Onidajį» 9 – YCB & APSD-CEB

BĆ­bĆ©lƬ MĆ­mį»Ģ YorĆ¹bĆ” ƒde ƒn

Onidajį» 9:1-57

Abimeleki

1Ní ọjọ́ kan Abimeleki ọmọ Jerubbaali lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin ìyá rẹ̀ ní Ṣekemu ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ àti gbogbo àwọn ìbátan ìyá rẹ̀ wí pé, 2“Ẹ bi gbogbo àwọn ará Ṣekemu léèrè, ‘Èwo ló sàn fún un yín, ṣé kí gbogbo àwọn àádọ́rin ọmọ Jerubbaali jẹ ọba lórí yín ni tàbí kí ẹnìkan ṣoṣo ṣe àkóso yín?’ Ṣùgbọ́n ẹ rántí pé ẹran-ara yín àti ẹ̀jẹ̀ yín ni èmi ń ṣe.”

3Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ sọ èyí ní etí àwọn ará Ṣekemu, ọkàn wọn fà sí àti tẹ̀lé Abimeleki torí, wọ́n sọ wí pé, “Arákùnrin wa ní í ṣe.” 4Wọ́n fún un ní àádọ́rin ṣékélì fàdákà láti ilé òrìṣà Baali-Beriti, Abimeleki fi owó náà gba àwọn jàǹdùkú àti aláìníláárí ènìyàn tí wọ́n sì di olùtẹ̀lé rẹ̀. 5Ó kó wọn lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Ofira, níbẹ̀ ní orí òkúta kan ṣoṣo ni ó ti pa àádọ́rin nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn Jerubbaali, ṣùgbọ́n Jotamu, àbíkẹ́yìn nínú àwọn ọmọ Jerubbaali, bọ́ yọ nítorí pé ó sá pamọ́. 6Gbogbo àwọn ará Ṣekemu àti àwọn ará Beti-Milo pàdé pọ̀ ní ẹ̀bá igi óákù ní ibi òpó ní Ṣekemu láti fi Abimeleki jẹ ọba.

7Nígbà tí wọ́n sọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí fún Jotamu, ó gun orí ṣóńṣó òkè Gerisimu lọ, ó sì ké lóhùn rara pé, “Ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin àgbàgbà Ṣekemu, kí Ọlọ́run le tẹ́tí sí yín. 8Ní ọjọ́ kan àwọn igi jáde lọ láti fi òróró yan ọba fún ara wọn. Wọ́n pe igi Olifi pé, ‘Wá ṣe ọba wa.’

9“Ṣùgbọ́n igi Olifi dá wọn lóhùn pé, ‘Èmi yóò ha fi òróró mi sílẹ̀ èyí tí a ń lò láti fi ọ̀wọ̀ fún àwọn ọlọ́run àti ènìyàn kí èmi sì wá ṣe olórí àwọn igi?’

10“Àwọn igi sọ fún igi ọ̀pọ̀tọ́ pé, ‘Wá jẹ ọba ní orí wa.’

11“Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀tọ́ dá wọn lóhùn pé, ‘Kí èmi fi èso mi tí ó dára tí ó sì dùn sílẹ̀ láti wá ṣe olórí àwọn igi?’

12“Àwọn igi sì tún sọ fún àjàrà pé, ‘Wá, kí o ṣe ọba wa.’

13“Ṣùgbọ́n àjàrà dáhùn pé, ‘Ṣé kí èmi dẹ́kun àti máa so èso wáìnì mi èyí tí ó ń mú inú Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn dùn láti máa ṣe olórí àwọn igi?’

14“Ní ìparí gbogbo àwọn igi lọ bá igi ẹ̀gún wọ́n sì sọ fún un pé, ‘Wá kí ó ṣe ọba wa.’

