Orílẹ̀-èdè Israẹli bá àwọn ará Kenaani tókù jagun
1Lẹ́yìn ikú Joṣua, ni orílẹ̀-èdè Israẹli béèrè lọ́wọ́ Olúwa pé, “Èwo nínú ẹ̀yà wa ni yóò kọ́kọ́ gòkè lọ bá àwọn ará Kenaani jagun fún wa?”
2Olúwa sì dáhùn pé, “Juda ni yóò lọ; nítorí pé èmi ti fi ilẹ̀ náà lé e lọ́wọ́.”
3Nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà Juda béèrè ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Simeoni arákùnrin wọn pé, “Ẹ wá bá wa gòkè lọ sí ilẹ̀ tí a ti fi fún wa, láti bá àwọn ará Kenaani jà kí a sì lé wọn kúrò, àwa pẹ̀lú yóò sì bá a yín lọ sí ilẹ̀ tiyín bákan náà láti ràn yín lọ́wọ́.” Àwọn ọmọ-ogun Simeoni sì bá àwọn ọmọ-ogun Juda lọ.
4Nígbà tí àwọn ọmọ-ogun Juda sì kọlu wọ́n, Olúwa sì fi àwọn ará Kenaani àti àwọn ará Peresi lé wọn lọ́wọ́, wọ́n sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin ní Beseki. 5Ní Beseki ni wọ́n ti rí Adoni-Beseki, wọ́n sì bá a jagun, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ará Kenaani àti Peresi. 6Ọba Adoni-Beseki sá àsálà, ṣùgbọ́n ogun Israẹli lépa rẹ̀ wọ́n sì bá a, wọ́n sì gé àwọn àtàǹpàkò ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀.
7Nígbà náà ni Adoni-Beseki wí pé, “Àádọ́rin ọba ni èmi ti gé àtàǹpàkò wọn tí wọ́n sì ń ṣa èérún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tábìlì mi. Báyìí Ọlọ́run ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí ohun tí mo ṣe sí wọn.” Wọ́n sì mú un wá sí Jerusalẹmu, ó sì kú síbẹ̀.
8Àwọn ológun Juda sì ṣẹ́gun Jerusalẹmu, wọ́n sì kó o, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú, wọ́n sì dáná sun ìlú náà.
9Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ogun Juda sọ̀kalẹ̀ lọ láti bá àwọn ará Kenaani tí ń gbé ní àwọn ìlú orí òkè ní gúúsù àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ òkè lápá ìwọ̀-oòrùn Juda jagun. 101.10: Jo 15.13-19.1.10-15: Jo 15.14-19.Ogun Juda sì tún ṣígun tọ ará Kenaani tí ń gbé Hebroni (tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiriati-Arba) ó sì ṣẹ́gun Ṣeṣai, Ahimani àti Talmai. 11Láti ibẹ̀, wọ́n sì wọ́de ogun láti ibẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Debiri (tí à ń pè ní Kiriati-Seferi nígbà kan rí).
12Kalebu sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Aksa fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati-Seferi, tí ó sì gbà á ní ìgbéyàwó.” 13Otnieli ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu sì gbà á, báyìí ni Kalebu sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Aksa fún un ní ìyàwó.
14Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Aksa lọ sí ọ̀dọ̀ Otnieli, ó rọ̀ ọ́ kí ó béèrè ilẹ̀ oko lọ́wọ́ baba rẹ̀. Nígbà náà ni Aksa sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, Kalebu sì béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe fún ọ?”
15Aksa sì dáhùn pé, “Mo ń fẹ́ kí o ṣe ojúrere kan fún mi, nígbà ti o ti fún mi ní ilẹ̀ ní gúúsù, fún mi ní ìsun omi náà pẹ̀lú.” Kalebu sì fún un ní ìsun òkè àti ìsun ìsàlẹ̀.
16Àwọn ìran Keni tí wọ́n jẹ́ àna Mose bá àwọn ọmọ Juda gòkè láti ìlú ọ̀pẹ lọ sí aginjù Juda ní gúúsù Aradi; wọ́n sì lọ, orílẹ̀-èdè méjèèjì sì jùmọ̀ ń gbé pọ̀ láti ìgbà náà.
