Numeri 23 – YCB & NRT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 23:1-30

Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ àkọ́kọ́ Balaamu

1Balaamu wí fún Balaki pé, “Kọ́ pẹpẹ méje fún mi níbí, kí o sì mú akọ màlúù méje àti àgbò méje wá fún mi.” 2Balaki ṣe bí Balaamu ti sọ, àwọn méjèèjì fi akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

3Nígbà náà Balaamu sọ fún Balaki pé, “Dúró ti ẹbọ sísun rẹ kí èmi sì lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan. Bóyá Olúwa yóò farahàn mí. Ohunkóhun tí ó bá fihàn mí, èmi yóò wí fún ọ.” Nígbà náà ó sì lọ sí ibi gíga.

4Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀, Balaamu sì sọ pé, “Mo tí ṣe pẹpẹ méje, lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan mo ti fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ.”

5Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ sí ẹnu Balaamu ó wí pé, “Padà sí ọ̀dọ̀ Balaki kí o sì jẹ́ iṣẹ́ yìí fún un.”

6Ó sì padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì ba tí ó dúró ti ẹbọ sísun rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìjòyè Moabu. 7Nígbà náà ni Balaamu sọ ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ jáde wí pé,

“Balaki mú mi láti Aramu wá,

ọba Moabu láti òkè ìlà-oòrùn wá

Ó wí pé, ‘Wá fi Jakọbu bú fún mi;

wá, kí o sì jẹ́rìí sí Israẹli.’

8Báwo ní èmi ó ṣe fi bú

àwọn tí Ọlọ́run kò fi bú?

Báwo ni èmi ó ṣe bá wọn wí

àwọn tí Olúwa kò bá wí?

9Láti ṣóńṣó ibi gíga orí àpáta ni mo ti rí wọn,

láti orí ibi gíga ni mo ti ń wò wọ́n.

Mo rí àwọn ènìyàn tí ń gbé lọ́tọ̀

wọn kò sì ka ará wọn kún ara àwọn orílẹ̀-èdè.

10Ta ni ó lè ka eruku Jakọbu

tàbí ka ìdámẹ́rin Israẹli?

Jẹ́ kí èmi kú ikú olódodo,

kí ìgbẹ̀yìn mi kí ó dà bí tirẹ̀!”

11Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí lo ṣe fún mi? Mo gbé ọ wá láti fi àwọn ọ̀tá mi bú, ṣùgbọ́n o kò ṣe nǹkan kan, ṣùgbọ́n o bùkún wọn!”

12Ó sì dáhùn wí pé, “Ṣé kí n má sọ nǹkan tí Olúwa fi sí mi lẹ́nu?”

Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ èkejì Balaamu

13Nígbà náà Balaki sọ fún un pé, “Wá pẹ̀lú mi sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn; wà á rí díẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn. Láti ibẹ̀, wá fi wọ́n bú fún mi.” 14Ó sì lọ sí pápá Sofimu ní orí òkè Pisga, ó sì kọ́ pẹpẹ méje síbẹ̀ ó sì fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

15Balaamu ṣo fún Balaki pé, “Dúró níbí ti ẹbọ sísun rẹ nígbà tí mo bá lọ pàdé rẹ̀ níbẹ̀.”

16Olúwa pàdé Balaamu ó sì fi ọ̀rọ̀ sí ní ẹnu wí pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ Balaki kí o sì jíṣẹ́ fún un.”

17Nígbà náà ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì bá à tí ó dúró ti ẹbọ sísun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Moabu. Balaki sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni Olúwa wí?”

18Nígbà náà ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ sísọ,

“Dìde, Balaki;

kí o sì gbọ́ mi ọmọ Sippori.

19Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn, tí yóò fi purọ́,

tàbí ọmọ ènìyàn, tí ó lè yí ọkàn rẹ̀ padà.

Ǹjẹ́ ó sọ̀rọ̀ kí ó má ṣe é?

Ǹjẹ́ ó ti ṣèlérí kí ó má mu un ṣẹ?

20Èmi gba àṣẹ láti bùkún;

Ó sì ti bùkún, èmi kò sì lè yípadà.

21“Kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan nínú Jakọbu,

kò sì rí búburú kankan nínú Israẹli.

Olúwa Ọlọ́run wọn sì wà pẹ̀lú wọn.

Ìhó ọba sì wà pẹ̀lú wọn.

22Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá,

wọ́n ní agbára màlúù ẹhànnà.

23Kò ní àfọ̀ṣẹ sí Jakọbu,

tàbí àfọ̀ṣẹ sí àwọn Israẹli.

Nísinsin yìí a ó sọ nípa ti Jakọbu

àti Israẹli, ‘Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe!’

24Àwọn ènìyàn náà yóò dìde bí abo kìnnìún;

wọ́n yóò sì gbé ara wọn sókè bí i kìnnìún

òun kì yóò sì dùbúlẹ̀ títí yóò fi jẹ ohun ọdẹ

títí yóò sì fi mu nínú ẹ̀jẹ̀ ohun pípa.”

25Nígbà náà ni Balaki wí fún Balaamu pé, “O kò kúkú fi wọ́n bú, bẹ́ẹ̀ ni o kò súre fún wọn rárá!”

