Daily Manna for Wednesday, February 12, 2020

Daily Manna is a daily Bible devotional service provided by Biblica. The Scripture is provided in many forms and is new every day. It is a great way to receive the encouragement and hope found in the Word of God.

Verse of the Day

1 Kronika 16:23-31

Kọrin sí Olúwa gbogbo ayé;
    ẹ máa fi ìgbàlà rẹ̀ hàn láti ọjọ́ dé ọjọ́.
Kéde ògo à rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
    ohun ìyàlẹ́nu tí ó ṣe láàrín gbogbo ènìyàn.

Nítorí títóbi ni Olúwa òun sì ni ìyìn yẹ Jùlọ;
    òun ni kí a bẹ̀rù ju gbogbo àwọn Ọlọ́run lọ.
Nítorí gbogbo àwọn ọlọ́run orílẹ̀-èdè jẹ́ àwọn òrìṣà,
    ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run.
Dídán àti ọláńlá ni ó wà níwájú rẹ̀;
    agbára àti ayọ̀ ni ó wà ní ibi ibùgbé rẹ̀.

Fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè,
    ẹ fi ògo àti ipá fún Olúwa.
Fún Olúwa ní ìyìn nítorí orúkọ rẹ̀;
    gbé ọrẹ kí ẹ sì wá síwájú rẹ̀.
Sìn Olúwa nínú inú dídùn ìwà mímọ́ rẹ̀.
    Wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé!
    Ayé sì fi ìdí múlẹ̀; a kò sì le è ṣí i.

Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn;
    Jẹ́ kí wọn kí ó sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, pé “Olúwa jẹ ọba!”