2 Chroniques 26 – BDS & YCB

La Bible du Semeur

2 Chroniques 26:1-23

Ozias est fidèle à l’Eternel et il est béni

(2 R 14.21-22 ; 15.1-3)

1Alors tout le peuple de Juda prit son fils Ozias26.1 Appelé Azaria en 2 R 14.21-22 ; 15.1-7., âgé de seize ans, pour le proclamer roi à la place de son père Amatsia. 2C’est lui qui ramena Eiloth sous la domination de Juda et qui la reconstruisit, après la mort du roi26.2 Voir 2 Ch 8.17.. 3Ozias était âgé de seize ans à son avènement, et il régna cinquante-deux ans à Jérusalem26.3 De 792 à 740 av. J.-C., dont une corégence avec son père Amatsia de 792 à 767 av. J.-C.. Sa mère se nommait Yekolia. Elle était de Jérusalem. 4Il fit ce que l’Eternel considère comme juste, imitant en tout point son père Amatsia.

5Il s’attacha à Dieu tant que vécut Zacharie26.5 Zacharie semble avoir été un conseiller d’Ozias. qui lui enseignait la crainte de Dieu26.5 D’après plusieurs manuscrits hébreux, l’ancienne version grecque et la version syriaque. D’autres manuscrits hébreux ont : les révélations de Dieu.. Aussi longtemps qu’il resta attaché à l’Eternel, Dieu lui accorda la réussite. 6Il fit campagne contre les Philistins et démolit les remparts de Gath, ceux de Yabné et ceux d’Ashdod. Il fortifia plusieurs villes dans la région d’Ashdod et dans d’autres territoires philistins26.6 Ozias oriente ses conquêtes vers le sud-est et le sud-ouest, le nord étant bloqué par le puissant Jéroboam II du royaume du Nord.. 7Dieu l’assista dans la lutte contre les Philistins, contre les Arabes établis à Gour-Baal, et contre les Maonites26.7 Voir note 20.1.. 8Les Ammonites lui payèrent un tribut et sa renommée se répandit au loin jusqu’en Egypte, car il était devenu extrêmement puissant. 9Ozias bâtit des tours fortifiées à Jérusalem au-dessus de la porte de l’Angle, de la porte de la Vallée et à l’angle. 10Il construisit aussi des tours de garde dans les régions de steppes et fit creuser beaucoup de citernes pour les nombreux troupeaux qu’il possédait. Il favorisa les agriculteurs dans le Bas-Pays et la plaine côtière, et les vignerons dans les régions montagneuses et sur le Carmel, car il aimait beaucoup la terre. 11Il avait une armée bien entraînée. Pour aller au combat, elle avait été organisée en divisions d’après le nombre des hommes recrutés par le secrétaire Yeïel et le commissaire Maaséya, sous la direction de Hanania, haut fonctionnaire du roi. 122 600 chefs de groupes familiaux commandaient ces guerriers valeureux. 13Ils avaient sous leurs ordres une armée de 307 500 combattants toujours prêts à engager le combat avec force pour défendre le roi contre ses ennemis. 14A chaque campagne26.14 Autre traduction : à toute l’armée., Ozias leur distribuait des boucliers, des lances, des casques, des cuirasses, des arcs et des pierres de fronde. 15Il fit aussi fabriquer à Jérusalem des engins conçus par un artisan habile et destinés à être placés sur les tours et aux angles des murailles pour tirer des flèches et lancer de grosses pierres. Ainsi, sa renommée s’étendit au loin, car il fut merveilleusement aidé jusqu’à ce qu’il soit devenu puissant.