15“Igi ẹ̀gún dá àwọn igi lóhùn pé, ‘Bí olóòtítọ́ ni ẹ bá fẹ́ yàn mí ní ọba yín. Ẹ sá àsálà sí abẹ́ ibòòji mi; ṣùgbọ́n tí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí iná jáde láti inú igi ẹ̀gún kí ó sì jó àwọn igi kedari àti ti Lebanoni run!’

16“Báyìí tí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yin ṣe ohun tí ó ní ọlá àti pẹ̀lú ẹ̀mí òtítọ́ ní fífi Abimeleki jẹ ọba, tí ó bá ṣe pé ohun tí ó tọ́ ni ẹ ṣe sí Jerubbaali àti ìdílé rẹ̀, bí ẹ bá san ẹ̀san tó yẹ fún un. 17Nítorí pé baba mi jà nítorí yín, ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu láti gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Midiani; 18ṣùgbọ́n lónìí ẹ̀yin ṣọ̀tẹ̀ sí ilé baba mi, ní orí òkúta kan ṣoṣo ni ẹ ti pa àwọn àádọ́rin ọmọ rẹ̀, ẹ̀yin sì ti fi Abimeleki ọmọ ẹrúbìnrin rẹ̀ jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn Ṣekemu nítorí tí ó jẹ́ arákùnrin yín. 19Bí ohun tí ẹ ṣe sí Jerubbaali àti ìdílé rẹ̀ bá jẹ́ ohun tí ó yẹ, tí ẹ sì ṣe òtítọ́ inú sí i, kí ẹ ní ayọ̀ nínú Abimeleki kí òun náà sì ní ayọ̀ nínú yín. 20Ṣùgbọ́n tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí iná jó jáde wá láti ọ̀dọ̀ Abimeleki kí ó sì jó yín run. Ẹ̀yin ará Ṣekemu àti ará Beti-Milo, kí iná pẹ̀lú jáde láti ọ̀dọ̀ yín wá ẹ̀yin ará Ṣekemu àti ará Beti-Milo kí ó sì jó Abimeleki run.”

21Lẹ́yìn tí Jotamu ti sọ èyí tan, ó sá àsálà lọ sí Beeri, ó sì gbé níbẹ̀ nítorí ó bẹ̀rù arákùnrin rẹ̀ Abimeleki.

22Lẹ́yìn tí Abimeleki ti ṣe àkóso Israẹli fún ọdún mẹ́ta, 23Ọlọ́run rán ẹ̀mí búburú sáàárín Abimeleki àti àwọn ará Ṣekemu, àwọn ẹni tí ó hu ìwà ọ̀tẹ̀. 24Ọlọ́run ṣe èyí láti gbẹ̀san àwọn ìwà búburú, àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀ àwọn àádọ́rin ọmọ Jerubbaali lára Abimeleki arákùnrin wọn àti lára àwọn ènìyàn Ṣekemu, ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́ láti pa àwọn arákùnrin rẹ̀. 25Nítorí ìkórìíra tí wọ́n ni sí àwọn olórí, ni Ṣekemu dẹ àwọn ènìyàn sí àwọn orí òkè láti máa dá àwọn ènìyàn tó ń kọjá lọ́nà, kí wọn sì máa jà wọ́n lólè, àwọn kan ló sọ èyí fún Abimeleki.

26Gaali ọmọ Ebedi àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá sí Ṣekemu, àwọn ará Ṣekemu sì gbẹ́kẹ̀lé wọn, wọ́n sì fi inú tán wọn. 27Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde lọ sí oko, wọ́n sì ṣa èso àjàrà wọn jọ, wọ́n fún èso àjàrà náà, wọ́n sì ṣe àjọ̀dún nínú ilé òrìṣà wọn. Nígbà tí wọ́n ń jẹ tí wọ́n ń mu wọ́n fi Abimeleki ré. 28Gaali ọmọ Ebedi dáhùn pé, “Ta ni Abimeleki tàbí ta ni Ṣekemu tí àwa ó fi sìn ín? Ọmọ Jerubbaali kọ́ ní ṣe tàbí Sebulu kọ́ ní igbákejì rẹ̀? Ẹ má sin àwọn ará Hamori baba àwọn ará Ṣekemu, èéṣe tí a ó fi sin Abimeleki? 29Ìbá se pé àwọn ènìyàn yìí wà ní abẹ́ ìṣàkóso mi ni! Èmi ìbá bọ́ àjàgà rẹ̀ kúrò ní ọrùn yín. Èmi yóò wí fún Abimeleki pé, ‘Kó gbogbo àwọn ogun rẹ jáde láti jà.’ ”

