2 Beresosɛm 10 – AKCB & YCB

Akuapem Twi Contemporary Bible

2 Beresosɛm 10:1-19

Atifi Fam Mmusuakuw Tew Atua

1Rehoboam kɔɔ Sekem, efisɛ na Israel nyinaa ahyia hɔ sɛ wɔrebesi no hene. 2Bere a Nebat babarima Yeroboam tee sɛ Salomo awu no, ofi Misraim bae, efisɛ oguan fii ɔhene Salomo nsam kɔtenaa Misraim. 3Israel mpanyimfo soma ma wɔkɔfaa Yeroboam, na ɔne Israel nyinaa kɔɔ sɛ wɔne Rehoboam rekɔkasa. 4Wɔkae se, “Wʼagya hyɛɛ yɛn ma yɛyɛɛ adwumaden. Yɛsrɛ wo, tew saa adwumaden ne sonkahiri adesoa duruduru a wʼagya de soaa yɛn no so. Woyɛ saa a, yɛbɛsom wo nokware mu.”

5Rehoboam buae se, “Momma me nnansa na menwene mo asɛm yi ho. Ɛno akyi, mommra mmegye me mmuae.” Enti nnipa no san kɔe.

6Na Ɔhene Rehoboam kɔɔ ne mpanyimfo bi a na wotu nʼagya Salomo fo ne wɔn kosusuw asɛm no ho. Obisaa wɔn se, “Moka asɛm no ho dɛn? Mmuae bɛn na memfa mma saa nnipa yi?”

7Mpanyimfo yi buae se, “Sɛ woyɛ nnipa no yiye, na woyɛ ayamye kyerɛ wɔn ma ɛsɔ wɔn ani a, wɔn nso bɛyɛ wo nkurɔfo nokwafo.”

8Nanso Rehoboam amfa afotu a mpanyimfo no maa no no. Mmom, ɔkɔɔ nʼatipɛnfo mmabun bi a ɔne wɔn sii so a na wotu no fo no nkyɛn. 9Obisaa wɔn se, “Mo nso mo adwene ne dɛn? Mmuae bɛn na memfa nkɔma nnipa a wɔpɛ sɛ metew adesoa a mʼagya de soaa wɔn no so?”

10Mmerante no buae se, “Asɛm a ɛsɛ sɛ woka kyerɛ wɔn ne se, ‘Me nsateaa ketewa no mu piw sen mʼagya asen mu. Na sɛ modwene sɛ na ɔyɛ den wɔ mo so a, montwɛn na mubehu sɛnea mete.’ 11Yiw, na mʼagya yɛ den wɔ mo so, nanso me de, mɛyɛ nea ɛkyɛn saa. Sɛ mʼagya kaa mo mpire a, me de, mede nkekantwɛre na ɛbɛhwe mo.”

12Nnansa akyi no, Yeroboam ne nnipa no nyinaa san baa sɛ wɔrebetie Rehoboam mmuae sɛnea ɔkae no. 13Na Rehoboam de ahantan kasa kyerɛɛ wɔn. Wamfa mpanyimfo no afotu, 14na ɔfaa mmerante no afotu. Ɔka kyerɛɛ nnipa no se, “Na mʼagya ma moyɛ adwumaden, na me de, mɛkyɛn saa! Sɛ mʼagya kaa mo mpire a, me de, mede nkekantwɛre na ɛbɛhwe mo!” 15Enti ɔhene no anyɛ nnipa no abisade no ho hwee. Saa nsɛm a esisii yi yɛ Onyankopɔn nhyehyɛe, efisɛ ɛmaa Awurade nkɔm a ɔnam odiyifo Ahiya a ofi Silo no hyɛɛ Nebat babarima Yeroboam no baa mu.

16Bere a Israel huu sɛ ɔhene no anyɛ wɔn abisade amma wɔn no, wɔteɛteɛɛ mu se,

“Dawid ne nʼadedi ntoaso no mfa wɔn ho.

Yɛne Yisai babarima no nni twaka biara.

Israel, momma yɛnkɔ yɛn afi.

Dawid, kɔhwehwɛ wʼankasa wo fi.”

Enti Israel nyinaa san kɔɔ fie. 17Na Rehoboam kɔɔ so dii Israelfo a na wɔtete Yuda nkurow so no so hene.

