Matiu 14 – YCB & NTLR

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Matiu 14:1-36

A bẹ́ Johanu Onítẹ̀bọmi lórí

114.1-2: Mk 6.14-16; Lk 9.7-9; Mk 8.28.Ní àkókò náà ni Herodu ọba tetrarki gbọ́ nípa òkìkí Jesu, 2ó wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Dájúdájú Johanu onítẹ̀bọmi ni èyí, ó jíǹde kúrò nínú òkú. Ìdí nìyí tí ó fi ní agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí.”

314.3-4: Mk 6.17-18; Lk 3.19-20; Le 18.16; 20.21.Nísinsin yìí Herodu ti mú Johanu, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì fi sínú túbú, nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀, 4nítorí Johanu onítẹ̀bọmi ti sọ fún Herodu pé, “Kò yẹ fún ọ láti fẹ́ obìnrin náà.” 514.5-12: Mk 6.19-29.Herodu fẹ́ pa Johanu, ṣùgbọ́n ó bẹ̀rù àwọn ènìyàn nítorí gbogbo ènìyàn gbàgbọ́ pé wòlíì ni.

6Ní ọjọ́ àsè ìrántí ọjọ́ ìbí Herodu, ọmọ Herodia obìnrin jó dáradára, ó sì tẹ́ Herodu lọ́run gidigidi. 7Nítorí náà ni ó ṣe fi ìbúra ṣe ìlérí láti fún un ní ohunkóhun ti ó bá béèrè fún. 8Pẹ̀lú ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó béèrè pé, “Fún mi ni orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú àwopọ̀kọ́”. 9Inú ọba bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí ìbúra rẹ̀ àti kí ojú má ba à tì í níwájú àwọn àlejò tó wà ba jẹ àsè, ó pàṣẹ pé kí wọ́n fún un gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́. 10Nítorí náà, a bẹ́ orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú ilé túbú. 11A sì gbé orí rẹ̀ jáde láti fi fún ọmọbìnrin náà nínú àwopọ̀kọ́, òun sì gbà á, ó gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ. 12Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu wá gba òkú rẹ̀, wọ́n sì sin ín. Wọ́n sì wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jesu.

Jesu bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ènìyàn

1314.13-21: Mk 6.32-44; Lk 9.10-17; Jh 6.1-13; Mt 15.32-38.Nígbà tí Jesu gbọ́ ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó kúrò níbẹ̀, ó bá ọkọ̀ ojú omi lọ sí ibi kọ́lọ́fín kan ní èbúté láti dá wà níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ẹsẹ̀ rìn tẹ̀lé e láti ọ̀pọ̀ ìlú wọn. 14Nígbà ti Jesu gúnlẹ̀, tí ó sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, inú rẹ̀ yọ́ sí wọn, ó sì mú àwọn aláìsàn láradá.

15Nígbà ti ilẹ̀ ń ṣú lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí pé, “Ibi yìí jìnnà sí ìlú ilẹ̀ sì ń ṣú lọ. Rán àwọn ènìyàn lọ sí àwọn ìletò kí wọ́n lè ra oúnjẹ jẹ.”

16Ṣùgbọ́n Jesu fèsì pé, “Kò nílò kí wọ́n lọ kúrò. Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.”

17Wọ́n sì dalóhùn pé, “Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì lọ níhìn-ín.”

18Ó wí pé, “Ẹ mú wọn wá fún mi níhìn-ín yìí.” 1914.19: Mk 14.22; Lk 24.30.Lẹ́yìn náà, ó wí fún àwọn ènìyàn kí wọ́n jókòó lórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì. Ó gbé ojú rẹ̀ sí ọ̀run. Ó béèrè ìbùkún Ọlọ́run lórí oúnjẹ náà, Ó sì bù ú, ó sì fi àkàrà náà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti pín in fún àwọn ènìyàn. 20Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kó àjẹkù jọ, ó kún agbọ̀n méjìlá. 21Iye àwọn ènìyàn ni ọjọ́ náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin, láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.

Jesu rìn lójú omi

2214.22-23: Mk 6.45-46; Jh 6.15-17.Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n bọ sínú ọkọ̀ wọn, àti kí wọ́n máa kọjá lọ ṣáájú rẹ̀ sí òdìkejì. Òun náà dúró lẹ́yìn láti tú àwọn ènìyàn ká lọ sí ilé wọn. 23Lẹ́yìn tí ó tú ìjọ ènìyàn ká tán, ó gun orí òkè lọ fúnra rẹ̀ láti lọ gba àdúrà. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, òun wà nìkan níbẹ̀, 2414.24-33: Mk 6.47-52; Jh 6.16-21.ní àkókò yìí ọkọ̀ ojú omi náà ti rin jìnnà sí etí bèbè Òkun, tí ìjì omi ń tì í síwá sẹ́yìn, nítorí ìjì ṣe ọwọ́ òdì sí wọn.

