Daily Manna for Wednesday, April 7, 2021

Daily Manna is a daily Bible devotional service provided by Biblica. The Scripture is provided in many forms and is new every day. It is a great way to receive the encouragement and hope found in the Word of God.

Verse of the Day

2 Samuẹli 22:1-7

Dafidi sì kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sí Olúwa ní ọjọ́ tí Olúwa gbà á kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ Saulu. 22.2-51: Sm 18.2-50.Ó sì wí pé:

Olúwa ni àpáta mi, àti Olùgbàlà mi;

Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò,

àti ìwo ìgbàlà mi, ibi ìsádi gíga mi.

Àti ibi ìlùmọ̀ mi, Olùgbàlà mi;

ìwọ ni ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá.

“Èmi ké pe Olúwa, tí ó yẹ láti máa yìn,

ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.

Nígbà tí ìbìlù ìrora ikú yí mi káàkiri;

tí àwọn ìṣàn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.

Ọ̀já isà òkú yí mi káàkiri;

ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí.

“Nínú ìpọ́njú mi, èmi ké pé Olúwa,

èmi sì gbé ohùn mi sókè sí Ọlọ́run mi.

Ó sí gbóhùn mi láti tẹmpili rẹ̀

igbe mí wọ etí rẹ̀.