Oniwaasu 4 – YCB & CARST

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Oniwaasu 4:1-16

Ìnilára, làálàá, àti àìlọ́rẹ̀ẹ́

1Mo sì tún wò ó, mo sì rí gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn,

mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni,

wọn kò sì ní olùtùnú kankan,

agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lára,

wọn kò sì ní olùtùnú kankan.

2Mo jowú àwọn tí wọ́n ti kú

tí wọ́n sì ti lọ,

ó sàn fún wọn ju àwọn

tí wọ́n sì wà láààyè lọ.

3Nítòótọ́, ẹni tí kò tí ì sí sàn ju

àwọn méjèèjì lọ:

ẹni tí kò tí ì rí iṣẹ́ búburú

tí ó ń lọ ní abẹ́ oòrùn.

4Mo sì tún mọ̀ pẹ̀lú, ìdí tí ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́ tagbára tagbára láti ṣe àṣeyọrí, nítorí pé wọn ń jowú àwọn aládùúgbò wọn ni. Ṣùgbọ́n, asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

5Aṣiwèrè ká ọwọ́ rẹ̀ kò

ó sì ba tara rẹ̀ jẹ́.

6Oúnjẹ ẹ̀kúnwọ́ kan pẹ̀lú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì pẹ̀lú wàhálà,

àti gbígba ìyànjú àti lé afẹ́fẹ́ lọ.

7Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo tún rí ohun asán kan lábẹ́ oòrùn.

8Ọkùnrin kan ṣoṣo dá wà;

kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbí.

Kò sí òpin nínú làálàá rẹ̀ gbogbo,

síbẹ̀, ọrọ̀ kò tẹ́ ojú rẹ̀ lọ́rùn.

Bẹ́ẹ̀ ni kò sì wí pé, “Nítorí ta ni èmí ṣe ń ṣe làálàá,

àti wí pé, èétiṣe tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi?”

Eléyìí náà asán ni,

iṣẹ́ òsì!

9Ẹni méjì sàn ju ẹnìkan,

nítorí wọ́n ní èrè rere fún làálàá wọn.

10Tí ọ̀kan bá ṣubú lulẹ̀,

ọ̀rẹ́ rẹ̀ le è ràn án lọ́wọ́ kí ó fà á sókè,

ṣùgbọ́n ìyọnu ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣubú

tí kò sì ní ẹni tí ó le è ràn án lọ́wọ́!

11Àti pẹ̀lú pé, bí ẹni méjì bá sùn pọ̀, wọn yóò móoru.

Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnìkan ṣe le è dá nìkan móoru?

12Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan,

àwọn méjì le è gbìjà ara wọn,

ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn ún yára fà já.

Asán ni ipò gíga

13Òtòṣì ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ tí ó ṣe ọlọ́gbọ́n, ó sàn ju arúgbó àti aṣiwèrè ọba lọ tí kò mọ bí yóò ti ṣe gba ìmọ̀ràn. 14Nítorí pé láti inú túbú ni ó ti jáde láti jẹ ọba, bí a tilẹ̀ bí i ní tálákà ní ìjọba rẹ̀. 15Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn lábẹ́ oòrùn, pẹ̀lú ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ kejì tí yóò gba ipò ọba yìí. 16Gbogbo àwọn tí ó wà níwájú wọn kò sì lópin, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ní ó jẹ ọba lé lórí, ẹni tí ó wà ní ipò yìí kò dùn mọ́ àwọn tí ó tẹ̀lé wọn nínú. Asán ni eléyìí pẹ̀lú jẹ́, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

Размышления 4:1-17

1И вновь посмотрел я и увидел все те угнетения, которые делаются под солнцем:

я видел слёзы угнетённых,

но никто их не утешит;

сила на стороне их угнетателей,

а у них нет утешителя.

2И посчитал я, что те, кто уже умер,

счастливее тех, кто ещё жив.

3Но лучше всего тому,

кто ещё не был рождён,

кто ещё не видел зла,

которое творится под солнцем.

4И увидел я, что весь труд и все достижения происходят от зависти людей друг к другу. И это тоже пустое, это – погоня за ветром.

5Глупый сидит сложа руки

и слабеет от голода.

6Лучше одна горсть с покоем,

чем две горсти с трудом

и погоней за ветром.

Одиночество

7И снова увидел я нечто пустое под солнцем:

8вот одинокий человек,

и никого нет рядом с ним;

нет у него ни сына, ни брата.

Трудам его нет конца,

но глаза его не насыщаются богатством.

«Для кого же я тружусь, – думает он, –

и почему я лишаю себя удовольствий?»

Это тоже пустое –

несчастное дело!

9Двоим лучше, чем одному,

потому что они получат хорошую награду за свой труд.

10Если один упадёт,

то его друг поможет ему встать.

Но горе тому, кто упадёт,

и не будет никого, кто помог бы ему подняться!

11И если двое лягут вместе, то им будет тепло.

Но как согреться одному?

12Хотя одного и можно одолеть,

двое смогут защититься.

Верёвка, свитая из трёх нитей, не скоро порвётся.

Возвышение – пусто

13Лучше бедный, но мудрый юноша, чем старый, но глупый царь, который уже не прислушивается к советам. 14Юноша вышел из темницы, чтобы стать царём, хотя он и родился бедным в своём царстве. 15Я увидел, что все, кто жил и ходил под солнцем, последовали за юношей – преемником царя. 16Не было числа народу, что был на его стороне. Но тем, кто родился позже, не был угоден преемник. Это тоже пустое, это – погоня за ветром.

Благоговение перед Всевышним

17Следи за своим поведением, когда идёшь в дом Всевышнего. Лучше прийти туда, чтобы слушать, нежели приносить необдуманную жертву, подобно глупцам, которые даже не знают, что творят зло.