Numeri 17 – YCB & NIRV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 17:1-13

Ọ̀pá Aaroni rúwé

1Olúwa sì sọ fún Mose pé, 2“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí o sì gba ọ̀pá méjìlá lọ́wọ́ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ olórí ìdílé ẹ̀yà ìran wọn, kọ orúkọ ènìyàn kọ̀ọ̀kan sí ara ọ̀pá rẹ̀. 3Lórí ọ̀pá Lefi kọ orúkọ Aaroni, nítorí ọ̀pá kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ wà fún olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan tí yóò jẹ́ orí fún ẹ̀yà ìran kọ̀ọ̀kan. 4Kó wọn sí àgọ́ ìpàdé níwájú ẹ̀rí níbi tí èmi ti ń pàdé yín. 5Ọ̀pá tí ó bá yí jẹ́ ti ẹni tí èmi bá yàn yóò rúwé, èmi yóò sì dá kíkùn gbogbo ìgbà àwọn ọmọ Israẹli sí yín dúró.”

6Nígbà náà Mose bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, àwọn olórí wọn sì fún un ní ọ̀pá méjìlá, ọ̀pá kan fún olórí kọ̀ọ̀kan ẹ̀yà ìran wọn, ọ̀pá Aaroni sì wà lára àwọn ọ̀pá náà. 7Mose sì fi ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú Olúwa nínú àgọ́ ẹ̀rí.

817.8-10: Hb 9.4.Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì Mose wọ inú àgọ́ ẹ̀rí lọ, ó sì rí ọ̀pá Aaroni, tí ó dúró fún ẹ̀yà Lefi, kì í ṣe wí pé ó hù nìkan, ṣùgbọ́n ó rúwé, ó yọ ìtànná, ó sì so èso almondi. 9Nígbà náà ni Mose kó gbogbo àwọn ọ̀pá jáde láti iwájú Olúwa wá fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n wò wọ́n, ẹnìkọ̀ọ̀kan sì mú ọ̀pá tirẹ̀.

10Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú ọ̀pá Aaroni padà wá síwájú ẹ̀rí, láti fi pamọ́ gẹ́gẹ́ bí àmì fún àwọn ọlọ̀tẹ̀. Èyí ó sì mú òpin bá kíkùn sínú wọn sí mi, kí wọn kí ó má ba à kú.” 11Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti páláṣẹ fún un.

12Àwọn ọmọ Israẹli sọ fún Mose pé, “Àwa yóò kú! A ti sọnù, gbogbo wa ti sọnù! 13Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ tabanaku Olúwa yóò kú. Ṣé gbogbo wa ni yóò kú?”

New International Reader’s Version

Numbers 17:1-13

Aaron’s Walking Stick Produces Buds

1The Lord said to Moses, 2“Speak to the Israelites. Get 12 walking sticks from them. Get one from the leader of each of Israel’s tribes. Write the name of each man on his walking stick. 3Write Aaron’s name on Levi’s walking stick. There must be one stick for the head of each of Israel’s tribes. 4Put the walking sticks in the tent of meeting. Place them in front of the ark where the tablets of the covenant law are kept. That is where I meet with you. 5The walking stick that belongs to the man I choose will begin to grow new shoots. The Israelites are never happy with what you do. I will put an end to what they are saying.”

6So Moses spoke to the Israelites. Their leaders gave him 12 walking sticks. They gave one for the leader of each of Israel’s tribes. Aaron’s walking stick was among them. 7Moses put the sticks in front of the Lord in the tent where the tablets of the covenant law were kept.

8The next day Moses entered the tent. He looked at Aaron’s walking stick. It stood for the tribe of Levi. Moses saw that it had begun to grow new shoots. It had also produced buds and flowers and almonds. 9Then Moses brought out all the walking sticks from in front of the Lord. He brought them to all the Israelites. They looked at them. And each man took his own walking stick.

10The Lord said to Moses, “Put Aaron’s walking stick back in front of the ark where the tablets of the covenant law are kept. The stick will be kept there as a warning to those who refuse to obey. They are never happy with what I do. Aaron’s walking stick will put an end to what they are saying. Then they will not die.” 11Moses did just as the Lord commanded him.

12The Israelites said to Moses, “We’ll die! We are lost! All of us are lost! 13Anyone who even comes near the Lord’s holy tent will die. Are all of us going to die?”