Nehemiah 13 – YCB & CARSA

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Nehemiah 13:1-31

Àtúnṣe ìkẹyìn tí Nehemiah ṣe

113.1: De 23.3-5.Ní ọjọ́ náà ni a ka ìwé Mose sókè sí etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn, nínú rẹ̀ ni a ti rí i tí a kọ ọ́ sílẹ̀ pé a kò gbọdọ̀ gba àwọn ará a Ammoni tàbí àwọn ará a Moabu sí àárín ìjọ ènìyàn Ọlọ́run láéláé. 2Nítorí wọn kò mú oúnjẹ àti omi wá pàdé àwọn ọmọ Israẹli lọ́nà, dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Balaamu ní ọ̀wẹ̀ láti gégùn ún lé wọn lórí. (Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa yí ègún náà padà sí ìbùkún.) 3Nígbà tí àwọn ènìyàn gbọ́ òfin yìí, wọ́n yọ gbogbo àwọn àjèjì ènìyàn tí ó darapọ̀ mọ́ wọn kúrò láàrín àwọn Israẹli.

4Ṣáájú èyí a ti fi Eliaṣibu àlùfáà ṣe alákòóso yàrá ìkó nǹkan ilé Ọlọ́run wa sí. Ó súnmọ́ Tobiah pẹ́kípẹ́kí. 5Ó sì ti pèsè yàrá ńlá kan fún un, èyí tí a ń lò tẹ́lẹ̀ fún ìtọ́jú ọrẹ ọkà, tùràrí àti àwọn ohun èlò tẹmpili àti ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró ti a fi lélẹ̀ bí ìlànà fún àwọn ọmọ Lefi, àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà àti pẹ̀lú gbogbo ọrẹ fún àwọn àlùfáà.

6Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo èyí ń lọ lọ́wọ́, èmi kò sí ní Jerusalẹmu, nítorí pé ní ọdún kejìlélọ́gbọ̀n Artasasta ọba Babeli ni mo padà tọ ọba lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣe díẹ̀, mo gba ààyè lọ́dọ̀ọ rẹ̀. 7Mo sì padà sí Jerusalẹmu. Níhìn-ín ni mo ti mọ̀ nípa onírúurú ohun búburú tí Eliaṣibu ti ṣe ní ti pípèsè yàrá fún Tobiah nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run. 8Kò tẹ́ mi lọ́rùn rárá, mo kó gbogbo ohun èlò ìdílé e Tobiah dà síta láti inú iyàrá náà. 9Mo pàṣẹ kí wọn ya àwọn iyàrá náà sí mímọ́, mo sì kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run padà síbẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti tùràrí.

10Mo sì tún gbọ́ pé, kò fi àwọn ìpín tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn Lefi, àwọn akọrin tí ń ṣe àkóso ìsìn sì ti padà sí ẹnu onírúurú iṣẹ́ wọn. 11Nígbà náà ni mo bá àwọn ìjòyè wí, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí a fi kọ ilé Ọlọ́run sílẹ̀?” Nígbà náà ni mo pè wọ́n jọ pọ̀, mo sì fi olúkúlùkù sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀.

12Gbogbo Juda mú ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró wá sínú yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí. 13Mo sì fi àlùfáà Ṣelemiah, Sadoku akọ̀wé àti ọmọ Lefi kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pedaiah ṣe alákòóso àwọn yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí. Mo sì yan Hanani ọmọ Sakkuri, ọmọ Mattaniah bí olùrànlọ́wọ́ ọ wọn. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni a kà sí àwọn tó ṣé e gbẹ́kẹ̀lé. Àwọn ni a yàn láti máa pín ohun èlò fún àwọn arákùnrin wọn.

14Rántí ì mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o má sì ṣe gbàgbé ohun tí mo fi òtítọ́ ṣe fún ilé Ọlọ́run mi yìí àti fún iṣẹ́ ẹ rẹ̀ gbogbo.

15Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, mo rí àwọn ènìyàn ní Juda tí wọ́n ń fúntí ní ọjọ́ ìsinmi, tí wọ́n sì ń gbé ọkà wọlé, tí wọn ń di ẹrù lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pẹ̀lú wáìnì, èso àjàrà, ọ̀pọ̀tọ́ àti onírúurú ẹrù. Wọ́n sì ń kó gbogbo èyí wá sí Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi. Nítorí náà, mo kìlọ̀ fún wọn nípa títa oúnjẹ ní ọjọ́ náà. 16Àwọn ará Tire ti ń gbé nínú Jerusalẹmu ń gbé ẹja àti onírúurú ọjà wá fún títà ní ọjọ́ ìsinmi fún àwọn ènìyàn Jerusalẹmu àti fún àwọn ọmọ Juda. 17Mo bá àwọn ọlọ́lá Juda wí, mo wí fún wọn pé, “Èwo ni ohun búburú tí ẹ ń ṣe yìí ti ẹ ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́. 18Ṣé àwọn baba ńlá yín kò ha ti ṣe nǹkan kan náà tí Ọlọ́run wa fi mú gbogbo àjálù yìí wá orí wa, àti sórí ìlú yìí? Báyìí, ẹ̀yin tún ń ru ìbínú sókè sí i sórí Israẹli nípa bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́.”

