Romu 2 – YCB & NUB

Yoruba Contemporary Bible

Romu 2:1-29

Ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run

12.1: Ro 14.22.Nítorí náà, aláìríwí ni ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́ tí ń dá ni lẹ́jọ́: nítorí nínú ohun tí ìwọ ń ṣe ìdájọ́ ẹlòmíràn, ìwọ ń dá ara rẹ lẹ́bi; nítorí ìwọ tí ń dájọ́ ń ṣe ohun kan náà nínú èyí tí ìwọ ń dá ni lẹ́jọ́. 2Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé ìdájọ́ Ọlọ́run jẹ́ òtítọ́ si gbogbo àwọn tí ó ń ṣe irú ohun báwọ̀nyí. 3Nítorí bí ìwọ tí ń ṣe ènìyàn lásán bá ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń ṣe irú ohun báwọ̀nyí, tí ìwọ tìkára rẹ ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ ro èyí pé ìwọ o yọ nínú ìdájọ́ Ọlọ́run bí? 42.4: Ef 1.7; 2.7; Fp 4.19; Kl 1.27.Tàbí ìwọ ń gàn ọrọ̀ oore àti ìpamọ́ra àti sùúrù rẹ̀? Ìwọ kò ha mọ̀ pé oore Ọlọ́run ni ó ń fà ọ́ lọ sì ìrònúpìwàdà?

5Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí líle àti àìronúpìwàdà ọkàn rẹ̀, ìwọ ń to ìbínú jọ fún ara rẹ de ọjọ́ ìbínú àti ìfihàn ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run. 62.6: Mt 16.27; 1Kọ 3.8; 2Kọ 5.10; If 22.12.Ọlọ́run yóò san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀: 7Àwọn ẹni tí ń fi sùúrù nínú rere ṣíṣe, wá ògo àti ọlá àti àìdíbàjẹ́ ni yóò fi ìyè àìnípẹ̀kun fún. 8Ṣùgbọ́n fún àwọn onímọ̀-tara-ẹni-nìkan, tí wọn kò sì gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọn ń tẹ̀lé ọ̀nà búburú, wọn yóò ní ìrírí ìrunú àti ìbínú rẹ̀. 9Ìpọ́njú àti ìrora, yóò wà lórí olúkúlùkù ọkàn ènìyàn tí ń hùwà ibi: ti Júù ṣáájú, àti àwọn Helleni pẹ̀lú; 10ṣùgbọ́n ògo, àti ọlá, àti àlàáfíà, fún olúkúlùkù ẹni tí ń hùwà rere, fún Júù, ṣáájú àti fún àwọn Helleni pẹ̀lú: 11Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn.

122.12: Ro 3.19; 1Kọ 9.21.Gbogbo àwọn tí ó ṣẹ̀ ní àìlófin wọn ó sì ṣègbé láìlófin: àti iye àwọn tí ó ṣẹ̀ lábẹ́ òfin, àwọn ni a ó fi òfin dá lẹ́jọ́; 132.13: Jk 1.22-23,25.Nítorí kì í ṣe àwọn olùgbọ́ òfin ni ẹni ìdáláre lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn olùṣe òfin ni a ó dá láre. 14Nítorí nígbà tí àwọn aláìkọlà, tí kò ní òfin, bá ṣe ohun tí ó wà nínú òfin nípa ìwà ẹ̀dá, àwọn wọ̀nyí, jẹ́ òfin fún ara wọn bí wọn kò tilẹ̀ ní òfin. 15Àwọn ẹni tí ó fihàn pé, a kọ̀wé iṣẹ́ òfin sí wọn lọ́kàn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn pẹ̀lú sì tún ń jẹ́ wọn lẹ́rìí, àti pé, èrò ọkàn wọn tí ó jẹ́ ọ̀nà ìfinisùn, sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn ní ìsinsin yìí. 162.16: Su 12.14; Ro 16.25; 1Kọ 4.5.Èyí yóò farahàn ní ọjọ́ náà nígbà tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ Jesu Kristi ṣe ìdájọ́ àwọn àṣírí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere mi.

Àwọn Júù àti òfin

17Ṣùgbọ́n bí a bá ń pe ìwọ ní Júù, tí o sì sinmi lé òfin, tí o sì ń ṣògo nínú ìbálòpọ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run, 182.18: Fp 1.10.tí o sì mọ ìfẹ́ rẹ̀, tí o sì fọwọ́sí ohun tí ó dára jùlọ, nítorí tí a ti kọ́ ọ ní òfin; 19tí o sì dá ara rẹ lójú pé ìwọ ni amọ̀nà àwọn afọ́jú, ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà ni òkùnkùn, 202.20: Ro 6.17; 2Tm 1.13.Olùkọ́ àwọn aláìmòye, olùkọ́ àwọn ọmọdé, ẹni tí ó ní ètò ìmọ̀ àti òtítọ́ òfin lọ́wọ́, 212.21: Mt 23.3-4.Ǹjẹ́ ìwọ tí o ń kọ́ ẹlòmíràn, ìwọ kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ tí ó ń wàásù kí ènìyàn má jalè, ìwọ ha ń jalè bí? 22Ìwọ tí o wí pé, kí ènìyàn má ṣe panṣágà, ìwọ ń ṣe panṣágà bí? Ìwọ tí o kórìíra òrìṣà, ìwọ ń ja tẹmpili ní olè bí? 23Ìwọ ti ń ṣògo nínú òfin, ìwọ ha ń bu Ọlọ́run ni ọlá kù nípa rírú òfin? 242.24: Isa 52.5.Nítorí gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́, “Orúkọ Ọlọ́run sá à di ìsọ̀rọ̀-òdì sí láàrín àwọn aláìkọlà nítorí yín.”

