Daily Manna for Thursday, January 14, 2021

Daily Manna is a daily Bible devotional service provided by Biblica. The Scripture is provided in many forms and is new every day. It is a great way to receive the encouragement and hope found in the Word of God.

Verse of the Day

Saamu 95:1-7

Saamu 95

Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí Olúwa

Ẹ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.

Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́

kí a sì pòkìkí rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò

orin àti ìyìn.

Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni,

ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.

Ní ọwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà,

ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.

Tirẹ̀ ni Òkun, nítorí òun ni ó dá a

àti ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.

Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a foríbalẹ̀ kí a sìn ín,

Ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú

Olúwa ẹni tí ó dá wa;

95.7-11: Hb 3.7-11; 4.3-11.Nítorí òun ni Ọlọ́run wa

àwa sì ni ènìyàn pápá rẹ̀,

àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ rẹ̀.

Lónìí tí ìwọ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,