Romu 7 – YCB & CARST

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Romu 7:1-25

Àpèjúwe kan láti inú ìgbéyàwó

1Ẹ̀yin kò ha mọ̀, ara: nítorí èmí bá àwọn tí ó mọ òfin sọ̀rọ̀ pé, òfin ní ipá lórí ènìyàn níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà láààyè nìkan? 27.2: 1Kọ 7.39.Fún àpẹẹrẹ, nípa òfin ní a de obìnrin mọ́ ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ náà wà láààyè, ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, a tú u sílẹ̀ kúrò nínú òfin ìgbéyàwó náà. 3Nígbà náà, bí ó bá fẹ́ ọkùnrin mìíràn nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láààyè, panṣágà ní a ó pè é. Ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin náà, kí yóò sì jẹ́ panṣágà bí ó bá ní ọkọ mìíràn.

47.4: Ro 6.2,11; Ga 2.19; Kl 1.22.Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin pẹ̀lú ti di òkú sí òfin nípa ara Kristi, kí ẹ̀yin kí ó lè ní ẹlòmíràn, àní ẹni náà tí a jí dìde kúrò nínú òkú, kí àwa kí ó lè so èso fún Ọlọ́run. 57.5: Ro 6.13,21; 8.8; Jk 1.15.Nítorí ìgbà tí a wa nípa ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ nípa ti òfin, ma ń ṣiṣẹ́ nínú wa, tí a sì ń so èso tí ó yẹ fún ikú. 6Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa kíkú ohun tó so wá pọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, a ti tú wa sílẹ̀ kúrò nínú òfin, kí a lè sin ín ní ìlànà tuntun ti Ẹ̀mí, kì í ṣe ní ìlànà àtijọ́ tí ìwé òfin gùnlé.

Bíbá ẹ̀ṣẹ̀ wọ ìjàkadì

77.7: Ro 3.20; 5.20; Ek 20.17; De 5.21.Ǹjẹ́ àwa o ha ti wí, nígbà náà? Òfin ha ń ṣe ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n èmi kì bá tí mọ ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́, bí kò ṣe nípa òfin. Èmi kì bá tí mọ ojúkòkòrò, bí kò ṣe bí òfin ti wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò.” 87.8: 1Kọ 15.56.Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ sì ti ipa òfin rí ààyè ṣiṣẹ́ onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nínú mi. Nítorí láìsí òfin, ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ikú. 9Èmi sì ti wà láààyè láìsí òfin nígbà kan rí; ṣùgbọ́n nígbà tí òfin dé, ẹ̀ṣẹ̀ sọjí èmi sì kú. 107.10: Le 18.5; Ro 10.5.Mo ṣàkíyèsí pé òfin tí ó yẹ kí ó mú ìyè wá ni ó padà mú ikú wá. 11Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ti ipa òfin rí ààyè láti tàn mí jẹ, ó sì ti ipa òfin ṣe ikú pa mi. 127.12: 1Tm 1.8.Bẹ́ẹ̀ ni mímọ́ ni òfin, mímọ́ sì ni àṣẹ, àti òdodo, àti dídára.

13Ǹjẹ́ ohun tí ó dára ha di ikú fún mi bí? Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n kí ẹ̀ṣẹ̀, kí ó lè farahàn bí ẹ̀ṣẹ̀, ó ń ti ipa ohun tí ó dára ṣiṣẹ́ ikú nínú mi, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè ti ipa òfin di búburú rékọjá.

147.14: 1Kọ 3.1.Nítorí àwa mọ̀ pé ohun ẹ̀mí ni òfin, ṣùgbọ́n ẹni ti ara ni èmi, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. 157.15: Ga 5.17.Èmi pàápàá, kò mọ̀ ohun tí èmi ń ṣe. Nítorí pé, ohun tí mo fẹ́ ṣe gan an n kò ṣe é, ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìíra ni mo ń ṣe. 16Ṣùgbọ́n bí mo bá ṣe ohun tí èmi kò fẹ́, mo gbà pé òfin dára. 17Ṣùgbọ́n bí ọ̀rọ̀ ṣe rí yìí kì í ṣe èmi ni ó ṣe é bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi. 18Èmi mọ̀ dájú pé kò sí ohun tí ó dára kan tí ń gbé inú mi, àní, nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ mi. Èmi fẹ́ ṣe èyí tí ó dára, ṣùgbọ́n kò sé é ṣe. 19Nítorí ohun tí èmi ṣe kì í ṣe ohun rere tí èmi fẹ́ láti ṣe; rárá, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́, èyí nì ni èmi ń ṣe. 20Nísinsin yìí, bí mo bá ń ṣe nǹkan tí n kò fẹ́ láti ṣe, kì í ṣe èmí fúnra mi ni ó ṣe é, bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ nínú ni ó ṣe é.

