Numeri 19 – YCB & SNC

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 19:1-22

Omi Ìwẹ̀nùmọ́

1Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, 2“Èyí ni ohun tí òfin Olúwa pàṣẹ béèrè lọ́wọ́ yín. Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí wọn mú ẹgbọrọ ọ̀dọ́ màlúù pupa tí kò lábùkù tàbí àbàwọ́n, lára èyí tí a kò tí ì di àjàgà mọ́. 3Ẹ mú fún Eleasari àlùfáà, yóò sì mu jáde lọ sí ẹ̀yìn ibùdó kí ó sì pa á ní ojú rẹ. 4Nígbà náà ni Eleasari àlùfáà yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí ìka ọwọ́ rẹ̀ yóò sì wọn lẹ́ẹ̀méje ní ọ̀kánkán iwájú àgọ́ ìpàdé. 5Ní ojú rẹ̀ ni àlùfáà yóò ti sun ọ̀dọ́ abo màlúù yìí: awọ ara rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹran-ara àti ìgbẹ́ rẹ̀. 6Àlùfáà yóò mú igi kedari, hísópù àti òwú òdòdó yóò sì jù wọ́n sí àárín ọ̀dọ́ abo màlúù tí a ń sun. 7Lẹ́yìn náà, àlùfáà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi lẹ́yìn náà ó lè wá sínú àgọ́. Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. 8Ẹni tí ó sun ún náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pẹ̀lú omi, òun náà yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

9“Ẹni tó wà ní mímọ́ ni yóò kó eérú ọ̀dọ́ màlúù náà lọ sí ibi tí a yà sí mímọ́ lẹ́yìn ibùdó. Kí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli kó o pamọ́ fún lílò fún omi ìwẹ̀nùmọ́. Ó jẹ́ ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. 10Ọkùnrin tí ó kó eérú ọ̀dọ́ abo màlúù náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún àwọn ọmọ Israẹli àti fún àwọn àjèjì tí ó ń gbé láàrín wọn.

11“Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú ẹnikẹ́ni, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje. 12Ó gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje; nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ pé kò wẹ ara rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje yóò jẹ́ aláìmọ́. 13Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú ẹnìkan tí kò sì wẹ ara rẹ̀ mọ́, ó ba àgọ́ Olúwa jẹ́. A ó ké irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ọmọ Israẹli. Nítorí pé a kò tí ì wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ lé e lórí, ó jẹ́ aláìmọ́, àìmọ́ rẹ̀ sì wà lára rẹ̀.

14“Èyí ni òfin tí ó jẹ mọ́ bí ènìyàn bá kú nínú àgọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ inú àgọ́ àti ẹni tí ó wà nínú àgọ́ yóò di aláìmọ́ fún ọjọ́ méje, 15gbogbo ohun èlò tí a kò bá fi omọrí dé ni yóò jẹ́ aláìmọ́.

16“Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní ìta tí ó sì fi ọwọ́ kan ẹni tí a fi idà pa tàbí ẹni tí ó kú ikú àtọ̀runwá, tàbí bí ẹnìkan bá fi ọwọ́ kan egungun òkú ènìyàn tàbí isà òkú, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje.

17“Fún aláìmọ́ ènìyàn, mú eérú díẹ̀ lára eérú ọrẹ ìwẹ̀nùmọ́ sínú ìgò, kí o sì da omi tó ń sàn lé e lórí. 18Nígbà náà, ọkùnrin tí a yà sí mímọ́ yóò mú hísópù díẹ̀ yóò rì í sínú omi yóò sì fi wọ́n àgọ́ àti gbogbo ohun èlò tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ àti àwọn ènìyàn tí ó wà níbẹ̀. O gbọdọ̀ tún fi wọ́n ẹnikẹ́ni tí ó fi ọwọ́ kan egungun òkú ènìyàn tàbí isà òkú, tàbí ẹni tí ó kú ikú ara rẹ̀, tàbí ẹni tí ó kú ikú àti ọ̀run wá. 19Ọkùnrin tí ó mọ́ ni kí ó bu omi wọ́n àwọn ènìyàn aláìmọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ọjọ́ keje, ní ọjọ́ keje ó gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ mọ́. Ẹni tí a wẹ̀mọ́ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pẹ̀lú omi, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà yóò mọ́. 20Ṣùgbọ́n bí ẹni tí ó bá jẹ́ aláìmọ́ kò bá wẹ ara rẹ̀ mọ́, a gbọdọ̀ gé e kúrò nínú ìjọ ènìyàn, nítorí wí pé ó ti ba àgọ́ Olúwa jẹ́. A kò tí ì fi omi ìwẹ̀nùmọ́ sí ara rẹ̀, ó sì jẹ́ aláìmọ́. 21Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún wọn.

