2 Samuel 16 – APSD-CEB & YCB

Ang Pulong Sa Dios

2 Samuel 16:1-23

Si David ug si Ziba

1Igo lang nakalapas ug gamay si David sa tumoy sa bukid sa dihang gitagbo siya ni Ziba nga sulugoon ni Mefiboshet. May dala siyang duha ka asno nga gikargahan ug 200 ka buok nga pan, 100 ka kumkom nga pasas, 100 ka hinog nga prutas,16:1 prutas: Tingali prutas nga igos o pomegranata. ug bino nga gisulod sa sudlanan nga panit. 2Gipangutana ni David si Ziba, “Nganong nagdala ka niana?” Mitubag si Ziba, “Ang mga asno alang sa imong pamilya aron ilang masakyan, ang mga pan ug mga prutas aron inyong kan-on sa imong mga kauban, ug ang bino aron inyong imnon kon kapuyon kamo sa kamingawan.”

3Nangutana si David, “Asa si Mefiboshet, ang apo sa imong agalon nga si Saul?” Mitubag si Ziba, “Nagpabilin siya sa Jerusalem, tungod kay naghunahuna siya nga ibalik kaniya sa mga Israelinhon niining panahona ang gingharian sa iyang lolo.” 4Miingon si David, “Kon mao kana, ihatag ko na kanimo karon ang tanang gipanag-iya ni Mefiboshet.” Miingon si Ziba, “Mahal nga Hari, andam ako sa pag-alagad kanimo. Hinaut nga malipay ka kanako.”

Gipanghimaraot ni Shimei si David

5Sa dihang duol na si Haring David sa Bahurim, may tawo nga migawas niadto nga lungsod ug ginapanghimaraot niya si David. Kining tawhana mao si Shimei nga anak ni Gera ug paryente ni Saul. 6Gibato niya si David ug ang iyang mga opisyal bisan ug gilibotan si David sa iyang mga tawo ug mga sinaligan nga guwardya. 7Mao kini ang iyang panghimaraot kang David: “Ayaw pagsulod sa among lungsod, ikaw nga mamumuno ug daotan nga tawo! 8Gipanimaslan ka na sa Ginoo tungod sa imong pagpatay kang Saul ug sa panimalay niini, kinsa imong gipulihan ingon nga hari. Giilog mo ang gingharian gikan kang Saul, apan karon gihatag kini sa Ginoo sa imong anak nga si Absalom. Miabot kanimo kini nga kalaglagan tungod sa imong pagkamamumuno.”

9Miingon sa hari si Abishai nga anak ni Zeruya, “Mahal nga Hari, nganong gipasagdan mo lang nga panghimaraoton ka nianang tawo nga sama lang sa patay nga iro? Tugoti ako nga putlan siyag ulo.” 10Apan miingon ang hari, “Kamong mga anak ni Zeruya, unsay inyong labot? Kon gisugo siya sa Ginoo nga panghimaraoton ako, kinsa ako nga mopugong kaniya?” 11Unya miingon si David kang Abishai ug sa tanan niyang mga opisyal, “Kon ang akong anak mismo nagatinguha sa pagpatay kanako, unsa pa kaha kining paryente ni Saul?16:11 paryente ni Saul: sa Hebreo, Benjaminhon. Pasagdi lang ninyo siya kay ang Ginoo ang nagsugo kaniya. 12Basin pa ug makita sa Ginoo ang akong kalisod, ug balosan niya ug kaayohan ang panghimaraot nga akong nadawat karon.”

13Busa nagpadayon si David ug ang iyang mga tawo sa paglakaw samtang nagpaatbang usab kanila sa paglakaw si Shimei agi sa kilid sa bungtod. Samtang nagalakaw sila, padayon nga gipanghimaraot ni Shimei si David, ug gilabay ug bato ug yuta. 14Gikapoy pag-ayo si David ug ang tanan niyang mga tawo, busa namahulay sila pag-abot nila sa Suba sa Jordan.16:14 sa Suba sa Jordan: Wala kini sa Hebreo, apan makita sa usa ka Griego nga teksto.