30Nígbà tí Sebulu, alákòóso ìlú náà gbọ́ ohun tí Gaali ọmọ Ebedi sọ, inú bí i gidigidi. 31Ó ránṣẹ́ sí Abimeleki pé, “Gaali ọmọ Ebedi àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá láti máa gbé ní Ṣekemu ṣùgbọ́n, wọ́n ń rú àwọn ènìyàn sókè láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ. 32Wá ní òru kí ìwọ àti àwọn ogun rẹ sá pamọ́ dè wọ́n nínú igbó. 33Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù bí oòrùn ti ń yọ ìwọ yóò wọ inú ìlú náà lọ láti bá a jà. Yóò sì ṣe nígbà tí Gaali àti àwọn ogun rẹ̀ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ bá jáde sí ọ láti bá ọ jà, ìwọ yóò ṣe ohunkóhun tí o bá fẹ́ sí wọn.”

34Abimeleki àti gbogbo àwọn ogun rẹ̀ sì jáde ní òru, wọ́n sì sá pamọ́ sí ọ̀nà mẹ́rin yí Ṣekemu ká. 35Gaali ọmọ Ebedi jáde síta, ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà ibodè ìlú náà ní àkókò tí Abimeleki àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jáde kúrò níbi tí wọn sá pamọ́ sí.

36Nígbà tí Gaali rí àwọn ènìyàn náà, ó sọ fún Sebulu pé, “Wò ó, àwọn ènìyàn ń ti orí òkè sọ̀kalẹ̀ wá!”

Sebulu sì wí fún un pé, “Òjìji òkè wọ̀n-ọn-nì ni ìwọ rí bi ẹni pé ènìyàn.”

37Gaali ké ó ní, “Wòkè, àwọn ènìyàn ń tọ̀ wá bọ̀ láti agbede-méjì ilẹ̀ wá àti ẹ̀gbẹ́ kan sì ń ti ọ̀nà igi óákù Meonenimu wá.”

38Nígbà náà ni Sebulu dá a lóhùn pé, “Níbo ni ẹnu tí ó ń ṣe ni wà báyìí. Ṣe bí o wí pé, ‘Ta ni Abimeleki tí àwa ó fi máa sìn ín?’ Àwọn ẹni tí ó gàn án kọ́ nìyí? Jáde lọ kí o sì bá wọn jà!”

39Gaali sì síwájú àwọn ogun ará Ṣekemu lọ kọjú Abimeleki láti bá wọn jagun. 40Abimeleki sì lé e, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ogun ṣubú wọ́n sì gbọgbẹ́ bí wọ́n ṣe ń sálọ, títí dé ẹnu-ọ̀nà ibùdó ìlú náà. 41Abimeleki dúró sí Aruma, nígbà tí Sebulu lé Gaali àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kúrò ni Ṣekemu, kò sì jẹ́ kí wọ́n gbé Ṣekemu mọ́.

