Oniwaasu 6 – YCB & OL

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Oniwaasu 6:1-12

1Mo ti rí ibi mìíràn lábẹ́ oòrùn. 2Ọlọ́run fún ọkùnrin kan ní ọrọ̀, ọlá àti ọlà kí ó má ba à ṣe aláìní ohunkóhun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kò fún un ní àǹfààní láti gbádùn wọn, dípò èyí, àlejò ni ó ń gbádùn wọn. Asán ni èyí, ààrùn búburú gbá à ni.

3Ọkùnrin kan le è ní ọgọ́rùn-ún ọmọ kí ó sì wà láààyè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, síbẹ̀ kò sí bí ó ti le wà láààyè pẹ́ tó, bí kò bá le è gbádùn ohun ìní rẹ̀ kí ó sì gba ìsìnkú tí ó tọ́, mo sọ wí pé ọlẹ̀ ọmọ tí a sin sàn jù ú lọ. 4Ó wà láìní ìtumọ̀, ó lọ nínú òkùnkùn, nínú òkùnkùn sì ni orúkọ rẹ̀ fi ara pamọ́ sí. 5Bí ó ti jẹ́ wí pé kò rí oòrùn tàbí mọ ohunkóhun, ó ní ọ̀pọ̀ ìsinmi ju ti ọkùnrin náà lọ. 6Kódà, bí ó wà láààyè fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún méjì yípo ṣùgbọ́n tí ó kùnà láti gbádùn ohun ìní rẹ̀. Kì í ṣe ibìkan ni gbogbo wọn ń lọ?

7Gbogbo wàhálà tí ènìyàn ń ṣe nítorí àtijẹ ni

síbẹ̀ ikùn rẹ̀ kò yó rí.

8Kí ni àǹfààní tí ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní lórí aṣiwèrè?

Kí ni èrè tálákà ènìyàn

nípa mímọ bí yóò ṣe hùwà níwájú àwọn tókù?

9Ohun tí ojú rí sàn

ju ìfẹnuwákiri lọ.

Asán ni eléyìí pẹ̀lú

ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

10Ohunkóhun tí ó bá ti wà ti ní orúkọ,

ohun tí ènìyàn jẹ́ sì ti di mí mọ̀;

kò sí ènìyàn tí ó le è ja ìjàkadì

pẹ̀lú ẹni tí ó lágbára jù ú lọ.

11Ọ̀rọ̀ púpọ̀,

kì í ní ìtumọ̀

èrè wo ni ènìyàn ń rí nínú rẹ̀?

12Àbí, ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún ènìyàn ní ayé fún ọjọ́ ayé kúkúrú àti asán tí ó ń là kọjá gẹ́gẹ́ bí òjìji? Ta ni ó le è sọ fún mi, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn lẹ́yìn tí ó bá lọ tán? Kò sí!

O Livro

Eclesiastes 6:1-12

1Há um mal que vi acontecer, frequentemente, em toda a parte e com toda a gente. 2Deus deu a alguns grandes riquezas e honra, de tal forma que podem ter tudo quanto pretendem, mas não lhes permite gozarem do que têm. Outros, vindos de outro lado, é que ficam com o que eles tinham! Ora isto é ilusão e sofrimento cruel.

3Se um indivíduo tiver uma centena de filhos e filhas, e viver até ser muito velho, mas ao morrer deixar tão pouco dinheiro que os filhos nem sequer lhe possam fazer um funeral decente, digo que era melhor que tivesse sido um nado-morto. 4O seu nascimento não teria sido considerado e acabaria por ir para as trevas, sem ter tido um nome. 5Não teria visto o Sol e nem sequer se daria conta da sua existência, e isso teria sido melhor do que ser velho e infeliz. 6Ainda que viva dois mil anos, mas não tiver felicidade, de que serve isso? Afinal, não estamos todos a caminhar para o mesmo fim?

7Todo o homem trabalha para comer e, contudo, o seu apetite jamais encontra satisfação. 8Que vantagem tem, então, o sábio sobre o insensato, ou que vantagem tem o pobre em saber como enfrentar a vida?

9Mais vale aquilo que se vê do que aquilo que se imagina. O andar só a sonhar com coisas belas é loucura, é andar a correr atrás do vento.

10Todas as coisas têm já o seu destino fixado; muito antes, já está decidido aquilo que qualquer homem deverá ser. De nada serve discutir com Deus sobre o nosso destino.

11Quanto mais se falar, menos significado terão as nossas palavras; por isso, de que serve procurar falar a todo o custo?

12Nestes poucos dias da nossa vida de ilusão, quem é que nos pode dizer a melhor forma de desfrutar a vida que passa como uma sombra? Quem é que pode saber o futuro, depois de ter morrido?