Nehemiah 3 – YCB & KLB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Nehemiah 3:1-32

Àwọn tí ó mọ odi

1Eliaṣibu olórí àlùfáà àti àwọn àlùfáà arákùnrin rẹ̀ lọ ṣiṣẹ́, wọ́n sì tún ibodè Àgùntàn mọ. Wọ́n yà á sí mímọ́, wọ́n sì gbé ìlẹ̀kùn dúró sí ibi tí ó yẹ, wọ́n mọ ọ́n títí dé ilé ìṣọ́ ọgọ́rùn-ún, èyí tí wọ́n yà sí mímọ́ títí dé ilé ìṣọ́ gíga Hananeli. 2Àwọn ọkùnrin Jeriko sì mọ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Sakkuri ọmọ Imri sì mọ ní ẹ̀gbẹ́ àwọn ọkùnrin Jeriko.

3Àwọn ọkùnrin Senaa ni wọ́n mọ ibodè ẹja. Wọ́n kún ọ̀pọ̀ ìgbéró rẹ̀, wọ́n sì gbé ìlẹ̀kùn rẹ̀, ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè e rẹ̀ sí ààyè e wọn. 4Meremoti ọmọ Uriah, ọmọ Hakosi tún èyí tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ẹ wọn mọ. Ẹni tí ó tún wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni Meṣullamu ọmọ Berekiah, ọmọ Meṣesabeli tún èyí ti ó wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn mọ. Bákan náà ni ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Sadoku ọmọ Baanah náà tún odi mọ. 5Èyí tí ó tún wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn ni àwọn ọkùnrin Tekoa tún mọ, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́lá kò ṣe àtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà lábẹ́ àwọn olórí wọn.

6Jehoida ọmọ Pasea àti Meṣullamu ọmọ Besodeiah ni wọ́n tún ẹnu ibodè àtijọ́ ṣe. Wọ́n kún bíìmù rẹ̀, wọ́n ri àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè rẹ̀ sí ààyè wọn. 7Lẹ́yìn in wọn ni àtúnṣe tún wà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin Gibeoni àti Mispa; Melatiah ti Gibeoni àti Jadoni ti Meronoti; àwọn ibi tí ó wà lábẹ́ àṣẹ baálẹ̀ agbègbè Eufurate. 8Usieli ọmọ Harhiah, ọ̀kan lára àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, túnṣe àtúnṣe èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀; àti Hananiah, ọ̀kan lára àwọn tí ó ń ṣe tùràrí, túnṣe àtúnṣe èyí tí ó tún tẹ̀lé e. Wọ́n mú Jerusalẹmu padà bọ̀ sípò títí dé Odi gbígbòòrò. 9Refaiah ọmọ Huri, alákòóso ìdajì agbègbè Jerusalẹmu, tún èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣe. 10Ní ẹ̀gbẹ́ èyí Jedaiah ọmọ Haramafu tún èyí tí ó wà ní ọ̀ọ́kán ilé rẹ̀ mọ, Hattusi ọmọ Haṣbneiah sì tún tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mọ. 11Malkiah ọmọ Harimu àti Haṣubu ọmọ Pahati-Moabu tún ẹ̀gbẹ́ kejì ṣe àti ilé ìṣọ́ ìléru. 12Ṣallumu ọmọ Halloheṣi, alákòóso ìdajì agbègbè Jerusalẹmu tún ti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mọ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀.

13Ibodè àfonífojì ni Hanuni àti àwọn ará Sanoa tún mọ. Wọ́n tún un kọ́, wọ́n ri àwọn ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè rẹ̀ sí ààyè rẹ̀. Wọ́n sì tún tún ẹgbẹ̀rún (1,000) kan ìgbọ̀nwọ́ odi mọ títí dé ẹnu ibodè ààtàn.

14Ẹnu ibodè Ààtàn ni Malkiah ọmọ Rekabu, alákòóso agbègbè Beti-Hakeremu tún mọ. Ó tún un mọ, ó sì gbé àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè rẹ̀ sí ààyè wọn.

15Ẹnu ibodè orísun ni Ṣalluni Koli-Hose, alákòóso agbègbè Mispa tún mọ. Ó tún ún mọ, ó kan òrùlé e rẹ̀ yíká, ó gbé àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn idẹ rẹ̀ ró sí ààyè wọn. Ó tún tún odi adágún Siloamu mọ, ní ẹ̀gbẹ́ ọgbà ọba, títí dé àwọn àtẹ̀gùn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti ìlú Dafidi. 16Lẹ́yìn in rẹ̀ ni, Nehemiah ọmọ Asbuku, alákòóso ìdajì agbègbè Beti-Suri ṣe àtúnmọ dé ibi ọ̀ọ́kán òdìkejì ibojì Dafidi, títí dé adágún omi àtọwọ́dá àti títí dé ilé àwọn alágbára.

17Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn ará a Lefi, ní abẹ́ ẹ Rehumu ọmọ Bani. Lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni Haṣabiah, alákòóso ìdajì agbègbè Keila ṣe àtúnṣe fún agbègbè tirẹ̀. 18Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn Lefi arákùnrin wọn ní abẹ́ àkóso Binnui ṣe àtúnṣe, Bafai ọmọ Henadadi, ìjòyè àwọn ìdajì agbègbè Keila. 19Lẹ́yìn rẹ̀ ni Eseri ọmọ Jeṣua, alákòóso Mispa, tún ìbò mìíràn ṣe, láti ibìkan tí ó kojú sí ibi gíga sí ilé-ìhámọ́ra títí dé orígun. 20Lẹ́yìn rẹ̀ ni Baruku ọmọ Sakkai fi ìtara tún apá mìíràn ṣe, láti orígun dé ẹnu-ọ̀nà ilé Eliaṣibu olórí àlùfáà. 21Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Meremoti ọmọ Uriah, ọmọ Hakosi tún apá mìíràn ṣe, láti ẹnu-ọ̀nà ilé Eliaṣibu títí dé òpin rẹ̀.

22Àtúnṣe tí a tún túnṣe lẹ́yìn rẹ̀ ní àwọn àlùfáà ní àyíká agbègbè túnṣe. 23Lẹ́yìn wọn ni Benjamini àti Haṣubu tún èyí ti iwájú ilé wọn ṣe; lẹ́yìn wọn ni, Asariah ọmọ Maaseiah ọmọ Ananiah tún ti ẹ̀gbẹ́ ilé rẹ̀ ṣe. 24Lẹ́yìn rẹ̀ ni Binnui ọmọ Henadadi tún apá mìíràn ṣe, láti ilé Asariah dé orígun àti kọ̀rọ̀, 25àti Palali ọmọ Usai tún òdìkejì orígun ṣe àti ilé ìṣọ́ tí ó yọ sóde láti ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ààfin ọba ti òkè lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbègbè àwọn olùṣọ́. Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Pedaiah ọmọ Paroṣi 26àti àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili tí ó ń gbé ní òkè Ofeli ṣe àtúnṣe títí dé ibi ọ̀kánkán òdìkejì ibodè omi sí ìhà ìlà-oòrùn àti ilé ìṣọ́ tí ó yọ sóde. 27Lẹ́yìn wọn ni àwọn ènìyàn Tekoa tún apá mìíràn ṣe, láti ilé ìṣọ́ ńlá tí ó yọ sóde títí dé ògiri Ofeli.

28Àwọn àlùfáà ni ó ṣe àtúnṣe òkè ibodè ẹṣin ṣe, ẹnìkọ̀ọ̀kan ní iwájú ilé e rẹ̀. 29Lẹ́yìn wọn, Sadoku ọmọ Immeri tún ọ̀kánkán òdìkejì ilé rẹ̀ ṣe. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Ṣemaiah ọmọ Ṣekaniah, olùṣọ́ ibodè ìhà ìlà-oòrùn ṣe àtúnṣe. 30Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Hananiah ọmọ Ṣelemiah, àti Hanuni ọmọ ẹ̀kẹfà Salafi, tún apá ibòmíràn ṣe. Lẹ́yìn wọn ni, Meṣullamu ọmọ Berekiah tún ọ̀kánkán òdìkejì ibùgbé ẹ̀ ṣe. 31Lẹ́yìn in rẹ̀ ni Malkiah, ọ̀kan nínú àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ṣe àtúnṣe títí dé ilé àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn oníṣòwò, ní ọ̀kánkán òdìkejì ibodè àyẹ̀wò títí dé yàrá òkè kọ̀rọ̀; 32àti láàrín yàrá òkè kọ̀rọ̀ àti ibodè àgùntàn ni àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà àti àwọn oníṣòwò túnṣe.

Korean Living Bible

느헤미야 3:1-32

예루살렘 성벽 재건

1그때 대제사장 엘리아십이 그의 동료 제사장들과 함께 먼저 양문을 세워 봉헌하고 문짝을 달았다. 그런 다음 그들은 함메아 망대와 하나넬 망대까지 성벽을 쌓아 봉헌하였다.

2그리고 여리고 사람들은 성벽의 그 다음 부분을 건축하고 이므리의 아들 삭굴은 그 다음 부분을 건축하였다.

3하스나아 집안 사람들은 생선문을 건축하여 들보를 얹고 문짝을 달아 자물쇠와 빗장을 설치하였다.

4그리고 학고스의 손자이며 우리아의 아들 므레못은 성벽의 그 다음 부분을, 므세사벨의 손자이며 베레갸의 아들 므술람은 그 다음 부분을, 바아 나의 아들 사독은 그 다음 부분을 건축하였으며

5그 다음 부분은 드고아 사람들이 건축하였는데 그들의 지도자들은 노동을 하지 않았다.