19Nígbà tí ojú ọjọ́ ń bora ní ẹnu ibodè Jerusalẹmu, ṣáájú ọjọ́ ìsinmi, mo pàṣẹ pé kí a ti àwọn ìlẹ̀kùn, kí wọn má sì ṣí i títí tí ọjọ́ ìsinmi yóò fi kọjá. Mo yan àwọn ìránṣẹ́ mi láti ṣọ́ ẹnu ibodè, kí a má ba à lè gbé ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ ìsinmi. 20Síbẹ̀, àwọn tí ń tà àti àwọn tí ń rà sùn ẹ̀yìn odi Jerusalẹmu ní ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì. 21Ṣùgbọ́n mo kìlọ̀ fún wọn pé, “Èétijẹ́ ti ẹ̀yin fi ń sùn ní ẹ̀yin odi ní òru? Bí ẹ̀yìn bá tún dánwò mọ́, èmi yóò fi ọwọ́ líle mú yín.” Láti ọjọ́ náà lọ, wọn kò sì wá ní ọjọ́ ìsinmi mọ́. 22Nígbà náà ni mo pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi pé kí wọn ya ara wọn sí mímọ́, kí wọn sì ṣọ́ ẹnu ibodè kí a lè pa ọjọ́ ìsinmi mọ́.

Tún rántí mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o sì fi àánú un rẹ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí i títóbi ìfẹ́ ẹ̀ rẹ.

23Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, mo rí àwọn ọkùnrin Juda tí wọ́n fẹ́ àwọn obìnrin láti Aṣdodu, Ammoni àti Moabu. 24Ìdajì àwọn ọmọ wọn ń sọ èdè Aṣdodu tàbí èdè ọ̀kan lára àwọn ènìyàn mìíràn tókù, wọn kò sì mọ bí a ṣe ń sọ èdè Juda. 25Mo bá wọn wí mo sì gégùn ún lé wọn lórí. Mo lu àwọn ènìyàn díẹ̀ nínú wọn mo sì fa irun orí wọn tu. Mo mú kí wọn búra ní orúkọ Ọlọ́run, kí wọn wí pé, “Ẹ̀yin kì yóò fi àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó tàbí fún ẹ̀yin tìkára yín. 26Kì í ha á ṣe àwọn ìgbéyàwó bí irú èyí ni ọba Solomoni fi dá ẹ̀ṣẹ̀? Láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, kò sí ọba kan bí i tirẹ̀. Ọlọ́run rẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀, Ọlọ́run sì fi jẹ ọba lórí i gbogbo Israẹli, ṣùgbọ́n àwọn obìnrin àjèjì ti sọ ọ́ sínú òfin ẹ̀ṣẹ̀. 27Ǹjẹ́ ó ha yẹ kí àwa tún gbọ́ báyìí pé ẹ̀yin náà tún ń ṣe àwọn nǹkan tí ó burú jọjọ wọ̀nyí tí ẹ sì ń ṣe aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífẹ́ àwọn obìnrin àjèjì?”

28Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Joiada, ọmọ Eliaṣibu olórí àlùfáà jẹ́ àna Sanballati ará a Horoni. Mo sì lé e jáde kúrò lọ́dọ̀ mi.

29Rántí wọn, Ọlọ́run mi, nítorí wọ́n ti ba iṣẹ́ àlùfáà jẹ́ pẹ̀lú májẹ̀mú iṣẹ́ àlùfáà àti ti àwọn Lefi.

30Nítorí náà, mo ya àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi sí mímọ́ kúrò nínú gbogbo ohun àjèjì, mo sì yan iṣẹ́ fún wọn, olúkúlùkù sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀. 31Mo sì tún pèsè fún ọrẹ, igi—pákó ní àkókò tí a yàn àti fún àwọn èso àkọ́so.

Rántí mi fún rere, Ọlọ́run mi.

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

Неемия 13:1-31

Удаление аммонитян и моавитян из Исраила

1В тот день народу читали вслух из Таурата, книги Мусы, и нашли написанным там, что никакого аммонитянина и моавитянина нельзя принимать в общество Аллаха, 2потому что они не встретили исраильтян с пищей и водой, но наняли Валаама, чтобы проклясть их. (Но наш Бог превратил проклятие в благословение.)13:1-2 См. Втор. 23:3-5. 3Услышав этот закон, они удалили из Исраила всех, кто происходил от чужеземцев.

Восстановление порядка в храме

4Перед этим заботе священнослужителя Элиашива были вверены хранилища дома нашего Бога. Он был тесно связан с Товией 5и приготовил для него большую комнату, где прежде хранили хлебные приношения, благовония и храмовую утварь, а также десятины зерна, молодого вина и масла, предназначенные по Закону для левитов, певцов и привратников, а ещё пожертвования для священнослужителей.