42Ní ọjọ́ kejì àwọn ará Ṣekemu sì jà lọ́ sí oko, ẹnìkan ló ṣe òfófó rẹ̀ fún Abimeleki. 43Ó kó àwọn ènìyàn rẹ̀, ó pín wọn sí ẹgbẹ́ mẹ́ta ó sì sá pamọ́ sí inú oko. Nígbà tí ó sì rí tí àwọn ènìyàn náà ń jáde kúrò nínú ìlú, ó dìde ó gbóguntì wọ́n. 44Abimeleki àti àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sáré síwájú, wọ́n gba ẹnu ibodè ìlú náà, wọ́n sì dúró níbẹ̀. Àwọn ẹgbẹ́ méjì tókù sì sáré sí àwọn tó wà ní oko wọ́n sì gbóguntì wọ́n. 45Ní gbogbo ọjọ́ náà ni Abimeleki fi bá àwọn ará ìlú náà jà, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì pa àwọn ènìyàn ìlú náà ó wó ìlú náà palẹ̀ pátápátá ó sì fọ́n iyọ̀ sí i.

46Àwọn ènìyàn ilé ìṣọ́ Ṣekemu gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sálọ fún ààbò sí inú ilé ìṣọ́ òrìṣà El-Beriti. 47Nígbà tí wọ́n sọ fún Abimeleki pé gbogbo àwọn ènìyàn ilé ìṣọ́ Ṣekemu kó ara wọn jọ pọ̀. 48Abimeleki àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ gun òkè Salmoni lọ. Ó gé àwọn ẹ̀ka díẹ̀ pẹ̀lú àáké, ó gbé àwọn ẹ̀ka wọ̀nyí sí èjìká rẹ̀. Ó sọ fún àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe ohun tí ẹ rí tí mo ń ṣe yìí ní kíákíá.” 49Báyìí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gé àwọn ẹ̀ka igi wọn tẹ̀lé Abimeleki. Wọ́n kó wọn ti ilé ìṣọ́ agbára níbi tí àwọn ènìyàn sá pamọ́ sí wọ́n sì fi iná sí i, tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn ọkùnrin ilé ìṣọ́ Ṣekemu fi kú pẹ̀lú. Gbogbo àwọn ènìyàn náà tí ó tó ẹgbẹ̀rún (1,000) ènìyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin sì kú.

50Abimeleki tún lọ sí Tebesi, ó yí ìlú náà ká pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀. 51Ilé ìṣọ́ kan tí ó ní agbára sì wà nínú ìlú náà. Gbogbo àwọn ènìyàn ìlú náà ọkùnrin àti obìnrin sá sínú ilé ìṣọ́ náà. Wọ́n ti ara wọn mọ́ ibẹ̀ wọ́n sì sálọ sí inú àjà ilé ìṣọ́ náà. 52Abimeleki lọ sí ìsàlẹ̀ ilé ìṣọ́ náà, ó sì ń bá a jà. Ṣùgbọ́n bí ó ti súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé ìṣọ́ náà láti dáná sun ún, 53obìnrin kan sọ ọmọ ọlọ lu Abimeleki lórí, ó sì fọ́ ọ ní agbárí.

54Ní ojú kan náà ni ó pe ẹni tí ó ru àpáta rẹ̀ pé, “Yára yọ idà rẹ kí o sì pa mí, kí wọn má ba à sọ pé, ‘Obìnrin ni ó pa á.’ ” Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì fi ọ̀kọ̀ gún un, ó sì kú. 55Nígbà tí àwọn ará Israẹli rí i pé Abimeleki kú, olúkúlùkù wọn padà sí ilé rẹ̀.

56Báyìí ni Ọlọ́run san ẹ̀san ìwà búburú ti Abimeleki hù sí baba rẹ̀ ní ti pípa tí ó pa, àwọn àádọ́rin arákùnrin rẹ̀. 57Ọlọ́run jẹ́ kí ìwà búburú àwọn ará Ṣekemu pẹ̀lú padà sí orí wọn. Ègún Jotamu ọmọ Jerubbaali pàápàá wá sí orí wọn.

