Nehemiah 11 – YCB & CARS

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Nehemiah 11:1-36

Àwọn olùgbé tuntun ní Jerusalẹmu

1Nísinsin yìí àwọn olórí àwọn ènìyàn tẹ̀dó sí Jerusalẹmu, àwọn ènìyàn tókù sì dìbò láti mú ẹnìkọ̀ọ̀kan jáde nínú àwọn mẹ́wàá mẹ́wàá láti máa gbé ní Jerusalẹmu, ìlú mímọ́, nígbà tí àwọn mẹ́sàn-án tókù yóò dúró sí àwọn ìlú u wọn. 2Àwọn ènìyàn súre fún gbogbo àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn láti gbé ní Jerusalẹmu.

311.3-22: 1Ki 9.2-34.Wọ̀nyí ni àwọn olórí agbègbè ìjọba tí wọ́n tẹ̀dó sí Jerusalẹmu (díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Israẹli àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ìran àwọn ìránṣẹ́ Solomoni ń gbé àwọn ìlú Juda, olúkúlùkù ń gbé lórí ilẹ̀ ìní rẹ̀ ní àwọn ìlú náà. 4Nígbà tí àwọn ènìyàn tókù nínú àwọn Juda àti Benjamini ń gbé ní Jerusalẹmu).

Nínú àwọn ọmọ Juda:

Ataiah ọmọ Ussiah ọmọ Sekariah, ọmọ Amariah, ọmọ Ṣefatia, ọmọ Mahalaleli, ìran Peresi;

5àti Maaseiah ọmọ Baruku, ọmọ Koli-Hose, ọmọ Hasaiah, ọmọ Adaiah, ọmọ Joiaribu, ọmọ Sekariah, ọmọ Ṣilo.

6Àwọn ìran Peresi tó gbé ní Jerusalẹmu jẹ́ àádọ́rinlénírinwó ó dín méjì (468) alágbára ọkùnrin.

7Nínú àwọn ìran Benjamini:

Sallu ọmọ Meṣullamu, ọmọ Joẹdi, ọmọ Pedaiah, ọmọ Kolaiah, ọmọ Maaseiah, ọmọ Itieli, ọmọ Jeṣaiah, 8àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Gabbai àti Sallai jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rún ó lé mẹ́jọ (928) ọkùnrin.

9Joẹli ọmọ Sikri ni olórí òṣìṣẹ́ wọn, Juda ọmọ Hasenuah sì ni olórí agbègbè kejì ní ìlú náà.

10Nínú àwọn àlùfáà:

Jedaiah; ọmọ Joiaribu; Jakini;

11Seraiah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraioti, ọmọ Ahitubu, àwọn ni olórí tó ń bojútó ilé Ọlọ́run, 12àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ ní tẹmpili jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó lé mẹ́rìnlélógún (822) ọkùnrin:

Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Pelaiah, ọmọ Amisi, ọmọ Sekariah, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkiah, 13àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olórí ìdílé jẹ́ òjìlúgba ó lé méjì (242) ọkùnrin:

Amaṣai ọmọ Asareeli, ọmọ Ahsai, ọmọ Meṣilemoti, ọmọ Immeri, 14àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin jẹ́ méjìdínláàádóje (128).

Olórí òṣìṣẹ́ ẹ wọn ni Sabdieli ọmọ Hagedolimu.

15Láti inú àwọn ọmọ Lefi:

Ṣemaiah ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah ọmọ Bunni;

16Ṣabbetai àti Josabadi, olórí méjì nínú àwọn ọmọ Lefi, àwọn tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ tí ó wà ní ẹ̀yìn àgbàlá ilé Ọlọ́run;

17Mattaniah ọmọ Mika, ọmọ Sabdi, ọmọ Asafu, adarí tí ó ń ṣáájú ìdúpẹ́ àti àdúrà;

Bakbukiah ẹnìkejì láàrín àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀;

àti Abida ọmọ Ṣammua, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni.

18Àwọn ọmọ Lefi nínú ìlú mímọ́ jẹ́ ọ̀rìnlélúgba ó lé mẹ́rin (284).

19Àwọn aṣọ́nà:

Akkubu, Talmoni, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, tí wọ́n máa ń ṣọ́nà jẹ́ méjìléláàádọ́sàn-án (172) ọkùnrin.

20Àwọn tókù nínú àwọn ọmọ Israẹli, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, wà ní gbogbo ìlú u Juda, olúkúlùkù lórí ilẹ̀ ìní tirẹ̀.

21Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili ń gbé lórí òkè Ofeli, Siha àti Giṣpa sì ni alábojútó wọn.

22Olórí òṣìṣẹ́ àwọn ọmọ Lefi ní Jerusalẹmu ní Ussi ọmọ Bani, ọmọ Haṣabiah, ọmọ Mattaniah ọmọ Mika. Ussi jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìran Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin ojúṣe nínú ìjọ́sìn ní ilé Ọlọ́run. 23Àwọn akọrin wà ní abẹ́ àṣẹ ọba, èyí tí ó n díwọ̀n iṣẹ́ ojoojúmọ́ wọn.

24Petahiah ọmọ Meṣesabeli, ọ̀kan nínú àwọn Sera ọmọ Juda ní aṣojú ọba nínú ohun gbogbo tí ó jẹ mọ́ ti àwọn ènìyàn náà.

