìún méjìlá dúró lórí àtẹ̀gùn mẹ́ta, ọ̀kan àti ní ìhà olúkúlùkù àtẹ̀gùn kò sì sí irú rẹ̀ tí a ti ṣe rí fún ìjọba mìíràn. 20Gbogbo ohun èlò mímú ìjọba Solomoni ọba ni ó jẹ́ kìkì wúrà, àti gbogbo ohun èlò ààfin ní igbó Lebanoni ni ó jẹ́ wúrà mímọ́. Kò sì ṣí èyí tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ Solomoni. 21Ọba ní ọkọ̀ tí a fi ń tajà tí àwọn ọkùnrin Hiramu ń bojútó. Ẹ̀ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ó máa ń padà, ó ń gbé wúrà àti fàdákà àti eyín erin àti ìnàkí.

22Ọba Solomoni sì tóbi nínú ọláńlá àti ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba tí ó kù lórí ilẹ̀ ayé lọ. 23Gbogbo àwọn ọba ayé ń wá ojúrere lọ́dọ̀ Solomoni láti gbọ́n ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn rẹ̀. 24Ní ọdọọdún, olúkúlùkù ẹni tí o wá mú ẹ̀bùn ohun èlò wúrà àti fàdákà àti aṣọ ìbora, ìhámọ́ra, àti tùràrí, àti ẹṣin àti ìbáaka wá.

25Solomoni sì ní ẹgbàajì ilé fún àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́, àti ẹgbàafà àwọn ẹṣin, tí ó fi pamọ́ nínú ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú rẹ̀ nínú Jerusalẹmu. 26Ó sì jẹ ọba lórí gbogbo àwọn ọba láti odò Eufurate títí dé ilé àwọn ará Filistini àti títí ó fi dé agbègbè ti Ejibiti. 27Ọba sì sọ fàdákà dàbí òkúta ní Jerusalẹmu, àti igi kedari ni ó sì ṣe bí igi sikamore, tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. 28A sì mú àwọn ẹṣin Solomoni wa láti ilẹ̀ òkèrè láti Ejibiti àti láti gbogbo ìlú.

Ikú Solomoni

29Àti gẹ́gẹ́ bí ìyókù iṣẹ́ ìjọba Solomoni, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn Natani wòlíì, àti nínú ìsọtẹ́lẹ̀ Ahijah ará Ṣilo àti nínú ìran Iddo, wòlíì tí o so nípa Jeroboamu ọmọ Nebati? 309.30,31: 1Ọb 11.42-43.Solomoni jẹ ọba ní Jerusalẹmu lórí gbogbo àwọn Israẹli fún ogójì ọdún 31Solomoni sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi baba rẹ̀, Rehoboamu, ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.