Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Nahumu 1:1-15

1Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ nípa Ninefe. Ìwé ìran Nahumu ará Elkoṣi.

Ìbínú Olúwa sí Ninefe

2Ọlọ́run ń jẹ owú, ó sì ń gbẹ̀san.

Olúwa ń gbẹ̀san, ó sì kún fún ìbínú

Olúwa ń gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀,

Ìbínú rẹ̀ kò sì yí padà lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀

31.3: Isa 10.5-34; Sf 2.12-15.Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára;

Olúwa kì yóò fi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láìjìyà.

Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú afẹ́fẹ́ àti nínú ìjì,

Ìkùùkuu sánmọ̀ sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀.

4Ó bá Òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ;

Ó sìsọ gbogbo odò di gbígbẹ.

Baṣani àti Karmeli sì rọ,

Ìtànná Lebanoni sì rẹ̀ sílẹ̀.

5Àwọn òkè ńlá wárìrì níwájú rẹ̀,

àwọn òkè kéékèèkéé sì di yíyọ́,

ilẹ̀ ayé sì jóná níwájú rẹ̀,

àní ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

6Ta ni ó lé dúró níwájú ìbínú rẹ̀?

Ta ni ó lé faradà gbígbóná ìbínú rẹ̀?

Ìbínú rẹ̀ tú jáde bí iná;

àwọn àpáta sì fọ́ túútúú níwájú rẹ̀.

7Rere ni Olúwa,

òun ni ààbò ní ọjọ́ ìpọ́njú.

Òun sì tọ́jú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e,

8Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìkún omi ńlá

ní òun yóò fi ṣe ìparun láti ibẹ̀ dé òpin;

òkùnkùn yóò sì máa lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀.

9Kí ni ẹ̀yìn ń gbìmọ̀ lòdì sí Olúwa?

Òun yóò fi òpin sí i,

ìpọ́njú kì yóò wáyé ní ìgbà kejì

10Wọn yóò sì lọ́lù papọ̀ bí ẹ̀gún òṣùṣú

wọn yóò sì mu àmupara nínú ọtí wáìnì wọn

a ó sì run wọn gẹ́gẹ́ bi àgékù koríko gbígbẹ

11Láti ọ̀dọ̀ rẹ, ìwọ Ninefe, ni ẹnìkan ti jáde wá

tí ó ń gbèrò ibi sí Olúwa

ti ó sì ń gbìmọ̀ búburú.

12Báyìí ni Olúwa wí:

“Bí wọ́n tilẹ̀ ni ìfọwọ́sowọ́pọ̀, tí wọ́n sì pọ̀ níye,

Ṣùgbọ́n, báyìí ní a ó ké wọn lulẹ̀,

nígbà tí òun ó bá kọjá.

Bí mo tilẹ̀ ti pọ́n ọ lójú ìwọ Juda, èmi kì yóò pọ́n ọ lójú mọ́.

13Nísinsin yìí ni èmi yóò já àjàgà wọn kúrò ní ọrùn rẹ

èmi yóò já ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ rẹ dànù.”

14Olúwa ti fi àṣẹ kan lélẹ̀ nítorí tìrẹ Ninefe:

“Ìwọ kì yóò ni irú-ọmọ láti máa jẹ́ orúkọ rẹ mọ́,

Èmi yóò pa ère fínfín àti ère dídà run

tí ó wà nínú tẹmpili àwọn ọlọ́run rẹ.

Èmi yóò wa ibojì rẹ,

nítorí ẹ̀gbin ni ìwọ.”

151.15: Isa 40.9; 52.7; Ap 10.36; Ro 10.15.Wò ó, lórí àwọn òkè,

àwọn ẹsẹ̀ ẹni tí ó mú ìròyìn ayọ̀ wá,

ẹni tí ó ń kéde àlàáfíà,

Ìwọ Juda, pa àṣẹ rẹ tí ó ní ìrònú mọ́,

kí ó sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ.

Àwọn ènìyàn búburú kì yóò sì gbóguntì ọ́ mọ́;

wọn yóò sì parun pátápátá.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

那鴻書 1:1-15

1以下是關於尼尼微的預言,是伊勒歌斯那鴻的啟示書。

耶和華向尼尼微發怒

2耶和華是痛恨不貞、施行報應的上帝。

耶和華施行報應,充滿烈怒。

耶和華報應祂的仇敵,向他們發烈怒。

3耶和華不輕易發怒,有偉大的能力。

耶和華斷不以有罪的為無罪。

祂行走在旋風和暴風中,

雲彩是祂腳下的塵土。

4祂斥責大海,使大海乾涸;

祂使一切河流枯竭。

巴珊迦密的草木凋零,

黎巴嫩的鮮花衰殘。

5在祂面前,群山震動,丘陵消融。

在祂面前,大地隆起,

世界和世上的一切都戰慄。

6祂發怒,誰能站立?

祂發烈怒,誰能承受?

祂的憤怒如火焰噴湧而出,

磐石在祂面前崩裂。

7耶和華是良善的,

是人患難時的避難所;

祂看顧那些信靠祂的人。

8祂必用滔滔洪水滅絕祂的敵人,

把他們驅逐到黑暗中。

9尼尼微人啊,

你們為何圖謀抵擋耶和華?

祂要徹底毀滅你們,

無需擊打兩次。

10你們像糾結的荊棘,

又像酩酊大醉的人,

要如乾稭被火燒盡。

11你們當中有一個人,

一個邪惡的陰謀者,

圖謀抵擋耶和華。

12耶和華說:

「儘管尼尼微勢力強大、人口眾多,

但必被剷除,化為烏有。

我的子民啊,我使你們受了苦,

但必不再使你們受苦。

13現在我要打碎他們套在你們頸項上的軛,

鬆開你們身上的鎖鏈。」

14尼尼微啊,

耶和華已發出有關你的命令:

「你的名不會傳於後世。

我要摧毀你神廟中雕刻和鑄造的偶像。

我要為你掘好墳墓,

因為你毫無用處。」

15看啊,

傳喜訊、報平安的人穿山越嶺而來。

猶大啊,

慶祝你的節期,

還你許的願吧!

邪惡之人將不再侵擾你,

他們都將被徹底毀滅。