Ang Pulong Sa Dios

Hukom 9:1-57

Si Abimelec

1Usa ka adlaw, miadto si Abimelec nga anak ni Gideon9:1 Gideon: sa Hebreo, Jerubaal. Mao usab kini sa bersikulo 2, 5, 24, 28, 57. sa mga paryente sa iyang inahan sa Shekem. Miingon siya kanila, 2“Pangutan-a ninyo ang tanang taga-Shekem kon unsay gusto nila: pangulohan sila sa 70 ka mga anak ni Gideon o sa usa lang ka tawo? Hinumdomi ninyo nga ako inyong kadugo.”

3Busa nakigsulti ang mga paryente ni Abimelec sa mga taga-Shekem. Misugot sila nga si Abimelec ang mangulo kanila, tungod kay paryente nila siya. 4Gihatagan nila si Abimelec ug 70 ka buok nga pilak gikan sa templo ni Baal Berit, ug gigamit niya kini sa pagsuhol ug mga bugoy nga mosunod kaniya. 5Miadto si Abimelec sa balay sa iyang amahan sa Ofra, ug gipamatay niya ang iyang 709:5 70: Ang buot ipasabot, mga banabana 70. ka mga igsoon sa amahan nga si Gideon ibabaw sa usa ka bato. Apan si Jotam nga mao ang kamanghoran wala mapatay kay mitago siya. 6Miadto ang mga taga-Shekem ug taga-Bet Millo sa dakong kahoy sa Shekem ug didto gihimo nilang hari si Abimelec.

7Sa dihang nabalitaan kini ni Jotam, mitungas siya ibabaw sa Bukid sa Gerizim ug misinggit kanila, “Mga taga-Shekem, pamatia ninyo kining isugilon ko kaninyo aron pamation kamo sa Dios. 8Usa niana ka higayon, ang mga kahoy nangita ug mohari kanila. Miingon sila sa kahoyng olibo, ‘Ikaw ang maghari kanamo.’ 9Mitubag ang olibo, ‘Mas pilion ko pa ba ang paghari kaninyo kaysa paghatag ug lana nga gamiton sa pagpasidungog sa mga dios ug sa mga tawo? Dili gayod!

10“Busa miingon sila sa kahoy nga igos, ‘Ikaw na lang ang maghari kanamo.’ 11Apan mitubag ang kahoy nga igos, ‘Mas pilion ko pa ba ang paghari kaninyo kaysa paghatag ug lamian ug tam-is nga bunga? Dili gayod!

12“Busa miingon sila sa ubas, ‘Ikaw na lang ang maghari kanamo.’ 13Mitubag ang ubas, ‘Mas pilion ko pa ba ang paghari kaninyo kaysa paghatag ug bino nga makapalipay sa mga dios ug sa mga tawo? Dili gayod!

14“Busa miingon na lang silang tanan sa kahoyng tunokon, ‘Ikaw na lang ang maghari kanamo.’ 15Mitubag ang kahoyng tunokon, ‘Kon gusto gayod ninyo nga ako ang maghari kaninyo, pasilong kamo sa akong landong. Kon magdumili kamo, magpagawas ako ug kalayo nga mosunog sa mga kahoyng sedro sa Lebanon.’ ”

16Mipadayon si Jotam sa pag-ingon, “Matarong ba ug husto ang inyong paghimo kang Abimelec nga hari? Maayo ba ang inyong gihimo ngadto sa akong amahan ug sa iyang pamilya? Gibalosan ba ninyo sa kaayo ang maayo niyang gihimo alang kaninyo? 17Hinumdomi ninyo nga nakiggira ang akong amahan aron luwason kamo gikan sa mga Midianhon. Gisakripisyo niya ang iyang kinabuhi alang kaninyo. 18Apan karon nakigbatok kamo sa pamilya sa akong amahan. Gipatay ninyo ang 70 niya ka mga anak ibabaw sa usa lang ka bato. Ug gihimo ninyong hari si Abimelec nga anak lang sa akong amahan sa iyang sulugoong babaye, tungod kay paryente ninyo siya. 19Kon alang kaninyo matarong ug husto ang inyong gihimo ngadto sa akong amahan ug sa iyang panimalay karong adlawa, hinaut nga malipay kamo kang Abimelec ug siya malipay usab kaninyo. 20Apan kon dili, hinaut nga laglagon ni Abimelec kamong mga taga-Shekem ug Bet Millo, ug kamo usab molaglag kaniya.9:20 hinaut nga laglagon… kaniya: sa Hebreo, hinaut nga mogawas ang kalayo gikan kang Abimelec ug lamyon ang mga taga-Shekem ug Bet Millo, ug mogawas ang kalayo gikan sa Shekem ug Bet Millo ug lamyon si Abimelec.21Pagkahuman ug sulti niadto ni Jotam, miikyas siya ngadto sa Beer ug didto nagpuyo tungod kay nahadlok siya sa iyang igsoon nga si Abimelec.

