Numeri 1 – YCB & OL

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 1:1-54

Ìkànìyàn

11.1-46: Nu 26.1-51.Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ní aginjù Sinai nínú àgọ́ àjọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì ní ọdún kejì tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ó wí pé: 2“Ka gbogbo àgbájọ ènìyàn Israẹli nípa ẹbí wọn, àti nípa ìdílé baba wọn, to orúkọ wọn olúkúlùkù ọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. 3Ìwọ àti Aaroni ni kí ẹ kà gbogbo ọmọkùnrin Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn láti ọmọ ogún ọdún sókè, àwọn tí ó tó lọ sójú ogun. 4Kí ẹ mú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan láti inú olúkúlùkù ẹ̀yà kí ó sì wá pẹ̀lú yín, kí olúkúlùkù jẹ́ olórí ilé àwọn baba rẹ̀.

5“Orúkọ àwọn ọkùnrin tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nìyí:

“Láti ọ̀dọ̀ Reubeni, Elisuri ọmọ Ṣedeuri;

6Láti ọ̀dọ̀ Simeoni, Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai;

7Láti ọ̀dọ̀ Juda, Nahiṣoni ọmọ Amminadabu;

8Láti ọ̀dọ̀ Isakari, Netaneli ọmọ Ṣuari;

9Láti ọ̀dọ̀ Sebuluni, Eliabu ọmọ Heloni;

10Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Josẹfu:

láti ọ̀dọ̀ Efraimu, Eliṣama ọmọ Ammihudu;

Láti ọ̀dọ̀ Manase, Gamalieli ọmọ Pedasuri;

11Láti ọ̀dọ̀ Benjamini, Abidani ọmọ Gideoni;

12Láti ọ̀dọ̀ Dani, Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai;

13Láti ọ̀dọ̀ Aṣeri, Pagieli ọmọ Okanri;

14Láti ọ̀dọ̀ Gadi, Eliasafu ọmọ Deueli;

15Láti ọ̀dọ̀ Naftali, Ahira ọmọ Enani.”

16Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n yàn nínú àwùjọ ènìyàn, olórí àwọn ẹ̀yà baba wọn. Àwọn ni olórí àwọn ẹbí Israẹli.

17Mose àti Aaroni mú àwọn ènìyàn tí a dárúkọ wọ̀nyí 18wọ́n sì pe gbogbo àwùjọ ènìyàn Israẹli jọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì. Àwọn ènìyàn sì dárúkọ baba ńlá wọn nípa ẹbí àti ìdílé wọn. Wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan láti ọmọ ogún ọdún sókè, 19gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe kà wọ́n nínú aginjù Sinai.

20Láti ìran Reubeni tí í ṣe àkọ́bí Israẹli:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn, lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 21Àwọn tí a kà ní ẹ̀yà Reubeni jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàlélógún ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (46,500).

22Láti ìran Simeoni:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà, wọ́n sì to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 23Iye àwọn tí á kà nínú ẹ̀yà Simeoni jẹ́ ẹgbàá-mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n ó-lé-ọ̀ọ́dúnrún (59,300).

24Láti ìran Gadi:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ẹbí àti ìdílé wọn. 25Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Gadi jẹ́ ẹgbàá-méjìlélógún ó-lé-àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀jọ (45,650).

26Láti ìran Juda:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 27Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Juda jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàdínlógójì ó-lé-ẹgbẹ̀ta (74,600).

28Láti ìran Isakari:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 29Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó-lé-irínwó (54,400).

30Láti ìran Sebuluni:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 31Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Sebuluni jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínlọ́gbọ̀n ó-lé-egbèje (57,400).

32Láti inú àwọn ọmọ Josẹfu:

Láti ìran Efraimu:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 33Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Efraimu jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).

34Láti ìran Manase:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 35Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Manase jẹ́ ẹgbàá ẹ́rìndínlógún ó-lé-igba (32,200).

36Láti ìran Benjamini:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 37Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Benjamini jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tà-dínlógún ó-lé-egbèje (35,400).

38Láti ìran Dani:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 39Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Dani jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélọ́gbọ̀n ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (62,700).

40Láti ìran Aṣeri:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 41Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Aṣeri jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500).

42Láti ìran Naftali:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún ó lé, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 43Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Naftali jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó-lé-egbèje (53,400).

44Wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí Mose àti Aaroni kà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn olórí méjìlá (12) fún Israẹli, tí ẹnìkọ̀ọ̀kan ṣojú fún ìdílé rẹ̀. 45Gbogbo ọmọkùnrin Israẹli tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún (20) sókè, tó sì lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn. 46Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó-lé-egbéjì-dínlógún-dínàádọ́ta, (603,550).

