Numero 26 – APSD-CEB & YCB

Ang Pulong Sa Dios

Numero 26:1-65

Ang Ikaduhang Pagsensos

1Human sa katalagman, miingon ang Ginoo kang Moises ug kang Eleazar nga anak sa pari nga si Aaron, 2“Esensus ninyo ang tibuok katilingban sa Israel basi sa ilang pamilya—tanan nga nagpangidaron ug 20 ka tuig pataas nga makahimo sa pagserbisyo isip sundalo sa Israel.” 3Busa nakigsulti si Eleazar nga pari ug si Moises sa mga Israelinhon didto sa kapatagan sa Moab sa daplin sa Suba sa Jordan atbang sa Jerico. 4Miingon sila, “Sensosa ang mga tawo nga nagaedad ug 20 ka tuig pataas, sumala sa gisugo sa Ginoo kang Moises.”

Mao kini ang mga Israelinhon nga migawas gikan sa Ehipto:

5Ang mga kaliwat ni Reuben, nga kamagulangang anak ni Jacob,26:5 Jacob: sa Hebreo, Israel. mao ang pamilya ni Hanoc, Palu, 6Hezron, ug Carmi. 7Mikabat ug 43,730 ang mga kaliwat ni Reuben.

8Ang anak ni Palu mao si Eliab, 9ug ang mga anak ni Eliab mao sila si Nemuel, Datan, ug Abiram. Kini si Datan ug si Abiram mao ang mga pangulo sa katilingban nga nakigkunsabo kang Kora sa pagrebelde batok sa Ginoo pinaagi sa pagsupak kang Moises ug kang Aaron. 10Apan gilamoy sila sa yuta uban kang Kora, kansang 250 ka mga sumusunod nangamatay pinaagi sa kalayo. Kining maong panghitabo nahimong pasidaan ngadto sa mga Israelinhon. 11Apan ang mga anak ni Kora wala maapil ug kamatay niining hitaboa.

12Ang mga kaliwat ni Simeon mao ang mga pamilya ni Nemuel, Jamin, Jakin, 13Zera, ug Saul. 14Mikabat ug 22,200 ang mga kaliwat ni Simeon.

15Ang mga kaliwat ni Gad mao ang mga pamilya nila ni Zefon, Hagi, Shuni, 16Ozni, Eri, 17Arod, ug Areli. 18Mikabat ug 40,500 ang mga kaliwat ni Gad.

19Si Juda dunay duha ka anak nga si Er ug Onan, nga namatay sa yuta sa Canaan. 20Apan may mga kaliwat gihapon si Juda nga mao ang mga pamilya nila ni Shela, Perez, ug Zera. 21Ang mga kaliwat ni Perez mao ang mga pamilya nga naggikan kanila ni Hezron ug ni Hamul. 22Mikabat ug 76,500 ang mga kaliwat ni Juda.

23Ang mga kaliwat ni Isacar mao ang mga pamilya nila ni Tola, Pua, 24Jashub, ug Shimron. 25Mikabat ug 64,300 ang mga kaliwat ni Isacar.

26Ang mga kaliwat ni Zebulun mao ang mga pamilya nila ni Sered, Elon, ug Jalel. 27Mikabat ug 60,500 ang mga kaliwat ni Zebulun.

28Ang mga kaliwat ni Jose naggikan sa duha niya ka anak nga si Manase ug Efraim. 29Ang mga kaliwat ni Manase mao ang mga pamilya nga naggikan kang Makir ug sa anak niining si Gilead. 30Ang mga anak ni Gilead mao sila si Iezer, 31Asriel, Helek, Shekem, 32Shemida, ug Hefer. 33Ang anak ni Hefer nga si Zelofehad walay anak nga lalaki, apan may mga anak siya nga babaye nga ang mga ngalan mao sila si Mala, Noa, Hogla, Milca, ug Tirza. 34Mikabat ug 52,700 ang mga kaliwat ni Manase.

35Ang mga kaliwat usab ni Efraim mao ang mga pamilya nila ni Shutela, Beker, Tahan, 36ug sa anak ni Shutela nga si Eran. 37Mikabat ug 32,500 ang mga kaliwat ni Efraim. Kini nga mga pamilya nga naggikan kang Manase ug Efraim mao ang mga kaliwat ni Jose.

