3 Mose 16 – AKCB & YCB

Akuapem Twi Contemporary Bible

3 Mose 16:1-34

Mpata Da

1Aaron mmabarima baanu a wowuwuu wɔ Awurade anim no wu akyi no, Awurade ka kyerɛɛ Mose se, 2“Bɔ wo nua Aaron kɔkɔ sɛ, ɔnnkɔ kronkronbea hɔ wɔ ntwamtam no akyi; beae a apam adaka no si ne mmɔborɔhunu beae hɔ kwa. Ɔkɔ hɔ a obewu, efisɛ mʼankasa mewɔ omununkum a ɛkata mpata beae so no mu.

3“Sɛ ɔpɛ sɛ ɔkɔ hɔ a, nea ɛsɛ sɛ ɔyɛ ni: Ɛsɛ sɛ ɔde nantwinini ba ba ma wɔde bɔ bɔne ho afɔre na ɔde odwennini nso ba ma wɔde bɔ ɔhyew afɔre. 4Ɛsɛ sɛ oguare na ɔhyɛ atade hanahana ne ne nhyɛase na ɔbɔ nkyekyeremu ne abotiri. 5Afei, Israelfo bɛbrɛ no mmirekyi abien a wɔde bɛbɔ wɔn bɔne ho afɔre ne odwennini a wɔde bɛbɔ wɔn ɔhyew afɔre.

6“Ɛsɛ sɛ Aaron de nantwi ba no bɛma Awurade sɛ bɔne ho afɔre a ɔrebɔ ama ne ho de ayɛ mpata ama ne ho ne ne fifo. 7Afei, ɔde mmirekyi abien no bɛba Awurade anim wɔ Ahyiae Ntamadan no ano. 8Ɛsɛ sɛ ɔbɔ mmirekyi no so ntonto hu Awurade de, ne nea ɛsɛ sɛ wɔsan de no kɔ. 9Aaron de abirekyi a wɔde no rebɛbɔ Awurade afɔre no bɛbɔ bɔne ho afɔre. 10Wɔrenkum abirekyi baako a waka no na wɔde no aba Awurade anim. Wɔbɛyɛ mpata ho dwumadi bi agu ne so na wɔde no akɔ sare so akogyaw no wɔ hɔ sɛ mpata guan.

11“Aaron de nantwinini ba no bɛbɔ bɔne ho afɔre ama ne ho ne ne fifo. 12Ɛsɛ sɛ ɔfa ade a wɔhyew aduhuam wɔ mu a nnyansramma a wɔfaa wɔ Awurade afɔremuka no so ayɛ no ma. Afei ɔde aduhuam a wɔayam no muhumuhu bɛyɛ ne nsam na ɔde akɔ ntwamtam no akyi. 13Ɛhɔ na ɔde aduhuam no begu ogya no so wɔ Awurade anim na ayɛ wusiw kumɔnn wɔ mpata beae apam ne adaka (a abo apon a wɔakyerɛw Mmaransɛm Du agu so wɔ mu) no so nyinaa sɛnea ɛbɛyɛ a ɔrenwu. 14Na ɔde nantwinini ba no mogya no bi bɛba na ɔde ne nsateaa baako abɔ mu apete mpata beae hɔ apuei fam na wapete no mpɛn ason wɔ anim.

15“Afei, ɛsɛ sɛ ofi adi na ɔde abirekyi no kɔbɔ ɔmanfo no bɔne ho afɔre na wɔde ne mogya no ba ntwamtam no akyi na wɔpete gu mpata hɔ ne anim sɛnea ɔde nantwinini ba no mogya no yɛe no ara pɛ. 16Na ɛkyerɛ sɛ wayɛ mpata ama beae kronkron hɔ, efisɛ Israelfo bɔne ama efi aka beae hɔ ne Ahyiae Ntamadan no a wɔasi wɔ wɔn mfimfini hɔ no. 17Sɛ Aaron wura Ahyiae Ntamadan no mu kɔ kronkronbea hɔ rekɔyɛ mpata adwuma no a, ɛnsɛ sɛ obiara kɔ hɔ bi, gye sɛ ɔyɛ mpata no ma ne ho ne ne fifo ne Israelfo nyinaa wie.