L’orgueil et la faute d’Ozias

16Mais lorsqu’il fut devenu puissant, son cœur se gonfla d’orgueil, ce qui entraîna sa perte. Il fut rebelle à l’Eternel son Dieu car il pénétra dans son temple pour offrir des parfums sur l’autel des parfums26.16 Seuls les prêtres avaient le droit d’offrir l’encens (Nb 3.10 ; 17.5 ; 18.7 ; 1 Ch 23.13). Peut-être Ozias voulait-il imiter les rois païens environnants qui étaient à la fois rois et prêtres ?. 17Le prêtre Azaria entra derrière lui accompagné de quatre-vingts prêtres de l’Eternel, qui, avec courage, 18s’opposèrent au roi Ozias et lui dirent : Ce n’est pas à toi, Ozias, d’offrir l’encens à l’Eternel, mais c’est réservé aux prêtres, descendants d’Aaron, qui ont été consacrés pour cela. Sors du sanctuaire, car tu commets un acte de rébellion et, de par l’Eternel Dieu, cet acte ne sera pas à ta gloire.

19Alors Ozias, qui tenait un encensoir à la main, se mit en colère contre les prêtres. Au même moment, alors qu’il était là, dans le temple de l’Eternel, près de l’autel des parfums, une affection de la peau apparut sur son front en présence des prêtres. 20Le grand-prêtre Azaria et tous les prêtres le regardèrent et aperçurent des taches malignes sur son front. Ils l’expulsèrent immédiatement du Temple26.20 La maladie de peau dont était affecté le roi le rendait rituellement impur, ce qui entraînait son exclusion de la communauté (Lv 13.45-46)., tandis que lui-même se dépêchait de sortir parce que l’Eternel l’avait frappé.

(2 R 15.5-7)

21Le roi Ozias resta affecté de cette maladie jusqu’au jour de sa mort et vécut dans une maison d’isolement comme impur, tenu à l’écart du temple de l’Eternel. Son fils Yotam avait la charge du palais royal et gouvernait le peuple du pays. 22Les autres faits et gestes d’Ozias, des premiers aux derniers, a été consigné par écrit par le prophète Esaïe, fils d’Amots.

23Ozias rejoignit ses ancêtres décédés et fut enterré auprès d’eux sur un terrain de sépultures, car on disait : « Il était atteint d’une maladie rendant impur. »

Son fils Yotam lui succéda sur le trône.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 26:1-23

Ussiah ọba Juda

126.1-4: 2Ọb 14.21,22; 15.2,3.Nígbà náà gbogbo ènìyàn Juda mú Ussiah, ẹni tí ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìn-dínlógún wọ́n sì fi jẹ ọba ní ipò baba rẹ̀ Amasiah. 2Òun ni ẹni náà tí ó tún Elati kọ́, ó sì mú padà sí Juda lẹ́yìn ìgbà tí Amasiah ọba ti sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀.

3Ussiah sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìn-dínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjìléláadọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jekoliah; ó sì wá láti Jerusalẹmu. 4Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bi baba rẹ̀ Amasiah ti ṣe. 5Ó sì wá Olúwa ní ọjọ́ Sekariah, ẹni tí ó ní òye nínú ìran Ọlọ́run. Níwọ́n ọjọ́ tí ó wá ojú Olúwa, Ọlọ́run fún un ní ohun rere.

6Ó sì lọ sí ogun pẹ̀lú Filistini ó sì wó odi Gati lulẹ̀, Jabne àti Aṣdodu. Ó sì kó ìlú rẹ̀ tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ Aṣdodu àti níbìkan láàrín àwọn ará Filistini. 7Ọlọ́run sì ràn án lọ́wọ́ lórí àwọn ará Filistini àti Arabia tí ń gbé ní Gur-baali àti lórí àwọn ará Mehuni. 8Àwọn ará Ammoni gbé ẹ̀bùn wá fún Ussiah, orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri títí ó fi dé àtiwọ Ejibiti, nítorí ó ti di alágbára ńlá.

9Ussiah sì kọ́ ilé ìṣọ́ ní Jerusalẹmu níbi ẹnu-bodè igun, àti níbi ẹnu-bodè Àfonífojì àti níbi ìṣẹ́po odi ó sì mú wọn le 10Ó sì tún ilé ìṣọ́ aginjù kọ́, ó sì gbẹ́ kànga púpọ̀, nítorí ó ni ẹran ọ̀sìn púpọ̀ ní ilẹ̀ ìsàlẹ̀ àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó sì ní àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ ní pápá àti ọgbà àjàrà ní orí òkè ní ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn àgbẹ̀ ṣíṣe.