252.25: Jr 9.25.Nítorí ìkọlà ní èrè nítòótọ́, bí ìwọ bá pa òfin mọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá jẹ́ arúfin, ìkọlà rẹ di àìkọlà. 262.26: 1Kọ 7.19; Ap 10.35.Nítorí náà bí àwọn aláìkọlà bá pa ìlànà òfin mọ́, a kì yóò ha kà wọ́n sí àwọn tí a kọ nílà bí? 272.27: Mt 12.41.Aláìkọlà nípa àdánidá, bí ó bá pa òfin mọ́, yóò dá ẹ̀bi fún ìwọ tí ó jẹ́ arúfin nípa ti àkọsílẹ̀ òfin àti ìkọlà.

282.28: Mt 3.9; Jh 8.39; Ro 9.6-7; Ga 6.15.Kì í ṣe èyí tí ó farahàn ní òde ni Júù, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe èyí tí ó farahàn ní ara ni ìkọlà: 292.29: 2Kọ 3.6; Fp 3.3; Kl 2.11; 1Pt 3.4.Ṣùgbọ́n Júù ti inú ni Júù, àti ìkọlà sì ni ti ọkàn nínú ẹ̀mí tí kì í ṣe ti àkọsílẹ̀, ìyìn ẹni tí kò sí lọ́dọ̀ ènìyàn, bí kò ṣe lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

Swedish Contemporary Bible

Romarbrevet 2:1-29

Guds dom över synden

1Därför har du ingen ursäkt för att döma andra, vem du än är. Om du dömer en annan för det han gör, dömer du ju samtidigt dig själv, eftersom du handlar på samma sätt som han. 2Vi vet att Gud är rättvis när han dömer de människor som lever på det här viset. 3Men du som dömer dina medmänniskor, du tror väl inte att Gud bara ska ha överseende med dig, trots att du handlar precis likadant? 4Föraktar du Guds stora godhet, tolerans och tålamod? Inser du inte att han genom sin godhet vill få dig att vända om?

5Med din envishet och ditt obotfärdiga hjärta drar du över dig vrede till vredens dag, då det ska visa sig att Gud dömer rättvist. 6Då ska var och en få lön efter sina gärningar. 7Gud ska ge evigt liv åt dem som utan att tröttna fortsätter att göra det goda och söker härlighet, ära och odödlighet. 8Men han ska i sin vrede straffa dem som bara tänker på sig själva, vänder sig bort från sanningen och gör det som är orätt. 9Nöd och ångest ska drabba varje människa som gör det onda, först juden, sedan greken. 10Men härlighet, ära och frid ges till var och en som gör det goda, först juden, sedan greken. 11Gud behandlar alla lika.

12Alla som syndar utan lag ska också förgås utan lag, och alla som syndar under lagen ska dömas genom lagen. 13Det är nämligen inte de som hör lagen som blir rättfärdiga inför Gud, utan de som följer den. 14När andra folk, som inte har lagen, ändå av naturen lyder det som står i den, är de en lag för sig själva, trots att de inte har lagen. 15De visar genom sina handlingar att lagen är skriven i deras hjärtan. Deras samveten talar ju genast om för dem om de handlar rätt eller fel. 16Att det är så kommer att visa sig den dag då Gud ska döma det dolda hos människorna, enligt det evangelium jag har fått från Jesus Kristus.

Judarna och Moses lag

17Du som kallar dig jude litar på lagen och är stolt över din Gud, 18känner hans vilja och kan bedöma det väsentliga, eftersom lagen ger dig vägledning. 19Du anser dig kunna leda de blinda och vara ett ljus för dem som lever i mörker, 20vägleda de oförståndiga och undervisa de omogna, för du har både kunskap och sanning i lagens gestalt. 21Du undervisar andra men inte dig själv. Du säger till andra att de inte ska stjäla, men är själv en tjuv. 22Du säger att det är fel att vara otrogen i äktenskapet, men är själv otrogen. Du avskyr avgudar, men plundrar avgudatempel.

23Du är stolt över lagen men drar skam över Gud genom att bryta den. 24Det står ju skrivet: ”Andra folk hånar Guds namn på grund av er.”2:24 Se Jes 52:5.

25Omskärelsen2:25 Omskärelse, dvs. att skära bort förhuden på männen, var ett sätt att ingå förbund som praktiserades av många folk. Men judarna ingick förbund med Gud själv. Jfr 1 Mos 17:9-14. gör bara nytta om du lyder lagen. Men om du inte gör det, då är du som en oomskuren. 26Om någon oomskuren lyder lagens bud, ska han inte betraktas som omskuren? 27Han som fysiskt inte är omskuren men ändå följer lagen kommer att döma dig, som har både skriften och omskärelsen men bryter mot lagen.

28Jude är man nämligen inte bara till det yttre, och inte heller är omskärelsen bara det yttre och fysiska. 29Nej, jude är man i sitt inre, och den verkliga omskärelsen är det som sker i det inre, i hjärtat, genom Anden, inte bokstavligt. Den människan blir ärad av Gud, inte av människor.