Nakigkita si Hushai kang Absalom

15Sa laing bahin, miabot si Absalom, si Ahitofel, ug ang uban pang mga Israelinhon sa Jerusalem. 16Miabot usab didto si Hushai nga Arkanhon, nga amigo ni David, ug miadto siya kang Absalom ug miingon kaniya, “Malungtarong kinabuhi alang sa Mahal nga Hari! Malungtarong kinabuhi alang sa Mahal nga Hari!” 17Gipangutana ni Absalom si Hushai, “Asa na ang imong pagkamaunongon sa imong amigo nga si David? Nganong wala ka mouban kaniya?” 18Mitubag si Hushai, “Kanimo ako mouban kay ikaw ang gipili sa Ginoo ug sa tibuok katawhan sa Israel nga mahimong hari. 19Gawas niana, kinsa pa ba ang akong alagaran kondili ikaw nga anak sa akong agalon nga si David? Maingon nga nagaalagad ako sa imong amahan, mag-alagad usab ako kanimo.”

Ang Tambag ni Ahitofel kang Absalom

20Unya, miingon si Absalom kang Ahitofel, “Sultihi ako kon unsay atong buhaton.” 21Mitubag si Ahitofel, “Pakigdulog sa mga asawa sa imong amahan nga iyang gibilin aron mag-atiman sa palasyo. Unya mahibaloan sa tanang mga Israelinhon nga gipasuko mo pag-ayo ang imong amahan, ug tungod niini molig-on pa gayod ang suporta sa imong mga tawo kanimo.” 22Busa nagpatindog sila ug tolda alang kang Absalom sa atop sa palasyo, ug makita sa tibuok Israel nga nagasulod siya didto sa pagpakigdulog sa mga asawa sa iyang amahan.

23Niadtong panahona nagsunod gayod si Absalom sa mga tambag ni Ahitofel, sama sa gihimo ni David. Kay giisip nila ang tambag ni Ahitofel nga gikan sa Dios.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Samuẹli 16:1-23

Dafidi àti Ṣiba

1Nígbà tí Dafidi sì fi díẹ̀ kọjá orí òkè náà, sì wò ó, Ṣiba ìránṣẹ́ Mefiboṣeti sì ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀, òun àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì tí a ti dì ní gàárì, àti igba ìṣù àkàrà lórí wọn, àti ọgọ́rùn-ún síírí àjàrà gbígbẹ, àti ọgọ́rùn-ún èso ẹ̀rún, àti ìgò ọtí wáìnì kan.

2Ọba sì wí fún Ṣiba pé, “Kí ni wọ̀nyí?”

Ṣiba sì wí pé, “Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ̀nyí ni fún àwọn ará ilé ọba láti máa gùn àti àkàrà yìí, àti èso ẹ̀rún yìí ni fún àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin láti jẹ; àti ọtí wáìnì yìí ni fún àwọn aláàárẹ̀ ní ijù láti mu.”

3Ọba sì wí pé, “Ọmọ olúwa rẹ dà?”

Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Wò ó, ó jókòó ní Jerusalẹmu; nítorí tí ó wí pé, ‘Lónìí ni ìdílé Israẹli yóò mú ìjọba baba mi padà wá fún mi.’ ”

4Ọba sì wí fún Ṣiba pé, “Wò ó, gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Mefiboṣeti jẹ́ tìrẹ.”

Ṣiba sì wí pé, “Mo túúbá, jẹ́ kí n rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ, olúwa mi ọba.”

Ṣimei Bú Dafidi

5Dafidi ọba sì dé Bahurimu, sì wò ó, Ọkùnrin kan ti ibẹ̀ jáde wá, láti ìdílé Saulu wá, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣimei, ọmọ Gera: ó sì ń bú èébú bí o tí ń bọ̀. 6Ó sì sọ òkúta sí Dafidi, àti sí gbogbo ìránṣẹ́ Dafidi ọba, àti sí gbogbo ènìyàn, gbogbo àwọn alágbára ọkùnrin sì wà lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti lọ́wọ́ òsì rẹ̀. 7Báyìí ni Ṣimei sì wí nígbà tí ó ń yọ èébú, “Jáde, ìwọ ọkùnrin ẹ̀jẹ̀, ìwọ ọkùnrin Beliali. 8Olúwa mú gbogbo ẹ̀jẹ̀ ìdílé Saulu padà wá sí orí rẹ, ní ipò ẹni tí ìwọ jẹ ọba; Olúwa ti fi ìjọba náà lé Absalomu ọmọ rẹ lọ́wọ́: sì wò ó, ìwà búburú rẹ ni ó mú èyí wá bá ọ, nítorí pé ọkùnrin ẹ̀jẹ̀ ni ìwọ.”

