
Daily Manna for Friday, January 15, 2021
Daily Manna is a daily Bible devotional service provided by Biblica. The Scripture is provided in many forms and is new every day. It is a great way to receive the encouragement and hope found in the Word of God.
Marku 3:13-19
3.13: Mt 5.1; Lk 6.12.Jesu gun orí òkè lọ, ó sì pe àwọn kan tí ó yàn láti wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá. Ó yan àwọn méjìlá, kí wọn kí ó lè wà pẹ̀lú rẹ̀, àti kí ó lè rán wọn lọ láti wàásù àti láti lágbára láti lé àwọn ẹ̀mí Èṣù jáde.
3.16-19: Mt 10.2-4; Lk 6.14-16; Ap 1.13.Wọ̀nyí ni àwọn méjìlá náà tí ó yàn:
Simoni (ẹni ti ó sọ àpèlé rẹ̀ ní Peteru)
Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ (àwọn ẹni tí Jesu sọ àpèlé wọ́n ní Boanaji, èyí tí ó túmọ̀ sí àwọn ọmọ àrá).
Àti Anderu,
Filipi,
Bartolomeu,
Matiu,
Tomasi,
Jakọbu ọmọ Alfeu,
Taddeu,
Simoni tí ń jẹ́ Sealoti (ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ tí o ń ja fun òmìnira àwọn Júù).
3.19: Mk 2.1; 7.17.Àti Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi í hàn níkẹyìn.