38Ang mga kaliwat ni Benjamin mao ang mga pamilya nila ni Bela, Ashbel, Ahiram, 39Shufam, ug Hufam. 40Ang mga kaliwat ni Bela mao ang mga pamilya nila ni Ard ug Naaman. 41Mikabat ug 45,600 ang mga kaliwat ni Benjamin.

42Ang mga kaliwat ni Dan mao ang mga pamilya ni Shuham. 43Mikabat ug 64,400 ang mga kaliwat ni Dan.

44Ang mga kaliwat ni Asher mao ang mga pamilya nila ni Imna, Ishvi, ug Beria. 45Ang mga kaliwat ni Beria mao ang mga pamilya nila ni Heber ug Malkiel. 46(May anak nga babaye si Asher nga si Sera.) 47Mikabat ug 53,400 ang mga kaliwat ni Asher.

48Ang mga kaliwat ni Naftali mao ang mga pamilya nila ni Jazeel, Guni 49Jezer, ug Shilem. 50Mikabat ug 45,400 ang mga kaliwat ni Naftali.

51Ang gidaghanon sa tanang mga lalaki nga Israelinhon nga giihap mikabat ug 601,730.

52Unya miingon ang Ginoo kang Moises, 53“Bahina ang yuta ingon nga ilang panulondon basi sa gidaghanon sa kada tribo. 54Ang tribo nga daghan, bahini ug dako ug ang tribo nga gamay ra bahini ug gamay. 55Kinahanglan pinaagi sa pagripa ang pagbahin sa yuta subay sa tribo diin sila nasakop. 56Ang bahin nila mag-agad sa gidak-on sa ilang pamilya.”

57Ang mga kaliwat ni Levi mao ang mga pamilya nila ni Gershon, Kohat, ug Merari. 58Ug kanila naggikan ang mga pamilya nila ni Libni, Hebron, Mali, Mushi, ug Kora.

Si Kohat mao ang amahan ni Amram. 59Ug ang asawa ni Amram mao si Jokebed nga kaliwat usab ni Levi. Natawo si Jokebed sa Ehipto. Si Amram ug Jokebed mao ang mga ginikanan nila ni Aaron, Moises, ug Miriam. 60Si Aaron mao ang amahan nila ni Nadab, Abihu, Eleazar, ug Itamar. 61Apan namatay si Nadab ug si Abihu sa dihang migamit silag kalayo nga dili maoy ginagamit sa ilang paghalad sa Ginoo.

62Ang gidaghanon sa mga lalaking kaliwat ni Levi nga nagaedad ug usa ka bulan pataas mikabat ug 23,000. Wala sila iapil sa kinatibuk-an nga ihap sa gidaghanon sa mga Israelinhon kay wala man silay bahin sa yuta nga gipanunod sa mga Israelinhon.

63Mao kini ang mga Israelinhon nga naihap ni Moises ug ni Eleazar nga pari didto sa kapatagan sa Moab sa daplin sa Jordan atbang sa Jerico. 64Wala nay naapil gikan sa nahaunang pag-ihap nga gihimo ni Moises ug ni Aaron nga pari sa kamingawan sa Sinai, 65kay miingon ang Ginoo kanila kaniadto nga sigurado gayong mangamatay sila sa kamingawan. Ug walay usa nga nahibilin gawas kang Caleb nga anak ni Jefune, ug kang Josue nga anak ni Nun.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 26:1-65

Ìkànìyàn ẹlẹ́ẹ̀kejì

126.1-51: Nu 1.1-46.Lẹ́yìn àjàkálẹ̀-ààrùn Olúwa sọ fún Mose àti Eleasari ọmọ Aaroni, àlùfáà pé 2“Ka iye gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọ́n; láti ẹni ogun (20) ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó lè jà lójú ogun ní Israẹli.” 3Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti Moabu pẹ̀lú Jordani tí ó kọjá Jeriko, Mose àti Eleasari àlùfáà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn ó wí pé, 4“Ka iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ-ogun (20) ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.”

Èyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí ó jáde láti Ejibiti wá:

526.5-51: Nu 1.22-46.Àwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí ọmọkùnrin Israẹli,

láti ẹni ti ìdílé Hanoku, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé Hanoku ti jáde wá;

Láti ìdílé Pallu, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé àwọn ọmọ Pallu ti jáde wá;

6ti Hesroni, ìdílé àwọn ọmọ Hesroni;

ti Karmi, ìdílé àwọn ọmọ Karmi.

7Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Reubeni; àwọn tí a sì kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélógún ó-lé-ẹgbẹ̀sán ó-dínàádọ́rin (43,730).