9Abiṣai ọmọ Seruiah sì wí fún ọba pé, “Èéṣe tí òkú ajá yìí fi ń bú olúwa mi ọba? Jẹ́ kí èmi kọjá, èmi bẹ̀ ọ́, kí èmi sì bẹ́ ẹ́ lórí.”

10Ọba sì wí pé, “Kín ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yin ọmọ Seruiah? Bí ó bá ń bú èébú, nítorí tí Olúwa ti wí fún un pé: ‘Bú Dafidi!’ Ta ni yóò sì wí pé, ‘kín ni ìdí tí o fi ṣe bẹ́ẹ̀.’ ”

11Dafidi sì wí fún Abiṣai, àti fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wò ó, ọmọ mi tí ó ti inú mi wá, ń wá mi kiri: ǹjẹ́ mélòó mélòó ni ará Benjamini yìí yóò sì ṣe? Fi í sílẹ̀, sì jẹ́ kí o máa yan èébú; nítorí pé Olúwa ni ó sọ fún un. 12Bóyá Ọlọ́run yóò wo ìpọ́njú mi, Olúwa yóò sì fi ìre san án fún mi ní ipò èébú rẹ̀ lónìí.”

13Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń lọ ní ọ̀nà, Ṣimei sì ń rìn òdìkejì òkè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì ń yan èébú bí ó ti ń lọ, ó sì ń sọ ọ́ lókùúta, ó sì ń fọ́n erùpẹ̀. 14Ọba, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì dé Jordani, ó sì rẹ̀ wọ́n, wọ́n sì sinmi níbẹ̀.

Huṣai farahàn Absalomu bí ẹni tí ó ní ìfẹ́ sí i

15Absalomu àti gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn ọkùnrin Israẹli sì wá sí Jerusalẹmu, Ahitofeli sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 16Ó sì ṣe, nígbà tí Huṣai ará Arki, ọ̀rẹ́ Dafidi tọ Absalomu wá, Huṣai sì wí fún Absalomu pé, “Kí ọba ó pẹ́! Kí ọba ó pẹ́.”

17Absalomu sì wí fún Huṣai pé, “Oore rẹ sí ọ̀rẹ́ rẹ ni èyí? Èéṣe tí ìwọ kò bá ọ̀rẹ́ rẹ lọ?”

18Huṣai sì wí fún Absalomu pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ nítorí ẹni tí Olúwa, àti gbogbo àwọn ènìyàn yìí, àti gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli bá yàn, tirẹ̀ lèmi ó jẹ́, òun lèmi ó sì bá jókòó. 19Àti pé, ta ni èmi ó sì sìn? Kò ha yẹ kí èmi ó máa sìn níwájú ọmọ rẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń sìn rí níwájú baba rẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó sìn níwájú rẹ.”

Absalomu wọlé tọ àwọn obìnrin baba rẹ̀

20Absalomu sì wí fún Ahitofeli pé, “Ẹ bá ará yín gbìmọ̀ ohun tí àwa ó ṣe.”

21Ahitofeli sì wí fún Absalomu pé, “Wọlé tọ àwọn obìnrin baba rẹ lọ, tí ó fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé, gbogbo Israẹli yóò sì gbọ́ pé, ìwọ di ẹni ìríra sí baba rẹ, ọwọ́ gbogbo àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ yóò sì le.” 22Wọ́n sì tẹ́ àgọ́ kan fún Absalomu ní òrùlé; Absalomu sì wọlé tọ àwọn obìnrin baba rẹ̀ lójú gbogbo Israẹli.

23Ìmọ̀ Ahitofeli tí ó máa ń gbà ni ìgbà náà, ó dàbí ẹni pé ènìyàn béèrè nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́run: bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ìmọ̀ Ahitofeli fún Dafidi àti fún Absalomu sì rí.