25Ní déédé ago mẹ́rin òwúrọ̀, Jesu tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi. 2614.26: Lk 24.37.Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù ba wọn gidigidi, wọ́n rò pé “iwin ni,” wọ́n kígbe tìbẹ̀rù tìbẹ̀rù.

27Lójúkan náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni ẹ má ṣe bẹ̀rù.”

28Peteru sì ké sí i pé, “Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni nítòótọ́, sọ pé kí n tọ̀ ọ́ wà lórí omi.”

2914.29: Jh 21.7.Jesu dá a lóhùn pé, “Ó dára, máa bọ̀ wá.”

Nígbà náà ni Peteru sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀. Ó ń rìn lórí omi lọ sí ìhà ọ̀dọ̀ Jesu. 30Nígbà tí ó rí afẹ́fẹ́ líle, ẹ̀rù bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ó kígbe lóhùn rara pé, “Gbà mí, Olúwa.”

3114.31: Mt 6.30; 8.26; 16.8.Lójúkan náà, Jesu na ọwọ́ rẹ̀, ó dìímú, ó sì gbà á. Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣiyèméjì ìwọ onígbàgbọ́ kékeré?”

32Àti pé, nígbà ti wọ́n sì gòkè sínú ọkọ̀, ìjì náà sì dúró jẹ́ẹ́. 3314.33: Mt 28.9,17.Nígbà náà ni àwọn to wà nínú ọkọ̀ náà foríbalẹ̀ fún un wọ́n wí pé, “Nítòótọ́ Ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ í ṣe.”

3414.34-36: Mk 6.53-56; Gẹ 6.22.Nígbà tí wọn rékọjá sí apá kejì wọ́n gúnlẹ̀ sí Genesareti. 35Nígbà tiwọn mọ̀ pé Jesu ni, wọn sì ránṣẹ́ sí gbogbo ìlú náà yíká. Wọ́n sì gbé gbogbo àwọn aláìsàn tọ̀ ọ́ wá. 3614.36: Mk 3.10; Nu 15.38; Mt 9.20.Àwọn aláìsàn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó gba àwọn láyè láti fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sì rí ìwòsàn.

Nouă Traducere În Limba Română

Matei 14:1-36

Ioan Botezătorul decapitat

(Mc. 6:14-29; Lc. 3:19-20; 9:7-9)

1În vremea aceea, tetrarhul Irod1 Irod Antipa (care a domnit între anii 4 î.Cr.–39 d.Cr.), unul dintre fiii lui Irod cel Mare. Tetrarhul domnea peste a patra parte a unei regiuni, fiind inferior unui rege și stăpânind doar cu aprobarea romanilor (vezi Flavius Josephus, Antichități, XVII.11.4). a auzit despre faima lui Isus 2și le-a zis slujitorilor săi: „Acesta este Ioan Botezătorul! A fost înviat dintre cei morți și de aceea lucrează aceste puteri prin el!“

3Căci Irod, după ce a pus mâna pe Ioan, l-a legat și l-a pus în închisoare din cauza Irodiadei3 Nepoată a lui Irod cel Mare, căsătorită mai întâi cu Filip, fratele vitreg al lui Irod Antipa (a nu se confunda cu tetrarhul Filip; vezi Lc. 3:1). Vezi Flavius Josephus, Antichități, XVIII.5.4., soția lui Filip, fratele său, 4deoarece Ioan îi zicea: „Nu-ți este permis s-o ai de soție!“4 Cf. Lev. 18:16; 20:21. 5Irod ar fi vrut să-l omoare, dar se temea de mulțime, pentru că oamenii îl considerau pe Ioan un profet.

6Însă, la sărbătorirea zilei de naștere a lui Irod, fiica Irodiadei a dansat înaintea invitaților și i-a plăcut lui Irod, 7așa că el i-a promis cu jurământ că-i va da orice va cere. 8Îndemnată de mama ei, ea i-a zis: „Dă-mi aici, pe o tavă, capul lui Ioan Botezătorul!“ 9Regele s-a întristat, dar, din cauza jurămintelor și a celor ce ședeau la masă, a poruncit să-i fie dat capul 10și a trimis un călău să-l decapiteze pe Ioan în închisoare. 11Capul lui a fost adus pe o tavă și dat fetei, iar aceasta i l-a dus mamei sale. 12Ucenicii lui Ioan au venit, i-au luat trupul și l-au înmormântat. Apoi s-au dus și L-au anunțat pe Isus.

