Nehemiah 2 – YCB & NRT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Nehemiah 2:1-20

Artasasta rán Nehemiah lọ Jerusalẹmu

1Ní oṣù Nisani, ní ogún ọdún ìjọba ọba Artasasta, nígbà tí a gbé wáìnì wá fún un, mo gbé wáìnì náà, mo fi fún ọba, ìbànújẹ́ kò hàn ní ojú mi rí ní iwájú rẹ̀. 2Nítorí náà ni ọba béèrè lọ́wọ́ mi pé, “Èéṣe tí ojú rẹ fi fàro nígbà tí kò rẹ̀ ọ́? Èyí kì í ṣe ohun mìíràn bí kò ṣe ìbànújẹ́ ọkàn.”

Ẹ̀rù bà mí gidigidi, 3ṣùgbọ́n mo wí fún ọba pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! Èéṣe tí ojú mi ko ṣe ní fàro, nígbà tí ìlú tí a sin àwọn baba mi sí wà ní ahoro, tí a sì ti fi iná run àwọn ibodè rẹ̀?”

4Ọba wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”

Nígbà náà, ni mo gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run, 5mo sì dá ọba lóhùn pé, “Ti ó bá wu ọba, tí ìránṣẹ́ rẹ bá sì rí ojúrere ní ojú rẹ, jẹ́ kí ó rán mi lọ sí ìlú náà ní Juda níbi tí a sin àwọn baba mi nítorí kí èmi lè tún un kọ́.”

6Nígbà náà ni ọba, pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ tí ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bi mí pé, “Báwo ni ìrìnàjò náà yóò ṣe pẹ́ ọ tó, nígbà wo sì ni ìwọ yóò padà?” Ó dùn mọ́ ọba láti rán mi lọ, bẹ́ẹ̀ ni mo dá àkókò kan.

7Mo sì tún wí fún ọba pé, “Bí ó bá wu ọba, kí ó fún mi ní lẹ́tà sí àwọn baálẹ̀ òkè odò Eufurate kí wọ́n le mú mi kọjá títí èmi yóò fi dé Juda láìléwu. 8Kí èmi sì gba lẹ́tà kan lọ́wọ́ fún Asafu, olùṣọ́ igbó ọba, nítorí kí ó lè fún mi ní igi láti fi ṣe àtẹ́rígbà fún ibodè ilé ìṣọ́ tẹmpili àti fún odi ìlú náà àti fún ilé tí èmi yóò gbé?” Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run mi wà lórí mi, ọba fi ìbéèrè mi fún mi. 9Bẹ́ẹ̀ ni mo lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn baálẹ̀ agbègbè Eufurate, mo sì fún wọn ní àwọn lẹ́tà ọba. Ọba sì ti rán àwọn ológun àti àwọn ẹlẹ́ṣin ogun pẹ̀lú mi.

10Nígbà tí Sanballati ará Horoni àti Tobiah ará a Ammoni tí wọ́n jẹ́ ìjòyè gbọ́ nípa èyí pé, ẹnìkan wá láti mú ìtẹ̀síwájú bá àlàáfíà àwọn ará Israẹli inú bí wọn gidigidi.

Nehemiah bẹ àwọn odi Jerusalẹmu wò

11Mo sì lọ sí Jerusalẹmu, lẹ́yìn ìgbà tí mo dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. 12Mo jáde ní òru pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀. Èmi kò sì sọ fún ẹnìkankan ohun tí Ọlọ́run mi ti fi sí ọkàn mi láti ṣe fún Jerusalẹmu. Kò sí ẹranko kankan pẹ̀lú mi, bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo tí mo gùn.

13Ní òru, mo jáde lọ sí àfonífojì ibodè sí ìhà kànga Jakali àti sí ẹnu ibodè Ààtàn àti ẹnu ibodè rẹ̀ èyí tí ó ti wó odi Jerusalẹmu tí ó lulẹ̀, tí a ti fi iná sun. 14Nígbà náà ni mo lọ sí ẹnu ibodè orísun àti sí adágún omi ọba, ṣùgbọ́n kò sí ààyè tó fún ẹranko mi láti kọjá; 15bẹ́ẹ̀ ni mo gòkè àfonífojì ní òru, mo ń wo odi. Ní ìparí, mo padà sẹ́yìn, mo sì tún wọlé láti ibodè àfonífojì. 16Àwọn olórí kò mọ ibi tí mo lọ tàbí mọ ohun tí mo ń ṣe, nítorí èmi kò tí ì sọ fún àwọn ará Júù tàbí àwọn àlùfáà tàbí àwọn ọlọ́lá tàbí àwọn ìjòyè tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn tí yóò máa ṣe iṣẹ́ náà.