21Nítorí náà, èmi kíyèsi pé òfin ní ń ṣiṣẹ́ nínú mi, nígbà tí èmi bá fẹ́ ṣe rere, búburú wà níbẹ̀ pẹ̀lú mi. 227.22: Sm 1.2.Nínú ìjìnlẹ̀ ọkàn mi mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run; 237.23: 5.17.mo rí òfin mìíràn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi, èyí tí ń gbógun ti òfin tó tinú ọkàn mi wá, èyí tí ó sọ mi di ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi. 247.24: Ro 6.6; Kl 2.11.Èmi ẹni òsì! Ta ni yóò ha gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ara kíkú yìí? 25Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa!

Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi fúnra mi jẹ́ ẹrú sí òfin Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ mo jẹ́ ẹrú fún òfin ẹ̀ṣẹ̀.

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

Римлянам 7:1-25

Свободны от Закона

1Братья, я обращаюсь к вам как к знающим Закон; разве вы не знаете, что Закон имеет силу над человеком, пока человек жив? 2Замужняя женщина, например, связана законом о браке со своим мужем, пока он жив. Если же муж умрёт, она освобождается от этого закона. 3И поэтому, если она выходит замуж за другого, когда её муж ещё жив, она тем самым нарушает супружескую верность, но если её муж умер, то она свободна от закона и не может быть обвинена в супружеской измене, выйдя замуж за другого.

4Также и с вами, братья мои. Вы умерли для Закона через телесную смерть Масеха, чтобы вам принадлежать Другому, Тому, Кто был воскрешён из мёртвых, и приносить плод Всевышнему. 5Когда мы жили сообразно своей грешной природе, то Закон пробуждал в нас греховные желания, действовавшие в членах нашего тела, и плодом их была смерть. 6Сейчас же, когда мы умерли для того, что когда-то нас связывало, мы были освобождены от Закона, чтобы служить Всевышнему по-новому, с помощью Святого Духа7:6 Или: «в обновлённом духе»., а не как раньше – по букве Закона.

Закон и грех

7Что же это значит? Что Закон – это грех? Конечно нет. Однако я бы и не знал, что такое грех, если бы не существовал Закон. Я бы, например, не знал, что значит желать, если бы Закон не говорил: «Не пожелай»7:7 Исх. 20:17; Втор. 5:21.. 8Грех, найдя предлог в этом повелении, породил во мне всевозможные желания, но без Закона грех мёртв. 9Я7:9 Я – большинство толкователей верит в то, что здесь и далее Павлус говорит о себе и своём жизненном опыте, но здесь также возможен намёк на Адама, или народ Исроила, или даже на любого человека, включая и ныне живущих. когда-то жил, не зная Закона, но когда я узнал повеление Всевышнего, грех во мне ожил, 10а я умер. Оказалось, что повеление, которое должно было принести жизнь, принесло смерть. 11Потому что грех, используя само повеление, обманул меня и привёл к духовной смерти! 12Но Закон святой, и повеление также святое, справедливое и хорошее.

13Так что же, хорошее принесло мне смерть? Нет! Но чтобы грех мог проявить себя как грех, он, действуя через хорошее, произвёл во мне смерть. И таким образом, через повеление, мы смогли яснее увидеть, насколько ужасен грех.

Внутренняя борьба

14Мы знаем, что Закон духовен. Я же телесен, продан в рабство греху. 15Я и сам не понимаю, что делаю. То, что я хочу, я не делаю, а вместо этого делаю то, что ненавижу. 16И если я делаю то, чего не хочу, то я тем самым соглашаюсь, что сам Закон хорош. 17Ведь это уже делаю не я сам, а грех, который живёт во мне. 18Я знаю, что во мне, то есть в моей греховной природе, нет ничего хорошего, потому что я хочу делать добро, но не могу. 19И то, что я делаю, – это не то добро, которое я хотел бы делать. Я продолжаю делать зло, которого не хочу делать. 20Итак, если я делаю то, чего не хочу, то это уже не я делаю, а живущий во мне грех.

21Я обнаружил, что здесь действует такой закон: когда я хочу делать добро, то зло уже тут как тут. 22Внутренне я радуюсь Закону Всевышнего, 23но в моём теле действует другой закон. Этот закон ведёт войну против закона моего разума и делает меня пленником закона греха, который действует в членах моего тела. 24Несчастный я человек! Кто бы избавил меня от этого тела смерти? 25Но благодарение Всевышнему, Который сделал это через Исо Масеха, нашего Повелителя!

Итак, моим разумом я служу Закону Всевышнего, а телом я раб закону греха.