Rutu pàdé Boasi
1Naomi ní ìbátan kan láti ìdílé Elimeleki ọkọ rẹ̀, aláàánú ọlọ́rọ̀, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Boasi.
2Rutu ará Moabu sì wí fún Naomi pé, “Jẹ́ kí èmi kí ó lọ sí inú oko láti ṣá ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tí èmi yóò bá ojúrere rẹ̀ pàdé.”
Naomi sì sọ fún un pé, “Máa lọ, ọmọbìnrin mi.” 3Rutu sì jáde lọ láti ṣá ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ lẹ́yìn wọn. Ó wá jẹ́ wí pé inú oko Boasi tí ó ti ìdílé Elimeleki wá ni ó lọ láìmọ̀-ọ́n-mọ̀.
4Nígbà náà ni Boasi dé láti Bẹtilẹhẹmu tí ó sì kí àwọn olùkórè wí pé, “Kí Olúwa wà pẹ̀lú yín.”
Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Kí Olúwa bùkún fún ọ.”
5Boasi sì béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùkórè wí pé, “Ti ta ni ọ̀dọ́mọbìnrin yẹn?”
6Ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olórí àwọn olùkórè náà sì fèsì pé, “Ọ̀dọ́mọbìnrin ará Moabu tí ó tẹ̀lé Naomi wá láti ilẹ̀ Moabu ni. 7Ó sọ wí pé, ‘Kí ń jọ̀wọ́ jẹ́ kí òun máa ṣá ọkà lẹ́yìn àwọn olùkórè.’ Ó sì ti ń ṣe iṣẹ́ kárakára láti òwúrọ̀ títí di ìsinsin yìí nínú oko àyàfi ìgbà tí ó lọ láti sinmi fún ìgbà díẹ̀ lábẹ́ ibojì.”
8Nígbà náà ni Boasi sọ fún Rutu pé, “Gbọ́ ọmọbìnrin mi, má ṣe lọ sí oko mìíràn láti ṣá ọkà, má sì ṣe kúrò ní ibi. Dúró níbí pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi. 9Wo ibi tí wọ́n ti ń kórè kí o sì máa tẹ̀lé àwọn obìnrin. Mo ti pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin kí wọ́n má ṣe fi ọwọ́ kàn ọ́. Nígbàkúgbà tí òǹgbẹ bá sì ń gbẹ ọ́, lọ kí ó sì mu omi nínú àmù èyí tí àwọn ọkùnrin ti pọn omi sí nínú.”
10Rutu wólẹ̀, ó sì wí fún Boasi pé, “Èéṣe tí èmi fi bá ojúrere rẹ pàdé tó báyìí, tí o sì kíyèsi mi, èmi àjèjì àti àlejò?”
11Boasi sì fèsì wí pé, “Èmi ti gbọ́ gbogbo bí o ti ń ṣe sí ìyá ọkọ ọ̀ rẹ láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú àti bí o ti ṣe fi baba àti ìyá rẹ àti ilẹ̀ rẹ sílẹ̀, tí o sì wá láti gbé láàrín àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ rí. 12Kí Olúwa kí ó san ẹ̀san ohun tí ìwọ ṣe fún ọ. Kí o sì gba èrè kíkún láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run Israẹli, abẹ́ ìyẹ́ ẹni tí ìwọ sá wá fún ààbò.”
13Rutu sì fèsì wí pé, “Kí èmi kí ó máa rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ rẹ síwájú sí i olúwa mi. Ìwọ ti tù mí nínú nípa sísọ ọ̀rọ̀ rere sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò tó ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.”
14Nígbà tí àkókò oúnjẹ sì tó, Boasi sọ fún Rutu pé, “Wá gba ìwọ̀n àkàrà yìí kí o sì fi run wáìnì kíkan.”
Òun sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùkórè, Boasi sì fún un ní ọkà yíyan. Òun sì jẹ́, ó yó, ó sì tún ṣẹ́kù. 15Nígbà tí ó sì dìde láti máa ṣá ọkà, Boasi pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ wí pé, “Bí ó tilẹ̀ ń ṣà láàrín oko ọkà pàápàá, ẹ má ṣe dí i lọ́wọ́. 16Bí kò ṣe pé kí ẹ mú lára àwọn ìtí sílẹ̀ fún láti ṣá, kí ẹ má sì ṣe ba a wí.”
17Rutu sì ń ṣá ọkà títí ó fi di ìrọ̀lẹ́, nígbà tí ó sì pa ọkà barle tí ó rí ṣà, tí ó sì fẹ́ ẹ tán, èyí tí ó rí sì tó ìwọ̀n garawa kan (lítà méjìlélógún). 18Ó sì gbé e, ó sì lọ sí ìlú, ìyá ọkọ rẹ sì rí ọkà tí ó rí ṣà bi o tí pọ̀ tó, Rutu sì mú oúnjẹ tí ó jẹ kù lẹ́yìn tí ó ti yó tan fún ìyá ọkọ rẹ̀.
19Ìyá ọkọ rẹ̀ sì bi í léèrè wí pé, “Níbo ni ìwọ ti ṣá ọkà lónìí? Àti wí pé oko ta ni ìwọ gbé ṣiṣẹ́? Alábùkún fún ni ọkùnrin náà tí ó bojú wò ọ.”
Rutu sì sọ ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀ pé, “Ní oko ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Boasi ni mo ti ṣiṣẹ́ lónìí.”