11Ussiah sì ní àwọn ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n kọ́ dáradára, wọ́n múra tán láti lọ pẹ̀lú ẹgbẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí iye kíkà wọn gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ Jeieli akọ̀wé àti Maaseiah ìjòyè lábẹ́ ọwọ́ Hananiah, ọ̀kan lára àwọn olórí ogun ọba. 12Àpapọ̀ iye olórí àwọn alágbára akọni ogun jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá (2,600). 13Lábẹ́ olórí àti olùdarí wọn, wọ́n sì jẹ́ alágbára akọni ogun ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (307,500), tí ó ti múra fún ogun ńlá náà, àti alágbára ńlá jagunjagun kan láti ran ọba lọ́wọ́ sí ọ̀tá rẹ̀. 14Ussiah sì pèsè ọ̀kọ̀, asà, akọ́rọ́, àti ohun èlò ìhámọ́ra ọrun títí dé òkúta kànnàkànnà fún ọwọ́ àwọn ọmọ-ogun. 15Ní Jerusalẹmu ó sì ṣe ohun ẹ̀rọ ìjagun, iṣẹ́ ọwọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn, láti wà lórí ilé ìṣọ́ àti lórí igun odi láti fi tafà àti láti fi sọ òkúta ńlá. Orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri, nítorí a ṣe ìrànlọ́wọ́ ìyanu fún un títí ó fi di alágbára.

16Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí Ussiah jẹ́ alágbára tán, ìgbéraga rẹ̀ sì gbé e ṣubú. Ó sì di aláìṣòótọ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì wọ ilé Olúwa láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí. 17Asariah àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọgọ́rin alágbára àlùfáà Olúwa mìíràn sì tẹ̀lé e. 18Wọ́n sì takò ọba Ussiah, wọn sì wí pé, “Kò dára fún ọ, Ussiah, láti sun tùràrí sí Olúwa. Èyí fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Aaroni, ẹni tí ó ti yà sí mímọ́ láti sun tùràrí. Fi ibi mímọ́ sílẹ̀, nítorí tí ìwọ ti jẹ́ aláìṣòótọ́, ìwọ kò sì ní jẹ́ ẹni ọlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run.”

19Ussiah, ẹni tí ó ní àwo tùràrí ní ọwọ́ rẹ̀ tó ṣetán láti sun tùràrí sì bínú. Nígbà tí ó sì ń bínú sí àwọn àlùfáà níwájú wọn, níwájú pẹpẹ tùràrí ní ilé Olúwa, ẹ̀tẹ̀ sì yọ jáde ní iwájú orí rẹ̀. 2026.20-23: 2Ọb 15.5-7.Nígbà tí Asariah olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn àlùfáà yòókù sì wò ó, wọ́n sì rí i wí pé ó ní ẹ̀tẹ̀ níwájú orí rẹ̀, Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì sáré gbé e jáde pẹ̀lúpẹ̀lú, òun tìkára rẹ̀ ti fẹ́ láti jáde, nítorí tí Olúwa ti kọlù ú.

21Ọba Ussiah sì ní ẹ̀tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Ó sì gbé ní ilé àwọn adẹ́tẹ̀, a sì ké e kúrò ní ilé Olúwa. Jotamu ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.

22Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Ussiah láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ láti ọwọ́ wòlíì Isaiah ọmọ Amosi. 23Ussiah sì sùn pẹ̀lú àwọn baba, rẹ̀ a sì sin sí ẹ̀gbẹ́ wọn nínú oko ìsìnkú fún ti iṣẹ́ tí àwọn ọba, nítorí àwọn ènìyàn wí pé “Ó ní ààrùn ẹ̀tẹ̀,” Jotamu ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.