Numeri 9 – YCB & HOF

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 9:1-23

Àsè ìrékọjá

19.1-5: El 12.1-14,21-28.Olúwa sọ fún Mose nínú aginjù Sinai ní oṣù kìn-ín-ní ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti wí pé, 2“Mú kí àwọn ọmọ Israẹli máa pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní àsìkò rẹ̀. 3Ẹ ṣe é ní àsìkò rẹ̀ gan an ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀.”

4Mose sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n máa pa àjọ ìrékọjá mọ́. 5Wọ́n sì ṣe àjọ ìrékọjá ní aginjù Sinai ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

6Àwọn díẹ̀ nínú wọn kò lè ṣe àjọ ìrékọjá lọ́jọ́ náà nítorí pé wọ́n di aláìmọ́ nítorí òkú ènìyàn. Nítorí èyí wọ́n wá sọ́dọ̀ Mose àti Aaroni lọ́jọ́ náà. 7Wọ́n sọ fún Mose pé, “A di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ló dé tí a kò fi ní í le è fi ọrẹ wa fún Olúwa pẹ̀lú àwọn ará Israẹli yòókù ní àsìkò tí a ti yàn.”

8Mose sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dúró kí n ba lè mọ ohun tí Olúwa yóò pàṣẹ nípa yín.”

9Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, 10“Sọ fún àwọn ará Israẹli: ‘Bí ẹnìkan nínú yín tàbí nínú ìran yín bá di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn tàbí bí ó bá lọ sí ìrìnàjò síbẹ̀ yóò pa àjọ ìrékọjá Olúwa mọ́. 11Wọn yóò ṣe tiwọn ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì. Wọn yóò jẹ ẹran náà, pẹ̀lú àkàrà aláìwú àti ewúro. 129.12: Ek 12.46; Jh 19.36.Wọn kò gbọdọ̀ ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀, wọn kò sì gbọdọ̀ ṣẹ́ eegun rẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé gbogbo ìlànà fún ṣíṣe àjọ ìrékọjá. 13Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan tó wà ní mímọ́ tí kò sì lọ sí ìrìnàjò bá kọ̀ láti pa àjọ ìrékọjá mọ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí pé kò mú ọrẹ Olúwa wá ní àsìkò tí ó yẹ. Ẹni náà yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

14“ ‘Bí àlejò tí ń gbé láàrín yín bá fẹ́ ṣe àjọ ìrékọjá Olúwa, ó gbọdọ̀ pa á mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àti òfin rẹ̀. Ìlànà kan náà ni kí ẹ ní fún àlejò àti àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ yín.’ ”

Ìkùùkuu lórí àgọ́

159.15-23: El 40.36-38.Ní ọjọ́ tí wọ́n gbé àgọ́ ró, èyí tí í ṣe àgọ́ ẹ̀rí, dúró, ìkùùkuu àwọsánmọ̀ bò ó mọ́lẹ̀. Ìkùùkuu náà sì dàbí iná ní orí àgọ́ láti ìrọ̀lẹ́ títí di òwúrọ̀. 16Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí nígbà gbogbo; ìkùùkuu bò ó, àti pé ní alẹ́ ìrísí rẹ̀ sì dàbí iná. 17Nígbàkígbà tí ìkùùkuu yìí bá ká sókè kúrò lórí àgọ́ ni àwọn ọmọ Israẹli yóò dìde láti máa lọ; ibikíbi tí ìkùùkuu náà bá dúró sí ni àwọn ọmọ Israẹli yóò pa ibùdó wọn sí. 18Nípa àṣẹ Olúwa ni àwọn ọmọ Israẹli ń jáde lọ, nípa àṣẹ Olúwa náà sì ni wọ́n ń pa ibùdó wọn. Nígbà tí ìkùùkuu bá dúró sórí àgọ́, àwọn náà yóò dúró sí ibùdó. 19Nígbà tí ìkùùkuu bá dúró sórí àgọ́ fún ìgbà pípẹ́, síbẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli gbọ́rọ̀ sí àṣẹ Olúwa wọn kò sì ní gbéra láti lọ. 20Ìgbà mìíràn ìkùùkuu lè wà lórí àgọ́ fún ọjọ́ díẹ̀; síbẹ̀ ní àṣẹ Olúwa, wọn yóò dúró ní ibùdó, bí ó sì tún yá, ní àṣẹ rẹ̀ náà ni wọn yóò gbéra. 21Ìgbà mìíràn ìkùùkuu lè dúró láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀, nígbà tó bá ṣí kúrò ní àárọ̀, wọn ó gbéra. Ìbá à ṣe ní ọ̀sán tàbí òru, ìgbàkígbà tí ìkùùkuu bá tó kúrò náà ni wọn ó tó gbéra. 22Ìbá à ṣe fún ọjọ́ méjì, oṣù kan tàbí ọdún kan ni ìkùùkuu fi dúró sórí àgọ́, àwọn ọmọ Israẹli yóò dúró ní ibùdó wọn, wọn kò ní gbéra; ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá lọ sókè ni wọn ó tó o gbéra. 23Nípa àṣẹ Olúwa ni wọ́n ń pa ibùdó wọn, nípa àṣẹ Olúwa náà sì ni wọ́n ń gbéra. Wọ́n gbọ́rọ̀ sí àṣẹ Olúwa ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose.