18“Afei, ɔbɛkɔ afɔremuka no ho wɔ Awurade anim akɔyɛ mpata ama afɔremuka no. Ɛsɛ sɛ ɔde nantwinini ba no ne abirekyi mogya no sra mmɛn a etuatua afɔremuka no ho no ho. 19Na ɔde ne nsateaa baako bɛpete mogya no mpɛn ason agu afɔremuka no so de atew ho afi Israelfo bɔne no ho ayɛ no kronkron.

20“Sɛ owie mpata a ɛfa kronkronbea hɔ ne Ahyiae Ntamadan no ho nsɛm nyinaa ne afɔremuka no ho a, ɔde abirekyi no bɛba anikann. 21Na ɔde ne nsa abien agu aboa no apampam, na waka atirimɔden ne atuatew a Israelfo ayɛ, wɔn bɔne nyinaa de agu abirekyi no apampam, na obi a wɔayi no sɛ ɔnyɛ saa adwuma no de aboa no bɛkɔ sare so. 22Enti abirekyi no bɛsoa nnipa no bɔne nyinaa de akɔ asase a obi nte so no so na nipa no agyaa no wɔ sare so hɔ.

23“Afei, Aaron bɛkɔ Ahyiae Ntamadan mu hɔ bio akɔworɔw nʼatade hanahana a ɔhyɛɛ wɔ ntwamtam no akyi no na wagyaw wɔ hɔ. 24Ɔbɛkɔ akoguare wɔ faako a wɔatew hɔ ho na wahyɛ ne ntade no bio na wafi adi akɔbɔ ɔno ankasa ɔhyew afɔre asan abɔ ɔhyew afɔre ama nnipa no na wayɛ mpata ama ne ho ne wɔn. 25Ɔbɛhyew srade de abɔ bɔne ho afɔre wɔ afɔremuka no so.

26“Akyiri no, ɔbarima a ɔde abirekyi no kɔɔ sare so kogyaa no no bɛhoro ne ntama na waguare na wasan aba beae hɔ bio. 27Na nantwi ba ne abirekyi a wɔde bɔɔ bɔne ho afɔre no a Aaron de wɔn mogya kɔɔ kronkronbea hɔ kɔyɛɛ mpata no, wɔde wɔn bɛkɔ nsraban no akyi baabi akɔhyew a wɔn ho nwoma ne wɔn ayamde ka ho. 28Akyiri no, onipa a ɔrebɛhyew afɔrebɔde no bɛhoro ne ntama, aguare na wasan akɔ beae hɔ bio.

29“Eyi yɛ mmara a ɛwɔ hɔ daa. Ɔsram a ɛto so ason no nnafua du so no, ɛnsɛ sɛ moyɛ adwuma biara, na mmom, momfa saa da no nkari mo ho nhwɛ wɔ ahobrɛase mu. Saa mmara yi ka wɔn a wɔwoo wɔn wɔ asase yi so anaa ahɔho a wɔne Israelfo te; 30efisɛ da yi na wɔde kae mo mpata ne mo ahodwira wɔ mo bɔne ho wɔ Awurade anim. 31Ɛyɛ homeda a ɛsɛ sɛ mode home enti ɛsɛ sɛ mudi da no dinn wɔ ahobrɛase mu. Ɛyɛ mmara a ɛbɛtena hɔ daa. 32Saa ahyɛde yi, Ɔsɔfopanyin a wɔasra no no a obesi ne nena Aaron anan na obedi ho dwuma wɔ beae hɔ. Ɔno nko ara na ɔwɔ ho kwan sɛ ɔhyɛ atade kronkron hanahana no 33na ɔyɛ mpata wɔ kronkronbea hɔ wɔ Ahyiae Ntamadan mu hɔ, wɔ afɔremuka no so de ma asɔfo no ne nnipa no.

34“Eyi bɛyɛ mmara a ɛbɛtena hɔ daa ama mo, na Israelfo bɔne nti, moagyina so afe biara de ayɛ mpata ama Israelfo afi wɔn bɔne nyinaa mu.”

