Daily Manna for Thursday, February 13, 2020

Daily Manna is a daily Bible devotional service provided by Biblica. The Scripture is provided in many forms and is new every day. It is a great way to receive the encouragement and hope found in the Word of God.

Verse of the Day

Sefaniah 3:14-17

Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Sioni,
    kígbe sókè, ìwọ Israẹli!
Fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn,
    ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.
Olúwa ti mú ìdájọ́ rẹ wọ̀n-ọn-nì
    kúrò, ó sì ti ti àwọn ọ̀tá rẹ padà sẹ́yìn.
Olúwa, ọba Israẹli wà pẹ̀lú rẹ,
    Ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù ibi kan mọ́.
Ní ọjọ́ náà, wọn yóò sọ fún Jerusalẹmu pé,
    “Má ṣe bẹ̀rù Sioni;
    má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀.
Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ,
    Ó ní agbára láti gbà ọ là.
Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀;
    Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀,
    Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.”