Hoffnung für Alle

4. Mose 9:1-23

Das erste Passahfest in der Wüste

1Im 1. Monat des 2. Jahres nachdem die Israeliten Ägypten verlassen hatten, sprach der Herr in der Wüste Sinai zu Mose:

2»Ihr sollt das Passahfest zur vorgeschriebenen Zeit feiern: 3am Abend des 14. Tages in diesem Monat. Haltet euch an alle Bestimmungen und Vorschriften für das Fest!« 4Mose teilte es den Israeliten mit. 5So feierten sie am Abend des 14. Tages im 1. Monat das Passahfest in der Wüste Sinai. Sie befolgten dabei alle Anweisungen des Herrn.

6Einige Männer aber hatten zuvor eine Leiche berührt. Dadurch waren sie am Tag des Passahfestes unrein und konnten nicht mitfeiern. Sie fragten daher Mose und Aaron um Rat: 7»Wir haben einen Toten berührt und sind dadurch unrein geworden. Sollen wir deshalb etwa vom Fest ausgeschlossen werden? Wir würden auch gerne dabei sein und wie alle anderen Israeliten dem Herrn unsere Opfer darbringen!« 8Mose antwortete: »Wartet hier! Ich will hören, was der Herr dazu sagt.«

9Der Herr sprach zu Mose: 10»Was ich dir jetzt sage, soll für immer gelten: Wer sich durch die Berührung eines Toten verunreinigt hat oder auf einer weiten Reise ist und deshalb nicht am Fest teilnehmen kann, 11der soll es genau einen Monat später nachholen. Dann soll er das Passahlamm wie sonst auch mit bitteren Kräutern essen und mit Brot, das ohne Sauerteig gebacken ist. 12Er darf nichts davon bis zum nächsten Morgen übrig lassen und dem Lamm keinen Knochen brechen. Er muss alle Bestimmungen und Vorschriften für das Passahfest genau befolgen. 13Aber wenn jemand das Fest im 1. Monat nicht feiert, obwohl er rein ist und sich auch nicht auf Reisen befindet, hat er sein Leben verwirkt. Er darf nicht länger zur Gemeinschaft eures Volkes gehören. Er hat mir, dem Herrn, sein Opfer nicht zur festgelegten Zeit dargebracht und muss die Folgen dieser Sünde tragen. 14Wenn ein Ausländer, der sich eurem Volk angeschlossen hat, zu meiner Ehre das Passahfest feiern will, muss auch er dabei alle Vorschriften beachten. Für Einheimische und Ausländer soll dasselbe Recht gelten!«

Der Herr führt sein Volk

15Als man das heilige Zelt aufgestellt hatte, in dem die Gesetzestafeln aufbewahrt wurden, kam die Wolke des Herrn und bedeckte es. In der folgenden Nacht leuchtete sie wie Feuer. 16Sie blieb von nun an über dem Heiligtum. Am Tag glich sie einer Wolke und nachts einem Feuer. 17Wenn sie aufstieg, brachen die Israeliten auf und folgten ihr. Und wo sie sich niederließ, schlugen sie ihr Lager wieder auf. 18Durch die Wolke gab ihnen der Herr das Zeichen zum Weiterziehen oder Haltmachen. Solange die Wolke auf dem Heiligtum ruhte, ließen die Israeliten ihre Zelte stehen. 19Das dauerte manchmal sehr lange. Auch dann hielten sie sich an die Weisung des Herrn und brachen nicht auf. 20Es kam auch vor, dass sie nur wenige Tage an einem Ort blieben, ganz wie der Herr es befahl. 21Manchmal ließ die Wolke sich am Abend nieder und stieg schon am nächsten Morgen wieder auf. Dann zogen die Israeliten sofort los. Die Wolke konnte einen Tag und eine Nacht bleiben, 22aber auch zwei Tage, einen Monat oder noch länger. Immer wenn die Wolke auf dem heiligen Zelt ruhte, schlugen die Israeliten ihre Zelte auf und blieben so lange, bis die Wolke sich wieder erhob. 23Sie folgten bei ihrem Zug durch die Wüste den Weisungen des Herrn und taten, was er ihnen durch Mose sagte.