Sekariah 1 – YCB & APSD-CEB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Sekariah 1:1-21

Ìpè láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run

1Ní oṣù kẹjọ ọdún kejì ọba Dariusi, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Sekariah ọmọ Berekiah, ọmọ Iddo pé:

2Olúwa ti bínú sí àwọn baba ńlá yín. 3Nítorí náà sọ fún àwọn ènìyàn. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Ẹ padà sí ọ̀dọ̀ mi,’ báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘èmi náà yóò sì padà sí ọ̀dọ̀ yín,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 4Ẹ má dàbí àwọn baba yín, àwọn tí àwọn wòlíì ìṣáájú ti ké sí wí pé, báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Ẹ yípadà nísinsin yìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín,’ àti kúrò nínú ìwà búburú yín; ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sí ti èmi, ni Olúwa wí. 5Àwọn baba yín, níbo ni wọ́n wà? Àti àwọn wòlíì, wọ́n ha wà títí ayé? 6Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi àti ìlànà mi, ti mo pa ní àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì, kò ha tún bá àwọn baba yín?

“Wọ́n sì padà wọ́n wí pé, ‘Gẹ́gẹ́ bí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti rò láti ṣe sí wa, gẹ́gẹ́ bi ọ̀nà wa, àti gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa, bẹ́ẹ̀ ní o ti ṣe sí wa.’ ”

Ènìyàn láàrín àwọn igi miritili

7Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kọkànlá, tí ó jẹ́, oṣù Sebati, ní ọdún kejì Dariusi, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Sekariah, ọmọ Berekiah ọmọ Iddo wá, pé.

8Mo rí ìran kan ni òru, si wò ó, ọkùnrin kan ń gun ẹṣin pupa kan, òun sì dúró láàrín àwọn igi maritili tí ó wà ní ibi òòji; lẹ́yìn rẹ̀ sì ni ẹṣin pupa, adíkálà, àti funfun gbé wà.

9Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni wọ̀nyí olúwa mi?”

Angẹli tí ń ba mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Èmi ó fi ohun tí àwọn wọ̀nyí jẹ́ hàn ọ́.”

10Ọkùnrin tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili sì dáhùn ó sì wí pé, “Wọ̀nyí ní àwọn tí Olúwa ti rán láti máa rìn sókè sódò ni ayé.”

11Wọ́n si dá angẹli Olúwa tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili náà lóhùn pé, “Àwa ti rìn sókè sódò já ayé, àwa sí ti rí i pé gbogbo ayé wà ní ìsinmi àti àlàáfíà.”

12Nígbà náà ni angẹli Olúwa náà dáhùn ó sì wí pé, “Olúwa àwọn ọmọ-ogun, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ kì yóò fi ṣàánú fún Jerusalẹmu, àti fún àwọn ìlú ńlá Juda, ti ìwọ ti bínú sí ni àádọ́rin ọdún wọ̀nyí?” 13Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ ìtùnú dá angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn.

14Angẹli ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Ìwọ kígbe wí pé, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Èmi ń fi ìjowú ńlá jowú fún Jerusalẹmu àti fún Sioni. 15Èmi sì bínú púpọ̀púpọ̀ si àwọn orílẹ̀-èdè tí ó rò wí pé òun ní ààbò. Nítorí nígbà tí mo bínú díẹ̀, wọ́n ran ìparun lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú.’

16“Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí: ‘Mo padà tọ Jerusalẹmu wá pẹ̀lú àánú; ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, a ó kọ́ ilé mi sínú rẹ̀, a o sí ta okùn ìwọ̀n kan jáde sórí Jerusalẹmu.’

17“Máa ké síbẹ̀ pé, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘A o máa fi ìre kún ìlú ńlá mi síbẹ̀; Olúwa yóò sì máa tu Sioni nínú síbẹ̀, yóò sì yan Jerusalẹmu síbẹ̀.’ ”

Ìwo mẹ́rin àti alágbẹ̀dẹ mẹ́rin

18Mo si gbé ojú sókè, mo sì rí, sì kíyèsi i, ìwo mẹ́rin. 19Mo sì sọ fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kí ni nǹkan wọ̀nyí?”

Ó si dà mí lóhùn pé, “Àwọn ìwo wọ̀nyí ni ó tí tú Juda, Israẹli, àti Jerusalẹmu ká.”

20Olúwa sì fi alágbẹ̀dẹ mẹ́rin kan hàn mí. 21Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni àwọn wọ̀nyí wá ṣe?”

O sì sọ wí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni ìwo tí ó ti tú Juda ká, tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò fi gbé orí rẹ̀ sókè? Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí wá láti dẹ́rùbà wọ́n, láti lé ìwo àwọn orílẹ̀-èdè jáde, ti wọ́n gbé ìwo wọn sórí ilẹ̀ Juda láti tú ènìyàn rẹ̀ ká.”