6바세아의 아들 요야다와 브소드야의 아들 므술람은 옛문을 건축하여 들보를 얹고 문짝을 달아 자물쇠와 빗장을 설치하였다.

7그리고 기브온 사람 믈라댜와 메로놋 사람 야돈이 기브온과 미스바 사람들과 함께 유프라테스강 서쪽 지방 총독의 관사까지 그 다음 성벽을 쌓았으며

8그 다음 부분은 금세공업자 할해야의 아들 웃시엘이 건축하였고 향품 제조업자인 하나냐는 넓은 성벽까지 그 다음 부분을 건축하였다.

9그리고 그 다음 부분은 예루살렘 지방 절반을 다스리는 후르의 아들 르바야가 건축하였고

10하루맙의 아들 여다야는 자기 집 맞은편의 성벽을 건축하였으며 그 다음 부분은 하삽느야의 아들 핫두스가 건축하였다.

11또 하림의 아들 말기야와 바핫 – 모압의 아들 핫숩은 그 다음 부분과 용광로 망대를 건축하였고

12그 다음 부분은 예루살렘 지방 절반을 다스리는 할로헤스의 아들 살룸과 그 딸들이 건축하였다.

13하눈과 사노아 주민들은 골짜기문을 건축하여 문짝을 달고 자물쇠와 빗장을 설치하였으며 그들은 또 똥문까지 성벽 3:13 히 ‘1,000규빗’450미터를 수리하였다.

14벧 – 학게렘 지방을 다스리는 레갑의 아들 말기야는 똥문을 건축하여 문짝을 달고 자물쇠와 빗장을 설치하였다.

15미스바 지방을 다스리는 골 – 호세의 아들 살룬은 샘문을 건축하여 지붕을 씌우고 문짝을 달아 자물쇠와 빗장을 설치하였으며 또 그는 왕의 동산 곁에 있는 3:15 또는 ‘셀라’실로암 못가의 성벽을 다윗성에서 내려오는 층계까지 건축하였다.

16다음은 벧 – 술 지방 절반을 다스리는 아스북의 아들 느헤미야가 다윗왕의 묘와 저수지와 용사의 집까지 성벽을 건축하였다.

17다음 부분은 레위 사람 바니의 아들 르훔이 건축하였으며 그일라 지방 절반을 다스리는 하사뱌는 그 다음 부분을,

18그일라 지방의 다른 절반을 다스리는 헤나닷의 아들 바왜는 그 다음 부분을 건축하였고

19미스바를 다스리는 예수아의 아들 에셀은 성 모퉁이까지 병기고 앞 부분을 건축하였다.

20그 다음은 삽배의 아들 바룩이 성 모퉁이에서부터 대제사장 엘리아십의 집 문까지 한 부분을 건축하였고

21엘리아십의 집 문에서부터 엘리아십의 집 모퉁이까지는 학고스의 손자이며 우리아의 아들인 므레못이 건축하였다.

22성벽의 그 다음 부분은 예루살렘 주변에 사는 제사장들이 건축하였고

23그 다음은 베냐민과 핫숩이 자기 집 앞의 성벽을 건축하였으며 그 다음은 아나냐의 손자이며 마아세야의 아들 아사랴가 자기 집 앞을 건축하였다.

24그리고 헤나닷의 아들 빈누이는 아사랴의 집에서부터 성 모퉁이까지 건축하였으며

25우새의 아들 발랄은 그 모퉁이에서부터 경비실 뜰 곁의 윗궁 망대 앞까지 건축하였고 그 다음 부분은 바로스의 아들 브다야가 건축하였다.

26또 오벨에 사는 3:26 원문에는 ‘느디님 사람들’성전 봉사자들은 동쪽 수문과 불쑥 나온 망대까지 건축하였다.

27드고아 사람들은 불쑥 나온 큰 망대 맞은편에서부터 오벨 성벽까지 건축하였으며

28그 다음은 제사장들이 북쪽 말문에서부터 각자 자기 집 앞의 성벽을 건축하였고

29그 다음은 임멜의 아들 사독이 자기 집 앞을 건축하였으며 그 다음 부분은 동쪽 문지기 스가냐의 아들 스마야가 건축하였다.

30그리고 셀레먀의 아들 하나냐와 살랍의 여섯째 아들 하눈은 그 다음 부분을 건축하였으며 다음은 베레갸의 아들 므술람이 자기 집 앞을 건축하였고

31금세공업자 말기야는 밉갓문 맞은편에 있는 성전 봉사자들과 상인들의 집에서부터 북동쪽의 성 모퉁이 누각까지 건축하였다.

32그리고 금세공업자들과 상인들은 마지막 부분인 성 모퉁이 누각에서부터 양문까지 건축하였다.