25Fún ìletò pẹ̀lú oko wọn, díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn Juda tí ń gbé Kiriati-Arba, àti àwọn ìletò agbègbè e rẹ̀, ní Diboni àti ìletò rẹ̀, ní Jekabseeli. 26Ní Jeṣua, ní Molada, ní Beti-Peleti 27ní Hasari-Ṣuali, ní Beerṣeba àti àwọn agbègbè rẹ̀. 28Ní Siklagi, ní Mekona àti àwọn ìletò rẹ̀, 29ní Ẹni-Rimoni, ní Sora, ní Jarmatu, 30Sanoa, Adullamu àti àwọn ìletò o wọn, ní Lakiṣi àti àwọn oko rẹ̀, àti ní Aseka àti àwọn ìletò rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé láti Beerṣeba títí dé àfonífojì Hinnomu.

31Àwọn ọmọ Benjamini láti Geba ń gbé ní Mikmasi, Aija, Beteli àti àwọn ìletò rẹ̀. 32Ní Anatoti, Nobu àti Ananiah, 33ní Hasori Rama àti Gittaimu, 34ní Hadidi, Seboimu àti Neballati, 35ní Lodi àti Ono, àti ní àfonífojì àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà.

36Nínú ìpín àwọn ọmọ Lefi ni Juda tẹ̀dó sí Benjamini.

Священное Писание

Неемия 11:1-36

Жители Иерусалима и Иудеи

(1 Лет. 9:1-17)

1Вожди народа поселились в Иерусалиме, а остальной народ бросал жребий, чтобы выбрать одного из десяти для того, чтобы жить в Иерусалиме, святом городе, тогда как прочие девять оставались в своих городах. 2Народ хвалил всех, кто добровольно соглашался жить в Иерусалиме.

3Вот вожди провинции, которые поселились в Иерусалиме (некоторые исраильтяне, священнослужители, левиты, храмовые слуги и потомки слуг Сулеймана жили в городах Иудеи, каждый – в своём владении в различных городах, 4а остальной народ из потомков Иуды и потомков Вениамина жил в Иерусалиме).

Из потомков Иуды:

Атая, сын Уззии, сына Закарии, сына Амарии, сына Шефатии, сына Малелеила, потомка Фареца; 5и Маасея, сын Баруха, сына Кол-Хозе, сына Хазаи, сына Адаи, сына Иоярива, сына Закарии, потомка Шелы. 6Потомков Фареца, живших в Иерусалиме, было 468 храбрых воинов.

7Из потомков Вениамина:

Саллу, сын Мешуллама, сына Иоеда, сына Педаи, сына Колаи, сына Маасея, сына Итиила, сына Иешаи, 8и за ним Габбай и Саллай – 928 человек. 9Иоиль, сын Зихри, был над ними начальником, а Иуда, сын Ассенуа, был вторым над городом.

10Из священнослужителей:

Иедая, сын Иоярива, Иахин, 11распорядитель в доме Всевышнего Серая, сын Хилкии, сына Мешуллама, сына Цадока, сына Мерайота, сына Ахитува, 12и их собратья, исполняющие работы при храме, – 822 человека; Адая, сын Иерохама, сына Пелалии, сына Амци, сына Закарии, сына Пашхура, сына Малхии, 13и его собратья, которые были главами семейств, – 242 человека; Амашсай, сын Азарила, сын Ахзая, сын Мешиллемота, сына Иммера, 14и его11:14 Или: «их». собратья – храбрые воины – 128 человек. Начальником над ними был Завдиил, сын Аггедолима.

15Из левитов:

Шемая, сын Хашува, сына Азрикама, сына Хашавии, сына Бунни; 16Шаббетай и Иозавад, двое из глав левитов, которым был вверен надзор за внешней работой при доме Всевышнего; 17Маттания, сын Михи, сына Завди, сына Асафа, главный начинатель благодарения при молитве; Бакбукия, второй среди его собратьев, и Авда, сын Шаммуа, сына Галала, сына Иедутуна. 18Всего левитов в святом городе было 284 человека.

19Привратники:

Аккув, Талмон и их собратья, которые несли дозор при воротах, – 172 человека.

20Остальные исраильтяне со священнослужителями и левитами находились во всех городах Иудеи, каждый в своём наделе.

21Храмовые слуги жили на холме Офел, и начальниками над ними были Циха и Гишпа.

22Начальником левитов в Иерусалиме был Уззий, сын Бани, сына Хашавии, сына Маттании, сына Михи. Уззий был одним из потомков Асафа, певцов, ответственных за служение в доме Всевышнего. 23Было особое царское повеление о них, которое определяло их ежедневное содержание.

24Петахия, сын Мешезавила, один из потомков сына Иуды Зераха, был царским представителем во всех делах, касающихся народа.

25А что касается селений с их полями, то некоторые из народа Иудеи жили в Кириат-Арбе и её окрестных селениях, в Дивоне и его селениях, в Кавцеиле и его селениях, 26в Иешуе, в Моладе, в Бет-Пелете, 27в Хацар-Шуале, в Беэр-Шеве и её селениях, 28в Циклаге, в Мехоне и её селениях, 29в Ен-Риммоне, в Цоре, в Иармуте, 30Заноахе, Адулламе и их селениях, в Лахише и на его полях, в Азеке и в её селениях. Они обитали от Беэр-Шевы до долины Гинном.

31Потомки вениамитян из Гевы жили в Михмасе, Гае, Вефиле и его селениях, 32в Анатоте, Нове и Анании, 33в Хацоре, Раме и Гиттаиме, 34в Хадиде, Цевоиме и Неваллате, 35в Лоде, Оно и в Ге-Харашиме («долине ремесленников»).

36Некоторые из групп левитов Иудеи поселились в землях Вениамина.