17Nígbà náà ni mo sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí wàhálà tí a ni: Jerusalẹmu wà nínú ìparun, ibodè rẹ̀ ni a sì ti fi iná jó. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tún odi Jerusalẹmu mọ, àwa kò sì ní jẹ́ ẹni ẹ̀gàn mọ́”. 18Èmi sì tún sọ fún wọn nípa bí ọwọ́ àánú Ọlọ́run mi ṣe wà lára mi àti ohun tí ọba ti sọ fún mi.

Wọ́n dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a bẹ̀rẹ̀ àtúnmọ rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere yìí.

19Ṣùgbọ́n nígbà tí Sanballati ará a Horoni, Tobiah ara olóyè Ammoni àti Geṣemu ará a Arabia gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n fi wá ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì fi wá ṣe ẹ̀sín. Wọ́n béèrè pé, “Kí ni èyí tí ẹ ń ṣe yìí? Ṣé ẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ni?”

20Mo dá wọn lóhùn, mo wí fún wọn pé, “Ọlọ́run ọ̀run yóò fún wa ní àṣeyọrí. Àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ láti tún un mọ, ṣùgbọ́n fún un yin, ẹ̀yin kò ní ìpín tàbí ipa tàbí ẹ̀tọ́ ohunkóhun tí ó jẹ mọ́ ìtàn ní Jerusalẹmu.”

New Russian Translation

Неемия 2:1-20

Возвращение Неемии в Иерусалим

1В месяце нисане, в двадцатом году правления царя Артаксеркса2:1 Ранней весной 445 г. до н. э., ему принесли вино; я взял его и поднес царю. Прежде я никогда не был перед ним печален, 2и царь спросил меня:

– Почему твое лицо так печально, когда ты не болен? Это не что иное, как тоска на сердце.

Я очень испугался, 3но сказал царю:

– Да живет царь вовеки! Как же моему лицу не быть печальным, если город, где похоронены мои предки, лежит в руинах, а его ворота уничтожены огнем?

4Царь сказал мне:

– Чего же ты хочешь?

Я помолился Богу небесному 5и ответил царю:

– Если это угодно царю, и если твой слуга нашел у тебя расположение, отпусти меня в Иудею, в город, где похоронены мои предки, чтобы мне отстроить его.

6Тогда царь сказал мне (а царица сидела рядом с ним):

– Сколько продлится твое путешествие, и когда ты вернешься?

Царю было угодно меня отпустить, и я назвал сроки. 7Еще я сказал ему:

– Если это угодно царю, пусть мне дадут письма к наместникам провинции за Евфратом, чтобы они пропускали меня, пока я не прибуду в Иудею. 8И пусть мне дадут письмо к Асафу, хранителю царских лесов, чтобы он дал мне дерева для того, чтобы сделать балки для ворот крепости при храме, для городской стены и для дома, где я буду жить.

Милостивая рука моего Бога была на мне, и царь исполнил мои просьбы. 9Я пришел к наместникам провинции за Евфратом и вручил им царские письма. А царь еще послал со мной военачальников и всадников.

10Когда хоронитянин Санбаллат и аммонитский вельможа Товия услышали об этом, они были крайне возмущены, что кто-то пришел заботиться о благе израильтян.

Неемия осматривает стены Иерусалима

11Я прибыл в Иерусалим и, пробыв там три дня, 12ночью тронулся в путь с несколькими людьми. Я никому не рассказал того, что мой Бог положил мне на сердце сделать для Иерусалима. Животных со мной не было, не считая того, на котором я ехал.

13Ночью я проехал через ворота Долины к Драконьему источнику и Навозным воротам, осматривая разрушенные стены Иерусалима и его сожженные ворота. 14Потом я проехал к воротам Источника и к царскому пруду, но там было мало места, чтобы пройти животному, на котором я ехал; 15и я поднялся ночью по долине, осматривая стены. Наконец, я повернул назад и возвратился через ворота Долины. 16Начальствующие не знали, куда я ходил и что делал – ведь я еще не говорил ни иудеям, ни священникам, ни знати, ни начальствующим, ни всем остальным, кому суждено было предпринять этот труд.

17Потом я сказал им:

– Вы видите, в какой мы беде: Иерусалим лежит в руинах, а его ворота сожжены. Пойдем, отстроим стену Иерусалима и не будем больше в бесчестии.

18Еще я рассказал им о милостивой руке моего Бога, что на мне, и о том, что сказал мне царь.

Они ответили:

– Так давайте же строить! – и взялись за это благое дело.

19Но когда об этом услышал хоронитянин Санбаллат, аммонитский вельможа Товия и араб Гешем, они принялись высмеивать нас и издеваться над нами.

– Что это вы делаете? – спрашивали они. – Против царя бунтуете?

20Я отвечал им, говоря:

– Бог небесный даст нам успех. Мы, Его слуги, начнем отстраивать эту стену, но что до вас – нет у вас части в Иерусалиме, ни права на него, ни памяти в нем.