17Ó sì ṣe, àwọn ológun Juda tẹ̀lé àwọn ológun Simeoni arákùnrin wọn, wọ́n sì lọ bá àwọn ará Kenaani tí ń gbé Sefati jagun, wọ́n sì run ìlú náà pátápátá, ní báyìí àwa yóò pe ìlú náà ní Horma (Horma èyí tí ń jẹ́ ìparun). 18Àwọn ogun Juda sì ṣẹ́gun Gasa àti àwọn agbègbè rẹ̀, Aṣkeloni àti Ekroni pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó yí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ká.
19Olúwa sì wà pẹ̀lú ẹ̀yà Juda, wọ́n gba ilẹ̀ òkè, ṣùgbọ́n wọn kò le lé àwọn ènìyàn tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí wọ́n ní kẹ̀kẹ́ ogun onírin. 20Gẹ́gẹ́ bí Mose ti ṣèlérí, wọ́n fún Kalebu ní Hebroni, ó sì lé àwọn tí ń gbé ibẹ̀ kúrò; àwọn náà ni ìran àwọn ọmọ Anaki mẹ́ta. 21Àwọn ẹ̀yà Benjamini ni wọn kò le lé àwọn Jebusi tí wọ́n ń gbé Jerusalẹmu, nítorí náà wọ́n ń gbé àárín àwọn Israẹli títí di òní.
22Àwọn ẹ̀yà Josẹfu sì bá Beteli jagun, Olúwa síwájú pẹ̀lú wọn. 23Nígbà tí ẹ̀yà Josẹfu rán àwọn ènìyàn láti lọ yọ́ Beteli wò (orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí ni Lusi). 24Àwọn ayọ́lẹ̀wò náà rí ọkùnrin kan tí ń jáde láti inú ìlú náà wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Fi ọ̀nà àtiwọ ìlú yìí hàn wá, àwa ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí, a ó sì ṣe àánú fún ọ.” 25Ó sì fi ọ̀nà ìlú náà hàn wọ́n, wọ́n sì fi ojú idà kọlu ìlú náà, ṣùgbọ́n wọ́n dá ọkùnrin náà àti gbogbo ìdílé rẹ̀ si. 26Ọkùnrin náà sí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Hiti, ó sì tẹ ìlú kan dó, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Lusi, èyí sì ni orúkọ rẹ̀ títí di òní.
271.27,28: Jo 17.11-13.Ṣùgbọ́n Manase kò lé àwọn ará Beti-Ṣeani àti ìlú rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì jáde, tàbí àwọn ará Taanaki àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, tàbí àwọn ará Dori àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, tàbí àwọn ará Ibleamu àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, tàbí àwọn ará Megido àti àwọn ìgbèríko tí ó yí i ká, torí pé àwọn ará Kenaani ti pinnu láti máa gbé ìlú náà. 28Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli di alágbára, wọ́n mú àwọn ará Kenaani sìn bí i ẹrú, ṣùgbọ́n wọn kò fi agbára lé wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ náà. 291.29: Jo 16.10.Efraimu náà kò lé àwọn ará Kenaani tí ó ń gbé Geseri jáde, ṣùgbọ́n àwọn ará Kenaani sì ń gbé láàrín àwọn ẹ̀yà Efraimu. 30Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Sebuluni kò lé àwọn ará Kenaani tí ń gbé Kitironi jáde tàbí àwọn ará Nahalali, ṣùgbọ́n wọ́n sọ wọ́n di ẹrú. Wọ́n sì ń sin àwọn ará Sebuluni. 31Bẹ́ẹ̀ ni Aṣeri kò lé àwọn tí ń gbé ní Akko tàbí ní Sidoni tàbí ní Ahlabu tàbí ní Aksibu tàbí ní Helba tàbí ní Afiki tàbí ní Rehobu. 32Ṣùgbọ́n nítorí àwọn ará Aṣeri ń gbé láàrín àwọn ará Kenaani tí wọ́n ni ilẹ̀ náà. 33Àwọn ẹ̀yà Naftali pẹ̀lú kò lé àwọn ará Beti-Ṣemeṣi àti Beti-Anati jáde; ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Naftali náà ń gbé àárín àwọn ará Kenaani tí ó ti ní ilẹ̀ náà rí, ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbé Beti-Ṣemeṣi àti Beti-Anati ń sìn ìsìn tipátipá. 34Àwọn ará Amori fi agbára dá àwọn ẹ̀yà Dani dúró sí àwọn ìlú orí òkè, wọn kò sì jẹ́ kí wọn sọ̀kalẹ̀ wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀. 35Àwọn ará Amori ti pinnu láti dúró lórí òkè Heresi àti òkè Aijaloni àti ti Ṣaalbimu, ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yà Josẹfu di alágbára wọ́n borí Amori wọ́n sì mú wọn sìn. 36Ààlà àwọn ará Amori sì bẹ̀rẹ̀ láti ìgòkè Akrabbimu kọjá lọ sí Sela àti síwájú sí i.