8Àwọn ọmọkùnrin Pallu ni Eliabu, 9àwọn ọmọkùnrin Elifelehu ni Nemueli àti Eliabu, Datani àti Abiramu. Èyí ni Datani àti Abiramu náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mose àti Aaroni tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kora nígbà tí wọ́n bá Olúwa jà. 10Ilẹ̀ sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì pọ̀ pẹ̀lú Kora, nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kú níbi tí iná ti run àwọn àádọ́tà-lé-nígba ọkùnrin (250). Tí wọ́n sì di ààmì ìkìlọ̀. 11Àwọn ọmọ Kora, bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò kú.

12Àwọn ọmọ ìran Simeoni bí ìdílé wọn:

ti Nemueli, ìdílé Nemueli;

ti Jamini, ìdílé Jamini;

ti Jakini, ìdílé Jakini;

13ti Sera, ìdílé Sera;

tí Saulu, ìdílé Saulu.

14Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Simeoni, ẹgbàá-mọ́kànlá ó-lé-igba. (22,200) ọkùnrin.

15Àwọn ọmọ Gadi bí ìdílé wọn:

ti Sefoni, ìdílé Sefoni;

ti Haggi, ìdílé Haggi;

ti Ṣuni, ìdílé Ṣuni;

16ti Osni, ìdílé Osni;

ti Eri, ìdílé Eri;

17ti Arodi, ìdílé Arodi;

ti Areli, ìdílé Areli.

18Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gadi tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).

19Àwọn ọmọ Juda ni Eri àti Onani, ṣùgbọ́n Eri àti Onani kú ní ilẹ̀ Kenaani.

20Àti àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Ṣela, ìdílé Ṣela;

ti Peresi, ìdílé Peresi;

ti Sera, ìdílé Sera.

21Àwọn ọmọ Peresi:

ti Hesroni, ìdílé Hesroni;

ti Hamulu, ìdílé Hamulu.

22Wọ̀nyí ni ìdílé Juda; gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínlógójì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (76,500).

23Àwọn ọmọ Isakari gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Tola, ìdílé Tola;

ti Pufa, ìdílé Pufa;

24ti Jaṣubu, ìdílé Jaṣubu;

ti Ṣimroni, ìdílé Ṣimroni.

25Wọ̀nyí ni ìdílé Isakari gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-méjìlélọ́gbọ̀n ó-lé-ọ̀ọ́dúnrún (64,300).

26Àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Seredi, ìdílé Seredi;

ti Eloni, ìdílé Eloni;

ti Jaleeli, ìdílé Jaleeli.

27Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (60,500).

28Àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; Manase àti Efraimu:

29Àwọn ọmọ Manase:

ti Makiri, ìdílé Makiri (Makiri sì bí Gileadi);

ti Gileadi, ìdílé àwọn ọmọ Gileadi.

30Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gileadi:

ti Ieseri, ìdílé Ieseri;

ti Heleki, ìdílé Heleki

31àti ti Asrieli, ìdílé Asrieli;

àti ti Ṣekemu, ìdílé Ṣekemu;

32àti Ṣemida, ìdílé àwọn ọmọ Ṣemida;

àti ti Heferi, ìdílé àwọn ọmọ Heferi.

33(Ṣelofehadi ọmọ Heferi kò sì ni ọmọkùnrin, bí kò ṣe ọmọbìnrin; orúkọ àwọn ọmọbìnrin ni Mahila, Noa, àti Hogla, Milka àti Tirsa).

34Wọ̀nyí ni ìdílé Manase tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (52,700).

35Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

láti ọ̀dọ̀ Ṣutelahi, ìdílé àwọn ọmọ Ṣutelahi;

ti Bekeri, ìdílé àwọn ọmọ Bekeri;

ti Tahani, ìdílé àwọn ọmọ Tahani.

36Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ṣutelahi:

ti Erani, ìdílé àwọn ọmọ Erani;

37Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Efraimu, àwọn tí a kà nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìn-dínlógún ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (32,500).

Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.

38Àwọn ọmọ Benjamini gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn nìyìí:

tí Bela, ìdílé àwọn ọmọ Bela;

ti Aṣbeli, ìdílé àwọn ọmọ Aṣbeli;

ti Ahiramu, ìdílé àwọn ọmọ Ahiramu;

39ti Ṣufamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣufamu;

ti Hufamu, ìdílé àwọn ọmọ Hufamu.