6Но когда всё это происходило, меня не было в Иерусалиме, ведь в тридцать второй год правления Артаксеркса, царя Вавилона13:6 Персидский царь Артаксеркс назван здесь царём Вавилона потому, что Персия завоевала Вавилонскую империю. (433 г. до н. э.), я уже вернулся к царю. Некоторое время спустя я отпросился у него 7и вернулся в Иерусалим. Здесь я узнал о зле, которое сделал Элиашив, приготовив во дворах дома Аллаха комнату для Товии. 8Я очень разгневался и выбросил все домашние вещи Товии из комнаты. 9Я приказал очистить комнаты и опять внёс в них утварь дома Аллаха, хлебные приношения и благовония.

10Ещё я обнаружил, что доли, предназначенные для левитов, не были им даны и что все левиты и певцы, проводившие служения, вернулись на свои поля. 11Я упрекнул начальников и спросил их:

– Почему оставлен дом Аллаха?

Затем я собрал их и расставил по местам. 12И тогда весь народ Иудеи принёс в хранилища десятины зерна, молодого вина и масла. 13Я вверил хранилища заботам священнослужителя Шелемии, Цадока, учителя Таурата, и левита по имени Педая и дал им в помощники Ханана, сына Заккура, сына Маттании, потому что эти люди считались надёжными. Им было поручено распределять запасы между их собратьями.

14Вспомни меня за это, Бог мой, и не изгладь моих благих дел, которые я сделал для дома моего Бога и для его служб.

Возобновление соблюдения субботы

15В те дни я увидел в Иудее людей, которые топтали виноград в давильнях в субботу13:15 Суббота – седьмой день недели у иудеев, день, посвящённый Вечному. В этот день, согласно повелению Вечного, исраильский народ должен был отдыхать и совершать ритуальные жертвоприношения (см. Исх. 31:12-17; Чис. 28:9-10)., завозили снопы с зерном и грузили их на ослов вместе с вином, виноградом, инжиром и всяким другим грузом. И всё это они везли в Иерусалим в субботу. Поэтому я предостерёг их, чтобы в этот день они не торговали едой. 16Люди из Тира, которые жили в Иерусалиме, привозили рыбу и всякие виды товаров и продавали их в Иерусалиме в субботу народу Иудеи. 17Я упрекнул знать Иудеи и сказал им:

– Что за злое дело вы делаете, оскверняя субботний день? 18Разве не то же самое делали ваши отцы, и наш Бог навёл на нас и на этот город всю эту беду? А вы сейчас, оскверняя субботу, разжигаете против Исраила ещё больший гнев.

19Когда перед субботой у ворот Иерусалима начали опускаться сумерки, я приказал запереть двери и не открывать их, пока не пройдёт суббота. Я поставил у ворот несколько человек из своих слуг, чтобы в субботу нельзя было внести никакого груза. 20Один или два раза купцы и торговцы всякого рода товаром ночевали вне Иерусалима. 21Но я предостерёг их и сказал:

– Зачем вы ночуете у стены? Если вы сделаете это ещё раз, я применю против вас силу.

И с того времени они уже не приходили в субботу. 22Затем я велел левитам очиститься и пойти стеречь ворота, чтобы сохранить субботний день святым.

Вспомни меня и за это, Бог мой, и помилуй меня по величию Твоей милости.

Запрет на смешанные браки

23Более того, в те дни я видел иудеев, которые женились на женщинах из Ашдода, Аммона и Моава. 24Половина их детей говорила на языке Ашдода или на языке какого-нибудь из прочих народов и не умела говорить по-иудейски. 25Я упрекал их и призывал на них проклятия. Я бил некоторых из них и таскал за волосы. Я заставил их поклясться именем Аллаха и сказал:

– Вы не должны отдавать своих дочерей замуж за сыновей других народов и не должны брать их дочерей в жёны своим сыновьям или самим себе. 26Не из-за таких ли вот браков впал в грех царь Исраила Сулейман? У многих народов не было царя, подобного ему. Его любил Аллах и сделал его царём над всем Исраилом, но чужеземные жёны ввели в грех даже его. 27Должны ли мы теперь слышать, что и вы совершаете всё это страшное зло и нарушаете верность нашему Богу, женясь на чужеземках?

28Один из сыновей Иояды, сына главного священнослужителя Элиашива, был зятем хоронитянина Санбаллата. И я прогнал его от себя.

29Вспомни их, Бог мой, ведь они осквернили священство и соглашение священнослужителей и левитов.

30Так я очистил их от всего иноземного и установил обязанности священнослужителям и левитам, каждому – своё дело. 31А ещё я позаботился о поставке дров в назначенные сроки и о первых плодах.

Вспомни меня, Бог мой, мне во благо.