22Human sa tulo ka tuig nga pagdumala ni Abimelec sa mga Israelinhon, 23gipaaway sa Dios si Abimelec ug ang katawhan sa Shekem. Mirebelde ang taga-Shekem kang Abimelec. 24Nahitabo kini aron mapanimaslan si Abimelec ug ang mga taga-Shekem nga mitabang kaniya sa pagpatay sa 70 ka mga anak ni Gideon nga iyang mga igsoon. 25Nagbutang ang mga taga-Shekem ug mga tawo sa kabukiran aron atangan si Abimelec. Ug gipangtulis nila ang tanang miagi didto. Nabalitaan kini ni Abimelec.

26Unya si Gaal nga anak ni Ebed mibalhin sa Shekem uban sa iyang mga igsoon. Misalig kaniya ang mga taga-Shekem. 27Nangadto sila sa uma, nanguhag ubas, ug naghimog bino. Unya nagpista sila didto sa templo sa ilang dios. Ug samtang nangaon sila ug nagainom didto, gitamay nila si Abimelec. 28Miingon si Gaal, “Unsa ba kitang mga taga-Shekem? Nganong magpailalom man kita kang Abimelec? Kinsa ba siya? Dili ba anak man lang siya ni Gideon, ug siya ug ang iyang opisyal nga si Zebul nagaalagad man sa katawhan ni Hamor nga amahan ni Shekem? Nganong magpailalom man kita kaniya? 29Kon ako pay inyong pangulo, wagtangon ko si Abimelec. Ingnon ko siya nga dugangan ang iyang mga sundalo ug makig-away kanato.”

30Nasuko si Zebul nga pangulo sa lungsod sa dihang nabalitaan niya ang giingon ni Gaal. 31Busa nagsugo siya ug mga mensahero sa sekreto sa pag-adto kang Abimelec. Mao kini ang iyang gipaingon, “Si Gaal ug ang iyang mga igsoon ania dinhi sa Shekem, ug gidani nila ang mga katawhan nga morebelde kanimo. 32Busa karong gabii, kuyoga ang imong mga tawo ug panago una kamo sa kaumahan sa gawas sa lungsod. 33Ugma, sa pagsidlak sa adlaw, kaliti ninyo ug sulong ang lungsod. Kon mosukol si Gaal ug ang iyang mga tawo, himoa ang gusto mong himuon kanila.”

34Busa pagkagabii, milakaw si Abimelec ug ang iyang mga tawo. Gibahin nila sa upat ang ilang grupo ug nagaatang sila sa gawas sa Shekem. 35Sa dihang nakita nila nga migawas si Gaal ug mitindog sa may pultahan sa lungsod, migawas sila gikan sa ilang gitagoan. 36Sa dihang nakita sila ni Gaal, miingon siya kang Zebul, “Tan-awa ra gud, may mga tawo nga nanglugsong gikan sa ibabaw sa mga bukid.” Mitubag si Zebul, “Mga anino kana sa mga bukid. Abi lang nimo ug mga tawo.”