Isus hrănește peste cinci mii de oameni

(Mc. 6:32-44; Lc. 9:10-17; In. 6:1-13)

13Când a auzit aceasta, Isus S-a retras de acolo într-o barcă, spre un loc pustiu, ca să fie doar El singur. Dar mulțimile, auzind lucrul acesta, L-au urmat pe jos din cetățile lor. 14Când a coborât din barcă, Isus a văzut o mare mulțime de oameni; I s-a făcut milă de ei și i-a vindecat pe cei bolnavi.

15Când s-a făcut seară, ucenicii Lui s-au apropiat, zicând:

– Locul acesta este pustiu și ora este deja târzie15 Lit.: ora deja a trecut, cel mai probabil o expresie idiomatică al cărei sens principal poate fi: este deja târziu. Alte două posibile sensuri în acest context sunt: (1) ora obișnuită la care se ia cina a trecut deja și (2) ora este deja prea înaintată pentru a continua să le dai învățături oamenilor.. Lasă mulțimile să se ducă prin sate ca să-și cumpere mâncare.

16Însă Isus le-a zis:

– Nu au nevoie să plece. Dați-le voi să mănânce!

17Ei I-au răspuns:

– N-avem aici decât cinci pâini și doi pești.

18El le-a zis:

– Aduceți-le aici, la Mine.

19După ce a poruncit ca mulțimile să fie așezate19 Israeliții și celelalte popoare din Orientul Mijlociu obișnuiau să mănânce în poziție semi-culcată. Vezi nota de la 8:11. pe iarbă, în grupuri, a luat cele cinci pâini și cei doi pești și, privind spre cer, a binecuvântat și a frânt pâinile. Apoi le-a dat ucenicilor, iar ucenicii le-au dat mulțimilor. 20Ei au mâncat cu toții și s-au săturat. Și au ridicat douăsprezece coșnițe pline cu firimiturile rămase. 21Cei ce mâncaseră erau aproape cinci mii de bărbați, în afară de femei și de copii.

Isus umblă pe mare

(Mc. 6:45-51; In. 6:16-21)

22Imediat după aceea, Isus i-a zorit pe ucenici să se urce în barcă și să treacă înaintea Lui de partea cealaltă a mării, în timp ce El va lăsa mulțimile să plece. 23După ce a lăsat mulțimile să plece, Isus S-a urcat pe munte, doar El singur, ca să Se roage. Se înserase, iar El era singur acolo. 24Barca se îndepărtase deja la mai multe stadii24 O stadie (gr.: stadios) măsura aproximativ 185 m. de țărm și era lovită de valuri, pentru că vântul era împotrivă.

25În a patra strajă a nopții25 Între orele 3:00–6:00. Evreii au împrumutat de la romani împărțirea nopții în 4 străji a câte 3 ore. În VT, noaptea era împărțită în 3 străji a câte 4 ore (apus–22:00; 22:00–2:00; 2:00–răsărit)., Isus a venit spre ei, umblând pe mare. 26Când ucenicii L-au văzut umblând pe mare, s-au înspăimântat și au zis: „Este o stafie!“ Și au țipat de frică.

27Dar Isus le-a vorbit imediat și le-a zis:

– Îndrăzniți! Eu sunt! Nu vă temeți!

28Petru, răspunzându-I, a zis:

– Doamne, dacă ești Tu, poruncește-mi să vin la Tine pe ape.

29Isus i-a zis:

– Vino!

Petru a coborât din barcă și a început să umble pe ape și să vină la Isus.

30Dar când a văzut vântul este puternic, i s-a făcut frică și, fiindcă începea să se scufunde, a strigat, zicând:

– Doamne, salvează-mă!

31Isus a întins imediat mâna, l-a apucat și i-a zis:

– Puțin credinciosule! De ce te-ai îndoit?

32După ce s-au urcat în barcă, vântul a încetat. 33Cei din barcă I s-au închinat, zicând: „Cu adevărat, Tu ești Fiul lui Dumnezeu!“

Isus vindecă bolnavii în Ghenezaret

(Mc. 6:53-56)

34După ce au trecut marea, au ajuns la țărm, în Ghenezaret. 35Când oamenii din locul acela L-au recunoscut pe Isus, au trimis vorbă în întreaga vecinătate și i-au adus astfel la El pe toți cei ce erau bolnavi. 36Îl rugau să-i lase doar să se atingă de marginea hainei Lui. Și toți care s-au atins au fost vindecați.