Ang Pulong Sa Dios

Zacarias 1:1-21

Ang Pagtawag sa Pagbalik ngadto sa Ginoo

1Sa ikawalo nga bulan sa ikaduha nga tuig sa paghari Darius, ang pulong sa Ginoo miabot kang Zacarias anak ni Berekia, anak ni Iddo: 2-3“Ang Ginoo nasuko pag-ayo sa mga katigulangan. Busa sultihi ang katawhan: Mao kini ang giingon sa Ginoo nga Makagagahum: ‘Balik kanako,’ nagaingon ang Ginoo nga Makagagahum, ‘ug ako mobalik kaninyo,’ naga-ingon ang Ginoo nga Makagagahum. 4Ayaw pagpakasama sa inyong mga katigulangan, diin ang nahaunang mga propeta nagdeklarar: Mao kini ang giingon sa Ginoo ‘Talikdi ang inyong dautang pamaagi ug binuhatan.’ Apan dili sila maminaw kanako, nagaingon ang Ginoo. 5Asa man ang inyong mga katigulangan karon? Ug ang mga Propeta, mabuhi ba sila sa kahangturan? 6Apan dili ba ang akong mga pulong ug mga gimbut-an, nga akong gisugo sa akong mga sulugoon ang propeta, naka-apas sa inyong mga katigulangan? Unya sila naghinulsol ug miingon, ‘Ang Ginoo nga Makagagahum naghimo diha kanato sa angayan sa atong paagi ug binuhatan. Ingon sa iyang gitinguha nga buhaton.’ ”

Ang Tawo taliwala sa mga kahoy nga Myrtol

7-8Sa ika biente-kuatro ka adlaw sa ika-onse ka bulan sa Shebat, sa ika-duha ka tuig ni Darius, ang pulong sa Ginoo miabot kang propeta Zacarias anak ni Berekia, ang anak ni Iddo. 9Nangutana ako sa anghel nga nakigsulti kanako, “Unsay buot ipasabot niini, sir?” Mitubag siya, “Ipahayag ko kanimo kon unsay buot ipasabot niini.” Sa panahon sa kagabhion adunay koy panan-awon, ug diha sa akong atubangan mao ang usa ka tawo nga nagsakay sa pula nga kabayo, nagbarug kini sa taliwala sa mga kahoy nga myrtol didto sa patag. Sa iyang likod mao ang mga pula, kaki ug puti nga mga kabayo.

10Unya ang tawo nga nagbarug sa taliwala sa kahoy nga myrtol mipasabut, “Mao ni sila ang gipadala sa Ginoo aron pad-adtu sa tibuok kalibutan.”

11Ug sila misulti sa anghel sa Ginoo nga nagbarug sa taliwala sa mga kahoy nga myrtol, “Kami miadtu sa tibuok kalibutan ug nakaplagan namo ang tibuok kalibutan nagapahulay ug malinawon.”

12Unya ang anghel sa Ginoo miingon, “Ginoo nga Makagagahum, hangtud kanus-a nimo ihikaw ang imong kaluoy sa Jerusalem ug sa mga lungsod sa Juda, nga imong gikalagutan sulod niining sitenta ka mga katuigan?” 13Busa ang Ginoo mitubag sa malumo ug makahupay nga mga pulong ngadto sa anghel nga nakigsulti kanako.

14Unya ang anghel nga nakigsulti kanako miingon, “Ipadayag kining mga pulong: Mao kini ang giingon sa Ginoo nga Makagagahum: ‘Ako nangabugho sa Jerusalem ug sa Zion, 15ug labihan ang akong kasuko sa mga nasud nga mibati nga luwas. Ako gamay lang ang kasuko, apan misubra sila sa ilang pagsilot.’ 16Busa mao kini ang giingon sa Ginoo: ‘Ako mubalik sa Jerusalem uban ang kaluoy, ug diha ang akong balay pagatuloron. Ug ang linya sa sukdanan mao kini paga-inaton kini sa tibuok Jerusalem,’ nagaingon ang Ginoo nga Makagagahum.

17“Idugang kini pagpadayag: Mao kini ang giingon sa Ginoo nga Makagagahum: ‘Ang Akong kalungsuran mubalik pag-awas sa kadagaya, ug ang Ginoo mubalik sa paghupay sa Zion ug pilion ko ang Jerusalem.’ ”

Upat ka mga Sungay ug Upat ka mga Panday

18Unya mihangad ako sa ibabaw, ug diha sa akong atubangan mga upat ka sungay. 19Ako nangutana sa anghel nga nakigsulti kanako, “Unsa kini sila?” Siya mitubag kanako, “Mao kini ang mga sungay nga mipatibulaag sa Juda, sa Israel ug sa Jerusalem.”

20Unya ang Ginoo mipakita kanako sa upat ka mga panday. 21Nangutana ako, “Unsa man kining ilang pagabuhaton?” Siya mitubag, “Mao kini ang mga sungay nga magpatibulaag sa Juda aron wala nay makapaisa sa ilang mga ulo, Apan ang mga panday miabot aron sa paglisang kanila ug paglabay kanila kining sungay sa mga nasud nga miisa sa ilang mga sungay batok sa yuta sa Juda sa pagpatibulaag sa iyang katawhan.”