40Àwọn ọmọ Bela ní ipasẹ̀ Ardi àti Naamani nìyìí:

ti Ardi, ìdílé àwọn ọmọ Ardi;

ti Naamani, ìdílé àwọn ọmọ Naamani.

41Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Benjamini; gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; àti àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-méjìlélógún ó-lé-ẹgbẹ̀jọ (45,600).

42Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Ṣuhamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣuhamu

Wọ̀nyí ni ìdílé Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: 43Gbogbo ìdílé àwọn ọmọ Ṣuhamu, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-méjìlélọ́gbọ̀n ó-lé-irínwó (64,400).

44Ti àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Imina, ìdílé àwọn ọmọ Imina;

ti Iṣfi, ìdílé àwọn ọmọ Iṣfi;

ti Beriah, ìdílé àwọn ọmọ Berii;

45Ti àwọn ọmọ Beriah:

ti Heberi, ìdílé àwọn ọmọ Heberi;

ti Malkieli, ìdílé àwọn ọmọ Malkieli.

46(Orúkọ ọmọ Aṣeri obìnrin nì jẹ́ Sera.)

47Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó-lé-egbèje (53,400).

48Ti àwọn ọmọ Naftali gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Jasieli, ìdílé àwọn ọmọ Jaseeli:

ti Guni, ìdílé àwọn ọmọ Guni;

49ti Jeseri, ìdílé àwọn ọmọ Jeṣeri;

ti Ṣillemu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣillemu.

50Wọ̀nyí ni ìdílé ti Naftali gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-méjìlélógún ó-lé-egbèje (45,400).

51Àpapọ̀ iye tí a kà nínú àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó-lé-ẹgbẹ̀sán ó-dínàádọ́rin (601,730).

52Olúwa sọ fún Mose pé, 53“Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ jẹ́ pínpín fún wọn gẹ́gẹ́ bí ogún wọn gẹ́gẹ́ bí iye orúkọ wọn 54Fún àwọn ọ̀pọ̀ ni kí ìwọ ó fún ní ogún ìlú púpọ̀ àti fún àwọn tí ó kéré ni kí ìwọ ó fi kékeré fún, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ gba ogún ìbí tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí a kọ. 55Rí dájú pé ilẹ̀ yìí gbọdọ̀ jẹ́ fífi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọn sì ti pọ̀ tó. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ ẹ̀yà àwọn baba wọn ni kí wọn kí ó ni í. 56Olúkúlùkù ogún ìní ni a gbọdọ̀ fi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pọ̀ tó láàrín ńlá àti kékeré.”

5726.57-62: Nu 1.47-49.Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Lefi tí a kà nínú wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Gerṣoni, ìdílé àwọn ọmọ Gerṣoni;

ti Kohati, ìdílé àwọn ọmọ Kohati;

ti Merari, ìdílé àwọn ọmọ Merari.

58Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Lefi;

ìdílé àwọn ọmọ Libni,

ìdílé àwọn ọmọ Hebroni,

ìdílé àwọn ọmọ Mahili,

ìdílé àwọn ọmọ Muṣi,

ìdílé àwọn ọmọ Kora.

(Kohati ni baba Amramu, 59Orúkọ aya Amramu sì ń jẹ́ Jokebedi, ọmọbìnrin Lefi, tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ejibiti. Òun sì bí Aaroni, Mose, àti Miriamu arábìnrin wọn fún Amramu. 60Aaroni ni baba Nadabu àti Abihu, Eleasari àti Itamari. 61Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú, nígbà tí wọ́n rú ẹbọ níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n mú iná àjèjì wá.)

62Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Lefi láti oṣù kan àti ju bẹ́ẹ̀ lọ ẹgbàá-mọ́kànlá ó-lé-lẹ́gbẹ̀rún (23,000). Wọn kò ka wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli tókù nítorí tí wọ́n kò gba ogún ìní lára wọn.

63Àwọn wọ̀nyí ni Mose àti Eleasari àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Israẹli ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá odò Jordani létí Jeriko. 6426.64,65: Nu 14.26-35.Kò sí ẹnìkan nínú àwọn tí Mose àti Aaroni àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Israẹli ní aginjù Sinai. 65Nítorí Olúwa ti sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kíkú ni wọn yóò kú sí aginjù, kò sì sí ẹnìkankan nínú wọn tí kò kú àfi Kalebu ọmọ Jefunne, àti Joṣua ọmọ Nuni.