Matiu 1 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Matiu 1:1-25

Àkọsílẹ̀ ìwé ìran Jesu Kristi

1Ìwé ìran Jesu Kristi, ẹni tí í ṣe ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu:

2Abrahamu ni baba Isaaki;

Isaaki ni baba Jakọbu;

Jakọbu ni baba Juda àti àwọn arákùnrin rẹ̀,

3Juda ni baba Peresi àti Sera,

Tamari sì ni ìyá rẹ̀,

Peresi ni baba Hesroni:

Hesroni ni baba Ramu;

4Ramu ni baba Amminadabu;

Amminadabu ni baba Nahiṣoni;

Nahiṣoni ni baba Salmoni;

5Salmoni ni baba Boasi, Rahabu sí ni ìyá rẹ̀;

Boasi ni baba Obedi, Rutu sí ni ìyá rẹ̀;

Obedi sì ni baba Jese;

6Jese ni baba Dafidi ọba.

Dafidi ni baba Solomoni, ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ aya Uriah tẹ́lẹ̀ rí.

7Solomoni ni baba Rehoboamu,

Rehoboamu ni baba Abijah,

Abijah ni baba Asa,

8Asa ni baba Jehoṣafati;

Jehoṣafati ni baba Jehoramu;

Jehoramu ni baba Ussiah;

9Ussiah ni baba Jotamu;

Jotamu ni baba Ahaṣi;

Ahaṣi ni baba Hesekiah;

10Hesekiah ni baba Manase;

Manase ni baba Amoni;

Amoni ni baba Josiah;

111.11: 2Ọb 24.14; Jr 27.20.Josiah sì ni baba Jekoniah àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní àkókò ìkólọ sí Babeli.

12Lẹ́yìn ìkólọ sí Babeli:

Jekoniah ni baba Ṣealitieli;

Ṣealitieli ni baba Serubbabeli;

13Serubbabeli ni baba Abihudi;

Abihudi ni baba Eliakimu;

Eliakimu ni baba Asori;

14Asori ni baba Sadoku;

Sadoku ni baba Akimu;

Akimu ni baba Elihudi;

15Elihudi ni baba Eleasari;

Eleasari ni baba Mattani;

Mattani ni baba Jakọbu;

16Jakọbu ni baba Josẹfu, ẹni tí ń ṣe ọkọ Maria, ìyá Jesu, ẹni tí í ṣe Kristi.

17Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo wọ́n jẹ́ ìran mẹ́rìnlá láti orí Abrahamu dé orí Dafidi, ìran mẹ́rìnlá á láti orí Dafidi títí dé ìkólọ sí Babeli, àti ìran mẹ́rìnlá láti ìkólọ títí dé orí Kristi.

Ìtàn ibí Jesu Kristi

181.18: Lk 1.26-38.Bí a ṣe bí Jesu Kristi nìyí, ní àkókò ti àdéhùn ìgbéyàwó ti parí láàrín Maria ìyá rẹ̀ àti Josẹfu, ṣùgbọ́n kí wọn tó pàdé, a rí i ó lóyún láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́. 19Nítorí Josẹfu ọkọ rẹ̀ tí í ṣe olóòtítọ́ ènìyàn kò fẹ́ dójútì í ní gbangba, ó ní èrò láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.

20Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ro èrò yìí tán, angẹli Olúwa yọ sí i ní ojú àlá, ó wí pé, “Josẹfu, ọmọ Dafidi, má fòyà láti fi Maria ṣe aya rẹ, nítorí oyún tí ó wà nínú rẹ̀ láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ni. 211.21: Lk 2.21; Jh 1.29; Ap 13.23.Òun yóò sì bí ọmọkùnrin, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, nítorí òun ni yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

22Gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì ṣẹ láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ èyí tí a sọ láti ẹnu wòlíì rẹ̀ wá pé: 231.23: Isa 7.14.“Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli,” (èyí tí ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa”).

24Nígbà tí Josẹfu jí lójú oorun rẹ̀, òun ṣe gẹ́gẹ́ bí angẹli Olúwa ti pàṣẹ fún un. Ó mú Maria wá sílé rẹ̀ ní aya. 25Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ ọ́n títí tí ó fi bí ọmọkùnrin, òun sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Jesu.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

馬太福音 1:1-25

耶穌基督的家譜

1耶穌基督是亞伯拉罕的子孫、大衛的後裔,以下是祂的家譜:

2亞伯拉罕以撒

以撒雅各

雅各猶大和他的兄弟,

3猶大她瑪法勒斯謝拉

法勒斯希斯崙1·3 」希臘文是「亞蘭」。

希斯崙

4亞米拿達

亞米拿達拿順

拿順撒門

5撒門喇合波阿斯

波阿斯路得俄備得

俄備得耶西

6耶西大衛王。

大衛烏利亞的妻子生所羅門

7所羅門羅波安

羅波安亞比雅

亞比雅亞撒

8亞撒約沙法

約沙法約蘭

約蘭烏西雅

9烏西雅約坦

約坦亞哈斯

亞哈斯希西迦

10希西迦瑪拿西

瑪拿西亞們

亞們約西亞

11約西亞耶哥尼雅和他的兄弟,

那時以色列人被擄往巴比倫

12被擄到巴比倫以後,

耶哥尼雅撒拉鐵

撒拉鐵所羅巴伯

13所羅巴伯亞比玉

亞比玉以利亞敬

以利亞敬亞所

14亞所撒督

撒督亞金

亞金以律

15以律以利亞撒

以利亞撒馬但

馬但雅各

16雅各約瑟

約瑟就是瑪麗亞的丈夫,

那被稱為基督1·16 基督」意思是「受膏者」。的耶穌就是瑪麗亞生的。

17這樣,從亞伯拉罕大衛共有十四代,從大衛到被擄至巴比倫也是十四代,從被擄至巴比倫到基督降生也是十四代。

耶穌的降生

18以下是耶穌基督降生的經過。

耶穌的母親瑪麗亞約瑟訂了婚,還沒有成親就從聖靈懷了孕。 19約瑟是個義人,不願公開地羞辱她,便決定暗中和她解除婚約。 20他正在考慮這事的時候,主的一位天使在夢中向他顯現,說:「大衛的後裔約瑟,不要怕,把瑪麗亞娶過來,因為她所懷的孕是從聖靈來的。 21她將生一個兒子,你要給祂取名叫耶穌1·21 耶穌」意思是「救主」。,因為祂要把自己的子民從罪惡中救出來。」

22這一切應驗了主藉著先知所說的話: 23「必有童貞女懷孕生子,祂的名字要叫以馬內利,意思是『上帝與我們同在』。」 24約瑟醒來,就遵從主的天使的吩咐和瑪麗亞結婚, 25只是在她生下孩子之前沒有與她同房。約瑟給孩子取名叫耶穌。