471.47: Nu 2.33.A kò ka àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi mọ́ àwọn ìyókù. 48Nítorí Olúwa ti sọ fún Mose pé, 49“Ìwọ kò gbọdọ̀ ka ẹ̀yà Lefi, tàbí kí o kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli: 501.50-53: Nu 3.5-8,21-37; 4.1-33; 8.19; 18.3,4,23.Dípò èyí yan àwọn ọmọ Lefi láti jẹ́ alábojútó àgọ́ ẹ̀rí, lórí gbogbo ohun èlò àti ohun gbogbo tó jẹ́ ti àgọ́ ẹ̀rí. Àwọn ni yóò máa gbé àgọ́ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, wọn ó máa mójútó o, kí wọn ó sì máa pàgọ́ yí i ká. 51Ìgbàkígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀síwájú, àwọn ọmọ Lefi ni yóò tú palẹ̀, nígbàkígbà tí a bá sì tún pa àgọ́, àwọn ọmọ Lefi náà ni yóò ṣe é. Àlejò tó bá súnmọ́ tòsí ibẹ̀, pípa ni kí ẹ pa á 52kí àwọn ọmọ Israẹli pa àgọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn olúkúlùkù ní ibùdó tirẹ̀ lábẹ́ ọ̀págun tirẹ̀. 53Àwọn ọmọ Lefi yóò jẹ́ alábojútó àti olùtọ́jú àgọ́ ẹ̀rí náà, kí ìbínú má ba à sí lára ìjọ àwọn ọmọ Israẹli; kí àwọn ọmọ Lefi sì máa ṣe ìtọ́jú àgọ́ ẹ̀rí náà.”

54Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

O Livro

Números 1:1-54

Recenseamento dos israelitas

1No primeiro dia do segundo mês1.1 Mês de Zive. Entre a lua nova do mês de abril e o mês de maio. do segundo ano depois dos israelitas terem deixado o Egito, o Senhor deu as seguintes instruções a Moisés, que se encontrava nessa ocasião na tenda do encontro, enquanto Israel estava acampado no deserto de Sinai: 2“Faz um recenseamento de todos os homens israelitas, 3-5a partir da idade de 20 anos, que sejam aptos para combater; indica também a tribo e a família de cada um.

Tu e Aarão ficarão responsáveis por essa iniciativa e serão assistidos pelos chefes de cada tribo, deste modo:

da tribo de Rúben: Elizur, filho de Sedeur;

6da tribo de Simeão: Selumiel, filho de Zurisadai;

7da tribo de Judá: Nassom, filho de Aminadabe;

8da tribo de Issacar: Netanel, filho de Zuar;

9da tribo de Zebulão: Eliabe, filho de Helom;

10Dos filhos de José:

Elisama, filho de Amiude, pela tribo de Efraim;

Gamaliel, filho de Pedazur, pela tribo de Manassés;

11da tribo de Benjamim: Abidã, filho de Gideoni;

12da tribo de Dan: Aiezer, filho de Amisadai;

13da tribo de Aser: Pagiel, filho de Ocrã;

14da tribo de Gad: Eliasafe, filho de Deuel;

15da tribo de Naftali: Airá, filho de Enã.”

16Foram estes os nomeados para a tarefa indicada.

17Moisés e Aarão, com os chefes acima indicados, 18convocaram todos os homens de Israel no primeiro dia do segundo mês com idade a partir de 20 anos para virem registar-se e indicar a sua tribo e família, 19tal como o Senhor ordenara a Moisés no deserto do Sinai.

Foi esta a contagem final:

20-21Rúben, o filho mais velho de Jacob: 46 500;

22-23Simeão: 59 300;

24-25Gad: 45 650;

26-27Judá: 74 600;

28-29Issacar: 54 400;

30-31Zebulão: 57 400;

32-33José: Efraim: 40 500;

34-35Manassés: 32 200;

36-37Benjamim: 35 400;

38-39Dan: 62 700;

40-41Aser: 41 500;

42-43Naftali: 53 400.

44-46O total de homens israelitas recenseados, aptos para o exército, foi de: 603 550.

47Esta relação não inclui os levitas, 48porque o Senhor tinha dito a Moisés 49que isentasse os levitas dessa obrigação e não os incluísse no recenseamento; 50-52pois a sua atividade está relacionada com o tabernáculo e o seu transporte. O seu dever é viver junto dele; assim, quando tiver de ser deslocado, os levitas terão de o desmontar para tornar a armá-lo onde for preciso. Outra pessoa, quem quer que seja, que venha a tocar nele morrerá. Cada tribo levantará o seu acampamento em áreas separadas, com a sua bandeira própria. 53Mas os levitas agrupar-se-ão à volta do tabernáculo como uma parede entre o povo e a severidade de Deus, que é santo, para os proteger da ira divina.

54Todas estas instruções do Senhor a Moisés foram postas em execução.