26Balaamu dáhùn ó sì wí fún Balaki pé, “Ǹjẹ́ èmi kò ha ti wí fún ọ pé, gbogbo èyí tí Olúwa bá sọ, òun ni èmi yóò ṣe?”

Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ẹ̀kẹta Balaamu

27Nígbà náà Balaki sọ fún Balaamu pé, “Wá jẹ́ kí èmi kí ó mú ọ lọ sí ibòmíràn bóyá yóò tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn kí ó fi wọ́n bú láti ibẹ̀ lọ.” 28Balaki gbé Balaamu wá sí orí òkè Peori, tí ó kọjú sí aginjù.

29Balaamu sì wí fún Balaki pé, “Mọ pẹpẹ méje fún mi níbí kí o sì pèsè akọ màlúù àti àgbò fún mi.” 30Balaki sì ṣe bí Balaamu ti sọ fún un, ó sì gbé akọ màlúù kan àti àgbò lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

New Russian Translation

Числа 23:1-30

1Валаам сказал Валаку:

– Построй мне здесь семь жертвенников и приготовь семь быков и семь баранов.

2Валак сделал, как сказал Валаам, и они вдвоем принесли на каждом жертвеннике по быку и барану. 3Валаам сказал Валаку:

– Стой здесь, у своих всесожжений, а я отойду в сторону. Может быть, Господь придет, чтобы встретиться со мной. Все, что Он мне откроет, я расскажу тебе.

И он ушел на голую вершину.

4Бог встретился с ним, и Валаам сказал:

– Я приготовил семь жертвенников и на каждом принес быка и барана.

5Господь научил Валаама, что сказать, и велел:

– Вернись к Валаку и передай ему это.

6Он вернулся к нему и нашел его стоящим возле своих всесожжений со всеми вождями Моава. 7И Валаам произнес пророчество:

– Из Арама привел меня Валак,

царь Моава – от гор восточных:

«Приди, прокляни мне Иакова;

приди, обреки Израиль на погибель».

8Как мне проклясть тех,

кого Бог не проклял?

Как на гибель обречь тех,

кого Бог не обрек?

9Со скальных вершин я на них смотрю,

с холмов я на них взираю.

Вижу народ, который отдельно живет

и не считает себя одним из народов.

10Кто же сочтет потомков Иакова –

их столько, сколько пылинок на земле, –

или четвертую часть Израиля?

Пусть я умру смертью праведных,

и пусть будет кончина моя, как у них!

11Валак сказал Валааму:

– Что ты со мной сделал? Я привел тебя проклясть моих врагов, а ты их благословляешь!

12Он ответил:

– Разве я не должен говорить то, что мне велит Господь?

Второе пророчество Валаама

13Тогда Валак сказал ему:

– Пойдем со мной в другое место, откуда ты сможешь их увидеть. Там ты увидишь только некоторых, не всех. Тогда прокляни их для меня оттуда.

14Он отвел его на поле Цофим на вершине Фасги, построил там семь жертвенников и принес на каждом быка и барана. 15Валаам сказал Валаку:

– Стой здесь, у своих всесожжений, пока я там встречусь с Ним.

16Господь встретился с Валаамом, научил его, что сказать, и велел:

– Вернись к Валаку и передай ему это.

17Он пошел к нему и нашел его стоящим возле своих всесожжений с вождями Моава. Валак спросил его:

– Что сказал Господь?

18Тогда Валаам произнес пророчество:

– Валак, соберись и слушай;

сын Циппора, внимай мне.

19Бог – не человек, чтобы лгать,

и не смертный, чтобы передумывать.

Неужели скажет Он и не сделает,

пообещает и не исполнит?

20Я получил повеление благословлять;

благословляет Он – я не могу отменить.

21Не видно несчастья23:21 Или: «греха». в Иакове,

не заметно беды в Израиле.

С ними Господь, их Бог,

провозглашенный ими Царем.

22Из Египта их вывел Бог;

сила их – сила дикого быка.

23Нет колдовства на Иакова,

нет ворожбы на Израиля23:23 Или: «Нет колдовства в Иакове, нет ворожбы в Израиле»..

Станут теперь говорить об Иакове

и об Израиле: «Вот что Бог сотворил!»

24Как львица встает народ;

как лев поднимается!

Не успокоится он, пока не пожрет добычу

и кровью жертв не напьется.

25Тогда Валак сказал Валааму:

– Не проклинай их и не благословляй!

26Валаам ответил:

– Разве я не говорил тебе, что должен делать все, что скажет Господь?

Третье пророчество Валаама

27Тогда Валак сказал Валааму:

– Пойдем, я отведу тебя в другое место. Может быть, Богу будет угодно дать тебе проклясть их мне оттуда.

28Валак отвел Валаама на вершину Пеора, обращенную к пустыне23:28 Букв: «над Йешимоном».. 29Валаам сказал Валаку:

– Построй мне здесь семь жертвенников и приготовь семь быков и семь баранов.

30Валак сделал, как сказал Валаам, и принес на каждом жертвеннике быка и барана.