37Miingon pag-usab si Gaal, “Tan-awa ra gud! May mga tawo nga nanglugsong gikan sa taliwala sa duha ka bukid, ug may usa ka grupo nga naggikan sa dakong kahoy sa mga manalagna!”

38Mitubag si Zebul kaniya, “Asa na man ang imong gipanghambog? Dili ba miingon ka man, ‘Ngano, kinsa ba si Abimelec nga magpailalom man kita kaniya?’ Karon ania na ang gitamay mo! Lakaw na, ug pakiggira kanila!”

39Busa gipangulohan ni Gaal ang mga taga-Shekem ug nakiggira sila kang Abimelec. 40Unya gigukod ni Abimelec si Gaal, apan miikyas siya. Nagkatag ang mga samaran hangtod sa may pultahan sa lungsod.

41Pagkahuman niadto, mipuyo si Abimelec sa Aruma. Wala gitugot ni Zebul nga mobalik si Gaal ug ang iyang mga igsoon sa Shekem.

42Pagkabuntag, nabalitaan ni Abimelec nga miadto sa kaumahan ang mga taga-Shekem. 43Busa gibahin niya sa tulo ka grupo ang iyang mga tawo. Miadto sila sa kaumahan ug nagaatang didto. Sa dihang nakita nila ang mga taga-Shekem nga migawas sa lungsod, midasdas dayon sila. 44Ang grupo ni Abimelec midali-dali pag-adto sa may pultahan sa lungsod aron pagbantay, samtang gipamatay sa duha ka grupo ang mga tawo nga tua sa kaumahan. 45Tibuok adlaw gayod nga nakiggira sila si Abimelec, ug nasakop ra gayod nila ang lungsod. Unya gipamatay nila ang tanang mga lumulupyo didto. Giguba nila ang lungsod ug unya gisabwagan ug asin. 46Sa dihang nabalitaan kini sa mga lumulupyo sa Tore sa Shekem, nanago sila sa lig-on nga bahin sa templo ni El Berit.9:46 El Berit: o, Baal Berit. 47Sa pagkahibalo niini ni Abimelec, 48gidala niya ang iyang mga tawo sa Bukid sa Zalmon. Pag-abot nila didto, mikuha si Abimelec ug atsa ug namutol ug mga sanga sa kahoy ug gipas-an kini. Unya iyang giingnan ang iyang mga tawo nga magdali ug sundon ang iyang gibuhat. 49Busa ang matag usa kanila namutol ug kahoy ug misunod kang Abimelec. Gitapok nila ang mga kahoy sa lig-on nga bahin sa templo ug gidagkotan. Nangamatay ang mga lumulupyo sa tore sa Shekem. Mga 1,000 tanan, apil ang mga babaye.

50Pagkahuman, miadto sila si Abimelec sa Tebez. Gilibotan nila kini ug gisakop. 51Apan may lig-ong tore sa lungsod, ug nanago ang tanang taga-Tebes didto. Unya nanira sila ug nanaka sa atop. 52Midasdas si Abimelec sa tore, apan sa dihang miduol siya sa pultahan aron unta pagsunog niini, 53gihulogan sa usa ka babaye ug galingan nga bato ang iyang ulo, ug miliki ang iyang ulo. 54Dali-dali niyang gitawag ang tawo nga tigdala sa iyang armas ug giingnan, “Ibta ang imong espada ug patya ako aron dili sila makaingon nga usa lang ka babaye ang nakapatay kanako.” Busa giduslak siya sa iyang sulugoon ug namatay. 55Sa dihang nakita sa mga Israelinhon nga patay na si Abimelec, namauli sila.

56Sa mao nga paagi, gipabayad sa Dios si Abimelec sa daotan niyang gihimo ngadto sa iyang amahan, nga mao ang pagpatay sa 70 niya ka mga igsoon. 57Gipabayad usab sa Dios ang mga taga-Shekem sa ilang pagkadaotan. Busa natuman ang tunglo ni Jotam nga anak ni Gideon.