犹大支派攻打迦南人
1约书亚去世以后,以色列人求问耶和华:“我们哪一个支派先上去攻打迦南人呢?” 2耶和华说:“犹大支派先去,我已把那片土地交在他们手中了。” 3犹大人对西缅人说:“请跟我们一同到我们分得的地方攻打迦南人,我们也会同样帮助你们。”于是,西缅人便与犹大人同去。 4犹大人攻打迦南人和比利洗人,耶和华使他们得胜,在比色杀了一万敌军。 5他们又在那里遇见亚多尼·比色,与他交战,打败了他带领的迦南人和比利洗人。 6亚多尼·比色逃跑,他们追上去擒住他,砍掉他的大拇指和大脚趾。 7亚多尼·比色说:“从前七十个王的大拇指和大脚趾被我砍掉,在我桌下捡食物碎屑,现在上帝照我的行为报应我了。”他们把他带到耶路撒冷,他死在了那里。
8犹大人攻陷耶路撒冷,杀了城内的所有居民,并放火焚城。 9随后,他们下去攻打住在山区、南地和丘陵的迦南人, 10又进攻住在希伯仑的迦南人,杀了示筛、亚希幔和挞买。希伯仑从前叫基列·亚巴。
11他们从那里出兵攻打底璧,那里从前叫基列·西弗。 12迦勒说:“谁攻取基列·西弗,我就把女儿押撒嫁给他。” 13迦勒的兄弟基纳斯的儿子俄陀聂攻取了那城,迦勒便把女儿押撒嫁给他。 14押撒出嫁的时候,劝丈夫向她父亲要一块田。她刚下驴,迦勒便问她:“你想要什么?” 15她回答说:“求你恩待我,你既然把南部的干地赐给我,求你也把水泉给我吧。”于是,迦勒把上泉和下泉都给了她。
16摩西岳父的后代基尼人和犹大人一同离开棕树城1:16 “棕树城”即“耶利哥”。,到犹大南部旷野的亚拉得附近,跟当地人一起居住。 17之后,犹大人随西缅人一起攻打洗法城内的迦南人,彻底毁灭了那城。因此那城叫何珥玛1:17 “何珥玛”意思是“覆灭之城”。。 18犹大人又夺取了迦萨、亚实基伦和以革伦三座城邑及周围地区。 19耶和华与犹大人同在。他们攻占了山区,却没能赶走平原的居民,因为那里的人有铁战车。 20照摩西的吩咐,迦勒得到了希伯仑。他把亚衲三族的人从那里赶走。 21便雅悯人没有赶走居住在耶路撒冷的耶布斯人,耶布斯人至今仍和他们住在一起。
22约瑟家族也上去攻打伯特利,耶和华与他们同在。 23他们先派人去打探伯特利,那里从前名叫路斯。 24探子看见一个人从城里出来,就对他说:“请你告诉我们进城的路,我们必善待你。” 25那人便告诉他们进城的路,他们杀了城内所有的居民,只放走了那人及其全家。 26后来,那人搬到赫人的地方,筑了一座城,称之为路斯,沿用至今。
27玛拿西人没有赶走伯·善、他纳、多珥、以伯莲和米吉多众城邑及周围村庄的居民,因为这些迦南人执意住在那里。 28以色列人强盛时,就强迫他们服劳役,却没有全部赶走他们。
29以法莲人没有赶走住在基色的迦南人,这些迦南人仍然住在他们当中。
30西布伦人没有赶走基伦和拿哈拉的居民,这些迦南人仍然住在他们当中,为他们服劳役。
31亚设人没有赶走亚柯、西顿、亚黑拉、亚革悉、黑巴、亚弗革和利合的居民, 32于是亚设人住在这些迦南人当中。
33拿弗他利人没有赶走伯·示麦和伯·亚纳的居民,于是就住在这些迦南人当中,强迫他们服劳役。
34亚摩利人强迫但人住在山区,不准他们下到平原。 35亚摩利人执意住在希烈山、亚雅伦和沙宾,但约瑟家族强盛时,就强迫他们服劳役。 36亚摩利人的边界从亚克拉滨山坡起,一直到西拉以北。