Ọjọ́ iwájú Jerusalẹmu
1Ègbé ni fún ìlú aninilára,
ọlọ̀tẹ̀ àti aláìmọ́.
2Òun kò gbọ́rọ̀ sí ẹnikẹ́ni,
òun kò gba ìtọ́ni,
òun kò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa,
bẹ́ẹ̀ ni òun kò súnmọ́ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀.
3Àwọn olórí rẹ̀ jẹ́ kìnnìún tí ń ké ramúramù,
àwọn onídàájọ́ rẹ̀, ìkookò àṣálẹ́ ni wọn,
wọn kò sì fi nǹkan kan kalẹ̀ fún òwúrọ̀.
4Àwọn wòlíì rẹ̀ gbéraga,
wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn.
Àwọn àlùfáà rẹ̀ ti ba ibi mímọ́ jẹ́,
wọ́n sì rú òfin.
5Olúwa ni àárín rẹ̀ jẹ́ olódodo;
kì yóò ṣe ohun tí kò tọ̀nà.
Àràárọ̀ ni ó máa ń mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sí ìmọ́lẹ̀,
kì í sì kùnà ní gbogbo ọjọ́ tuntun,
síbẹ̀ àwọn aláìṣòótọ́ kò mọ ìtìjú.
6“Èmi ti ké àwọn orílẹ̀-èdè kúrò,
ilé gíga wọn sì ti bàjẹ́.
Mo ti fi ìgboro wọn sílẹ̀ ní òfo
tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnìkankan kò kọjá níbẹ̀.
Ìlú wọn parun tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí
ẹnìkan tí yóò ṣẹ́kù,
kò sì ní sí ẹnìkan rárá.
7Èmi wí fún ìlú náà wí pé
‘Nítòótọ́, ìwọ yóò bẹ̀rù mi,
ìwọ yóò sì gba ìtọ́ni!’
Bẹ́ẹ̀ ni, a kì yóò ké ibùgbé rẹ̀ kúrò
bí ó ti wù kí ń jẹ wọ́n ní yà tó.
Ṣùgbọ́n síbẹ̀ wọ́n sì tún ní ìtara
láti ṣe ìbàjẹ́.
8Nítorí náà ẹ dúró dè mí,” ni Olúwa wí,
“títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò fi jẹ́rìí sí yin;
nítorí ìpinnu mi ni láti kó orílẹ̀-èdè jọ
kí èmi kí ó lè kó ilẹ̀ ọba jọ
àti láti da ìbínú mi jáde sórí wọn,
àní gbogbo ìbínú gbígbóná mi.
Nítorí, gbogbo ayé
ni a ó fi iná owú mi jẹ run.
9“Nígbà náà ni èmi yóò yí èdè àwọn ènìyàn padà sí èdè mímọ́,
nítorí kí gbogbo wọn bá a lè máa pe orúkọ Olúwa,
láti fi ọkàn kan sìn ín.
10Láti òkè odò Etiopia,
àwọn olùjọsìn mi, àwọn ènìyàn mi tí ó ti fọ́nká,
yóò mú ọrẹ wá fún mi.
11Ní ọjọ́ náà ni a kì yóò sì dójútì
nítorí gbogbo iṣẹ́ ibi ni tí ó ti ṣẹ̀ sí mi,
nígbà náà ni èmi yóò mu
kúrò nínú ìlú yìí, àwọn tí ń yọ̀ nínú ìgbéraga wọn.
Ìwọ kì yóò sì gbéraga mọ́
ní òkè mímọ́ mi.
12Ṣùgbọ́n Èmi yóò fi àwọn ọlọ́kàn tútù
àti onírẹ̀lẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ni àárín rẹ̀,
wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa.
13Àwọn ìyókù Israẹli kì yóò hùwà
ibi, wọn kì yóò sọ̀rọ̀ èké,
bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò rí ahọ́n àrékérekè ní
ẹnu wọn. Àwọn yóò jẹun, wọn yóò sì dùbúlẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kì yóò dẹ́rùbà wọ́n.”
14Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Sioni,
kígbe sókè, ìwọ Israẹli!
Fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn,
ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.
15Olúwa ti mú ìdájọ́ rẹ wọ̀n-ọn-nì
kúrò, ó sì ti ti àwọn ọ̀tá rẹ padà sẹ́yìn.
Olúwa, ọba Israẹli wà pẹ̀lú rẹ,
Ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù ibi kan mọ́.
16Ní ọjọ́ náà, wọn yóò sọ fún Jerusalẹmu pé,
“Má ṣe bẹ̀rù Sioni;
má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀.
17Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ,
Ó ní agbára láti gbà ọ là.
Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀;
Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀,
Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.”
18“Èmi ó kó àwọn tí ó ń banújẹ́ fún àjọ̀dún tí a yàn jọ,
àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀;
àwọn tí ẹ̀gàn rẹ̀ jásí ẹ̀rù.
19Ní àkókò náà
ni èmi yóò dojúkọ àwọn
tí ń ni yín lára,
èmi yóò gba àtiro là,
èmi yóò sì ṣa àwọn tí ó ti fọ́nká jọ,
èmi yóò fi ìyìn àti ọlá fún wọn ní
gbogbo ilẹ̀ tí a bá ti dójútì wọ́n.
20Ní àkókò náà ni èmi yóò ṣà yín jọ;
Nígbà náà ni èmi yóò mú un yín padà wá sílé.
Èmi yóò fi ọlá àti ìyìn fún un yín
láàrín gbogbo ènìyàn àgbáyé,
nígbà tí èmi yóò yí ìgbèkùn yín
padà bọ sípò ní ojú ara yín,”
ni Olúwa wí.