20Naomi sì wí fún un pé, “Kí Olúwa, kí ó bùkún fún ọkùnrin náà. Ọlọ́run kò dáwọ́ oore àti àánú ṣíṣe sí àwọn alààyè àti òkú dúró.” Naomi sì sọ síwájú sí i wí pé, “Ìbátan tí ó súnmọ́ wa pẹ́kípẹ́kí ni ọkùnrin náà ń ṣe, ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ra ohun ìní ìdílé padà.”
21Rutu, ará Moabu sì wí pé, “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó sọ fún mi pé, ‘Kí ń máa ṣá ọkà pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ òun, títí wọn yóò fi parí ìkórè.’ ”
22Naomi sì sọ fún Rutu, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, “Ìbá dára bí ó bá le bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́. Nítorí pé wọ́n le è dà ọ́ láàmú bí o bá lọ sí oko ẹlòmíràn.”
23Rutu sì bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin Boasi ṣiṣẹ́ títí tí wọ́n fi parí ìkórè ọkà barle àti ti jéró. Ó sì ń gbé pẹ̀lú ìyá ọkọ rẹ̀.
روت و بوعز
1در بيتلحم مرد ثروتمندی به نام بوعز زندگی میكرد كه از بستگان شوهر نعومی بود.
2روزی روت به نعومی گفت: «اجازه بده به كشتزارها بروم و در زمين كسی كه به من اجازهٔ خوشهچينی بدهد خوشههايی را كه بعد از درو باقی میماند، جمع كنم.»2:2 نگاه کنيد به لاويان 19:9و10؛ تثنيه 24:19.
نعومی گفت: «بسيار خوب دخترم، برو.»
3پس روت به كشتزار رفته، مشغول خوشهچينی شد. اتفاقاً كشتزاری كه او در آن خوشه میچيد از آن بوعز، خويشاوند شوهر نعومی بود. 4در اين وقت، بوعز از شهر به كشتزار آمد. او به دروگران سلام كرده، گفت: «خداوند با شما باشد.»
آنها نيز در جواب گفتند: «خداوند تو را بركت دهد.»
5سپس بوعز از سركارگرش پرسيد: «اين زنی كه خوشه میچيند كيست؟»
6او جواب داد: «اين همان زن موآبی است كه همراه نعومی از موآب آمده است. 7او امروز صبح به اينجا آمد و از من اجازه گرفت تا به دنبال دروگران خوشه بچيند. از صبح تا حالا مشغول خوشهچينی است و فقط كمی زير سايبان استراحت كرده است.»
8-9بوعز پيش روت رفت و به او گفت: «گوش كن دخترم، به كشتزار ديگری نرو، همینجا با كنيزان من باش و در كشتراز من به دنبال دروگران خوشهچينی كن. به كارگرانم دستور دادهام كه مزاحم تو نشوند. هر وقت تشنه شدی برو و از كوزههای آبِ آنها بنوش.»
10روت رو بر زمين نهاد و از او تشكر كرد و گفت: «چرا با اينكه میدانيد من يک بيگانهام، مرا مورد لطف خود قرار میدهيد؟»
11بوعز جواب داد: «میدانم پس از مرگ شوهرت چقدر به مادر شوهرت محبت كردهای و چگونه به خاطر او پدر و مادر و زادگاه خود را ترک كرده و با وی به اينجا آمدهای تا در ميان قومی زندگی كنی كه آنها را نمیشناختی. 12خداوند، خدای اسرائيل كه به او پناه آوردهای پاداش اين فداكاری تو را بدهد.»
13روت در پاسخ وی گفت: «سرور من، شما نسبت به من خيلی لطف داريد. من حتی يكی از كنيزان شما نيز به حساب نمیآيم ولی با اين وجود با سخنانتان مرا دلداری میدهيد!»
14موقع نهار، بوعز او را صدا زده، گفت: «بيا غذا بخور.» روت رفت و پيش دروگرها نشست و بوعز خوراكی پيش او گذاشت و روت خورد و سير شد و از آن خوراكی مقداری نيز باقی ماند. 15-16وقتی روت به سركارش رفت، بوعز به دروگرانش گفت: «بگذاريد او هر جا میخواهد خوشه جمع كند حتی در ميان بافهها، و مزاحم او نشويد. در ضمن عمداً خوشههايی از بافهها بيرون كشيده، بر زمين بريزيد تا او آنها را جمع كند.»
17روت تمام روز در آن كشتزار خوشهچينی كرد. غروب، آنچه را كه جمع كرده بود كوبيد و حدود ده كيلو جو به دست آمد. 18او آن را با باقيماندهٔ خوراک ظهر برداشته به شهر پيش مادر شوهرش برد.
19نعومی گفت: «دخترم، امروز در كجا خوشهچينی كردی؟ خدا به آن كسی كه به تو توجه نموده است بركت دهد.»
روت همهٔ ماجرا را برای مادر شوهرش تعريف كرد و گفت كه نام صاحب كشتزار بوعز است.
20نعومی به عروس خود گفت: «خداوند او را بركت دهد! خداوند به شوهر مرحوم تو احسان نموده و لطف خود را از ما دريغ نداشته است. آن شخص از بستگان نزديک ماست كه میتواند ولی ما باشد.»
21روت به مادر شوهرش گفت: «او به من گفت كه تا پايان فصل درو میتوانم در كشتزارش به دنبال دروگرانش خوشهچينی كنم.»
22نعومی گفت: «بله دخترم، بهتر است با كنيزان بوعز خوشهچينی كنی. برای تو كشتزار بوعز از هر جای ديگری امنتر است.»
23پس روت تا پايان فصل درو جو و گندم نزد كنيزان بوعز به خوشهچينی مشغول شد. او همچنان با مادر شوهرش زندگی میكرد.