18Ɔhene Rehoboam somaa Hadoram a na ɔhwɛ adwumayɛfo so no sɛ ɔnkɔhwɛ mma ɔman no nyɛ dinn, nanso Israelfo no siw no abo kum no. Bere a ɔhene Rehoboam tee saa asɛm no, ntɛm ara, ohuruw tenaa ne teaseɛnam mu, guan kɔɔ Yerusalem. 19Israel mmusuakuw a wɔwɔ atifi fam no ampene sɛ Dawid aseni biara bedi wɔn so, de besi nnɛ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 10:1-19

Israẹli sì ṣọ̀tẹ̀ lórí Rehoboamu

110.1-19: 1Ọb 12.1-19.Rehoboamu sì lọ sí Ṣekemu nítorí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ti lọ síbẹ̀ láti fi jẹ ọba. 2Nígbà tí Jeroboamu ọmọ Nebati gbọ́ ẹni ti ó wà ní Ejibiti, níbi tí ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ ọba Solomoni ó sì padà láti Ejibiti. 3Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà ó sì ránṣẹ́ sí Jeroboamu àti òun àti gbogbo àwọn Israẹli lọ sí ọ̀dọ̀ Rehoboamu wọ́n sì wí fún pé: 4“Baba rẹ gbé àjàgà tí ó wúwo lórí wa, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ mú un fúyẹ́, iṣẹ́ líle àti àjàgà wúwo tí ó gbé ka orí wa, àwa yóò sì sìn ọ́.”

5Rehoboamu sì dáhùn pé, “Ẹ padà wá sọ́dọ̀ mi lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn náà sì lọ.

6Nígbà náà ni ọba Rehoboamu fi ọ̀ràn lọ̀ àwọn àgbàgbà tí ó ti ń sin baba rẹ̀ Solomoni nígbà ayé rẹ̀, ó sì bi wọ́n léèrè pe, “Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe gbà mí ní ìmọ̀ràn láti dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí lóhùn?”

7Wọ́n sì dáhùn, “Tí ìwọ yóò bá ṣe rere sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kí o sì ṣe ìre fún wọn, kí o sì fún wọn ní ìdáhùn rere, wọn yóò sì máa jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ nígbà gbogbo.”

8Ṣùgbọ́n Rehoboamu kọ ìmọ̀ràn náà tí àwọn àgbàgbà fi fún un, ó sì fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn ọmọ ọkùnrin tí ó ti dàgbàsókè pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n sì ń dúró níwájú rẹ̀. 9Ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ìmọ̀ràn yín? Báwo ni kí a ṣe dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí wọ́n wí fún mi pé, ‘Mú kí àjàgà tí baba rẹ gbé lé wa kí ó fúyẹ́ díẹ̀.’ ”

10Àwọn ọ̀dọ́mọdé tí ó ti dàgbà pẹ̀lú rẹ dá a lóhùn pé, “sọ fún àwọn ènìyàn tí ó wí fún ọ wí pé, ‘Baba rẹ gbé àjàgà wúwo lórí wa, ṣùgbọ́n mú àjàgà wa fúyẹ́,’ wí fún wọn, pé ìka ọwọ́ mi kékeré, ó nípọn ju ìbàdí baba mi lọ. 11Baba mi gbé àjàgà wúwo ka orí yín; èmi yóò sì tún mú kí ó wúwo sì í. Baba mi fi pàṣán nà yín: ‘Èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèe.’ ”

12Ní ọjọ́ kẹta Jeroboamu àti gbogbo ènìyàn sì padà sí ọ̀dọ̀ Rehoboamu, gẹ́gẹ́ bí ọba ti sọ, “Ẹ padà wá sọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ kẹta.” 13Nígbà náà ni ọba dá wọn lóhùn ní ọ̀nà líle. Rehoboamu ọba sì kọ̀ ìmọ̀ràn àwọn àgbàgbà sílẹ̀, 14Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́mọdé, ó sì wí pé, “Baba mi mú kí àjàgà yín wúwo; Èmi yóò sì mú kí ó wúwo jù bẹ́ẹ̀ lọ. Baba mi nà yín pẹ̀lú pàṣán; Èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèe.” 15Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì fetísí àwọn ènìyàn, nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni. Láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ tí a ti sọ fún Jeroboamu ọmọ Nebati nípasẹ̀ Ahijah ará Ṣilo.

16Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i wí pé ọba kọ̀ láti gbọ́ tiwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn wí pé:

“Ìpín kí ní a ní nínú Dafidi,

ìní wo ni a ní nínú ọmọ Jese?

Ẹ lọ sí àgọ́ yín, ẹ̀yin Israẹli!

Bojútó ilé rẹ, ìwọ Dafidi!”

Bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọ sí ilé wọn. 17Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ Israẹli tí ń gbé ní ìlú Juda, Rehoboamu ń jẹ ọba lórí wọn.

18Ọba Rehoboamu rán Adoniramu jáde, ẹni tí ó wà ní ìkáwọ́ iṣẹ́ onírúurú, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli sọ ọ́ ní òkúta pa. Ọba Rehoboamu, gbìyànjú láti dé inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì sálọ sí Jerusalẹmu. 19Bẹ́ẹ̀ ni Israẹli sì wà ní ìṣọ̀tẹ̀ lórí ilé Dafidi títí fi di òní yìí.