Na Mose dii mmara a Awurade hyɛ maa no no nyinaa so.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 16:1-34

Ọjọ́ ètùtù ìwẹ̀nùmọ́ ẹ̀ṣẹ̀

1Olúwa sọ fún Mose lẹ́yìn ikú àwọn ọmọ Aaroni méjèèjì tí wọ́n kú nígbà tí wọ́n súnmọ́ Olúwa. 216.2,12: Hb 6.19; 9.7,25.Olúwa sì sọ fún Mose pé “Kìlọ̀ fún Aaroni arákùnrin rẹ pé kí ó má ṣe máa wá nígbà gbogbo sí ibi mímọ́ jùlọ tí ó wà lẹ́yìn aṣọ títa ní ibi tí àpótí ẹ̀rí àti ìtẹ́ àánú wà, kí ó má ba à kú” nítorí pé Èmi ó farahàn nínú ìkùùkuu lórí ìtẹ́ àánú.

316.3: Hb 9.7.Báyìí ni Aaroni yóò ṣe máa wá sí ibi mímọ́ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti àgbò fún ẹbọ sísun. 4Òun yóò sì wọ aṣọ funfun mímọ́ pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ funfun, yóò sì fi àmùrè funfun mímọ́ dì í: yóò sì dé fìlà funfun: àwọn aṣọ mímọ́ nìwọ̀nyí: Òun yóò sì fi omi wẹ̀, kí ó tó wọ̀ wọ́n. 5Òun yóò sì mú ọmọ ewúrẹ́ méjì láti ọ̀dọ̀ gbogbo àgbájọpọ̀ àwọn ọmọ Israẹli láti fi ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wọ́n: àti àgbò kan fún ẹbọ sísun.

6Aaroni yóò sì fi akọ màlúù rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ èyí tí ṣe ti ara rẹ̀ òun yóò sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀. 7Lẹ́yìn náà yóò sì mú ewúrẹ́ méjì náà wá sí iwájú Olúwa ní ibi ìlẹ̀kùn àgọ́ ìpàdé. 8Aaroni yóò sì dìbò ní ti àwọn ewúrẹ́ méjèèjì náà, ìbò àkọ́kọ́ fún ti Olúwa, àti èkejì fún ewúrẹ́ ìpààrọ̀. 9Aaroni yóò sì mú ewúrẹ́ tí ìbò Ọlọ́run mú, yóò sì fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 10Ṣùgbọ́n ewúrẹ́ tí ìbò bá mú gẹ́gẹ́ bí ewúrẹ́ ìpààrọ̀ ni a ó mú wá láààyè síwájú Olúwa láti fi ṣe ètùtù sí i àti láti jẹ́ kí ó lọ lọ́fẹ̀ẹ́, sí aginjù.

Ètùtù fún olórí àlùfáà

11Aaroni yóò sì mú akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀. Yóò sì pa akọ màlúù náà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀. 12Yóò sì mú àwo tùràrí tí ó kún fún èédú tí a ti sun pẹ̀lú iná láti orí pẹpẹ wá síwájú Olúwa: àti ẹ̀kúnwọ́ méjì tùràrí tí a gún kúnná yóò sì mú un wá sí ẹ̀yìn aṣọ títa. 13Yóò sì fi tùràrí náà lé orí iná níwájú Olúwa: kí èéfín tùràrí náà ba à le bo ìtẹ́ àánú tí ó wà ní orí àpótí ẹ̀rí kí o má ba à kú. 14Yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ ọmọ màlúù náà yóò sì fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn, ní iwájú ìtẹ́ àánú, yóò sì fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn nígbà méje níwájú ìtẹ́ àánú.

Ètùtù fún àwọn ènìyàn

1516.15: Hb 9.12.Nígbà yìí ni yóò pa ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà fún àwọn ènìyàn yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sí ẹ̀yìn aṣọ títa, bí ó ti ṣe ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà ni yóò ṣe ti ewúrẹ́ yìí, yóò sì wọ́n ọn sórí ìtẹ́ ètùtù àti síwájú ìtẹ́ ètùtù. 16Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún ibi mímọ́ jùlọ nítorí àìmọ́ àwọn ará Israẹli àti nítorí gbogbo ìrékọjá wọn àti ìṣọ̀tẹ̀ wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbogbo, bákan náà ni yóò sì ṣe fún àgọ́ ìpàdé, èyí tí ó wà láàrín wọn nínú àìmọ́ wọn. 17Kí ó má ṣe sí ẹyọ ènìyàn kan nínú àgọ́ ìpàdé nígbà tí òun bá wọ ibi mímọ́ lọ láti ṣe ètùtù: títí di ìgbà tí yóò fi jáde lẹ́yìn tí ó ba ṣe ètùtù fúnrarẹ̀ fún ìdílé rẹ̀ àti fún gbogbo àgbájọpọ̀ Israẹli.