“Ọkùnrin tí ó wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ àti ẹnikẹ́ni tí ó fi ọwọ́ kan omi ìwẹ̀nùmọ́ yóò di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. 22Gbogbo ohun tí ẹni tí ó jẹ́ aláìmọ́ bá fi ọwọ́ kàn yóò di àìmọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ọwọ́ kàn án yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.”

Slovo na cestu

4 Mojžíšova 19:1-22

1I mluvil Hospodin k Mojžíšovi a k Aronovi, řka: 2Toto jest ustanovení zákona, kteréž přikázal Hospodin, řka: Mluv k synům Izraelským, ať vezmouce, přivedou k tobě jalovici červenou bez vady, na níž by nebylo poškvrny, a na kterouž by ještě jho nebylo kladeno. 3A dáte ji Eleazarovi knězi, kterýž vyvede ji ven z stanů, a rozkáže ji zabiti před sebou. 4A vezma Eleazar kněz krve její na prst svůj, kropiti bude jí naproti stánku úmluvy sedmkrát. 5Potom káže tu jalovici spáliti před očima svýma; kůži její, i maso její, i krev její s lejny jejími dá spáliti. 6A vezma kněz dřeva cedrového, yzopu a červce dvakrát barveného, uvrže to vše do ohně, v kterémž ta jalovice hoří. 7I zpéře kněz roucha svá, a tělo své umyje vodou; potom vejde do stanů, a bude nečistý až do večera. 8Takž také i ten, kterýž ji pálil, zpéře roucha svá u vodě, a tělo své obmyje vodou, a nečistý bude až do večera. 9Popel pak té jalovice spálené smete muž čistý, a vysype jej vně za stany na místě čistém, aby byl všechněm synům Izraelským chován k vodě očištění, kteráž bude k očištění za hřích. 10A ten, kdož by smetl popel té jalovice, zpéře roucha svá a nečistý bude až do večera. A budou to míti synové Izraelští i příchozí, kterýž jest pohostinu u prostřed nich, za ustanovení věčné. 11Kdo by se dotkl těla kteréhokoli mrtvého člověka, nečistý bude za sedm dní. 12Takový očišťovati se bude tou vodou dne třetího a dne sedmého, i bude čistý; neočistí-li se pak dne třetího a dne sedmého, nebudeť čistý. 13Kdo by koli, dotkna se těla mrtvého člověka, kterýž umřel, neočistil se, příbytku Hospodinova poškvrnil. Protož vyhlazena bude duše ta z Izraele, nebo vodou očišťování není pokropen; nečistýť bude, a nečistota jeho zůstává na něm. 14Tento jest také zákon, kdyby člověk umřel v stanu: Kdo by koli všel do toho stanu, a kdo by koli byl v stanu, nečistý bude za sedm dní. 15Tolikéž všeliká nádoba odkrytá, kteráž by neměla svrchu přikryvadla na sobě, nečistá bude. 16Tak kdož by se koli dotkl na poli buď mečem zabitého, aneb mrtvého, buďto kosti člověka, aneb hrobu, nečistý bude za sedm dní. 17A vezmou pro nečistého popela z spálené za hřích, a nalejí na něj vody živé do nádoby. 18Potom vezme člověk čistý yzopu, a omočí jej v té vodě, a pokropí stanu, i všeho nádobí i lidí, kteříž by tu byli, tolikéž toho, kterýž dotkl se kosti, aneb zabitého, aneb mrtvého, aneb hrobu. 19Pokropí tedy čistý nečistého v den třetí a v den sedmý; a když jej očistí dne sedmého, zpéře šaty své, a umyje se vodou, a čistý bude u večer. 20Jestliže by pak kdo nečistý jsa, neočistil se, vyhlazena bude duše ta z prostředku shromáždění; nebo svatyně Hospodinovy poškvrnil, vodou očišťování nejsa pokropen; nečistý jest. 21I bude jim to za ustanovení věčné. Kdož by pak tou vodou očišťování kropil, zpéře roucha svá, a kdož by se dotkl vody očišťování, nečistý bude až do večera. 22Èehokoli dotkl by se nečistý, nečisté bude; člověk také, kterýž by se dotkl toho, nečistý bude až do večera.