18Lẹ́yìn náà òun yóò lọ sí ibi pẹpẹ tí ó wà níwájú Olúwa: yóò sì ṣe ètùtù fún pẹpẹ náà. Yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti nínú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà, yóò sì fi sí orí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwo pẹpẹ náà yíká. 19Lẹ́yìn náà, òun yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sórí rẹ̀ pẹ̀lú ìka rẹ̀ nígbà méje láti wẹ̀ ẹ́ mọ́ àti láti sọ ọ́ dí mímọ́ kúrò nínú àìmọ́ àwọn ọmọ Israẹli.

20Lẹ́yìn ti Aaroni ti parí ṣíṣe ètùtù ti ibi mímọ́ jùlọ, ti àgọ́ ìpàdé àti ti pẹpẹ: òun yóò sì mú ààyè ewúrẹ́ wá. 21Aaroni yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, yóò sì jẹ́wọ́ gbogbo ìwà búburú àti ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ara Israẹli lé e lórí: gbogbo ìrékọjá wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni yóò sì gbé ka orí ewúrẹ́ náà. Yóò sì rán an lọ sí ijù láti ọwọ́ ẹni tí a yàn fún iṣẹ́ náà. 22Ewúrẹ́ náà yóò sì ru gbogbo àìṣedéédéé wọn lọ sí ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé. Òun yóò sì jọ̀wọ́ ewúrẹ́ náà lọ́wọ́ lọ sínú ijù.

2316.23: El 44.19.Aaroni yóò sì padà wá sí ibi àgọ́ ìpàdé, yóò sì bọ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀, tí ó wọ̀ nígbà tí ó lọ sí ibi mímọ́ jùlọ, yóò sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀ 24Yóò sì fi omi wẹ ara rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan: yóò sì wọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wá ṣí iwájú: yóò sì rú ẹbọ sísun ti ara rẹ̀ àti ẹbọ sísun ti àwọn ènìyàn láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti fún àwọn ènìyàn: 25Òun yóò sì sun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà lórí pẹpẹ.

26Ẹni tí ó tú ewúrẹ́ ìpààrọ̀ náà sílẹ̀ yóò sì fọ aṣọ rẹ̀: yóò sì wẹ ara rẹ̀ nínú omi: lẹ́yìn èyí ó lè wá sí ibùdó. 2716.27: Hb 13.11.Ọ̀dọ́ akọ màlúù àti ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti mú ẹ̀jẹ̀ wọn wá sí ibi mímọ́ jùlọ ni kí a gbe jáde kúrò ní ibùdó. Awọ wọn ni a ó fi iná sun bákan náà. 28Ẹni tí ó sun wọ́n yóò sì fọ aṣọ rẹ̀: yóò sì wẹ ara rẹ̀: lẹ́yìn èyí ni ó tó le wọ ibùdó.

2916.29-34: Le 23.26-32; Nu 29.7-11.Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín: pé ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje ni ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín: kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan, yálà onílé tàbí àlejò tí ó ń gbé pẹ̀lú yín. 30Torí pé ní ọjọ́ yìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún yín láti sọ yín di mímọ́: kí ẹ̀yin bá à le mọ́ níwájú Olúwa yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo. 31Ọjọ́ yìí yóò jẹ́ ọjọ́ ìsinmi pátápátá fún un yín: ẹ̀yin yóò sì ṣẹ́ ara yín: Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé. 32Àlùfáà náà tí a ti fi òróró yàn tí a sì ti sọ di mímọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ilé ìsìn ní ipò baba rẹ̀: òun ni kí ó ṣe ètùtù: yóò sì wọ aṣọ funfun gbòò àní aṣọ mímọ́ náà: òun yóò sì ṣe ètùtù. 33Yóò sì ṣe ètùtù fún àgọ́ ìpàdé àti fún pẹpẹ: yóò sì ṣe ètùtù fún àlùfáà àti fún gbogbo àgbájọpọ̀ àwọn ènìyàn náà.

34“Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún yín: láti máa ṣe ètùtù fún àwọn ará Israẹli fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan lọ́dún.”

Ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.